Ojú Ìwòye Bíbélì
Èé Ṣe Tó Fi Yẹ Kí O Ṣàkóso Ìbínú Rẹ?
ÌBẸ̀RẸ̀ atọ́ka ìṣẹ̀lẹ̀ ibi ló jẹ́. John pariwo mọ́ Ginger, ìyàwó rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé, pé: “Nísinsìnyí tí ó jẹ́ pé èmi ni olórí ilé yìí, o kò lè máa kójútì bá mi nípa jíjoyè apẹ́lẹ́yìn.”a Fún ohun tí ó lé ní ìṣẹ́jú 45, ó ké rara mọ́ ọn bí ó ti ń ní kí ó jókòó sórí àga onítìmùtìmù síbẹ̀. Èébú wá di ọ̀pá ìdiwọ̀n àfiṣàpẹẹrẹ nínú ìgbéyàwó wọn. Ó bani nínú jẹ́ pé ìwà ìbínú tí John ń hù ń pọ̀ sí i. Yóò pa ilẹ̀kùn dé gbàgà, yóò lu tábìlì ilé ìgbọ́únjẹ gbà-gbà-gbà, yóò sì wakọ̀ níwàkuwà bí ó ti ń gbá ọwọ́ ìtọ́kọ̀ náà, ó sì ń tipa bẹ́ẹ̀ fi ẹ̀mí àwọn ẹlòmíràn sínú ewu.
Ó dunni pé bí ẹ ti mọ̀ dáradára láìsíyèméjì, irú ìṣẹ̀lẹ̀ àfinúrò tí ó tẹ̀ léra bẹ́ẹ̀ máa ń ṣẹlẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà. Ìbínú ọkùnrin yìí ha bójú mu, àbí kò lè ṣàkóso ara rẹ̀ ni? Ṣé gbogbo ìbínú ni kò tọ̀nà ni? Ìgbà wo ni ìbínú lè di èyí tí a kò ṣàkóso? Ìgbà wo ni ó di àṣejù?
A lè dá ìbínú tí a ṣàkóso láre. Fún àpẹẹrẹ, ìbínú Ọlọ́run ru sí àwọn ìlú ńlá ìgbàanì, oníwà pálapàla náà, Sódómù òun Gòmórà. (Jẹ́nẹ́sísì 19:24) Kí ló fà á? Nítorí pé àwọn ènìyàn tí ń gbé àwọn ìlú ńlá wọ̀nyẹn ń fi ìbálòpọ̀ oníwà ipá òun ìwà ìbàjẹ́ ṣèwàhù, bí a ti mọ̀ jákèjádò àgbègbè náà. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ tí wọ́n jẹ́ áńgẹ́lì bẹ ọkùnrin olódodo náà, Lọ́ọ̀tì, wò, àwùjọ àwọn ọ̀dọ́kùnrin akọluni pẹ̀lú àwọn àgbàlagbà ọkùnrin gbìyànjú láti jùmọ̀ fipá bá àwọn àlejò Lọ́ọ̀tì lò pọ̀. Ìwà pálapàla bíburú lékenkà wọn bí Jèhófà Ọlọ́run nínú lọ́nà ẹ̀tọ́.—Jẹ́nẹ́sísì 18:20; 19:4, 5, 9.
Bíi Bàbá rẹ̀, ìdí wà fún ọkùnrin pípé náà, Jésù Kristi, láti bínú. Ó yẹ kí tẹ́ńpìlì tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù jẹ́ ibùdó ìjọsìn fún àwọn àyànfẹ́ Ọlọ́run. Ó yẹ kí ó jẹ́ “ilé àdúrà” tí àwọn ènìyàn ti lè mú ẹbọ àti ọrẹ wọn wá fún Ọlọ́run, tí wọ́n sì lè gba ìtọ́ni nípa ọ̀nà rẹ̀ níbẹ̀, kí a sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n. Ká sọ ọ́ lọ́rọ̀ bẹ́ẹ̀, wọ́n lè bá Jèhófà sọ̀rọ̀ ní tẹ́ńpìlì náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn aṣáájú ìsìn ní ọjọ́ Jésù sọ tẹ́ńpìlì náà di “ilé ọjà títà” àti “hòrò àwọn ọlọ́ṣà.” (Mátíù 21:12, 13; Jòhánù 2:14-17) Wọ́n ń jèrè lẹ́nìkọ̀ọ̀kan ní títa àwọn ẹranko tí a ń lò bí ohun ìrúbọ. Ní gidi gan-an, wọ́n ń lọ́ agbo lọ́wọ́ gbà. Nítorí èyí, Ọmọkùnrin Ọlọ́run ní ẹ̀tọ́ lọ́nà pípé nígbà tí ó lé àwọn ọlọ́ṣà wọ̀nyẹn kúrò nínú ilé Bàbá rẹ̀. Lọ́nà tí ó ṣeé lóye, Jésù bínú!
Nígbà Tí Ẹ̀dá Ènìyàn Aláìpé Bá Bínú
Ènìyàn aláìpé náà lè bínú lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan lọ́nà ẹ̀tọ́. Gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Mósè yẹ̀ wò. A ṣẹ̀ṣẹ̀ dá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nídè kúrò ní Íjíbítì lọ́nà ìyanu ni. Jèhófà ti fi bí agbára rẹ̀ ṣe ju ti àwọn ọlọ́run èké Íjíbítì lọ hàn lọ́nà gbígbàfiyèsí nípa dída àjàkálẹ̀ àrùn mẹ́wàá lu àwọn ọmọ Íjíbítì. Ó wá ṣínà fún àwọn Júù láti sá là, nípa pípín Òkun Pupa níyà. Lẹ́yìn náà, ó ṣamọ̀nà wọn gba ẹsẹ̀ Òkè Ńlá Sínáì, níbi tí a ti ṣètò wọn sí orílẹ̀-èdè kan. Ní ṣíṣiṣẹ́ bí alárinà, Mósè lọ sí orí òkè ńlá náà láti gba àwọn òfin Ọlọ́run. Pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn òfin mìíràn, Jèhófà fún Mósè ní Òfin Mẹ́wàá náà, tí “ìka Ọlọ́run” kọ sórí àwọn wàláà òkúta tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yọ jáde lára òkè ńlá náà. Bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, nígbà tí Mósè sọ̀ látòkè, kí ni ó rí? Àwọn ènìyàn náà ti yí sí jíjọ́sìn ère ọmọ màlúù oníwúrà! Ẹ wo bí wọ́n ṣe tètè gbàgbé tó! Ọ̀sẹ̀ díẹ̀ péré ló ṣẹ̀ṣẹ̀ kọjá. Lọ́nà ẹ̀tọ́, “ìbínú Mósè bẹ̀rẹ̀ sí ru.” Ó fọ́ àwọn wàláà òkúta náà túútúú, ó sì ba ère ọmọ màlúù náà jẹ́.—Ẹ́kísódù 31:18; 32:16, 19, 20.
Lákòókò míràn lẹ́yìn náà, Mósè kò ṣàkóso ìbínú rẹ̀ nígbà tí àwọn ènìyàn náà ráhùn nípa àìsí omi. Bí wọ́n ti dá a lágara, ó pàdánù inú tútù, tàbí ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn tí a mọ̀ mọ́ ọn. Èyí ṣamọ̀nà sí àṣìṣe ńlá kan. Dípò kí Mósè gbé Jèhófà ga gẹ́gẹ́ bí Olùpèsè fún Ísírẹ́lì, ó sọ̀rọ̀ tìkanratìkanra sí àwọn ènìyàn náà, ó sì darí àfiyèsí sí ara rẹ̀ àti arákùnrin rẹ̀, Árọ́nì. Nípa bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run rí i pé ó yẹ láti bá Mósè wí. Kò ní jẹ́ kí ó wọ ilẹ̀ ìlérí náà. Lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yí ní Mẹ́ríbà, a kò tún mẹ́nu kàn án mọ́ pé, Mósè kò ṣàkóso ìbínú rẹ̀. Ó ṣe kedere pé, ó ti kọ́gbọ́n.—Númérì 20:1-12; Diutarónómì 34:4; Orin Dáfídì 106:32, 33.
Nítorí náà, ìyàtọ̀ wà láàárín Ọlọ́run àti ènìyàn. Jèhófà lè ‘dẹwọ́ ìbínú rẹ̀’ a sì ṣàpèjúwe rẹ̀ lọ́nà títọ́ bí ẹni tí ó “lọ́ra láti bínú” nítorí pé ìfẹ́ ni ànímọ́ rẹ̀ híhàn gbangba jù lọ, kì í ṣe ìbínú. Ìbínú rẹ̀ máa ń jẹ́ ti òdodo, ó máa ń bẹ́tọ̀ọ́mu, tí ó sì máa ń ṣàkóso. (Ẹ́kísódù 34:6; Aísáyà 48:9; Jòhánù Kíní 4:8) Ọkùnrin pípé náà, Jésù Kristi, máa ń lè ṣàkóso bí ó ṣe ń fi ìbínú rẹ̀ hàn; a ṣàpèjúwe rẹ̀ bí “ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn àyà.” (Mátíù 11:29) Ní ọwọ́ mìíràn, àwọn ènìyàn aláìpé, kódà àwọn ẹni ìgbàgbọ́ bíi Mósè, ti ní ìṣòro ṣíṣàkóso ìbínú wọn.
Bákan náà, àwọn ènìyàn ní gbogbogbòò ń kùnà láti ronú dáradára lórí ohun tí ó lè tìdí rẹ̀ jáde. Ṣíṣàìṣàkóso ìbínú ẹni lè ní àbájáde tí kò bára dé. Fún àpẹẹrẹ, kí ni àwọn ohun tó lè jẹ́ àbájáde híhàn gbangba rẹ̀ bí ọkọ kan kò bá ṣàkóso ìbínú rẹ̀ sí aya rẹ̀ débi tí ó fi lu ògiri lẹ́ṣẹ̀ẹ́, tí ó sì dáhò sí i? Ó ti ba ohun ìní jẹ́. Ó lè dá àpá sí ọwọ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n, ju ìyẹn lọ, ipa wo ni ipò ìbínú rẹ̀ yóò ní lórí ìfẹ́ àti ọ̀wọ̀ tí aya rẹ̀ ní fún un? Wọ́n lè tún ògiri ṣe láàárín ọjọ́ mélòó kan, ọwọ́ rẹ̀ sì lè jinná láàárín ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan; ṣùgbọ́n báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó fún un láti tún jèrè ìgbẹ́kẹ̀lé àti ọ̀wọ̀ aya rẹ̀?
Ní ti gidi, Bíbélì kún fún àpẹẹrẹ àwọn ènìyàn tí wọ́n kùnà láti ṣàkóso ìbínú wọn tí wọ́n sì jìyà àbájáde rẹ̀. Ṣàgbéyẹ̀wò àwọn díẹ̀. A lé Kéènì dà nù lẹ́yìn tí ó pa àbúrò rẹ̀, Ébẹ́lì. Bàbá Síméónì àti Léfì fi wọ́n bú nítorí pé wọ́n pa àwọn ọkùnrin Ṣékémù. Jèhófà da ẹ̀tẹ̀ lu Ùsáyà lẹ́yìn tí Ùsáyà runú sí àwọn àlùfáà tí wọ́n ń gbìyànjú láti tún ojú ìwòye rẹ̀ ṣe. Nígbà tí “inú” Jónà “ru fún ìbínú,” Jèhófà bá a wí. Gbogbo wọn jíhìn fún ìbínú wọn.—Jẹ́nẹ́sísì 4:5, 8-16; 34:25-30; 49:5-7; Kíróníkà Kejì 26:19; Jónà 4:1-11.
Àwọn Kristẹni Yóò Jíhìn
Bákan náà, àwọn Kristẹni lónìí gbọ́dọ̀ jíhìn ohun tí wọ́n bá ṣe fún Ọlọ́run, àti dé àyè kan, fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn. A lè rí èyí gan-an láti inú ọ̀nà tí Bíbélì gbà lo àwọn ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí ó túmọ̀ sí ìbínú. Ọ̀kan lára àwọn ọ̀rọ̀ méjì tí a sábà máa ń lò náà ni or·geʹ. Ní gbogbogbòò, a máa ń túmọ̀ rẹ̀ sí “ìrunú,” ó sì ní èrò ìwàlójúfò àti ìmọ̀ọ́mọ̀, lọ́pọ̀ ìgbà, pẹ̀lú èròǹgbà gbígbẹ̀san. Nítorí náà ni Pọ́ọ̀lù ṣe rọ àwọn Kristẹni ní Róòmù pé: “Ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ṣùgbọ́n ẹ yàgò fún ìrunú [or·geʹ]; nítorí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Tèmi ni ẹ̀san; dájúdájú èmi yóò san pa dà, ni Jèhófà wí.’” Dípò gbígbin àránkan nípa àwọn ará wọn sínú, ó rọ̀ wọ́n láti “fi ire [ṣẹ́gun] ibi.”—Róòmù 12:19, 21.
Ọ̀rọ̀ kejì tí a sábà máa ń lò ni thy·mosʹ. Gbòǹgbò ọ̀rọ̀ náà “ní ìpìlẹ̀ rẹ̀, túmọ̀ sí gbígbéra afẹ́fẹ́, omi, ilẹ̀, àwọn ẹranko, tàbí ènìyàn lọ́nà tí ń ṣèpalára.” Nípa bẹ́ẹ̀, a máa ń ṣàpèjúwe ọ̀rọ̀ náà lónírúurú ọ̀nà gẹ́gẹ́ bí “ìbújáde ìmọ̀lára jàgídíjàgan tìbínútìbínú,” “ìbújáde ìbínú,” tàbí “ìrugùdù èrò ìmọ̀lára, tí ń dí ìṣọ̀kan èrò orí lọ́wọ́, tí ó sì ń fa ìrúkèrúdò agbo ilé àti ti ìlú àti àìfọkànbalẹ̀.” Bí òkè ayọnáyèéfín kan tí ó lè bú gbàù láìṣe kìlọ̀kìlọ̀, kí ó sì tú eérú gbígbóná, òkúta, àti gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀, tí ó lè pani lára, kí ó sọni di aláàbọ̀ ara, kí ó sì pani, jáde, ṣe rí ni ọkùnrin tàbí obìnrin kan tí kò lè sàkóso ìbínú rẹ̀ rí. A lo ẹ̀yà ìsọdọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ náà thy·mosʹ nínú Gálátíà 5:20, níbi tí Pọ́ọ̀lù ti to “ìrufùfù ìbínú” pọ̀ pẹ̀lú “àwọn iṣẹ́ ti ẹran ara” (ẹsẹ 19) mìíràn, bí àgbèrè, ìwà àìníjàánu, àti mímu àmuyíràá. Dájúdájú, ìwà John—tí a ṣàpèjúwe ní ìbẹ̀rẹ̀—ṣàpèjúwe ohun tí ń jẹ́ “ìrufùfù ìbínú” dáradára.
Nítorí náà, irú ojú wo ló yẹ kí ìjọ Kristẹni fi wo àwọn ẹni tí a mọ̀ mọ̀ ọ́n, tí ń hùwà ipá sí ẹlòmíràn tàbí ohun ìní ẹlòmíràn léraléra láìjáwọ́? Ìbínú tí a kò ṣàkóso ń ba nǹkan jẹ́, ó sì ń fìrọ̀rùn yọrí sí ìwà ipá. Nígbà náà, Jésù ní ète rere lọ́kàn tí ó fi wí pé: “Mo wí fún yín pé olúkúlùkù ẹni tí ń bá a lọ ní kíkún fún ìrunú sí arákùnrin rẹ̀ yóò jíhìn fún kóòtù ìgbẹ́jọ́.” (Mátíù 5:21, 22) A rọ àwọn ọkọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín ẹ má sì ṣe bínú sí wọn lọ́nà kíkorò.” Ẹnì kan tí ó ní “ìtẹ̀sí fún ìrunú” kò tóótun gẹ́gẹ́ bí alábòójútó nínú ìjọ. Nítorí náà, kò yẹ kí a wo àwọn ẹni tí wọn kò bá lè ṣàkóso ìbínú wọn bí àpẹẹrẹ fún ìjọ. (Kólósè 3:19; Títù 1:7; Tímótì Kíní 2:8) Ní gidi, lẹ́yìn gbígbé ìṣesí, ọ̀nà ìhùwà, àti bí ìbàjẹ́ tí ẹnì kan ṣe nínú ìgbésí ayé àwọn ẹlòmíràn ṣe le tó wò, a lè yọ ẹni tí ó juwọ́ sílẹ̀ fún ìrufùfù ìbínú, tí a kò ṣàkóso náà níjọ—àbáyọrí apániláyà lèyí ní tòótọ́.
Ǹjẹ́ John tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀, wá mú èrò ìmọ̀lára rẹ̀ wá sábẹ́ àkóso nígbà kankan bí? Ó ha lè dẹwọ́ kíkówọnú ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú, ayáragbénidè tí ń burú sí i rẹ̀ nígbà kankan bí? Ó bani nínú jẹ́ pé pípariwomọ́ni náà dé orí títaari ẹni àti títini dà nù. Nínàka-àbùkù-síni yọrí sí fífìkagúnni lọ́nà tí ń dunni, tí ó sì ń fa àpá lára. John ń lo ìṣọ́ra láti má ṣe dá àpá sí àwọn ibi tí a lè tètè rí, ó sì gbìyànjú láti fi ìwà rẹ̀ bò. Síbẹ̀síbẹ̀, àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ó fàbọ̀ sórí gbígbá, kíkànlẹ́ṣẹ̀ẹ́, fífa irun àti bíbá a lò ní àwọn ọ̀nà tí ó tún burú jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ginger kò gbé pọ̀ pẹ̀lú John mọ́.
Kò yẹ kí èyí ṣẹlẹ̀. Ó ti ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n wà nínú irú ipò tí ó jọ èyí láti ṣàkóso ìbínú wọn. Nítorí náà, ẹ wo bí ó ti ṣe kókó tó láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ pípé ti Jésù Kristi. Kò ní ìrufùfù ìrunú tí a kò ṣàkóso rí. Ìbínú rẹ̀ máa ń jẹ́ lórí òdodo; ó máa ń ṣàkóso ìbínú rẹ̀. Lọ́nà tí ó bọ́gbọ́n mu, Pọ́ọ̀lù gba gbogbo wa nímọ̀ràn pé: “Ẹ fi ìrunú hàn, síbẹ̀ kí ẹ má sì ṣe ṣẹ̀; ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá yín nínú ipò ìtánnísùúrù.” (Éfésù 4:26) Ní mímọ pé a ní ààlà lọ́nà ìwọ̀ntúnwọ̀nsì gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn, àti pé a óò ká ohun tí a bá fúnrúgbìn, a ní ìdí rere láti kó ìbínú níjàánu.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ pa dà.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 18]
Saul Attempts the Life of David/The Doré Bible Illustrations/Dover Publications, Inc.