ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 6/15 ojú ìwé 26-29
  • Ìdájọ́ Òdodo—Nígbà Wo Àti Lọ́nà Wo?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìdájọ́ Òdodo—Nígbà Wo Àti Lọ́nà Wo?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìdájọ́ Wíwọ́
  • Ètò Ìdájọ́ Ènìyàn —Pẹ̀lú Àìlera Ènìyàn
  • “Èmi, Jèhófà, Nífẹ̀ẹ́ Ìdájọ́ Òdodo”
  • Ṣé Ìdájọ́ Òdodo Máa Wà?
    Àkójọ Àpilẹ̀kọ àti Fídíò
  • “Ó Ń Ṣe Ìdájọ́ Òdodo Ní Gbogbo Ọ̀nà Rẹ̀”
    Sún Mọ́ Jèhófà
  • Fara Wé Jèhófà—Máa Ṣe Òdodo àti Ìdájọ́ Òdodo
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Jèhófà—Orísun Òdodo àti Ìdájọ́ Òdodo
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 6/15 ojú ìwé 26-29

Ìdájọ́ Òdodo—Nígbà Wo Àti Lọ́nà Wo?

KÒ YẸ kí ẹ̀rù ìdájọ́ òdodo ba aláìṣẹ̀. Ní tòótọ́, àwọn ènìyàn níbi gbogbo ní ìdí láti dúpẹ́ bí orílẹ̀ èdè wọ́n bá ní ètò ìdájọ́ tí ń gbìyànjú láti rí sí i pé a ṣe ìdájọ́ òdodo. Irú ètò bẹ́ẹ̀ wé mọ́ àwọn òfin tí a là lẹ́sẹẹsẹ, àwọn ọlọ́pàá agbófinró, àti àwọn ilé ẹjọ́ tí yóò ṣe ìdájọ́. Àwọn Kristẹni tòótọ́ ń bọ̀wọ̀ fún ètò ìdájọ́ tí ó wà ní ibi tí wọ́n ń gbé, wọ́n ń ṣègbọràn sí ìmọ̀ràn Bíbélì pé kí wọ́n “wà lábẹ́ àwọn aláṣẹ onípò gíga.”—Róòmù 13:1-7.

Àmọ́ ṣá o, àwọn ètò ìdájọ́ ní onírúurú orílẹ̀ èdè ti ṣe àwọn àṣìṣe tí ń pani lára, tí ó sì ń dójú tini.a Dípò fífìyàjẹ ẹlẹ́bi, kí a sì dáàbòbo aláre, ọ̀pọ̀ ìgbà ni a ti fìyà jẹ aláre fún ẹ̀ṣẹ̀ tí kò dá. Àwọn mìíràn ti ṣẹ̀wọ̀n fún ọ̀pọ̀ ọdún, kí a tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá tú wọn sílẹ̀ bí wọ́n ti fẹ́ parí ọdún tí wọ́n dá fún wọn lẹ́wọ̀n, nítorí iyèméjì tí ó lágbára tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ dìde ní ti bóyá wọ́n jẹ̀bi àti bóyá ó yẹ kí wọ́n tilẹ̀ dájọ́ ẹ̀bi fún wọn rárá. Fún ìdí yìí, ọ̀pọ̀ ènìyàn ń béèrè pé, Ìdájọ́ òdodo yóò ha wà láé fún gbogbo ènìyàn bí? Bí yóò bá wà, nígbà wo ni àti lọ́nà wo? Ta ni a lè gbẹ́kẹ̀ lé pé kí ó dáàbòbo aláìṣẹ̀? Ìrètí wo sì ni ó wà fún àwọn tí a kò fi ìdájọ́ òdodo bá lò?

Ìdájọ́ Wíwọ́

Ní àwọn ọdún 1980, Germany ní ìrírí “ọ̀kan lára ọ̀nà ìdájọ́ tí ó ru ìmọ̀lára sókè jù lọ ní sáà ẹ̀yìn ogun,” nígbà tí wọ́n sọ ìyá kan sẹ́wọ̀n gbére fún pípa ọmọbìnrin rẹ̀ méjèèjì. Ṣùgbọ́n, ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, wọ́n ṣe àtúnyẹ̀wò àwọn ẹ̀rí tí wọ́n fi dá a lẹ́jọ́, wọ́n sì tú u sílẹ̀ títí wọ́n yóò fi tún ẹjọ́ náà gbọ́. Ìwé ìròyìn náà, Die Zeit ròyìn ní ọdún 1995 pé ìdájọ́ àkọ́kọ́ “lè jẹ́ ṣíṣi ẹjọ́ dá.” Títí di ìgbà tí a ń kọ ìwé yìí, obìnrin yìí ti lo ọdún mẹ́sàn-án nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n láìmọ̀ bóyá òun jẹ̀bi tàbí òun jàre.

Ní alẹ́ ọjọ́ kan ní November 1974, bọ́ǹbù méjì bú gbàmù ní àárín gbùngbùn ìlú Birmingham, ní ilẹ̀ England, ó sì pa ènìyàn 21. Chris Mullen, tí ó jẹ́ mẹ́ńbà Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin, kọ̀wé pé ó jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ tí “ẹnikẹ́ni ní ìlú Birmingham kò ní gbàgbé láé.” Lẹ́yìn náà, “a dájọ́ ẹ̀bi fún àwọn ọkùnrin mẹ́fà tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀ nítorí ìpànìyàn tí ó burú jù lọ nínú ìtàn ilẹ̀ Britain.” Lẹ́yìn náà, a wọ́gi lé ìdálẹ́bi náà—ṣùgbọ́n ó jẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n ti kọ́kọ́ fi imú dánrin fún ọdún 16!

Ken Crispin, tí í ṣe amòfin, ròyìn ẹjọ́ kan tí ó “gba àfiyèsí àwọn aráàlú lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ nínú àkọsílẹ̀ ọ̀ràn òfin ní ilẹ̀ Australia.” Ìdílé kan pabùdó sítòsí àgbègbè Ayers Rock nígbà tí ọmọ wọn jòjòló dàwátì, tí ó sọnù gbé. Wọ́n fẹ̀sùn ìpànìyàn kan ìyá ọmọ náà, wọ́n dá a lẹ́jọ́ ẹ̀bi, wọ́n sì sọ ọ́ sẹ́wọ̀n gbére. Ní 1987, lẹ́yìn tí ó ti ṣe ọdún mẹ́ta lẹ́wọ̀n, ìwádìí kan tí ìjọba ṣe fi hàn pé àwọn ẹ̀rí tí wọ́n fi dá a lẹ́jọ́ kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀. Wọ́n tú u sílẹ̀, wọ́n sì dárí jì í.

Wọ́n pa obìnrin ọmọ ọdún 18 kan ní gúúsù United States ní ọdún 1986. Wọ́n fẹ̀sùn ìpànìyàn yìí kan ọkùnrin kan tí yóò ti máa sún mọ́ ẹni àádọ́ta ọdún, wọ́n sọ pé ó jẹ̀bi, wọ́n sì dá ẹjọ́ ikú fún un. Ó lo ọdún mẹ́fà nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n ti àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí a dá ẹjọ́ ikú fún, kí wọ́n tó wá mọ̀ pé kò mọ nǹkan kan rárá nípa ìwà ọ̀daràn náà.

Àṣìṣe wọ̀nyí nínú ọ̀ràn ìdájọ́ ha wọ́pọ̀ bí? David Rudovsky ti Ilé Ìwé Àwọn Amòfin ní Yunifásítì Pennsylvania sọ pé: “Mo ti wà lẹ́nu iṣẹ́ yìí fún nǹkan bí ọdún 25, mo sì ti rí àìmọye ẹjọ́. Èmi yóò sọ pé àwọn tí a dá lẹ́jọ́ ẹ̀bi, ṣùgbọ́n tí wọ́n jàre ní tòótọ́ . . . yóò jẹ́ nǹkan bí ìdámárùn-ún sí mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún.” Crispin béèrè ìbéèrè tí ń dani láàmú yìí: “Àwọn aláìmọwọ́mẹsẹ̀ mìíràn ha wà tí wọ́n fọwọ́ lẹ́rán nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n bí?” Báwo ni irú àṣìṣe burúkú bẹ́ẹ̀ ṣe lè ṣẹlẹ̀?

Ètò Ìdájọ́ Ènìyàn —Pẹ̀lú Àìlera Ènìyàn

Ní ọdún 1991, Ilé Ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ti ilẹ̀ Britain là á mọ́lẹ̀ pé, “kò sí ètò ènìyàn tí ó jẹ́ pípé.” Bí òtítọ́ àti ìdúróṣinṣin àwọn ènìyàn tí ó ṣe ètò ìdájọ́ kan, tí wọ́n sì ń lò ó bá ti mọ, bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni òtítọ́ àti ìdúróṣinṣin ètò ìdájọ́ ọ̀hún yóò mọ. Àwọn ènìyàn kò lè ṣàìṣe àṣìṣe àti àbòsí, kí wọ́n sì ní ẹ̀tanú. Fún ìdí yìí, kò yẹ kí ó yà wá lẹ́nu pé ètò ìdájọ́ ènìyàn ní àwọn àléébù kan náà yìí. Gbé ohun tí ó tẹ̀ lé e yìí yẹ̀ wò.

Gẹ́gẹ́ bí Adájọ́ Rolf Bender ti Germany ti wí, nínú ìpín 95 nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo ẹjọ́ tí ó jẹ mọ́ ìwà ọ̀daràn, ọ̀rọ̀ ẹnu àwọn ẹlẹ́rìí ni a ń gbé ìpinnu kà. Ṣùgbọ́n irú àwọn ẹlẹ́rìí bẹ́ẹ̀ ha ṣeé gbára lé nígbà gbogbo bí? Adájọ́ Bender kò rò bẹ́ẹ̀. Ó fojú díwọ̀n pé ìlàjì àwọn ẹlẹ́rìí tó wá ń jẹ́rìí ní ilé ẹjọ́ kì í sọ òtítọ́. Bernd Schünemann, tí í ṣe àgbà ọ̀jọ̀gbọ́n nípa òfin tí ó jẹ mọ́ ìwà ọ̀daràn ní Yunifásítì ti Munich, ní Germany, sọ ọ̀rọ̀ tí ó jọ bẹ́ẹ̀. Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan pẹ̀lú ìwé ìròyìn náà, Die Zeit, Schünemann fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ohun tí àwọn ẹlẹ́rìí bá sọ ni ẹ̀rí pàtàkì—bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ṣeé gbára lé. “Èmi yóò sọ pé olórí ìdí tí a fi ń ṣi ẹjọ́ dá ni pé adájọ́ máa ń gbára lé ọ̀rọ̀ àwọn ẹlẹ́rìí tí kò ṣeé gbára lé.”

Àwọn ẹlẹ́rìí a máa ṣàṣìṣe; bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ọlọ́pàá. Àwọn ọlọ́pàá sábà máa ń mú àwọn ènìyàn nígbà tí wọ́n bá rí i pé àwọn kò rí ibi yẹ̀ ẹ́ sí, pàápàá jù lọ nígbà tí a bá hu ìwà ọ̀daràn tí ó bí àwọn aráàlú nínú gan-an. Nínú irú ipò bẹ́ẹ̀, ọlọ́pàá kan lè jìn sínú ọ̀fìn kíkó ayédèrú ẹ̀rí jọ, tàbí kí ó fipá mú ẹnì kan láti gbà pé ní tòótọ́ ni òun ṣe aṣemáṣe náà. Nígbà tí a tú àwọn ọkùnrin mẹ́fà tí a dájọ́ ẹ̀bi fún nítorí àwọn bọ́ǹbù tí a yìn ní ìlú Birmingham sílẹ̀, ìwé ìròyìn ilẹ̀ Britain náà, The Independent, gbé àkọlé yìí jáde: “Ọlọ́pàá Oníwà Ìbàjẹ́ Jẹ̀bi Ẹjọ́ Tí A Dá Àwọn Ènìyàn Mẹ́fà.” Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn náà, The Times, ti wí: “Àwọn ọlọ́pàá purọ́, wọ́n dìtẹ̀, wọ́n sì ṣẹ̀tàn.”

Nínú àwọn ẹjọ́ kan, ẹ̀tanú lè mú kí àwọn ọlọ́pàá àti àwọn aráàlú fura sí àwọn ènìyàn ìran kan, ẹ̀sìn kan, tàbí orílẹ̀ èdè kan. Gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn náà, U.S.News & World Report ti wí, wíwá ojútùú sí ìwà ọ̀daràn kan lè wá di “ọ̀ràn ẹ̀tanú sí ìran kan dípò kí ó jẹ́ ọ̀ràn ọgbọ́n orí.”

Gbàrà tí ẹjọ́ kan bá ti dé ilé ẹjọ́, kì í ṣe ohun tí àwọn ẹlẹ́rìí sọ nìkan ni ó lè nípa lórí ìpinnu tí a ó ṣe, ṣùgbọ́n ẹ̀rí tí ó bá ìlànà sáyẹ́ǹsì mu tún lè nípa lórí rẹ̀. Nísinsìnyí tí a ti ń lo ìjiyàn tí a gbé ka ìmọ̀ ìṣègùn dídíjú nínú ilé ẹjọ́, a lè rọ adájọ́ pé kí ó gbé ìpinnu ẹ̀bi tàbí àre ka ẹ̀kọ́ nípa bí ọta ìbọn ṣe ń fò, tàbí ìyàtọ̀ tí ó wà láàárín ìlà ọwọ́, ìṣọwọ́-kọ̀wé, àwọn èròjà tíntìntín inú ẹ̀jẹ̀, àwọ̀ irun, àwọn fọ́nrán aṣọ, tàbí àwọn ọ̀wọ́ èròjà DNA. Agbẹjọ́rò kan sọ pé àwọn ilé ẹjọ́ dojú kọ “àwùjọ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì apàṣẹwàá tí ń ṣàlàyé àwọn ìlànà dídíjú gan-an.”

Ní àfikún sí i, ìwé ìròyìn náà, Nature sọ pé kì í ṣe gbogbo onímọ̀ sáyẹ́ńsì ni ó fohùn ṣọ̀kan lórí ìtumọ̀ tí a ń fún àwọn ẹ̀rí tí a gbé ka ìmọ̀ ìṣègùn dídíjú. “Àríyànjiyàn gidi lè wà láàárín àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tí ń fi ìmọ̀ ìṣègùn ṣèwádìí ìwà ọ̀daràn.” Ó mà ṣe o, pé “àjàǹbàkù ẹ̀rí tí a gbé ka ìmọ̀ ìṣègùn dídíjú ti ṣokùnfa ọ̀pọ̀ àjàǹbàkù ìdájọ́.”

Ibi yòówù tí a ń gbé, gbogbo ètò ìdájọ́ tí a ń lò lọ́wọ́lọ́wọ́ fi àbùkù ẹ̀dá ènìyàn hàn. Nítorí náà, ta ni a lè gbẹ́kẹ̀ lé pé kí ó dáàbòbo aláìmọwọ́mẹsẹ̀? A ha lè retí láé láti rí ìdájọ́ òdodo? Ìrètí wo sì ni ó wà fún àwọn tí a dá lẹ́bi lọ́nà àìtọ́?

“Èmi, Jèhófà, Nífẹ̀ẹ́ Ìdájọ́ Òdodo”

Bí a kò bá fi ìdájọ́ òdodo bá ìwọ tàbí mẹ́ńbà ìdílé rẹ lò, Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù, Ọmọ rẹ̀, mọ ohun tí o ń fojú winá rẹ̀. Àìṣèdájọ́ òdodo tí ó múni gbọ̀n rìrì jù lọ ṣẹlẹ̀ nígbà tí a pa Kristi lórí òpó igi oró. Àpọ́sítélì Pétérù sọ fún wa pé Jésù “kò dá ẹ̀ṣẹ̀ kankan.” Síbẹ̀, àwọn ẹlẹ́rìí èké fẹ̀sùn kàn án, a dá a lẹ́bi, a sì pa á.—1 Pétérù 2:22; Mátíù 26:3, 4, 59-62.

Finú wòye ìmọ̀lára tí Jèhófà ní nípa irú ìyà tí wọ́n fi jẹ Ọmọ rẹ̀! Ìdájọ́ òdodo jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ànímọ́ pàtàkì Jèhófà. Bíbélì sọ fún wa pé: “Gbogbo ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìdájọ́ òdodo.”—Diutarónómì 32:4; Sáàmù 33:5.

Jèhófà fún ilẹ̀ Ísírẹ́lì ní ètò ìdájọ́ títayọ. Ní ti ọ̀ràn ìpànìyàn tí a kò rí ojútùú sí, ẹbọ ni a fi ń ṣètùtù ikú náà. A kì í fagbára mú àwọn adájọ́ láti wá ojútùú sí gbogbo ìwà ọ̀daràn láìka òtítọ́ náà sí pé ó lè yọrí sí dídẹ́bi fún aláìṣẹ̀. A kò lè fi ẹ̀rí tí kò ṣe tààràtà tàbí tí a gbé ka ìlànà sáyẹ́ǹsì dá ẹnikẹ́ni lẹ́jọ́ ìpànìyàn; ó kéré tán, a nílò ẹlẹ́rìí méjì tí ọ̀ràn ṣojú wọn. (Diutarónómì 17:6; 21:1-9) Àpẹẹrẹ wọ̀nyí fi hàn pé Jèhófà ní ọ̀pá ìdiwọ̀n gíga, ó sì máa ń fẹ́ láti rí i dájú pé a ṣe ìdájọ́ òdodo. Ní tòótọ́, ó sọ pé: “Èmi, Jèhófà, nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo.”—Aísáyà 61:8.

Àmọ́ ṣá o, ọwọ́ àwọn ènìyàn aláìpé bí tiwa ni ètò ìdájọ́ Ísírẹ́lì wà. Wọ́n gbé ìdájọ́ gbòdì nígbà mìíràn. Sólómọ́nì Ọba kọ̀wé pé: “Bí ìwọ bá rí ìnilára èyíkéyìí tí a ṣe sí ẹni tí ó jẹ́ aláìnílọ́wọ́ àti fífi ipá mú ìdájọ́ àti òdodo kúrò ní àgbègbè abẹ́ àṣẹ, má ṣe jẹ́ kí kàyéfì ṣe ọ́ lórí àlámọ̀rí náà.”—Oníwàásù 5:8.

Ó ṣeé ṣe fún Jèhófà láti mú àìṣèdájọ́ òdodo tí wọ́n ṣe sí Ọmọ rẹ̀ tọ́. Ìdánilójú èyí fún Jésù lókun, ẹni tí ó jẹ́ pé “nítorí ìdùnnú tí a gbé ka iwájú rẹ̀, ó fara da òpó igi oró.” Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ìfojúsọ́nà aláyọ̀ ti gbígbé nínú párádísè ilẹ̀ ayé lábẹ́ ìṣàkóso Mèsáyà, níbi tí ìdájọ́ òdodo yóò ti gbilẹ̀, lè fún wa lókun láti fara da gbígbọ́ tàbí kódà níní ìrírí àìṣèdájọ́ òdodo nínú ètò ògbólógbòó yìí. Kò sí ọṣẹ́ tàbí èṣe tí Jèhófà kò lè wò sàn ní àkókò tí ó tọ́ lójú rẹ̀. Kódà àwọn tí wọ́n pàdánù ìwàláàyè wọn nípasẹ̀ àṣìṣe nínú ìdájọ́ lè ní àjíǹde.—Hébérù 12:2; Ìṣe 24:15.

Bí a bá jìyà àìṣèdájọ́ òdodo, a lè dúpẹ́ pé ọ̀pọ̀ ètò ìdájọ́ ní àwọn ọ̀nà tí ó lè mú kí ó ṣeé ṣe láti mú ọ̀ràn náà tọ́. Àwọn Kristẹni lè lo irú ọ̀nà bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n, wọ́n máa ń rántí òtítọ́ yìí: Àwọn ètò ìdájọ́ aláìpé fi hàn pé ẹgbẹ́ àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn nílò àtúntò pàtàkì. Èyí yóò ṣẹlẹ̀ láìpẹ́—ní ọwọ́ Ọlọ́run.

Láìpẹ́, Jèhófà yóò fòpin sí ètò àwọn nǹkan aláìṣèdájọ́ òdodo yìí, òun yóò sì fi ètò tuntun ‘tí òdodo yóò máa gbé’ rọ́pò rẹ̀. A lè ní ìdánilójú pátápátá pé Ẹlẹ́dàá wa yóò ṣe ìdájọ́ òdodo nígbà náà nípasẹ̀ Jésù Kristi, Ọba rẹ̀ tí í ṣe Mèsáyà. Ìdájọ́ òdodo fún gbogbo ènìyàn kù sí dẹ̀dẹ̀! A mà dúpẹ́ fún ìfojúsọ́nà yìí o.—2 Pétérù 3:13.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ní ti gbogbo ẹjọ́ tí a mẹ́nu kàn níhìn-ín, kì í ṣe pé Ilé Ìṣọ́ ń sọ pé ẹnì kan jàre tàbí ẹnì kan jẹ̀bi, bẹ́ẹ̀ sì ni ìwé ìròyìn yìí ko ka ètò ìdájọ́ orílẹ̀-èdè kan sí èyí tí ó dára ju ti òmíràn lọ. Ìyẹn nìkan kọ́, ìwé ìròyìn yìí kì í ṣe alágbàwí ọ̀nà ìfìyàjẹni kan gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó dára jù òmíràn lọ. Ṣe ni àpilẹ̀kọ yìí wulẹ̀ ń sọ òtítọ́ ohun tí a gbọ́ pé ó ṣẹlẹ̀ ní àkókò tí a ń kọ ọ́.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 27]

Àwọn ètò ìdájọ́ tí kò mọ́yán lórí —pa pọ̀ pẹ̀lú ìjọba oníwà ìbàjẹ́, ẹ̀sìn ẹlẹ́gbin, àti ètò ìṣòwò onímàgòmágó—fi hàn pé àwùjọ ènìyàn nílò àtúntò pàtàkì

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 28]

Ìtùnú Láti Inú Ìwé Mìmọ́

Ní November 1952, Derek Bentley àti Christopher Craig fọ́ ilé ìkẹ́rùsí kan ní ìlú Croydon, nítòsí London, England. Bentley jẹ́ ọmọ ọdún 19, Craig sì jẹ́ ọmọ ọdún 16. A pe àwọn ọlọ́pàá, ṣùgbọ́n Craig yìnbọn pa ọ̀kan lára àwọn ọlọ́pàá náà. Craig ṣẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́sàn-án, ṣùgbọ́n wọ́n yẹgi mọ́ Bentley lẹ́sẹ̀ ní January 1953 nítorí ìpànìyàn náà.

Iris, tí í ṣe arábìnrin Bentley, fi 40 ọdún ké gbàjarè pé arákùnrin òun kọ́ ni ó pànìyàn. Ní ọdún 1993, Ọbabìnrin tọrọ àforíjì fún ìdájọ́ náà, ó gbà pé a kì bá ti yẹgi mọ́ Derek Bentley lẹ́sẹ̀ rárá. Iris Bentley kọ̀wé nípa ẹjọ́ náà nínú ìwé náà, Let Him Have Justice, pé:

“Ní nǹkan bí ọdún kan ṣáájú ìyìnbọn pa ọlọ́pàá náà, Derek pàdé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ní ojú pópó . . . Arábìnrin Lane ń gbé nítòsí wa ní Òpópónà Fairview, ó sì ké sí Derek wá sí ilé rẹ̀ láti wá gbọ́ àwọn ìtàn Bíbélì. . . . Ohun tí ó ṣèrànwọ́ ni pé àwọn ìtàn Bíbélì tí Arábìnrin Lane ké sí i wá gbọ́ ni a ti kà sínú ẹ̀rọ ìgbohùnsílẹ̀, ó sì yá Derek ní àwọn àwo náà [níwọ̀n bí Derek kò ti lè kàwé já gaara]. . . . Derek máa ń padà wálé wá sọ fún mi nípa àwọn nǹkan tí obìnrin náà sọ fún un, àwọn nǹkan bíi a óò tún padà wá lẹ́yìn tí a bá kú.”

Iris Bentley bẹ arákùnrin rẹ̀ wò nínú ẹ̀wọ̀n lẹ́yìn tí a dá ẹjọ́ ikú fún un. Kí ni ìmọ̀lára Derek? “Àwọn nǹkan tí Arábìnrin Lane sọ fún un ràn án lọ́wọ́ ní àwọn ọjọ́ díẹ̀ wọ̀nyẹn tí ó gbẹ̀yìn.”—Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.

Bí o bá jìyà nítorí ṣíṣi ẹjọ́ dá, yóò dára kí o máa ka àwọn òtítọ́ inú Bíbélì, kí o sì máa ṣe àṣàrò lórí wọn. Èyí lè pèsè ìtùnú ńláǹlà, nítorí pé Jèhófà Ọlọrun ni “Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo, ẹni tí ń tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa.”—2 Kọ́ríńtì 1:3, 4.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Àìṣèdájọ́ òdodo tí ó múni gbọ̀n rìrì ṣẹlẹ̀ nígbà tí a pa Kristi

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́