Lo Àǹfààní Aláìlẹ́gbẹ́ Yìí!
PETER ti tẹ̀ síwájú dáradára nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ nínú ìmọ̀ ìṣègùn nígbà tí ìhìn iṣẹ́ ìgbàlà ti Bíbélì gbà á lọ́kàn. Nígbà tí ó gboyè jáde, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi dókítà ní ilé ìwòsàn kan, àwọn ọ̀gá rẹ̀ fún un níṣìírí láìdábọ̀ pé kí ó di ògbóǹtagí oníṣẹ́ abẹ ọpọlọ. Àǹfààní kan tí ọ̀pọ̀ àwọn dókítà tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ kì yóò jẹ́ kí ó bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́ rárá nìyí.
Síbẹ̀, Petera pinnu láti má ṣe lo àǹfààní yìí. Èé ṣe? Ó ha jẹ́ pé kò ní ẹ̀mí ìlépa àṣeyọrí àti ìsúnniṣe tí a nílò ni bí? Rárá o, nítorí Peter ronú jinlẹ̀ lórí àǹfààní tí a nawọ́ rẹ̀ sí i náà ni. Lẹ́yìn tí ó di Ẹlẹ́rìí fún Jèhófà, tí ó ti ṣe ìyàsímímọ́, tí a sì ti batisí rẹ̀, ó fẹ́ láti lo àkókò púpọ̀ bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó nínú onírúurú apá iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni. Ó ronú pé, gbàrà tí òun bá ti tóótun gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́ abẹ ọpọlọ, iṣẹ́ òun yóò máa gba àkókò àti okun púpọ̀ sí i. Òun ha jẹ́ òmùgọ̀ láti yọ̀ọ̀da ìfojúsọ́nà títayọ lọ́lá yìí, àbí ó jẹ́ ọlọgbọ́n?
Lójú àwọn kan, ìpinnu Peter lè jọ ti òmùgọ̀. Ṣùgbọ́n, ó ronú lórí irú àwọn ẹsẹ Bíbélì bí Éfésù 5:15, 16. Níbẹ̀, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ máa ṣọ́ra láìgbagbẹ̀rẹ́ pé bí ẹ ṣe ń rìn kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n, ní ríra àkókò tí ó rọgbọ padà fún ara yín, nítorí pé àwọn ọjọ́ burú pin.”
Jọ̀wọ́ ṣàkíyèsí gbólóhùn náà “àkókò tí ó rọgbọ.” A túmọ̀ rẹ̀ láti inú ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí a lò nínú Bíbélì lọ́pọ̀ ìgbà láti tọ́ka sí àkókò tàbí sáà tí àwọn ohun kan pàtó sàmì sí tàbí tí ó yẹ wẹ́kú fún ìgbòkègbodò pàtó. Níhìn-ín, Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́ ọn pé, àwọn Kristẹni ní láti wá àkókò fún àwọn ọ̀ràn pàtàkì. Ní tòótọ́, wọ́n ní láti “wádìí dájú awọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.” (Fílípì 1:10) Ó jẹ́ ọ̀ràn títo àwọn ohun àkọ́múṣe lẹ́sẹẹsẹ.
Nígbà náà, bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ni ète Ọlọ́run fún àkókò wa? Kí ni ìfẹ́ inú Ọlọ́run fún àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀? Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì fi ọjọ́ wa hàn yàtọ̀ ní kedere gẹ́gẹ́ bí “ìgbà ìkẹyìn,” tàbí “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.” (Dáníẹ́lì 12:4; Tímótì Kejì 3:1) Kristi Jésù mú ohun tí yóò ṣe pàtàkì jù lọ ní ọjọ́ wa ṣe kedere. Ó sọ ní pàtó pé, ṣáájú òpin ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan búburú yìí, ‘a óò wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.’ Ìgbà náà gan-an ni òpin yóò tóó dé.—Mátíù 24:3, 14.
Nítorí náà, a ní láti lo gbogbo àǹfààní láti wàásù ìhìn rere Ìjọba náà, kí a sì sọni di ọmọ ẹ̀yìn. (Mátíù 28:19, 20) Níwọ̀n bí a kò ti ní tún àwọn ìgbòkègbodò wọ̀nyí ṣe mọ́ láé, àǹfààní ìkẹyìn nìyí láti sa gbogbo ipá wa nínú iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà yìí. “Nísinsìnyí ni àkókò ìtẹ́wọ́gbà ní pàtàkì.” Ní tòótọ́, “nísinsìnyí ni ọjọ́ ìgbàlà.”—Kọ́ríńtì Kejì 6:2.
Ṣíṣe Ìpinnu Tí Ó Bọ́gbọ́n Mu
Peter—ọ̀dọ́mọkùnrin tí a mẹ́nu kàn ní ìbẹ̀rẹ̀—ronú jinlẹ̀ lórí ìpinnu rẹ̀, ó sì gbé àwọn yíyàn rẹ̀ yẹ̀ wò. Ó rí i pé kì í ṣe ohun tí ó burú bí òún bá kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú èrò dídi oníṣẹ́ abẹ ọpọlọ. Ṣùgbọ́n kí ni ó ṣe pàtàkì jù lọ fún un? Ìgbòkègbodò rẹ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni ni, ní gbígbé ìjẹ́kánjúkánjú iṣẹ́ yìí yẹ̀ wò. Lọ́wọ́ kan náà, ó ní ojúṣe tí ó gbọ́dọ̀ ṣe. Ó ti gbéyàwó, ó sì ní láti ran aya rẹ̀ lọ́wọ́, ẹni tí ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù ní àkókò kíkún. (Tímótì Kìíní 5:8) Peter pẹ̀lú ní láti san gbèsè tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀ padà. Nígbà náà, kí ni ó pinnu láti ṣe?
Peter pinnu láti di ògbóǹtagí nínú ìmọ̀ fífi ìgbì ìmọ́lẹ̀ ṣèwòsàn, kí ó sì máa fi ìró ṣàyẹ̀wò àrùn. Èyí jẹ́ iṣẹ́ tí yóò gba kìkì iṣẹ́ ojúmọ́. Òun yóò sì gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lákòókò tí iṣẹ́ bá ń lọ lọ́wọ́. Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn kan lè rò pé èyí jẹ́ ipò kan tí kò yọrí ọlá tó bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n yóò fún un láyè láti yọ̀ọ̀da àkókò púpọ̀ sí i fún àwọn ìlépa tẹ̀mí.
Èrò míràn sún Peter láti ṣe ìpinnu. Níwọ̀n bí òun kò ti ṣèdájọ́ àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n ti lè pinnu láti ṣe ohun tí ó yàtọ̀, ó mọ̀ pé dídi ẹni tí ó tẹra bọ ọ̀ràn iṣẹ́ àmúṣe jù, léwu fún Kristẹni. Ó lè mú kí ó pa àwọn ẹrù iṣẹ́ rẹ̀ nípa tẹ̀mí tì. Àpẹẹrẹ mìíràn tí ó wé mọ́ ọ̀ràn iṣẹ́ ṣàpèjúwe èyí.
Oníwàásù kan tí ó jẹ́ alákòókò kíkún ti Ìjọba jẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ oníṣẹ́ ọnà. Ó ṣeé ṣe fún un láti ṣètìlẹ́yìn fún ara rẹ̀ ní ti ìnáwó nípa títa àwọn iṣẹ́ ọnà rẹ̀. Bí ó ti ń yọ̀ọ̀da èyí tí ó pọ̀ jù lọ nínú àkókò rẹ̀ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni tí ó ṣe pàtàkì jù lọ, ó lè tipa báyìí ṣètìlẹ́yìn fún ara rẹ̀ lọ́nà tí ó tẹ́ ẹ lọ́rùn. Ṣùgbọ́n, ìfẹ́ ọkàn láti tẹ̀ síwájú nínú iṣẹ́ ọnà rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í dàgbà. Ó wá tẹra bọ iṣẹ́ afọ̀dàdábírà àti iṣẹ́ ọnà, ó fi iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún sílẹ̀, nígbẹ̀yìngbẹ́yín ó di aláìṣiṣẹ́mọ́ ní ti ìgbòkègbodò ìwàásù Ìjọba náà. Nígbà tí ó yá, ó bẹ̀rẹ̀ sí í lọ́wọ́ nínú ìwà tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu, ní yíyọrí sí dídi ẹni tí kò jẹ́ apá kan ìjọ Kristẹni mọ́.—Kọ́ríńtì Kìíní 5:11-13.
Àkókò Wa Jẹ́ Àrà Ọ̀tọ̀
Gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ń ṣiṣẹ́ sin Jèhófà nísinsìnyí, dájúdájú a fẹ́ dúró gẹ́gẹ́ bí olùṣòtítọ́ sí i. A mọ̀ pé a ń gbé ní àkókò ṣíṣàrà ọ̀tọ̀ jù lọ nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn. Láti lè máa bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́ sin Ọlọ́run àti láti lè kojú àwọn àyíká ipò òde òní lọ́nà gbígbéṣẹ́, a lè ní láti ṣe onírúurú àtúnṣe. A lè fi èyí wé àkókò ìkórè fún àgbẹ̀ kan. Ìyẹn jẹ́ sáà ìgbòkègbodò àrà ọ̀tọ̀, nígbà tí a ń retí pé kí àwọn òṣìṣẹ́ oko làkàkà ju ti ìgbàkígbà rí lọ, kí wọ́n sì fi ọ̀pọ̀ ọjọ́ ṣiṣẹ́. Èé ṣe? Nítorí pé, a gbọ́dọ̀ kó irè náà jọ láàárín sáà kúkúrú.
Àkókò kúkúrú ni ó ṣẹ́ kù fún ètò ìgbékalẹ̀ búburú ti àwọn nǹkan ìsinsìnyí. Wàyí o, ju ti ìgbàkígbà rí lọ, Kristẹni tòótọ́ kan ní láti làkàkà láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, kí ó sì tẹ̀ lé ipasẹ̀ rẹ̀. Ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé fi ohun tí ó ṣe pàtàkì jù lọ fún un hàn ní kedere. Ó wí pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣe àwọn iṣẹ́ ẹni tí ó rán mi nígbà tí ó ṣì jẹ́ ọ̀sán; òru ń bọ̀ nígbà tí ènìyàn kankan kò lè ṣiṣẹ́.” (Jòhánù 9:4) Ní sísọ pé òru ń bọ̀, Jésù ń tọ́ka sí àkókò àdánwò rẹ̀, kíkàn án mọ́gi, àti ikú rẹ̀, nígbà tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé yóò dópin, tí òun kì yóò sì lè lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ Bàbá rẹ̀ ọ̀run.
Lóòótọ́, nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ rẹ̀, Jésù lo àkókò rẹ̀ ní ṣíṣe iṣẹ́ ìyanu àti wíwo àwọn aláìsàn sàn. Síbẹ̀síbẹ̀, ó lo èyí tí ó pọ̀ jù lọ nínú àkókò rẹ̀ láti wàásù ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà àti láti “wàásù ìtúsílẹ̀ fún àwọn òǹdè” ìsìn èké. (Lúùkù 4:18; Mátíù 4:17) Jésù lo ìsapá aláápọn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó sì lo àkókò láti dá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n baà lè tẹ̀ lé ìpìlẹ̀ tí òun ti fi lélẹ̀, kí wọ́n sì máa bá iṣẹ́ ìwàásù náà nìṣó lọ́nà gbígbéṣẹ́. Jésù lo gbogbo àǹfààní láti gbé ire Ìjọba lárugẹ, ó sì fẹ́ kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe ohun kan náà.—Mátíù 5:14-16; Jòhánù 8:12.
Bíi Jésù, àwa tí a jẹ́ ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lóde òní ní láti fi ojú kan náà tí Jèhófà Ọlọ́run fi ń wo ipò aráyé wò ó. Àkókò ń tán lọ fún ètò ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan yìí, pẹ̀lú àánú, Ọlọ́run fẹ́ kí gbogbogbòò ní àǹfààní láti jèrè ìgbàlà. (Pétérù Kejì 3:9) Nítorí náà, kò ha ní dára láti fi gbogbo ìlépa mìíràn sí ipò kejì láti baà lè ṣe ìfẹ́ inú Jèhófà bí? (Mátíù 6:25-33) Ní pàtàkì, ní àkókò àrà ọ̀tọ̀ bí irú èyí, ohun tí àwọn ènìyàn lè kà sí ohun pàtàkì lè má ṣe pàtàkì nínú ìgbésí ayé wa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni.
Ẹnikẹ́ni nínú wa yóò ha kábàámọ̀ fífi ìfẹ́ inú Ọlọ́run sí ipò kíní nínú ìgbésí ayé wa bí? Ó dájú pé bẹ́ẹ̀ kọ́, nítorí pé ipa ọ̀nà Kristẹni ti ìfara-ẹni-rúbọ jẹ́ elérè ẹ̀san lọ́nà àgbàyanu. Fún àpẹẹrẹ, Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ní òótọ́ ni mo wí fún yín, Kò sí ẹnì kan tí ó fi ilé sílẹ̀ tàbí àwọn arákùnrin tàbí àwọn arábìnrin tàbí ìyá tàbí bàbá tàbí àwọn ọmọ tàbí àwọn pápá nítorí mi àti nítorí ìhìn rere tí kì yóò gba ìlọ́po ọgọ́rùn-ún nísinsìnyí ní sáà àkókò yìí, àwọn ilé àti àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin àti àwọn ìyá àti àwọn ọmọ àti àwọn pápá, pẹ̀lú àwọn inúnibíni, àti nínú ètò-ìgbékalẹ̀ àwọn nǹkan tí ń bọ̀ ìyè àìnípẹ̀kun.”—Máàkù 10:29, 30.
Kò sí ẹni tí ó lè fi owó díwọ̀n èrè tí àwọn tí wọ́n ń lo àkókò wọn láti yín Jèhófà àti láti pòkìkí ìhìn iṣẹ́ Ìjọba náà ń gbádùn. Wọ́n ń gbádùn ìbùkún púpọ̀ rẹpẹtẹ! Èyí ní nínú àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́, ìtẹ́lọ́rùn ṣíṣe ìfẹ́ inú Ọlọ́run, ẹ̀rín músẹ́ Ọlọ́run tí ó fi ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀ hàn, àti ìfojúsọ́nà fún ìyè àìlópin. (Ìṣípayá 21:3, 4) Ẹ sì wo irú ìbùkún tí ó jẹ́ láti ran àwọn ènìyàn lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí àti láti mú ọlá wá fún orúkọ mímọ́ Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí rẹ̀! Láìsí àní àní, ní tòótọ́, “ríra àkókò tí ó rọgbọ padà” jẹ́ ipa ọ̀nà ọlọgbọ́n àti èyí tí ó ní èrè. Wàyí o, ju ti ìgbàkígbà rí lọ, àkókò náà nìyí láti nípìn-ín nínú pípolongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Ìwọ yóò ha lo àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ yìí, kí o sì dì í mú ṣinṣin bí?
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Orúkọ àfidípò.