Gbogbo Wa Ni A Nílò fún Píparí Iṣẹ́ Náà
1 Gbogbo ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi ní láti mọ̀ pé ìsapá òun láti kọ́wọ́ ti iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà àti kíkópa nínú rẹ̀ ṣe pàtàkì gidigidi. Jésù mọ̀ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun yóò mú èso Ìjọba jáde ní ìwọ̀n tí ó yàtọ̀ síra. (Mát. 13:23) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé apá tí ó pọ̀ jù nínú ìgbòkègbodò ìwàásù ni ọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú ọ̀nà tí ń ṣiṣẹ́ kára ń ṣe, ó yẹ kí a gbóríyìn fún gbogbo àwọn tí ń fi ìháragàgà bá a nìṣó láti máa fi ògo fún Ọlọ́run nípa síso èso púpọ̀ bí ó bá ti lè ṣeé ṣe tó.—Jòh. 15:8.
2 Ìjùmọ̀sapá Ń Ṣàṣeparí Ohun Púpọ̀: Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé ìsapá gbogbo àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lápapọ̀ yóò mú kí wọ́n ṣe iṣẹ́ tí ó ju tòun. (Jòh. 14:12) Yálà àwọn àyíká ipò wa kò jẹ́ kí a lè ṣe púpọ̀ tàbí ó jẹ́ kí a lè ya àkókò tí ó pọ̀ sọ́tọ̀ fún wíwàásù Ìjọba náà, gbogbo wa ni a nílò fún píparí iṣẹ́ náà. Ó rí gan-an gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ti sọ pé: “Gbogbo ara náà, nípa síso wọ́n pọ̀ ní ìṣọ̀kan àti mímú kí wọ́n fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nípasẹ̀ gbogbo oríkèé tí ń pèsè ohun tí a nílò, ní ìbámu pẹ̀lú ìṣiṣẹ́ olúkúlùkù ẹ̀yà ara kọ̀ọ̀kan ní ìwọ̀n yíyẹ, ń mú kí ara náà dàgbà.”—Éfé. 4:16.
3 Àwọn kan lè ronú pé ìsapá àwọn kò já mọ́ nǹkan kan. Ṣùgbọ́n, ohun tí ó ṣe pàtàkì lójú Jèhófà ni pé kí iṣẹ́ ìsìn wa jẹ́ èyí tí a fi gbogbo ọkàn ṣe. Gbogbo ohun tí a bá ṣe fún un ṣeyebíye, ó sì mọrírì rẹ̀.—Fi wé Lúùkù 21:1-4.
4 Máa Kọ́wọ́ Ti Iṣẹ́ Náà Nìṣó: Gbogbo wa ni a ní àǹfààní láti fi ohun ti ara ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ náà tí a ń ṣe kárí ayé. Àwọn kan tún lè ṣètìlẹyìn fún iṣẹ́ Ìjọba náà nípa ṣíṣe òpò tí iṣẹ́ náà ń béèrè. Ẹnì kọ̀ọ̀kan lè sakun láti pèsè ìdáhùn tí ó múra sílẹ̀ dáadáa ní àwọn ìpàdé, kí ó sì kópa nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run. Nípa lílo àǹfààní àwọn àkókò tí a ní láti fún àwọn ẹlòmíràn níṣìírí, a ń ṣètìlẹyìn tí ó wúlò gidigidi fún ipò tẹ̀mí ìjọ, èyí yóò sì mú kí ìjọ túbọ̀ tóótun láti ṣàṣeparí iṣẹ́ tí a fi síkàáwọ́ rẹ̀.
5 Ní tòótọ́, gbogbo wa ni a nílò fún píparí iṣẹ́ náà. Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó yẹ kí ó rò pé a kò nílò òun. Ìsapá wa lápapọ̀ ní sísin Jèhófà, yálà ó pọ̀ tàbí ó kéré, ń yà wá sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn kan ṣoṣo tí ń jọ́sìn Ọlọ́run ní tòótọ́. (Mál. 3:18) Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè kópa lọ́nà tí ó jọjú nínú bíbọlá fún Jèhófà àti ní ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti mọ̀ ọ́n, kí wọ́n sì máa sìn ín.