ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w97 6/15 ojú ìwé 4-8
  • Báwo ni Ọlọ́run Ṣe Mí Sí Bíbélì?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Báwo ni Ọlọ́run Ṣe Mí Sí Bíbélì?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ó Béèrè fún Ìsapá Àfìṣọ́raṣe
  • Ìmọ̀ràn Tí Ó Ṣeé Mú Lò—Láti Ọ̀dọ̀ Ta Ni?
  • Ẹ̀dá Ènìyàn Ni Ó Kọ Ọ́—Èé Ṣe?
  • Ta Ni Òǹṣèwé Bíbélì?
    Jí!—2008
  • ‘Ẹ̀mí Mímọ́ Darí Wọn’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Ọgbọ́n Wà Nínú “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run”
    Sún Mọ́ Jèhófà
  • Ṣé Lóòótọ́ Ni “Ọlọ́run Mí Sí” Bíbélì?
    Jí!—2017
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
w97 6/15 ojú ìwé 4-8

Báwo ni Ọlọ́run Ṣe Mí Sí Bíbélì?

Ì BÁNISỌ̀RỌ̀ túbọ̀ fani mọ́ra lónìí ju ti ìgbàkígbà rí lọ nínú ọ̀rọ̀ ìtàn. Tẹlifóònù, ẹ̀rọ aṣàdàkọ ìsọfúnni, kọ̀ǹpútà—ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn ta ní lè rò pé àkókò kan yóò dé nígbà tí a óò fẹ́rẹ̀ẹ́ lè máa fi ìhìn iṣẹ́ ránṣẹ́ sí ibikíbi lágbàáyé lẹ́yẹ ò ṣọkà.

Ṣùgbọ́n ìbánisọ̀rọ̀ kan tí ó runi lọ́kàn sókè jù lọ ni èyí tí ó rú ènìyàn lójú—ìmísí àtọ̀runwá. Jèhófà mí sí nǹkan bí 40 òǹkọ̀wé tí wọ́n jẹ́ ẹ̀dá ènìyàn láti mú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí wọ́n kọ sílẹ̀ jáde, Bíbélì Mímọ́. Gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn ti ní ju ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ kan ṣoṣo lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni Jèhófà lo onírúurú ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ láti mí sí Ìwé Mímọ́.

Àpèkọ. Ọlọ́run sọ àwọn ìhìn iṣẹ́ pàtó kan jáde tí a wá kọ sínú Bíbélì lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.a Fún àpẹẹrẹ, gbé àwọn àṣẹ tí ó para pọ di májẹ̀mú Òfin yẹ̀ wò. Jèhófà wí fún Mósè pé: “Ìwọ kọ̀wé ọ̀rọ̀ wọ̀nyí: nítorí nípa ìmọ̀ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni èmi bá ìwọ àti Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú.” (Ẹ́kísódù 34:27) Mósè kọ ‘àwọn ọ̀rọ̀’ wọ̀nyẹn, tí ‘a ta látaré nípasẹ̀ àwọn áńgẹ́lì,’ a sì lè rí i nísinsìnyí nínú ìwé Ẹ́kísódù, Léfítíkù, Númérì, àti Diutarónómì, nínú Bíbélì.—Ìṣe 7:53.

Ọ̀pọ̀ àwọn wòlíì míràn, títí kan Aísáyà, Jeremáyà, Ìsíkẹ́ẹ̀lì, Ámósì, Náhúmù, àti Míkà, gba ìhìn iṣẹ́ pàtó láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ àwọn áńgẹ́lì. Nígbà míràn àwọn ọkùnrin wọ̀nyí máa ń bẹ̀rẹ̀ ìkéde wọn pẹ̀lú àpólà ọ̀rọ̀ náà: “Báyìí ni Olúwa wí.” (Aísáyà 37:6; Jeremáyà 2:2; Ìsíkẹ́ẹ̀lì 11:5; Ámósì 1:3; Míkà 2:3; Náhúmù 1:12) Lẹ́yìn náà, wọ́n ń kọ ohun tí Ọlọ́run sọ sílẹ̀.

Ìran, Àlá, àti Ojúran. Ìran jẹ́ èrò, ìṣẹ̀lẹ̀, tàbí ìhìn iṣẹ́ tí a fi sí ẹnì kan lọ́kàn nígbà tí ojú rẹ̀ dá, lọ́pọ̀ ìgbà nípasẹ̀ àwọn ọ̀nà àrà. Fún àpẹẹrẹ, Pétérù, Jákọ́bù, àti Jòhánù, “nígbà tí ojú wọ́n dá,” rí ìran Jésù tí a yí pa dà di ológo. (Lúùkù 9:28-36; Pétérù Kejì 1:16-21) Nínú àwọn ọ̀ràn kan, a fi ìhìn iṣẹ́ ránṣẹ́ nínú àlá, tàbí ìran òru, tí a fi sí ẹnì kan lọ́kàn nígbà tí onítọ̀hún ń sùn, tí kò sì mọra mọ́. Nípa báyìí, Dáníẹ́lì kọ̀wé nípa “ìran orí mi lórí àkéte mi”—tàbí, gẹ́gẹ́ bí atúmọ̀ èdè náà, Ronald A. Knox, ti túmọ̀ rẹ̀, “bí mo ṣe dùbúlẹ̀ tí mo ń wòye nínú àlá mi.”—Dáníẹ́lì 4:10.

Ó dájú pé ẹnì kan tí Jèhófà fi sínú ojúran ti wà ní ipò ìpọkànpọ̀ pátápátá, bí kò tilẹ̀ sùn wọra. (Fi wé Ìṣe 10:9-16.) Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, tí a tú sí “ojúran” (ekʹsta·sis) túmọ̀ sí ‘gbígbé nǹkan kúrò tàbí mímú nǹkan kúrò ní àyè rẹ̀ gan-an.’ Ó ní èrò mímú èrò inú wa kúrò ní àyè rẹ̀ gan-an. Nípa báyìí, ẹnì kan tí ó wà ní ojúran kì í mọ ohun tí ń lọ ní àyíká rẹ̀ mọ́ bí ó ti ń gba ìran náà. Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ irú ojúran bẹ́ẹ̀ ní àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wà nígbà tí “a gbà á lọ sínú párádísè [tí] ó sì gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tí a kò lè fẹnu sọ èyí tí kò bófin mu fún ènìyàn láti sọ.”—Kọ́ríńtì Kejì 12:2-4.

Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí àwọn tí wọ́n ṣàkọsílẹ̀ ìhìn iṣẹ́ tí Ọlọ́run pè fún wọn, àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì tí wọ́n rí ìran tàbí tí wọ́n lá àlá tàbí tí wọ́n wà ní ojúran sábà máa ń ní òmìnira díẹ̀ láti ṣàpèjúwe ohun tí wọ́n rí ní ọ̀rọ̀ ara wọn. A sọ fún Hábákúkù pé: “Kọ ìran náà, kí o sì hàn án lára wàláà, kí ẹni tí ń kà á, lè máa sáré.”—Hábákúkù 2:2.

Èyí ha túmọ̀ sí pé àwọn apá wọ̀nyí nínú Bíbélì kò ní ìmísí tó àwọn apá tí a pè kọ bí? Rárá o. Nípasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀, Jèhófà fi ìhìn iṣẹ́ rẹ̀ sínú ọkàn òǹkọ̀wé kọ̀ọ̀kan dáadáa, tí ó fi jẹ́ pé èrò Ọlọ́run ni ó gbé jáde kì í ṣe èrò ènìyàn. Bí Jèhófà tilẹ̀ fàyè gba òǹkọ̀wé náà láti yan àwọn ọ̀rọ̀ yíyẹ, ó darí èrò inú àti ọkàn àyà òǹkọ̀wé náà tí ó fi jẹ́ pé ojú rẹ̀ kò fo ìsọfúnni pàtàkì kankan, a sì fi ojú tí ó yẹ wo ọ̀rọ̀ náà nígbẹ̀yìngbẹ́yín, pé ó jẹ́ ti Ọlọ́run.—Tẹsalóníkà Kíní 2:13.

Ìṣípayá Àtọ̀runwá. Bíbélì ní àsọtẹ́lẹ̀ nínú—ọ̀rọ̀ ìtàn tí a ṣí payá, tí a sì kọ ṣáájú àkókò—tí ó ré kọjá agbára ẹ̀dá ènìyàn lásán. Àpẹẹrẹ kan ni ìdìde àti ìṣubú “ọba Hélénì” náà, Alẹkisáńdà Ńlá, tí a sọ tẹ́lẹ̀ ní nǹkan bí 200 ọdún ṣáájú! (Dáníẹ́lì 8:1-8, 20-22) Bíbélì tún ṣí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ẹ̀dá ènìyàn kò fojú rí payá. Àpẹẹrẹ kan ni dídá ọ̀run òun ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 1:1-27; 2:7, 8) Òmíràn sì tún ni, àwọn ìjíròrò tí ó ṣẹlẹ̀ ní ọ̀run, irú èyí tí a kọ sínú ìwé Jóòbù.—Jóòbù 1:6-12; 2:1-6.

Bí Ọlọ́run kò bá ṣí i payá ní tààràtà fún òǹkọ̀wé náà, yóò jẹ́ wí pé Ọlọ́run sọ ọ́ di mímọ̀ fún ẹnì kan, kí ìwọ̀nyí baà lè di apá kan ọ̀rọ̀ ìtàn àtẹnudẹ́nu tàbí alákọsílẹ̀, tí a tàtaré láti ìran kan sí òmíràn títí tí wọ́n fi di apá kan àkọsílẹ̀ Bíbélì. (Wo àpótí tí ó wà ní ojú ìwé 7.) Bí ó ti wù kí ó rí, a lè mọ̀ dájú pé, Jèhófà ni Orísun gbogbo irú ìsọfúnni bẹ́ẹ̀, ó sì darí àwọn òǹkọ̀wé rẹ̀ kí àkọsílẹ̀ wọn má baà di èyí tí àìpéye, àsọdùn, tàbí àròsọ kó àbààwọ́n bá. Pétérù kọ̀wé nípa àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí ẹ̀mí mímọ́ ti ń darí wọn.”b—Pétérù Kejì 1:21.

Ó Béèrè fún Ìsapá Àfìṣọ́raṣe

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé “ẹ̀mí mímọ́ ti ń darí” àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì, síbẹ̀síbẹ̀ ó ṣì béèrè pé kí wọ́n ronú jinlẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, Sólómọ́nì “ṣe àkíyèsí dáradára, ó sì wádìí, ó sì fi òwe púpọ̀ lélẹ̀ ní ẹsẹẹsẹ. [Ó] wádìí àtirí ọ̀rọ̀ dídùn èyí tí a sì kọ, ohun ìdúróṣinṣin ni, àní ọ̀rọ̀ òtítọ́.”—Oníwàásù 12:9, 10.

Àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì kan ní láti ṣèwádìí púpọ̀ láti lè kọ àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ wọn sílẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, Lúùkù kọ̀wé nípa àkọsílẹ̀ Ìhìn Rere rẹ̀ pé: “Mo ti tọpasẹ̀ ohun gbogbo láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìpéye, láti kọ̀wé wọn sí ọ ní ìṣètò tí ó bọ́gbọ́n mu.” Dájúdájú, ẹ̀mí Ọlọ́run bù kún ìsapá Lúùkù, ó sì dájú pé ó sún un láti ṣàwárí àwọn àkọsílẹ̀ ọ̀rọ̀ ìtàn tí ó ṣeé gbára lé àti láti fọ̀rọ̀ wá àwọn ẹlẹ́rìí tí wọ́n ṣeé gbára lé lẹ́nu wò, irú bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí wọ́n ṣì wà láàyè tí ó ṣeé ṣe kí Màríà, ìyá Jésù, pàápàá wà lára wọn. Lẹ́yìn náà, ẹ̀mí Ọlọ́run yóò darí Lúùkù láti kọ ìsọfúnni náà sílẹ̀ lọ́nà tí ó péye.—Lúùkù 1:1-4.

Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí Ìhìn Rere Lúùkù, àkọsílẹ̀ Jòhánù jẹ́ èyí tí ó fojú ara rẹ̀ rí, tí ó kọ ní nǹkan bí 65 ọdún lẹ́yìn tí Jésù kú. Kò sí àní-àní pé ẹ̀mí Jèhófà mú kí ọpọlọ Jòhánù jí pépé kí ọ̀pọ̀ àkókò tí ó ti kọjá má baà jẹ́ kí ó gbàgbé. Èyí yóò bá ohun tí Jésù ṣèlérí fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mu pé: “Olùrànlọ́wọ́ náà, ẹ̀mí mímọ́, èyí tí Bàbá yóò rán ní orúkọ mi, èyíinì ni yóò kọ́ yín ní ohun gbogbo tí yóò sì mú gbogbo àwọn ohun tí mo ti sọ fún yín pa dà wá sí ìrántí yín.”—Jòhánù 14:26.

Nínú àwọn ọ̀ràn kan, àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì fi àkọsílẹ̀ àwọn tí ọ̀ràn ṣojú wọn tí wọ́n jẹ́ òǹkọ̀wé ọ̀rọ̀ ìtàn àtijọ́ kún tiwọn, kì í sì í ṣe gbogbo àwọn òǹkọ̀wé ọ̀rọ̀ ìtàn àtijọ́ wọ̀nyí ni a mí sí. Jeremáyà ṣàkójọ Àwọn Ọba Kìíní àti Ìkejì lọ́nà yí. (Àwọn Ọba Kejì 1:18) Ẹ́sírà tọ́ka sí ó kéré tán orísun ìsọfúnni 14 tí a kò mí sí láti ṣàkójọ ọ̀rọ̀ inú Kíróníkà Kíní àti Ìkejì, títí kan “ìwé Kíróníkà ti Dáfídì ọba” àti “ìwé àwọn ọba Júdà àti Ísírẹ́lì.” (Kíróníkà Kíní 27:24; Kíróníkà Kejì 16:11) Mósè tilẹ̀ ṣàyọlò “ìwé Ogun OLÚWA”—tí ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ àkọsílẹ̀ tí ó ṣeé gbára lé nípa ogun tí àwọn ènìyàn Ọlọ́run ti jà.—Númérì 21:14, 15.

Nínú irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ kó ipa pàtàkì ní sísún àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì láti yan kìkì àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí ó ṣeé gbára lé, tí ó sì wá di apá kan àkọsílẹ̀ Bíbélì tí a mí sí.

Ìmọ̀ràn Tí Ó Ṣeé Mú Lò—Láti Ọ̀dọ̀ Ta Ni?

Bíbélì ní ọ̀pọ̀ ìmọ̀ràn tí ó ṣeé mú lò tí a gbé karí àwọn àyẹ̀wò ara ẹni tí ó gbéṣẹ́. Fún àpẹẹrẹ, Sólómọ́nì kọ̀wé pé: “Kò sí ohun tí ó dára fún ènìyàn ju kí ó jẹ, kí ó sì mu àti kí ó mú ọkàn rẹ̀ jadùn ohun rere nínú làálàá rẹ̀. Èyí ni mo rí pẹ̀lú pé, láti ọwọ́ Ọlọ́run wá ni.” (Oníwàásù 2:24) Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé, ìmọ̀ràn òun nípa ìgbéyàwó jẹ́ ‘gẹ́gẹ́ bí èrò òun’ bí ó tilẹ̀ fi kún un pé: “Dájúdájú mo rò pé èmi pẹ̀lú ní ẹ̀mí Ọlọ́run.” (Kọ́ríńtì Kíní 7:25, 39, 40) Dájúdájú Pọ́ọ̀lù ní ẹ̀mí Ọlọ́run, nítorí gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pétérù ti sọ, ohun tí Pọ́ọ̀lù kọ sílẹ̀ wà “ní ìbámu pẹ̀lú ọgbọ́n tí a fi fún un.” (Pétérù Kejì 3:15, 16) Nípa báyìí, bí ẹ̀mí Ọlọ́run ti darí rẹ̀, ó sọ èrò rẹ̀ jáde.

Nígbà tí àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì bá sọ irú ìdálójú ara ẹni bẹ́ẹ̀ jáde, wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ láti inú ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti kọ́ nínú Ìwé Mímọ́ tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó wọn àti bí wọ́n ṣe lò ó. A lè ní ìdálójú pé, àkọsílẹ̀ wọn wà ní ìbámu pẹ̀lú èrò Ọlọ́run. Ohun tí wọ́n kọ sílẹ̀ di apá kan Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

Àmọ́ ṣáá o, Bíbélì ní ọ̀rọ̀ àwọn kan tí èrò wọn lòdì. (Fi Jóòbù 15:15 wé 42:7.) Ó tún ní àwọn ọ̀rọ̀ díẹ̀ tí ó sọ ìmọ̀lára tí làásìgbò tí ó dé bá àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run mú wá jáde, bí irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ kò tilẹ̀ gbé bí ọ̀ràn náà ṣe rí gan-an jáde.c Bí ó tilẹ̀ ń sọ irú gbólóhùn ara ẹni bẹ́ẹ̀ jáde, ẹ̀mí Ọlọ́run ni ó ṣì ń darí òǹkọ̀wé náà láti kọ àkọsílẹ̀ tí ó péye, tí ó ṣèrànwọ́ láti dá èrò òdì mọ̀ àti láti ṣí i payá. Ní àfikún sí i, nínú ọ̀ràn kọ̀ọ̀kan, àyíká ọ̀rọ̀ ń mú un ṣe kedere sí òǹkàwé onílàákàyè kan láti mọ̀ bí èrò òǹkọ̀wé náà bá lẹ́sẹ̀ nílẹ̀.

Lákòótán, a lè ní ìgbọ́kànlé pé Bíbélì látòkè délẹ̀ jẹ́ ìhìn iṣẹ́ Ọlọ́run. Ní tòótọ́, Jèhófà rí i dájú pé, gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀ jẹ́ ète òun, ó sì pèsè ìtọ́ni ṣíṣe kókó fún àwọn tí wọ́n fẹ́ láti ṣiṣẹ́ sìn ín.—Róòmù 15:4.

Ẹ̀dá Ènìyàn Ni Ó Kọ Ọ́—Èé Ṣe?

Lílò tí Jèhófà lo àwọn ẹ̀dá ènìyàn láti kọ Bíbélì fi ọgbọ́n ńlá rẹ̀ hàn. Gbé èyí yẹ̀ wò: Bí Ọlọ́run bá fi ọ̀ràn náà lé àwọn áńgẹ́lì lọ́wọ́, Bíbélì yóò ha fani mọ́ra bí ó ṣe fani mọ́ra lónìí bí? Òtítọ́ ni pé, yóò dùn mọ́ wa láti kà nípa àwọn ànímọ́ Ọlọ́run àti ìbálò rẹ̀ ní fífi ojú ìwòye àwọn áńgẹ́lì wò ó. Ṣùgbọ́n bí kò bá ní ànímọ́ ẹ̀dá ènìyàn nínú, ì bá ṣòro fún wa láti lóye ìhìn iṣẹ́ inú Bíbélì.

Láti ṣàkàwé: Bíbélì lè wulẹ̀ ròyìn pé Ọba Dáfídì ṣe panṣágà, pé ó pànìyàn, pé ó sì ronú pìwà dà lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Síbẹ̀, ẹ wo bí ó ti sàn jù tó pé a ní ọ̀rọ̀ Dáfídì fúnra rẹ̀, bí ó ti sọ̀rọ̀ nípa làásìgbò tí ó bà á lọ́kàn jẹ́ nípa ìgbésẹ̀ rẹ̀ tí ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ìdáríjì Jèhófà! Ó kọ̀wé pé: “Nígbà gbogbo ni ẹ̀ṣẹ̀ mi sì ń bẹ níwájú mi. . . . Ìròbìnújẹ́ àti ìrora ọkàn àyà, Ọlọ́run, òun ni ìwọ kì yóò gàn.” (Orin Dáfídì 51:3, 17) Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí ànímọ́ ẹ̀dá ènìyàn tí ó ní, Bíbélì tani jí, ó kún fún onírúurú ọ̀rọ̀, ó sì fani mọ́ra.

Bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà yan ọ̀nà tí ó dára jù lọ láti fún wa ní Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Bí a tilẹ̀ lo àwọn ẹ̀dá ènìyàn tí wọ́n ní àìlera àti àṣìṣe, ẹ̀mí mímọ́ ni ó darí wọn, kí ó má baà sí àṣìṣe kankan nínú ìwé tí wọ́n kọ. Nípa báyìí, Bíbélì ní ìníyelórí gíga lọ́lá. Ìmọ̀ràn rẹ̀ múná dóko, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ nípa Párádísè ọjọ́ ọ̀la lórí ilẹ̀ ayé sì ṣeé gbára lé.—Orin Dáfídì 119:105; Pétérù Kejì 3:13.

Èé ṣe tí o kò fi sọ ọ́ dàṣà láti ka apá kan nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́? Pétérù kọ̀wé pé: “Ẹ ní ìyánhànhàn kan fún wàrà aláìlábùlà tí ó jẹ́ ti ọ̀rọ̀ náà, pé nípasẹ̀ rẹ̀ kí ẹ lè dàgbà dé ìgbàlà.” (Pétérù Kíní 2:2) Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ ohun tí Ọlọ́run mí sí, ìwọ yóò rí i pé gbogbo Ìwé Mímọ́ ni ó “ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún ìbániwí nínú òdodo, kí ènìyàn Ọlọ́run lè pegede ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.”—Tímótì Kejì 3:16, 17.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ó kéré tán, nínú ọ̀ràn kan, ìyẹn ní ti Òfin Mẹ́wàá, “ìka Ọlọ́run” fúnra rẹ̀ ni ó fi kọ ìsọfúnni náà. Mósè wulẹ̀ ṣàdàkọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn sínú àkájọ ìwé àti àwọn ohun ìkọ̀wé mìíràn ni.—Ẹ́kísódù 31:18; Diutarónómì 10:1-5.

b A lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, pheʹro, tí a túmọ̀ níhìn-ín sí “ti ń darí wọn,” ní ọ̀nà míràn nínú Ìṣe 27:15, 17 láti ṣàpèjúwe ọkọ̀ òkun kan tí ẹ̀fúùfù ń gbé. Nítorí náà, ẹ̀mí mímọ̀ ‘tọ́ ọ̀nà’ àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì. Ó sún wọn láti ṣá ìsọfúnni èyíkéyìí tí ó jẹ́ ayédèrú tì, kí wọ́n sì kọ kìkì èyí tí ó jẹ́ òkodoro sílẹ̀.

c Fún àpẹẹrẹ, fi Àwọn Ọba Kìíní 19:4 wé ẹsẹ 14 àti 18; Jóòbù 10:1-3; Orin Dáfídì 73:12, 13, 21; Jónà 4:1-3, 9; Hábákúkù 1:1-4, 13.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ibo Ni Mósè Ti Rí Ìsọfúnni Rẹ̀ Gbà?

MÓSÈ ni ó kọ ìwé Jẹ́nẹ́sísì nínú Bíbélì, ṣùgbọ́n gbogbo ohun tí ó kọ ṣẹlẹ̀ ṣáájú kí a tó bí i. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ibo ni ó ti rí ìsọfúnni rẹ̀ gbà? Ó ṣeé ṣe kí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ti ṣí i payá fún un, tàbí kí a ti tàtaré àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ díẹ̀ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ àtẹnudẹ́nu láti ìran kan sí èkejì. Níwọ̀n bí àwọn ẹ̀dá ènìyàn ti máa ń wà láàyè fún ìgbà pípẹ́ ní àkókò ìjímìjí, ọ̀pọ̀ ohun tí Mósè kọ sílẹ̀ nínú Jẹ́nẹ́sísì ni a ti lè tàtaré láti ọ̀dọ̀ Ádámù sí Mósè nípasẹ̀ ẹ̀dá ènìyàn márùn-⁠ún péré tí èkejì bá èkíní láyé​—⁠Mètúsélà, Ṣémù, Aísíìkì, Léfì, àti Ámúrámù.

Ní àfikún sí i, Mósè ti lè wo àwọn àkọsílẹ̀. Nípa èyí, ó yẹ fún àfiyèsí pé, léraléra ni Mósè lo àpólà ọ̀rọ̀ náà, “èyí ni ọ̀rọ̀ ìtàn,” ṣáájú kí ó tó sọ orúkọ ẹni náà tí ó fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 6:⁠9; 10:⁠1; 11:​10, 27; 25:​12, 19; 36:​1, 9; 37:⁠2, NW) Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé ọ̀rọ̀ Hébérù náà, toh·le·dhohthʹ, tí a túmọ̀ sí “ọ̀rọ̀ ìtàn” níhìn-⁠ín ń tọ́ka sí àkọsílẹ̀ ìtàn tí ó ti wà nílẹ̀ tí Mósè lò gẹ́gẹ́ bí orísun ìsọfúnni fún àkọsílẹ̀ rẹ̀. Àmọ́ ṣáá o, a kò lè fi gbogbo ẹnu sọ pé bí ọ̀rọ̀ ti rí nìyẹn.

Ó lè jẹ́ pé gbogbo ọ̀nà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí a mẹ́nu kàn lókè ni a gbà rí ìsọfúnni tí ó wà nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì​—⁠àwọn kan nípa ìṣípayá, àwọn kan nípa ọ̀rọ̀ àtẹnudẹ́nu, àwọn kan sì jẹ́ láti inú àkọsílẹ̀. Kókó tí ó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé, ẹ̀mí Jèhófà mí sí Mósè. Nítorí náà, a fojú tí ó tọ́ wo ohun tí ó kọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Ní onírúurú ọ̀nà, Ọlọ́run mí sí àwọn ènìyàn láti kọ Bíbélì

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́