Ẹ̀kọ́ 1
Bí O Ṣe Lè Mọ Ohun Tí Ọlọrun Ń Béèrè
Ìsọfúnni pàtàkì wo ni ó wà nínú Bibeli? (1)
Ta ni òǹṣèwé Bibeli? (2)
Èé ṣe tí o fi ní láti kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli? (3)
1. Bibeli jẹ́ ẹ̀bùn iyebíye kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun. Ó dà bíi lẹ́tà kan láti ọ̀dọ̀ bàbá onífẹ̀ẹ́ sí àwọn ọmọ rẹ̀. Ó sọ òtítọ́ nípa Ọlọrun—ẹni tí òún jẹ́ àti àwọn ìlànà rẹ̀—fún wa. Ó ṣàlàyé bí a ṣe lè kojú àwọn ìṣòro àti bí a ṣe lè rí ayọ̀ tòótọ́. Bibeli nìkan ṣoṣo ni ó sọ ohun tí a gbọ́dọ̀ ṣe láti mú inú Ọlọrun dùn, fún wa.—Orin Dafidi 1:1-3; Isaiah 48:17, 18.
2. Àwọn 40 ọkùnrin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ó kọ Bibeli, fún nǹkan bíi sáà 1,600 ọdún, bẹ̀rẹ̀ láti 1513 ṣáájú Sànmánì Tiwa. Ó jẹ́ àpapọ̀ ìwé kéékèèké 66. Ọlọrun ni ó mí sí àwọn tí ó kọ Bibeli. Èrò rẹ̀ ni wọ́n kọ sílẹ̀, kì í ṣe tiwọn. Nítorí náà, Ọlọrun lókè ọ̀run ni Òǹṣèwé Bibeli, kì í ṣe ènìyàn èyíkéyìí lórí ilẹ̀ ayé.—2 Timoteu 3:16, 17; 2 Peteru 1:20, 21.
3. Ọlọrun rí i dájú pé, a ṣe àdàkọ Bibeli, a sì pa á mọ́ ní pípé pérépéré. A ti tẹ ọ̀pọ̀ Bibeli jáde sí i ju ìwé èyíkéyìí mìíràn lọ. Kì í ṣe gbogbo ènìyàn ni yóò láyọ̀ láti rí i pé o ń kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí ìyẹ́n dá ọ dúró. Ọjọ́ ọ̀la rẹ ayérayé sinmi lórí mímọ Ọlọrun àti ṣíṣe ìfẹ́ rẹ̀, láìka àtakò èyíkéyìí sí.—Matteu 5:10-12; Johannu 17:3.