Ìròyìn Ìṣàkóso Ọlọ́run
◼ Ọ̀pọ̀ ẹ̀ka tí ó wà ní erékùṣù yí ká ayé ròyìn góńgó títayọ tuntun nínú àwọn akéde ní January. Díẹ̀ lára wọn ni Dominican Republic, Haiti, Martinique, Mauritius, Philippines, Taiwan, àti Trinidad.
◼ Ìbísí ti Seychelles fi ìpín 18 nínú ọgọ́rùn-ún ju ti ìpíndọ́gba ọdún tí ó kọjá, ìbísí ti St. Maarten sì jẹ́ ìpín 16 nínú ọgọ́rùn-ún.
◼ Ní Hong Kong, àwọn akéde ní ìpíndọ́gba 12.7 wákàtí.
◼ Gbọ̀ngàn Ìjọba àkọ́kọ́ ní Taiwan tí a yára kọ́ ni a parí ní February.