Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún June
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní June 1
Orin 223
8 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Ìròyìn Ìṣàkóso Ọlọ́run.
15 min: “Tí A Mú Gbára Dì Pátápátá fún Iṣẹ́ Rere Gbogbo.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ṣàlàyé ṣókí lórí Ilé-Ìṣọ́nà ti February 15, 1989, ojú ìwé 22 sí 24.
22 min: “Jíjẹ́rìí fún ‘Gbogbo Onírúurú Ènìyàn.’” Alàgbà ṣàlàyé pé ìwé tí a óò fi lọni ní June jẹ́ àwọn ìwé olójú ewé 192 tí a yàn, àti àdìpọ̀ oríṣi ìwé méjì tàbí mẹ́rin ní ẹ̀dínwó. Alàgbà kan àti àwọn akéde mélòó kan tí wọ́n jẹ́ onírìírí jọ jíròrò àwọn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí a dábàá. Ṣàlàyé ìdí tí ó fi yẹ kí a ní àwọn kókó mélòó kan lọ́kàn láti fi bẹ̀rẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ ní gbogbo ìgbà. Ṣàṣefihàn ṣókí kan tàbí méjì.
Orin 112 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní June 8
Orin 209
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò.
15 min: “Bíbójútó Àwọn Nǹkan Ìní Ọ̀gá Náà.” Ọ̀rọ̀ àsọyé láti ẹnu alàgbà, kí ó kárí ìsọfúnni tí ó wà nínú àkìbọnú.
20 min: “Gbogbo Wa Ni A Nílò fún Píparí Iṣẹ́ Náà.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ṣàlàyé ìdí tí àwọn alàgbà fi ń gbára lé ọ̀pọ̀ àwọn tí ó fi tinútinú yọ̀ǹda ara wọn láti ṣe àwọn nǹkan pípọndandan. Ṣàyẹ̀wò àwọn àìní àdúgbò, irú bí ìmọ́tótó àti àbójútó Gbọ̀ngàn Ìjọba, ríran àwọn aláìsàn àti àgbàlagbà lọ́wọ́, àti kíkárí ìpínlẹ̀. Ké sí àwọn alàgbà láti ṣàlàyé lórí bí wọ́n ṣe mọrírì ìtìlẹyìn tí ọ̀pọ̀ àwọn akéde ń fi tinútinú ṣe. Tẹnu mọ́ bí a ṣe nílò ìsapá ẹnì kọ̀ọ̀kan tó.
Orin 153 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní June 15
Orin 7
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó.
20 min: “Ẹ Fi Tokuntokun Lo Ara Yin Dé Gongo.” Ọ̀rọ̀ àsọyé tí a gbé karí Ilé-ìṣọ́nà ti May 15, 1986, ojú ìwé 10 sí 14. Jíròrò ìjẹ́pàtàkì iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà déédéé, kí o sì fún àwọn ará níṣìírí láti forúkọ sílẹ̀ ní September 1.
15 min: “Fífi Ìwà Rere Jẹ́rìí.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fi ọ̀rọ̀ wá àwọn ọ̀dọ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ mélòó kan lẹ́nu wò. Kí wọ́n sọ nípa bí ìwà rere Kristẹni wọn ṣe nípa lórí àwọn ẹlòmíràn lọ́nà rere. Sọ ìrírí kan tàbí méjì láti inú Ilé-Ìṣọ́nà ti January 1, 1995, ojú ìwé 24 àti 25.
Orin 170 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní June 22
Orin 61
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Sọ ìgbà tí ẹ parí ṣíṣe àyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ.
15 min: Bí A Ṣe Ń Bẹ̀rẹ̀ Ipa Ọ̀nà Ìwé Ìròyìn. Ṣàlàyé ohun tí a nílò: kọ gbogbo ìwé tí o fi sóde sílẹ̀, padà lọ láàárín ọ̀sẹ̀ méjì, jíròrò àwọn kókó tuntun láti inú àwọn ìwé ìròyìn ti lọ́ọ́lọ́ọ́, kí ẹni náà lè máa bá a lọ láti nífẹ̀ẹ́ sí i. Dábàá pé kí àwọn aládùúgbò, alájọṣiṣẹ́, akọ̀wé ilé ìtajà, àwọn tí ń tepo ọkọ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ wà lára ipa ọ̀nà ìwé ìròyìn wa. Fi àsansílẹ̀ owó olóṣù mẹ́fà lọ àwọn tí wọ́n ṣì ń nífẹ̀ẹ́ sí i. Ké sí akéde kan tàbí méjì láti sọ ìrírí tí ń gbéni ró nípa ipa ọ̀nà ìwé ìròyìn.
20 min: Àwọn Aṣáájú Ọ̀nà Ń Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́. Ọ̀rọ̀ àsọyé láti ẹnu alábòójútó iṣẹ́ ìsìn, kí ó ṣàtúnyẹ̀wò ìṣètò láti jẹ́ kí àwọn aṣáájú ọ̀nà fúnra wọn ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́. Ṣàlàyé bí a ṣe bẹ̀rẹ̀ irú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìtìlẹyìn bẹ́ẹ̀ sẹ́yìn. ( jv-E 100; km-E 9/79 1, 3) Iye àwọn ẹni tuntun tí ó ju mílíọ̀nù kan tí ó ṣe batisí ní ọdún mẹ́ta sẹ́yìn nílò ìdálẹ́kọ̀ọ́. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ “Àwọn Aṣáájú Ọ̀nà Ń Ran Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́wọ́” yìí ń ṣàmúlò ìrírí àti ìdálẹ́kọ̀ọ́ àwọn aṣáájú ọ̀nà déédéé àti àwọn aṣáájú ọ̀nà àkànṣe tí ó ti lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú Ọ̀nà. Ète rẹ̀ ni pé kí aṣáájú ọ̀nà kọ̀ọ̀kan ran akéde méjì lọ́wọ́ lọ́dún, kí wọ́n lè túbọ̀ jáfáfá sí i nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, kí wọ́n sì nàgà láti túbọ̀ nípìn-ín tí ó pọ̀ sí i. Kò sí ìdí tí ó fi yẹ kí èyí dààmú àwọn tí a ń ràn lọ́wọ́; ohun tí a fẹ́ tẹnu mọ́ ni fífi ìfẹ́ àti inú rere fúnni níṣìírí. Ètò tuntun yìí yóò mú kí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn púpọ̀ sí i túbọ̀ di òjíṣẹ́ tí ó jáfáfá.
Orin 207 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní June 29
Orin 114
10 min: Àwọn ìfilọ̀. Rán gbogbo ará létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá ti oṣù June sílẹ̀. Jíròrò ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní July.
15 min: Àwọn àìní àdúgbò tàbí Ìrẹ̀wẹ̀sì Ha Ti Bá Mi Bí? Ọ̀rọ̀ àsọyé láti ẹnu alàgbà tí a gbé ka Ilé-ìṣọ́nà ti December 15, 1987, ojú ìwé 18 àti 19, ìpínrọ̀ 14 sí 16. Fún àwọn tí wọ́n ti jẹ́ aláápọn fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún níṣìírí láti ronú nípa bí iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ wọn ṣe jẹ́ ojúlówó tó àti bí ó ṣe pọ̀ tó.
20 min: Gbogbo Wa Ni A Lè Jẹ́rìí Lọ́nà Tí Kì Í Ṣe Bí Àṣà. Ọ̀rọ̀ àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tí a gbé ka Ilé-ìṣọ́nà ti October 15, 1987, ojú ìwé 22 sí 27. Fi hàn bí àwọn tí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, ìdílé, tàbí àwọn tí ẹrù iṣẹ́ ti ara wọn gba àkókò wọn ṣe lè rí ọ̀pọ̀ àǹfààní láti ṣàjọpín ìhìn rere náà pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn lójoojúmọ́. Fi àwọn ìrírí àdúgbò mélòó kan kún un.
Orin 76 àti àdúrà ìparí.