ORÍ KEJE
A Ní Ọlọ̀tẹ̀ Nílé Bí?
1, 2. (a) Àpèjúwe wo ni Jesu ṣe láti tẹnu mọ́ àìṣòtítọ́ àwọn aṣáájú ìsìn Júù? (b) Kókó wo nípa àwọn àgùnbánirọ̀ ni a lè rí kọ́ nínú àpèjúwe Jesu?
NÍ ỌJỌ́ mélòó kan ṣáájú ikú rẹ̀, Jesu béèrè ìbéèrè amúni-ronú-jinlẹ̀ kan lọ́wọ́ àwùjọ àwọn aṣáájú ìsìn Júù. Ó sọ pé: “Kí ni ẹ̀yin rò? Ọkùnrin kan ní ọmọ méjì. Ní lílọ sọ́dọ̀ èyí àkọ́kọ́, ó wí pé, ‘Ọmọ, lọ ṣiṣẹ́ lónìí ninu ọgbà-àjàrà.’ Ní ìdáhùn ẹni yii wí pé, ‘Dájúdájú emi yoo lọ, sà,’ ṣugbọn kò jáde lọ. Ní títọ èkejì lọ, ó wí ohun kan naa. Ní ìfèsìpadà ẹni yii wí pé, ‘Dájúdájú emi kì yoo lọ.’ Lẹ́yìn ìgbà naa ó kábàámọ̀ ó sì jáde lọ. Èwo ninu awọn méjì naa ni ó ṣe ìfẹ́-inú baba rẹ̀?” Àwọn aṣáájú Júù fèsì pé: “Èyí èkejì.”—Matteu 21:28-31.
2 Níhìn-ín, Jesu ń tẹnu mọ́ àìṣòtítọ́ àwọn aṣáájú Júù. Wọ́n dà bí ọmọ àkọ́kọ́, wọ́n ṣèlérí láti ṣe ìfẹ́ Ọlọrun, wọn kò sì mú ìlérí wọn ṣẹ. Ṣùgbọ́n, ọ̀pọ̀ òbí yóò mọ̀ pé Jesu gbé àpèjúwe rẹ̀ karí ìmọ̀ kíkún tí ó ní nípa ìgbésí ayé ìdílé. Gẹ́gẹ́ bí ó ti fi hàn kedere, ó máa ń ṣòro láti mọ ohun tí àwọn ọ̀dọ́ ń rò tàbí sọ ohun tí wọn yóò ṣe. Ọ̀dọ́ kan lè ya ìpátá nígbà tí ó jẹ́ àgùnbánirọ̀, kí ó sì wá dàgbà di àgbàlagbà kan tí ó ní láárí, tí a bọ̀wọ̀ fún gidigidi. Ó yẹ kí a fi kókó yìí sọ́kàn bí a ti ń jíròrò ìṣòro ọ̀tẹ̀ àwọn ọ̀dọ́langba.
TA NI A LÈ PÈ NÍ ỌLỌ̀TẸ̀?
3. Èé ṣe tí àwọn òbí kò fi ní láti tètè sọ pé ọlọ̀tẹ̀ ni ọmọ wọn?
3 Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, o lè gbọ́ nípa àwọn ọ̀dọ́langba tí ń ṣọ̀tẹ̀ pátápátá sí àwọn òbí wọn. Ìwọ fúnra rẹ tilẹ̀ lè mọ̀ nípa ìdílé kan tí ó ní ọ̀dọ́langba tí ó jọ bíi pé ó ti ya pòkíì. Bí ó ti wù kí ó rí, kì í fìgbà gbogbo rọrùn láti mọ̀ bóyá ọmọ kan jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ ní ti gidi. Ní àfikún sí i, ó lè ṣòro láti lóye ìdí tí àwọn ọmọ kan fi ń ṣọ̀tẹ̀, tí àwọn mìíràn—láti inú agbo ilé kan náà pàápàá—kò sì ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àwọn òbí bá fura pé ọ̀kan lára àwọn ọmọ wọn ti ń di ọlọ̀tẹ̀ paraku, kí ni ó yẹ kí wọ́n ṣe? Láti dáhùn ìbéèrè yìí, a ní láti kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ẹni tí ọlọ̀tẹ̀ kan jẹ́.
4-6. (a) Ta ni a lè pè ní ọlọ̀tẹ̀? (b) Kí ni ó yẹ kí àwọn òbí ní lọ́kàn bí ọ̀dọ́langba wọn bá ń ṣàìgbọràn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan?
4 Kí a sọ ọ́ ní èdè tí ó rọrùn, ọlọ̀tẹ̀ jẹ́ ẹnì kan tí ó mọ̀-ọ́nmọ̀ ń ṣàìgbọràn sí tàbí ta ko ọlá àṣẹ gíga, tí ó sì ń tẹ̀ ẹ́ lójú léraléra. Dájúdájú, ‘wèrè dì sí àyà ọmọdé.’ (Owe 22:15) Nítorí náà, gbogbo ọmọ ní ń ta ko ọlá àṣẹ òbí àti ti àwọn ẹlòmíràn nígbà kan tàbí òmíràn. Èyí jẹ́ òtítọ́ ní pàtàkì nígbà ìdàgbàsókè ti ara àti ti èrò ìmọ̀lára, tí a mọ̀ sí ìgba àgùnbánirọ̀. Ìyípadà nínú ìgbésí ayé ẹnikẹ́ni yóò fa másùnmáwo, ìgba àgùnbánirọ̀ sì jẹ́ àkókò ìyípadà púpọ̀. Ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin rẹ ọ̀dọ́langba ń kúrò ní ọmọdé, ó sì ń lọ sí ipò àgbà. Fún ìdí yìí, ní àwọn ọdún ìgbà àgùnbánirọ̀, ó máa ń ṣòro fún àwọn òbí àti àwọn ọmọ kan láti wà ní ìrẹ́pọ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá, àwọn òbí máa ń gbìyànjú láti dá ìyípadà náà dúró, nígbà tí àwọn ọ̀dọ́langba ń fẹ́ láti mú kí ó yára kánkán.
5 Ọ̀dọ́langba tí ó jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ máa ń kọ àwọn ohun tí àwọn òbí rẹ̀ kà sí pàtàkì sílẹ̀. Bí ó ti wù kí ó rí, rántí pé ìwà àìgbọràn mélòó kan kò sọni di ọlọ̀tẹ̀. Nígbà tí ó bá sì kan ọ̀ran tẹ̀mí, àwọn ọmọ kan, lákọ̀ọ́kọ́, lè má fi ìfẹ́ hàn sí òtítọ́ Bibeli, ṣùgbọ́n wọ́n lè máà jẹ́ ọlọ̀tẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí òbí kan, má ṣe tètè sọ ọmọ rẹ lórúkọ burúkú.
6 Gbogbo ọ̀dọ́ ha ní ń ṣọ̀tẹ̀ sí ọlá àṣẹ òbí ní àwọn ọdún ìgbà àgùnbánirọ̀ bí? Bẹ́ẹ̀ kọ́ rárá. Ní ti gidi, ó jọ bíi pé ẹ̀rí fi hàn pé ìwọ̀nba kéréje àwọn ọ̀dọ́langba ní ń ṣọ̀tẹ̀ ní àwọn ọdún ìgbà àgùnbánirọ̀. Síbẹ̀, ọmọ kan tí ó jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ paraku ńkọ́? Kí ni ó lè fa irú ọ̀tẹ̀ bẹ́ẹ̀?
ÀWỌN OHUN TÍ Ń FA Ọ̀TẸ̀
7. Báwo ni àyíká abèṣù ṣe lè nípa lórí ọmọ kan láti ṣọ̀tẹ̀?
7 Àyíká ayé abèṣù jẹ́ ògúnnágbòǹgbò nínú ohun tí ń fa ọ̀tẹ̀. “Gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú naa.” (1 Johannu 5:19) Ayé tí ó wà lábẹ́ agbára Satani ti mú àṣà tí ń pani lára dàgbà, èyí tí àwọn Kristian gbọ́dọ̀ bá wọ̀yá ìjà. (Johannu 17:15) Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àṣà náà túbọ̀ jẹ́ pàrùpárù, ó túbọ̀ léwu, ó sì kún fún agbára ìdarí tí ó túbọ̀ burú lónìí ju ti ìgbà àtijọ́ lọ. (2 Timoteu 3:1-5, 13) Bí àwọn òbí kò bá kọ́ àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n kìlọ̀ fún wọn, kí wọ́n sì dáàbò bò wọ́n, “ẹ̀mí tí ń ṣiṣẹ́ nísinsìnyí ninu awọn ọmọ àìgbọ́ràn” lè tètè nípa lórí àwọn ọmọdé. (Efesu 2:2) Ìkìmọ́lẹ̀ láti ọ̀dọ ojúgbà tún tan mọ́ èyí. Bibeli sọ pé: ‘Ẹni tí ń bá aṣiwèrè kẹ́gbẹ́ yóò ṣègbé.’ (Owe 13:20) Bákan náà, ó ṣeé ṣe kí ẹ̀mí ayé yìí nípa lórí ẹni tí ń bá àwọn tí ẹ̀mí yẹn ti wọ̀ lọ́kàn kẹ́gbẹ́. Àwọn ọ̀dọ́ nílò ìrànlọ́wọ́ lemọ́lemọ́ bí wọn yóò bá lóye pé, ṣíṣègbọràn sí àwọn ìlànà Ọlọrun jẹ́ ìpìlẹ̀ ọ̀nà ìgbésí ayé dídára jù lọ.—Isaiah 48:17, 18.
8. Àwọn ohun wo ni ó lè mú ọmọ kan ṣọ̀tẹ̀?
8 Ohun mìíràn tí ń fa ọ̀tẹ̀ lè jẹ́ ẹ̀mí tí ó gbèrú nínú ilé. Fún àpẹẹrẹ, bí òbí kan bá jẹ́ ọ̀mùtí, ajòògùnyó, tàbí tí ń lu òbí kejì bolẹ̀, ojú tí ọ̀dọ́langba náà fi ń wo ìgbésí ayé lè máà gún régé. Ní àwọn ilé tí ó tòrò níwọ̀nba pàápàá, ọ̀tẹ̀ lè bẹ́ sílẹ̀ nígbà tí ọmọ kan bá ronú pé àwọn òbí òun kò lọ́kàn ìfẹ́ sí òun. Bí ó ti wù kí ó rí, kì í ṣe gbogbo ìgbà ni ó jẹ́ pé àwọn agbára ẹ̀yìn òde ní ń fa ọ̀tẹ̀ àwọn ọ̀dọ́langba. Àwọn ọmọ kan máa ń kọ àwọn ohun tí àwọn òbí wọn kà sí pàtàkì sílẹ̀, láìka níní àwọn òbí tí ń lo ìlànà Ọlọrun, tí ó sì ń dáàbò bò wọ́n gidigidi lọ́wọ́ ayé tí ó yí wọn ká sí. Kí ní ń fà á? Bóyá nítorí okùnfà míràn fún àwọn ìṣòro wa—àìpé ẹ̀dá ènìyàn. Paulu sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ti tipasẹ̀ ènìyàn kan [Adamu] wọ inú ayé ati ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa bayii tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nitori pé gbogbo wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀.” (Romu 5:12) Adamu jẹ́ ọlọ̀tẹ̀ onímọtara-ẹni-nìkan, ó sì fi ogún burúkú sílẹ̀ fún gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀. Àwọn èwe kan wulẹ̀ yàn láti ṣọ̀tẹ̀, gẹ́gẹ́ bí bàbá ńlá wọ́n ti ṣe.
ELI AGBỌ̀JẸ̀GẸ́ ÀTI REHOBOAMU ALEKOKO
9. Àwọn àṣejù wo nínú títọ́ ọmọ ni ó lè sún ọmọ kan ṣọ̀tẹ̀?
9 Ohun mìíràn tí ó ti ṣokùnfà ọ̀tẹ̀ àwọn ọ̀dọ́langba jẹ́ ojú ìwòye tí kò wà déédéé tí àwọn òbí ní nípa títọ́ ọmọ. (Kolosse 3:21) Àwọn òbí kan, tí ẹrù iṣẹ́ wọn ń jẹ lọ́kàn, ń ká àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ kò, wọ́n sì ń bá wọn wí ju bí ó ti yẹ lọ. Àwọn mìíràn gbọ̀jẹ̀gẹ́, wọn kì í pèsè ìtọ́sọ́nà tí yóò dáàbò bo àwọn àgùnbánirọ̀ wọn aláìnírìírí. Kò rọrùn rárá láti má ṣe jẹ́ aláṣejù nínú ọ̀kan nínú àwọn ọ̀ràn méjèèjì wọ̀nyí. Àìní ọmọ kọ̀ọ̀kan sì yàtọ̀ síra. Ọ̀kan lè nílò àbójútó ju èkejì lọ. Síbẹ̀, àpẹẹrẹ méjì nínú Bibeli yóò ṣèrànwọ́ láti fi ewu tí ń bẹ nínú jíjẹ́ aláṣejù ní ti líle koko tàbí gbígbọ̀jẹ̀gẹ́ hàn.
10. Bí ó tilẹ̀ ṣeé ṣe kí ó jẹ́ olórí àlùfáà olùṣòtítọ́, èé ṣe tí Eli fi jẹ́ òbí burúkú?
10 Eli, olórí àlùfáà ní Israeli ìgbàanì, jẹ́ bàbá. Ó ṣiṣẹ́ sìn fún 40 ọdún, ó sì dájú pé ó mọ Òfin Ọlọrun bí ẹni mowó. Ó ṣeé ṣe pé Eli fi ìṣòtítọ́ ṣe àwọn ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àlùfáà, ó sì lè ti fi Òfin Ọlọrun kọ́ àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, Hofni àti Finehasi, dáradára. Àmọ́ ṣáá o, Eli ti gba gbẹ̀rẹ́ jù fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀. Hofni àti Finehasi ṣiṣẹ́ sìn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà alábòójútó, ṣùgbọ́n “ọkùnrin aláìdára fún ohunkóhun,” tí ó lọ́kàn ìfẹ́ kìkì nínú títẹ́ ikùn àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn lọ́rùn, ni wọ́n. Síbẹ̀, nígbà tí wọ́n dẹ́ṣẹ̀ tí ń tini lójú lórí ilẹ̀ mímọ́, Eli kò láyà láti gbaṣẹ́ lọ́wọ́ wọn. Ó wulẹ̀ rọra bá wọn wí ni. Nípa ìgbọ̀jẹ̀gẹ́ rẹ̀, Eli bu ọlá fún àwọn ọmọ rẹ̀ ju Ọlọrun lọ. Nítorí èyí, àwọn ọmọ rẹ̀ ṣọ̀tẹ̀ sí ìjọsìn mímọ́ Jehofa, gbogbo agbo ilé Eli sì jìyà ìpọ́njú.—1 Samueli 2:12-17, 22-25, 29, NW; 3:13, 14; 4:11-22.
11. Kí ni àwọn òbí lè rí kọ́ nínú àpẹẹrẹ burúkú Eli?
11 Àwọn ọmọ Eli ti dàgbà nígbà tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n, ìtàn yìí tẹnu mọ́ ewu fífawọ́ ìbáwí sẹ́yìn. (Fi wé Owe 29:21.) Àwọn òbí kan lè rò pé ìgbọ̀jẹ̀gẹ́ jẹ́ ìfẹ́, ní kíkùnà láti gbé òfin ṣíṣe kedere, wíwà déédéé, tí ó sì bọ́gbọ́n mu kalẹ̀, kí wọ́n sì rí i pé a tẹ̀ lé e. Wọ́n ṣàìnáání fífìfẹ́ báni wí, àní nígbà tí a bá tẹ ìlànà Ọlọrun lójú pàápàá. Nítorí irú ìgbọ̀jẹ̀gẹ́ bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ wọ́n lè di ẹni tí kì í ka ọlá àṣẹ àwọn òbí tàbí ti ẹnikẹ́ni mìíràn sí.—Fi wé Oniwasu 8:11.
12. Àṣìṣe wo ni Rehoboamu ṣe nínú lílo ọlá àṣẹ?
12 Rehoboamu ṣàpẹẹrẹ ìwà àṣejù kejì nínú lílo ọlá àṣẹ. Òun ni ọba tí ó jẹ kẹ́yìn lórí àpapọ̀ ìjọba Israeli, ṣùgbọ́n òun kì í ṣe ọba rere. Rehoboamu ti jogún orílẹ̀-èdè kan tí àwọn ènìyàn inú rẹ̀ kò nítẹ̀ẹ́lọ́rùn nítorí àwọn ẹrù ìnira tí bàbá rẹ̀, Solomoni, ti gbé kà wọ́n lórí. Rehoboamu ha fi òye hàn bí? Rárá. Nígbà tí àwọn aṣojú kan sọ fún un pé kí ó dín lára ẹrù ìnira náà kù, ó kọ̀ láti fetí sí ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n àwọn àgbà, ó sì pàṣẹ pé kí a fi kún ẹrù ìnira àwọn ènìyàn náà. Agídí rẹ̀ mú kí àwọn ẹ̀yà mẹ́wàá àríwá ṣọ̀tẹ̀, a sì pín ìjọba náà sí méjì.—1 Awọn Ọba 12:1-21; 2 Kronika 10:19.
13. Báwo ni àwọn òbí ṣe lè yẹra fún àṣìṣe Rehoboamu?
13 Àwọn òbí lè kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì láti inú ìròyìn Bibeli nípa Rehoboamu. Wọ́n ní láti “máa wá Oluwa” nínú àdúrà, kí wọ́n sì ṣàyẹ̀wo ọ̀nà tí wọ́n ń gbà tọ́mọ ní ojú ìwòye ìlànà Bibeli. (Orin Dafidi 105:4) Oniwasu 7:7 sọ pé: “Ìnilára mú ọlọgbọ́n ènìyàn sínwín.” Àwọn ìtọ́sọ́nà, tí a lànà rẹ̀ dáradára, ń fàyè gba àwọn àgùnbánirọ̀ láti dàgbà, bí ó ti ń dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ ewu. Ṣùgbọ́n kò yẹ kí àwọn ọmọ dàgbà nínú àyíká tí ó le koko, tí ń káni lọ́wọ́ kò ju bí ó ti yẹ lọ, débi tí a fi ń ṣèdíwọ́ fún wọn láti mú ìgbáralé ara-ẹni àti ìgbọ́kànlé ara-ẹni tí ó bójú mu dàgbà. Bí àwọn òbí bá làkàkà láti wà déédéé nínú fífúnni lómìnira tí ó tó àti fífi àwọn ìtọ́sọ́nà tí ó fìdí múlẹ̀, tí ó sì ṣe kedere, lélẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́langba kì yóò nítẹ̀sí láti ṣọ̀tẹ̀.
KÍKÚNJÚ ÀWỌN ÀÌNÍ PÀTÀKÌ LÈ DÈNÀ Ọ̀TẸ̀
14, 15. Ojú wo ni ó yẹ kí àwọn òbí fi wo ìdàgbàsókè ọmọ wọn?
14 Bí àwọn òbí tilẹ̀ ń láyọ̀ láti rí àwọn ọmọ wọn tí ń dàgbà nípa ti ara láti ọmọdé jòjòló di àgbàlagbà, ìdààmú lè bá wọn nígbà tí ọmọ wọ́n àgùnbánirọ̀ bá bẹ̀rẹ̀ sí í kúrò ní ẹni tí ó gbára lé wọn sí ẹni tí ń dápinnu ṣe, lọ́nà yíyẹ. Lásìkò ìyípadà yìí, má ṣe jẹ́ kí ó yà ọ́ lẹ́nu bí ọ̀dọ́langba rẹ bá ń ṣorí kunkun tàbí ṣàìfọwọ́-sowọ́-pọ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ní in lọ́kàn pé góńgó àwọn Kristian òbí gbọ́dọ̀ jẹ́ láti tọ́ Kristian kan tí ó dàgbà dénú, tí ó dúró ṣinṣin, tí ó sì ṣeé gbára lé, dàgbà.—Fi wé 1 Korinti 13:11; Efesu 4:13, 14.
15 Bí ó ti wù kí ó nira tó, àwọn òbí ní láti jáwọ́ nínú àṣà kíkọ ìbéèrè èyíkéyìí fún òmìnira púpọ̀ sí i tí àgùnbánirọ̀ wọ́n bá béèrè. Ní ọ̀nà tí ó gbámúṣé, ọmọ kan ní láti dàgbà gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan. Ní ti gidi, nígbà tí wọ́n ṣì kéré, àwọn ọ̀dọ́langba kan máa ń ní ìwà àgbà. Fún àpẹẹrẹ, Bibeli sọ nípa Ọba Josiah ọ̀dọ́ pé: “Nígbà tí ó sì wà ní ọ̀dọ́mọdé [nǹkan bí ọmọ ọdún 15] síbẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wá Ọlọrun Dafidi.” Ó ṣe kedere pé ọ̀dọ́langba títayọ yìí jẹ́ ẹnì kan tí ó ṣeé gbára lé.—2 Kronika 34:1-3.
16. Bí a ti ń fún àwọn ọmọ ní ẹrù iṣẹ́ tí ó túbọ̀ ń pọ̀ sí i, kí ni wọ́n ní láti mọ̀?
16 Bí ó ti wù kí ó rí, òmìnira ń mú ìjíhìn lọ́wọ́. Nítorí náà, yọ̀ǹda fún ọmọ rẹ tí ń dàgbà láti nírìírí àbájáde díẹ̀ lára àwọn ìpinnu àti ìgbésẹ̀ rẹ̀. Ìlànà náà, “ohun yòówù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni oun yoo ká pẹlu,” kan àwọn ọ̀dọ́langba bí ó ti kan àwọn àgbàlagbà. (Galatia 6:7) A kò lè ràdọ̀ bo àwọn ọmọ títí ayérayé. Ṣùgbọ́n, bí ọmọ rẹ bá fẹ́ ṣe ohun tí kò bójú mu rárá ńkọ́? Gẹ́gẹ́ bí òbí tí ó mọṣẹ́ níṣẹ́, o gbọ́dọ̀ sọ pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o lè sọ àwọn ìdí tí o ní, kò sí ohun tí ó gbọ́dọ̀ yí bẹ́ẹ̀ kọ́ rẹ padà sí bẹ́ẹ̀ ni. (Fi wé Matteu 5:37.) Bí ó ti wù kí ó rí, gbìyànjú láti sọ pé “Bẹ́ẹ̀ kọ́” ní pẹ̀lẹ́tù, lọ́nà tí ó bọ́gbọ́n mu, níwọ̀n bí ‘ìdáhùn pẹ̀lẹ́ ti ń yí ìbínú padà.’—Owe 15:1.
17. Kí ni díẹ̀ lára àwọn àìní ọ̀dọ́langba tí òbí ní láti kúnjú?
17 Àwọn ọ̀dọ́ nílò ààbò tí ìbáwí ṣíṣe déédéé ń mú wá, àní bí wọn kì í tilẹ̀ fohùn ṣọ̀kan lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìkálọ́wọ́kò àti òfin nígbà gbogbo. Ó máa ń jáni kulẹ̀ bí a bá ń yí àwọn òfin padà lemọ́lemọ́, ní sísinmi lórí bí òbí kan ṣe nímọ̀lára ní àkókò náà. Síwájú sí i, bí àwọn ọ̀dọ́langba bá rí ìṣírí àti ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n nílò láti kojú àìdára-ẹni-lójú, ìtìjú, tàbí àìnígbẹkẹ̀lé nínú ara ẹni gbà, ó ṣeé ṣe kí wọ́n dàgbà di ẹni tí ó túbọ̀ dúró ṣinṣin. Àwọn ọ̀dọ́langba tún máa ń mọyì rẹ̀ bí àwọn òbí wọn bá fún wọn ní ìgbọ́kànlé tí ó tọ́ sí wọn.—Fi wé Isaiah 35:3, 4; Luku 16:10; 19:17.
18. Kí ni díẹ̀ lára àwọn òtítọ́ tí ń gbéni ró nípa àwọn ọ̀dọ́langba?
18 Ó lè tu àwọn òbí nínú láti mọ̀ pé, nígbà tí àlàáfíà, ìdúróṣinṣin, àti ìfẹ́ bá wà láàárín agbo ilé, àwọn ọmọ sábà máa ń ṣe dáradára. (Efesu 4:31, 32; Jakọbu 3:17, 18) Họ́wù, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ti borí àyíká ilé búburú pàápàá, bí wọ́n ti wá láti inú ìdílé tí ìmukúmu, ìwà ipá, tàbí agbára ìdarí mìíràn tí ń pani lára, ń yọ lẹ́nu, tí wọ́n sì ti dàgbà di ẹni tí ó ní láárí. Nítorí náà, bí o bá pèsè ilé, níbi tí àwọn ọ̀dọ́langba rẹ ti ní ìfọ̀kànbalẹ̀, tí wọ́n sì mọ̀ pé wọn yóò rí ìfẹ́, ìfẹ́ni, àti àfiyèsí gbà—àní bí ìkálọ́wọ́kò tí ó bójú mu àti ìbáwí ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà Ìwé Mímọ́ bá bá ìtìlẹ́yìn náà rìn pàápàá—ó ṣeé ṣe dáradára pé wọn yóò dàgbà di àgbàlagbà tí ìwọ yóò lè mú yangàn.—Fi wé Owe 27:11.
NÍGBÀ TÍ ÀWỌN ỌMỌ BÁ KÓ SÍNÚ ÌṢÒRO
19. Bí àwọn òbí tilẹ̀ ní láti tọ́ ọmọ ní ọ̀nà tí yóò tọ̀, ẹrù iṣẹ́ wo ni ó já lé ọmọ lórí?
19 Ìtọ́jú tí ó dára láti ọ̀dọ̀ òbí máa ń mú ìyàtọ̀ wá. Owe 22:6 sọ pé: “Tọ́ ọmọdé ní ọ̀nà tí yóò tọ̀: nígbà tí ó sì dàgbà tán, kì yóò kúrò nínú rẹ̀.” Síbẹ̀, àwọn ọmọ tí wọ́n ní ìṣòro ńlá láìka níní tí wọ́n ní àwọn òbí rere sí ńkọ́? Èyí ha ṣeé ṣe bí? Bẹ́ẹ̀ ni. A gbọ́dọ̀ lóye àwọn ọ̀rọ̀ inú owe yẹn ní ṣíṣàgbéyẹ̀wò àwọn ẹsẹ mìíràn tí ó tẹnu mọ́ ẹrù iṣẹ́ ọmọ láti “gbọ́” ti àwọn òbí rẹ̀ àti láti ṣègbọràn sí wọn. (Owe 1:8) Àtòbí àtọmọ gbọ́dọ̀ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ nínú lílo ìlànà Ìwé Mímọ́, bí ìṣọ̀kan yóò bá wà nínú ìdílé. Bí àwọn òbí àti àwọn ọmọ kò bá ṣiṣẹ́ pọ̀, ìṣòro yóò wà.
20. Nígbà tí àwọn ọmọ bá ṣàṣìṣe nítorí àìnírònú, ìgbésẹ̀ wo ni yóò lọ́gbọ́n nínú fún àwọn òbí láti gbé?
20 Báwo ni ó ṣe yẹ kí àwọn òbí hùwà padà nígbà tí ọ̀dọ́langba kan bá ṣàṣìṣe, tí ó sì kó sínú ìjọ̀ngbọ̀n? Nígbà yẹn gan-an ni ọ̀dọ́langba náà nílò ìrànlọ́wọ́ wọn jù lọ. Bí àwọn òbí náà bá rántí pé èwe aláìnírìírí ni àwọ́n ń bá lò, yóò rọrùn fún wọn láti dín ìtẹ̀sí ṣíṣàṣerégèé kù. Paulu gba àwọn tí ó dàgbà dénú nínú ìjọ nímọ̀ràn pé: “Bí ènìyàn kan bá tilẹ̀ ṣi ẹsẹ̀ gbé kí ó tó mọ̀ nipa rẹ̀, ẹ̀yin tí ẹ tóótun nipa ti ẹ̀mí ẹ gbìyànjú lati tọ́ irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ sọ́nà padà ninu ẹ̀mí ìwàtútù.” (Galatia 6:1) Àwọn òbí lè tẹ̀ lé ìlànà kan náà yìí, nígbà tí wọ́n bá ń bá ọ̀dọ́ tí ó ṣàṣìṣe nítorí àìnírònú rẹ̀ lò. Bí wọ́n ti ń ṣàlàyé ìdí tí ìwà rẹ̀ fi lòdì àti bí ó ṣe lè yẹra fún ṣíṣe irú àṣìṣe kan náà ní ọjọ́ mìíràn, àwọn òbí náà ní láti mú un ṣe kedere pé ìwà burúkú náà ni ó burú, kì í ṣe èwe náà.—Fi wé Juda 22, 23.
21. Ní títẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìjọ Kristian, báwo ni àwọn òbí ṣe ní láti hùwà padà bí àwọn ọmọ wọ́n bá dẹ́ṣẹ̀ wíwúwo?
21 Bí ìwà burúkú ọ̀dọ́ náà bá wúwo rinlẹ̀ ńkọ́? Nínú irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, ọmọ náà nílò àkànṣe ìrànwọ́ àti ìdarí jíjáfáfá. Nígbà tí mẹ́ḿbà kan nínú ìjọ bá dẹ́ṣẹ̀ wíwúwo, a ń rọ̀ ọ́ láti ronú pìwà dà, kí ó sì tọ àwọn alàgbà lọ fún ìrànlọ́wọ́. (Jakọbu 5:14-16) Gbàrà tí ó bá ti ronú pìwà dà, àwọn alàgbà yóò ṣiṣẹ́ pẹ̀lú rẹ̀ láti mú un padà bọ̀ sípò nípa tẹ̀mí. Nínú ìdílé, ẹrù iṣẹ́ ríran ọ̀dọ́ tí ó ṣàṣìṣe lọ́wọ́ já lé àwọn òbí lórí, bí wọ́n tilẹ̀ ní láti jíròrò ọ̀ràn náà pẹ̀lú àwọn alàgbà. Dájúdájú, wọn kò gbọdọ̀ gbìyànjú láti fi ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo rinlẹ̀ tí ọ̀kan lára àwọn ọmọ wọ́n dá pamọ́.
22. Ní fífara wé Jehofa, ẹ̀mí ìrònú wo ni ó yẹ kí àwọn òbí ní, bí ọmọ wọ́n bá ṣàṣìṣe wíwúwo?
22 Ìṣòro wíwúwo rinlẹ̀ tí ó kan ọmọ ẹni fúnra ẹni ń dánni wò. Nítorí pé ìmọ̀lára wọ́n ti pòrúurùu, àwọn òbí lè nímọ̀lára láti fìbínú halẹ̀ mọ́ oníwàkiwà ọmọ náà; ṣùgbọ́n èyí wulẹ̀ lè mú un burú sí i ni. Má ṣe gbàgbé pé, ọjọ́ ọ̀la ọmọdé yìí lè sinmi lórí bí a ṣe hùwà sí i ní àkókò líle koko yìí. Rántí pẹ̀lú pé, Jehofa ṣe tán láti dárí ji àwọn ènìyàn rẹ̀ nígbà tí wọ́n yà bàrá kúrò lọ́nà tí ó tọ́—bí wọn yóò bá ronú pìwà dà. Tẹ́tí sí àwọn àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ onífẹ̀ẹ́: “Oluwa wí pé, wá nísinsìnyí, kí ẹ sì jẹ́ kí a sọ àsọyé pọ̀: bí ẹ̀ṣẹ̀ yín bá rí bí òdòdó, wọn óò sì fún bí òjò dídì; bí wọ́n pọ́n bí àlàárì, wọn óò dà bí irun àgùntàn.” (Isaiah 1:18) Ẹ wo àpẹẹrẹ dáradára tí èyí jẹ́ fún àwọn òbí!
23. Nígbà tí ọ̀kan lára àwọn ọmọ wọ́n bá dẹ́ṣẹ̀ wíwúwo, báwo ni ó ṣe yẹ kí àwọn òbí hùwà, kí sì ni ó yẹ kí wọ́n yẹra fún?
23 Nítorí náà, gbìyànjú láti fún ọmọ oníwàkiwà náà níṣìírí láti yí ọ̀nà rẹ̀ padà. Wá ìmọ̀ràn tí ó múná dóko sọ́dọ̀ àwọn òbí onírìírí àti àwọn alàgbà ìjọ. (Owe 11:14) Gbìyànjú láti má ṣe fi bí ó ti ká ọ lára tó hùwà, kí o sì sọ tàbí ṣe ohun tí yóò mú kí ó nira fún ọmọ rẹ láti padà wá bá ọ. Yẹra fún ìrunú àti ìbínú tí kò níjàánu. (Kolosse 3:8) Má ṣe tètè sọ ìrètí nù. (1 Korinti 13:4, 7) Bí o ti ń kórìíra ìwà búburú, yẹra fún líle koko àti kíkorò mọ́ ọmọ rẹ. Ní pàtàkì jù lọ, àwọn òbí gbọ́dọ̀ làkàkà láti fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀, kí wọ́n sì jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wọn nínú Ọlọrun lágbára.
BÍBÁ ỌLỌ̀TẸ̀ PARAKU LÒ
24. Ipò burúkú wo ni ó máa ń ṣẹlẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nínú ìdílé Kristian, kí sì ni ó yẹ kí ó jẹ́ ìṣarasíhùwà òbí?
24 Nínú àwọn ọ̀ràn kan, ó ń ṣe kedere pé èwe kan ti ṣe ìpinnu fífẹsẹ̀ rinlẹ̀ láti ṣọ̀tẹ̀, kí ó sì kọ àwọn ohun tí Kristian kà sí pàtàkì sílẹ̀ pátápátá. Nígbà náà, àfiyèsí náà ní láti yí padà sórí gbígbé ìgbésí ayé ìdílé àwọn tí ó kù ró. Ṣọ́ra, kí o sì rí i pé o kò darí gbogbo okun rẹ sórí ọlọ̀tẹ̀ náà, sí ìpalára àwọn ọmọ yòókù. Dípò gbígbìyànjú láti fi ìṣòro náà pamọ́ fún àwọn mẹ́ḿbà ìdílé yòókù, jíròrò ọ̀ràn náà pẹ̀lú wọn dé ìwọ̀n tí ó bá yẹ, àti lọ́nà tí ń fini lọ́kàn balẹ̀.—Fi wé Owe 20:18.
25. (a) Ní títẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìjọ Kristian, ìgbésẹ̀ wo ni àwọn òbí lè gbé bí ọmọ kan bá di ọlọ̀tẹ̀ paraku? (b) Kí ni ó yẹ kí àwọn òbí ní lọ́kàn bí ọ̀kan lára àwọn ọmọ wọ́n bá ṣọ̀tẹ̀?
25 Aposteli Johannu sọ nípa ẹnì kan tí ó di ọlọ̀tẹ̀ aláìronúpìwàdà nínú ìjọ pé: “Ẹ máṣe gbà á sí ilé yín láé tabi kí i.” (2 Johannu 10) Àwọn òbí lè ronú pé ó pọn dandan láti gbé ìgbésẹ̀ kan náà nípa ọmọ àwọn tìkára wọn, tí ó bá ti tójú bọ́, tí ó sì ti di ọlọ̀tẹ̀ paraku. Bí ìgbésẹ̀ náà tilẹ̀ nira, tí ó sì ń roni lára, ó máa ń ṣe pàtàkì nígbà míràn láti lè dáàbò bo àwọn mẹ́ḿbà ìdílé yòókù. Agbo ilé rẹ nílò ààbò àti àbójútó rẹ, tí ń bá a lọ. Nítorí náà, máa bá a lọ láti pa ìlànà ìwà híhù, tí ó ṣe kedere, síbẹ̀, tí ó bójú mu, mọ́. Bá àwọn ọmọ yòókù jùmọ̀ sọ̀rọ̀ pọ̀. Lọ́kàn ìfẹ́ nínú bí wọ́n ti ń ṣe ní ilé ẹ̀kọ́ àti nínú ìjọ. Pẹ̀lúpẹ̀lù, jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé, bí o kò tilẹ̀ fọwọ́ sí àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀, o kò kórìíra ọlọ̀tẹ̀ ọmọ náà. Dẹ́bi fún ìwà burúkú náà, kì í ṣe ọmọ náà. Nígbà tí àwọn ọmọkùnrin Jakọbu méjì mú kí a ta ìdílé náà nù lẹ́gbẹ́, nítorí ìwà ìkà wọn, Jakọbu gégùn-ún fún ìbínú oníwà ipá wọn, kì í ṣe fún àwọn ọmọkùnrin náà fúnra wọn.—Genesisi 34:1-31; 49:5-7.
26. Nínú kí ni àwọn òbí tí ó mọṣẹ́ níṣẹ́ ti lè rí ìtùnú gbà, bí ọ̀kan lára àwọn ọmọ wọ́n bá ṣọ̀tẹ̀?
26 O lè bẹ̀rẹ̀ sí í dá ara rẹ lẹ́bi fún ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé rẹ. Ṣùgbọ́n, bí ìwọ́ bá ti fi tàdúràtàdúrà ṣe gbogbo ohun tí o lè ṣe, ní títẹ̀ lé ìmọ̀ràn Jehofa débi tí agbára rẹ mọ, kò sí ìdí láti ṣàríwísí ara rẹ láìyẹ. Tu ara rẹ nínú pẹ̀lú òtítọ́ náà pé, kò sí òbí tí ó pé, ṣùgbọ́n o ti fi tọkàntọkàn tiraka láti jẹ́ òbí rere kan. (Fi wé Ìṣe 20:26.) Láti ní ọlọ̀tẹ̀ paraku nínú ìdílé ń bani nínú jẹ́, ṣùgbọ́n, bí ó bá ṣẹlẹ̀ sí ọ, jẹ́ kí ó dá ọ lójú pé Ọlọrun lóye, òun kì yóò sì fi àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olùfọkànsìn sílẹ̀ láé. (Orin Dafidi 27:10) Nítorí náà, pinnu láti jẹ́ kí ilé rẹ jẹ́ ibi ààbò, tí ń fọkàn ẹni balẹ̀ nípa tẹ̀mí, fún àwọn ọmọ rẹ yòókù.
27. Ní rírántí òwe ọmọ onínàákúnàá, kí ni àwọn òbí ọlọ̀tẹ̀ ọmọ lè máa retí nígbà gbogbo?
27 Síwájú sí i, o kò gbọdọ̀ sọ ìrètí nù láé. Àwọn ìsapá rẹ àtẹ̀yìnwá nínú títọ́ ọ dàgbà lọ́nà títọ́ lè nípa lórí ọmọ tí ń ṣako lọ náà, kí ó sì pe orí rẹ̀ wálé, lásẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀. (Oniwasu 11:6) Ọ̀pọ̀ ìdílé Kristian ti ní irú ìrírí bíi tìrẹ, àwọn kan sì ti rí i tí àwọn ọmọ wọn oníwàkiwà padà bọ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣẹlẹ̀ sí bàbá inú òwe Jesu nípa ọmọ onínàákúnàá. (Luku 15:11-32) Ohun kan náà lè ṣẹlẹ̀ sí ọ.
BÁWO NI ÀWỌN ÌLÀNÀ BIBELI WỌ̀NYÍ ṢE LÈ ṢẸ̀RÀNWỌ́ FÚN . . . ÒBÍ LÁTI DÈNÀ Ọ̀TẸ̀ PARAKU NÍNÚ AGBO ILÉ?
Láìsí ìrànwọ́, ẹ̀mí ayé lè kó bá ọmọ kan.—Owe 13:20; Efesu 2:2.
Àwọn òbí kò gbọdọ̀ le koko jù, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò gbọdọ̀ gbọ̀jẹ̀gẹ́.—Oniwasu 7:7; 8:11.
A ní láti ṣiṣẹ́ lórí ìwà wíwọ́, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ẹ̀mí ìwà tútù.—Galatia 6:1.
Àwọn tí ó dẹ́ṣẹ̀ wíwúwo lè rí “ìmúláradá” bí wọ́n bá ronú pìwà dà, tí wọ́n sì tẹ́wọ́ gba ìrànlọ́wọ́.—Jakọbu 5:14-16.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 82]
TÚ ỌKÀN RẸ JÁDE
Àwọn àgùnbánirọ̀ yóò ṣe iyè méjì àti àníyàn tí ó ní í ṣe pẹ̀lú òmìnira púpọ̀ sí i tí wọ́n ń ní. Wọ́n lè máa ṣiyè méjì nípa agbára wọn láti bójú tó ara wọn nínú ayé. Ńṣe ni ó dà bí ìgbà tí wọ́n bá ń gbìyànjú láti rìn lórí ilẹ̀ yíyọ̀. Ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ tú ọkàn yín jáde fún àwọn òbí yín nípa ìbẹ̀rù àti àìdára-ẹni-lójú tí ẹ ń ní. (Owe 23:22) Tàbí bí o bá rò pé àwọn òbí rẹ ń ká ọ lọ́wọ́ kò ju bí ó ti yẹ lọ, bá wọn sọ̀rọ̀ láti fún ọ ní òmìnira díẹ̀ sí i. Wéwèé láti bá wọn sọ̀rọ̀ nígbà tí ará tù ọ́ àti nígbà tí ọwọ́ wọn kò dí. (Owe 15:23) Ẹ wá àkókò láti fetí sílẹ̀ sí ara yín.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 83]
Ó ṣeé ṣe pé àwọn ọmọdé yóò dàgbà di ẹni tí ó dúró ṣinṣin bí àwọn òbí wọn bá ràn wọ́n lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro ìgbà ọ̀dọ́langba wọn