ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 9/1 ojú ìwé 4-7
  • Ǹjẹ́ O Lè Gbára Lé Ẹ̀rí-ọkàn rẹ?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ O Lè Gbára Lé Ẹ̀rí-ọkàn rẹ?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Kíkọ́ Ẹ̀rí Ọkàn Lẹ́kọ̀ọ́
  • Ríronú Bí Ọlọ́run Ti Ń Ronú
  • Ìrànwọ́ fún Kíkọ́ Ẹ̀rí Ọkàn Lẹ́kọ̀ọ́
  • Níní “Èrò Inú Ti Kristi”
  • Jíjàǹfààní Ẹ̀rí Ọkàn Tí A Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́
  • Bó O Ṣe Lè Ní Ẹ̀rí Ọkàn Rere
    ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
  • Ǹjẹ́ o Kọ́ Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ Dáadáa?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ Ń sọ̀rọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kọ́ Ẹ̀rí Ọkàn Mi?
    Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 9/1 ojú ìwé 4-7

Ǹjẹ́ O Lè Gbára Lé Ẹ̀rí-ọkàn rẹ?

BÍ NǸKAN kò bá ṣe ìhùmọ̀ atọ́ka, irin iṣẹ́ tí ó ṣeé gbíyè lé ni ó jẹ́. Àríwá ni ọwọ́ rẹ̀, tí àgbègbè agbára òòfà ilẹ̀ ayé ń darí, sábà máa ń tọ́ka sí. Àwọn arìnrìn-àjò lè wá tipa bẹ́ẹ̀ gbẹ́kẹ̀ lé ìhùmọ̀ atọ́ka náà láti darí wọn sọ́nà nígbà tí kò bá sí ààlà ilẹ̀ tí yóò tọ́ wọn sọ́nà. Àmọ́, kí ni yóò ṣẹlẹ̀ bí a bá gbé ẹ̀mọ́ kan sẹ́gbẹ̀ẹ́ ìhùmọ̀ atọ́ka náà? Ọwọ́ rẹ̀ yóò yí sápá ibi tí ẹ̀mọ́ náà wà dípò kí ó tọ́ka sí àríwá. Kì í tún ṣe atọ́nisọ́nà tí ó ṣeé fọkàn tẹ̀ mọ́.

Ohun kan náà lè ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀rí ọ̀kan ènìyàn. Ẹlẹ́dàá fi agbára yìí sínú wa láti máa ṣiṣẹ́ bí atọ́nisọ́nà tí ó ṣeé fọkàn tẹ̀. Níwọ̀n bí a ti dá wa ní àwòrán Ọlọ́run, ó yẹ kí ẹ̀rí-ọkàn wa máa darí wa síbi tí ó tọ́ nígbà tí a bá ní ìdí láti ṣe ìpinnu. Ó yẹ kí ó sún wa láti fi àwọn ìlànà Ọlọ́run hàn. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27) Ó sábà máa ń ṣe bẹ́ẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, Kristẹni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé, àwọn kan tí wọn kò tilẹ̀ ní òfin Ọlọ́run tí a mí sí ń “ṣe àwọn ohun tí ó jẹ́ ti òfin lọ́nà ti ẹ̀dá.” Kí ló mú kí ó rí bẹ́ẹ̀? Nítorí pé “ẹ̀rí-ọkàn wọn ń jẹ́ wọn lẹ́rìí.”—Róòmù 2:14, 15.

Bí ó ti wù kí ó rí, kì í ṣe gbogbo ìgbà tí ó yẹ kí ẹ̀rí-ọkàn máa gúnni ní kẹ́ṣẹ́ ni ó ń ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí àìpé ẹ̀dá, a máa ń tẹ̀ síhà ṣíṣe àwọn ohun tí a mọ̀ pé kò yẹ. Pọ́ọ̀lù jẹ́rìí sí èyí ní wíwí pé: “Ní ti gidi, mo ní inú dídùn sí òfin Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú ẹni tí mo jẹ́ ní inú, ṣùgbọ́n mo rí òfin mìíràn nínú àwọn ẹ̀yà ara mi tí ń bá òfin èrò inú mi jagun, tí ó sì ń mú mi lọ ní òǹdè fún òfin ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wà nínú àwọn ẹ̀yà ara mi.” (Róòmù 7:22, 23) Bí ìfẹ́ ọkàn tí kò tọ́ bá ń sún wa ṣe àwọn ohun tí kò tọ́ léraléra, ẹ̀rí-ọkàn wa lè bẹ̀rẹ̀ sí kú díẹ̀díẹ̀, kí ó sì wá jásí pé kò ní máa sọ fún wa mọ́ pé irú ìwà bẹ́ẹ̀ kò dára.

Bí a tilẹ̀ jẹ́ aláìpé, a lè fi àwọn ìlànà Ọlọ́run tọ́ ẹ̀rí-ọkàn wa sọ́nà. Ní ti gidi, ó ṣe pàtàkì pé kí a ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹ̀rí ọkàn tí a kọ́ dáradára, tí ó sì mọ́ ń mú kí a ní ìbátan onífẹ̀ẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run, ó sì tún pọndandan fún ìgbàlà wa. (Hébérù 10:22; 1 Pétérù 1:15, 16) Síwájú sí i, ẹ̀rí-ọkàn rere yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tí ó bọ́gbọ́n mu nínú ìgbésí ayé wa, tí yóò mú kí a ní àlàáfíà àti ayọ̀. Onísáàmù sọ nípa ẹnì kan tí ó ní irú ẹ̀rí-ọkàn yẹn pé: “Òfin Ọlọ́run rẹ̀ ń bẹ ní ọkàn-àyà rẹ̀; àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ kì yóò gbò yèpéyèpé.”—Sáàmù 37:31.

Kíkọ́ Ẹ̀rí Ọkàn Lẹ́kọ̀ọ́

Kíkọ́ ẹ̀rí-ọkàn lẹ́kọ̀ọ́ kọjá wíwulẹ̀ há àwọn òfin kan sórí, kí a sì máa tẹ̀ lé wọn fínnífínní. Ohun tí àwọn Farisí ṣe nígbà ayé Jésù nìyẹn. Àwọn aṣáájú ìsìn wọ̀nyí mọ Òfin, wọ́n sì ti gbé òfin àtọwọ́dá tí ó kún rẹ́rẹ́ kalẹ̀, tí ó ṣeé ṣe kí ó wà fún ríran àwọn ènìyàn náà lọ́wọ́ kí wọ́n má bàa rú Òfin. Ìdí nìyẹn tí wọn kò fi jáfara láti ṣàwáwí nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ń ya ọkà ní ọjọ́ Sábáàtì, tí wọ́n sì ń jẹ erín ọkà. Wọ́n sì pe Jésù níjà nígbà tí ó wo ọkùnrin kan tí ọwọ́ rẹ̀ rọ sàn lọ́jọ́ Sábáàtì. (Mátíù 12:1, 2, 9, 10) Wọ́n là á sílẹ̀ nínú ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Farisí pé ohun méjèèjì tí wọ́n ṣe yìí jẹ́ rírú òfin kẹrin.—Ẹ́kísódù 20:8-11.

Ó hàn gbangba pé àwọn Farisí kọ́ nípa Òfin. Àmọ́, ṣe àwọn ìlànà Ọlọ́run tọ́ ẹ̀rí-ọkàn wọn sọ́nà? Ó dájú pé kò rí bẹ́ẹ̀! Kódà, gbàrà tí àwọn Farisí náà ṣe lámèyítọ́ tí kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ nípa ohun tí wọ́n rò pé ó jẹ́ ìrúfin Sábáàtì tán, wọ́n gbìmọ̀ ibi sí Jésù “kí wọ́n lè pa á run.” (Mátíù 12:14) Rò ó wò ná—àwọn aṣáájú ìsìn olùṣògo ara-ẹni wọ̀nyí fi ìbínú hàn sí jíjẹ ọkà tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ já àti sí wíwo ènìyàn sàn lọ́jọ́ Sábáàtì; àmọ́ ẹ̀rí-ọkàn wọn kò sì gún wọn ní kẹ́ṣẹ́ nípa ìgbìdánwò láti pa Jésù!

Àwọn olórí àlùfáà náà fi irú èrò tí a lọ́ lọ́rùn kan náà hàn. Àwọn ọkùnrin oníwà ìbàjẹ́ wọ̀nyí kò ronú rárá pé àwọn jẹ̀bi nígbà tí wọ́n mú 30 owó fàdákà fún Júdásì láti inú ìṣúra owó tẹ́ńpìlì kí ó lè fi Jésù lé wọn lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n nígbà tí Júdásì dá owó náà padà láìròtẹ́lẹ̀, tí ó dà á sínú tẹ́ńpìlì, ọ̀ràn nípa òfin bẹ̀rẹ̀ sí bá ẹ̀rí-ọkàn wọn jà. Wọ́n sọ pé: “Kò bófin mu láti dà wọ́n sínú ibi ìṣúra ọlọ́wọ̀, nítorí pé owó ẹ̀jẹ̀ ni wọ́n.” (Mátíù 27:3-6) Ó dájú pé àwọn olórí àlùfáà dààmú pé owó Júdásì ti wá di aláìmọ́. (Fi wé Diutarónómì 32:18.) Síbẹ̀, àwọn ènìyàn yìí kan náà kò rí ohun tí ó burú nínú sísanwó kí a lè fa Ọmọ Ọlọ́run lé wọn lọ́wọ́!

Ríronú Bí Ọlọ́run Ti Ń Ronú

Àwọn àpẹẹrẹ tí ó wà lókè yìí fi hàn pé kíkọ́ ẹ̀rí-ọkàn ń béèrè ju kíkó àwọn ohun tí a gbọ́dọ̀ ṣe àti èyí tí a kò gbọ́dọ̀ ṣe sọ́kàn. Òtítọ́ ni pé mímọ àwọn òfin Ọlọ́run ṣe pàtàkì, ṣíṣègbọràn sí wọn sì pọndandan fún ìgbàlà. (Sáàmù 19:7-11) Àmọ́, ní àfikún sí kíkọ́ òfin Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ mú ọkàn-àyà wa bá èrò Ọlọ́run ṣọ̀kan. Nígbà náà, a lè rí ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà tí ó tẹnu Aísáyà sọ pé: “Ojú rẹ yóò sì di ojú tí ń rí Olùkọ́ni rẹ Atóbilọ́lá. Etí rẹ yóò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ kan lẹ́yìn rẹ tí ń sọ pé: ‘Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀,’ bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ lọ sí apá ọ̀tún tàbí bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ lọ sí apá òsì.”—Aísáyà 30:20, 21; 48:17.

Dájúdájú, èyí kò túmọ̀ sí pé tí a bá ní àwọn ìpinnu àtàtà láti ṣe, ohùn kan yóò sọ ohun tí a óò ṣe fún wa. Ṣùgbọ́n, bí èrò wa bá ṣọ̀kan pẹ̀lú èrò Ọlọ́run nípa àwọn ọ̀ràn, ẹ̀rí-ọkàn wa yóò wà ní ìmúrasílẹ̀ láti ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tí yóò tẹ́ ẹ lọ́rùn.—Òwe 27:11.

Gbé ọ̀rọ̀ ti Jósẹ́fù, tí ó gbé ayé ní ọ̀rúndún kejìdínlógún ṣááju Sànmánì Tiwa, yẹ̀ wò. Nígbà tí ìyàwó Pọ́tífárì ní kí ó bá òun ṣe panṣágà, Jósẹ́fù kò gbà, ó sì wí pé: “Báwo ni èmi ṣe lè hu ìwà búburú ńlá yìí, kí n sì dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run ní ti gidi?” (Jẹ́nẹ́sísì 39:9) Ní ọjọ́ Jósẹ́fù, kò sí òfin kankan tí ó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, tí a kọ, tí ó dẹ́bi fún ìwà panṣágà. Síwájú sí i, Íjíbítì ni Jósẹ́fù ń gbé, kò sí nítòsí ibi tí ìdílé rẹ̀ ti lè rí i kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ tàbí tí àwọn baba ńlá ìgbàgbọ́ ti ń ṣàkóso. Kí ló wá jẹ́ kí Jósẹ́fù lè dènà àdánwò? Láìfi ọ̀pá pọ̀ọ̀lọ̀pọọlọ pejò, ẹ̀rí-ọkàn rẹ̀ tí ó ti kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ ni. Jósẹ́fù gba èrò Ọlọ́run pé ọkọ àti aya gbọ́dọ̀ jẹ́ “ara kan.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Nítorí náà, ó wá rí i pé kò ní dára kí òun gba ìyàwó ẹlòmíràn. Jósẹ́fù ronú bí Ọlọ́run ṣe ronú lórí ọ̀ràn náà. Ìwà panṣágà lòdì sí ojú ìwòye ìwà rere tí ó ní.

Lónìí, àwọn ènìyàn díẹ̀ ṣì wà tí wọ́n dà bí Jósẹ́fù. Ìṣekúṣe ń tàn kálẹ̀, ọ̀pọ̀ ènìyàn kò sì lérò pé àwọn gbọ́dọ̀ wà ní àìlábààwọ́n ní ti ìwà rere sí Ẹlẹ́dàá wọn, sí àwọn alára, tàbí sí ẹnì kejì wọn nínú ìgbéyàwó pàápàá. Ọ̀ràn náà jọ èyí tí a ṣàpèjúwe nínú ìwé Jeremáyà pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó ronú pìwà dà lórí ìwà búburú rẹ̀, pé, ‘Kí ni mo ṣe?’ Olúkúlùkù ń padà lọ sí ipa ọ̀nà gbígbajúmọ̀, bí ẹṣin tí ń já lọ fìà-fìà síbi ìjà ogun.” (Jeremáyà 8:6) Nípa bẹ́ẹ̀, ìdí púpọ̀ wà fún wa láti mú èrò wa bá ti Ọlọ́run mu ju ti ìgbàkigbà rí lọ. A ní ìpèsè àgbàyanu kan tí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.

Ìrànwọ́ fún Kíkọ́ Ẹ̀rí Ọkàn Lẹ́kọ̀ọ́

Ìwé Mímọ́ tí ó ní ìmísí “ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo, kí ènìyàn Ọlọ́run lè pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.” (2 Tímótì 3:16, 17) Kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yóò ràn wá lọ́wọ́ láti kọ́ ohun tí Bíbélì pè ní “agbára ìwòye” lẹ́kọ̀ọ́, kí a bàa lè fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́. (Hébérù 5:14) Yóò jẹ́ kí a nífẹ̀ẹ́ àwọn ohun tí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́, kí a sì kórìíra àwọn ohun tí òun kórìíra.—Sáàmù 97:10; 139:21.

Nígbà náà, ète tí a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jẹ́ láti mọ ohun tí òtítọ́ túmọ̀ sí àti ìjẹ́pàtàkì rẹ̀ dípò kúlẹ̀kúlẹ̀ ìmọ̀ Bíbélì lásán. Ile-Iṣọ Na, March 1, 1977, sọ pé: “Ninu ikẹkọ awọn Iwe Mimọ wa awa gbọdọ gbiyanju lati loye nipa idajọ, ifẹ ati ododo Ọlọrun ki a si gbin awọn wọnyi si isalẹ ọkan wa ki wọn le di apakan ara wa gẹgẹbi jijẹ onjẹ ati mímí ẽmí. Awa gbọdọ gbiyanju lati tubọ ji gìrì si ẹru iṣẹ wa nipa ti iwa rere nipa mimu imọlara dagbasoke nipa ohun ti iṣe rere ati ohun ti iṣe buburu. Ju eyini lọ, awa gbọdọ jẹki ẹri-ọkan wa ni imọlara nipa ẹru-iṣẹ rẹ̀ si Olufunni li Ofin ati Onidajọ ododo. (Isa. 33:22) Nitorinaa nigbati a ba nkẹkọ nipa Ọlọrun, awa gbọdọ gbiyanju lati ṣe afarawe rẹ̀ ninu ọna igbesi aiye gbogbo.”

Níní “Èrò Inú Ti Kristi”

Kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yóò tún ràn wá lọ́wọ́ láti ní “èrò inú ti Kristi,” ẹ̀mí ìgbọràn àti ìrẹ̀lẹ̀ tí Jésù fi hàn. (1 Kọ́ríńtì 2:16) Ṣíṣe ìfẹ́ Bàbá rẹ̀ jẹ́ ayọ̀, kì í wulẹ̀ ṣe ìgbòkègbodò kan tí a óò máa ṣe bí pé a ń darí ẹni, láìronú nípa rẹ̀. Onísáàmù náà, Dáfídì, ṣàpèjúwe ìṣarasíhùwà rẹ̀ nínú àsọtẹ́lẹ̀ kan tí ó kọ pé: “Láti ṣe ìfẹ́ rẹ, ìwọ Ọlọ́run mi, ni mo ní inú dídùn sí, òfin rẹ sì ń bẹ ní ìhà inú mi.”a—Sáàmù 40:8.

Níní “èrò inú ti Kristi” ṣe pàtàkì nínú kíkọ́ ẹ̀rí-ọkàn lẹ́kọ̀ọ́. Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé bí ẹ̀dá pípé, ó fi àwọn ànímọ́ àti àkópọ̀ ìwà Bàbá rẹ̀ hàn bí ara ẹ̀dá tí ó gbé wọ̀ ṣe gbà á láyè tó. Ìdí nìyẹn tí ó fi lè sọ pé: “Ẹni tí ó ti rí mi ti rí Baba pẹ̀lú.” (Jòhánù 14:9) Nínú gbogbo ipò tí Jésù dojú kọ lórí ilẹ̀ ayé, ohun tí Bàbá rẹ̀ fẹ́ kí ó ṣe gẹ́lẹ́ ni ó ṣe. Nítorí náà, nígbàkigbà tí a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìgbésí ayé Jésù, a ń rí irú ẹni tí Jèhófà Ọlọ́run jẹ́ ní ti gidi.

A kà pé Jèhófà jẹ́ “aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́.” (Ẹ́kísódù 34:6) Jésù fi àwọn ànímọ́ wọ̀nyí hàn léraléra lọ́nà tí ó ń gbà bá àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ lò. Nígbà tí wọ́n ń jiyàn ṣáá nípa èwo nínú wọn ló tóbi jù, Jésù fara balẹ̀ fi ọ̀rọ̀ ẹnu àti àpẹẹrẹ kọ́ wọn pé, “ẹni yòówù tí ó bá fẹ́ di ẹni ńlá láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ òjíṣẹ́ yín, ẹnì yòówù tí ó bá sì fẹ́ jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láàárín yín gbọ́dọ̀ jẹ́ ẹrú yín.” (Mátíù 20:26, 27) Èyí jẹ́ àpẹẹrẹ kan péré tí ń fi hàn pé a lè mú ara wa bá èrò Ọlọ́run mu nípa gbígbé ìgbésí ayé Jésù yẹ̀ wò.

Bí a bá ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù tó ni a óò ṣe gbára dì tó láti fara wé Bàbá wa ọ̀run, Jèhófà. (Éfésù 5:1, 2) Ẹ̀rí ọkàn tí a mú bá èrò Ọlọ́run mu yóò darí wa sí ọ̀nà tí ó tọ́. Jèhófà ṣèlérí fún àwọn tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé e pé: “Èmi yóò mú kí o ní ìjìnlẹ̀ òye, èmi yóò sì fún ọ ní ìtọ́ni nípa ọ̀nà tí ìwọ yóò máa tọ̀. Dájúdájú, èmi yóò fún ọ ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú ojú mi lára rẹ.”—Sáàmù 32:8.

Jíjàǹfààní Ẹ̀rí Ọkàn Tí A Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́

Níwọ̀n bí Mósè ti mọ bí ènìyàn aláìpé ti jẹ́ oníwà wíwọ́ tó, ó kìlọ̀ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ẹ fi ọkàn-àyà yín sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí mo ń sọ láti fi kìlọ̀ fún yín lónìí, kí ẹ̀yin lè máa pàṣẹ fún àwọn ọmọ yín láti máa kíyè sí pípa gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí mọ́.” (Diutarónómì 32:46) Àwa pẹ̀lú gbọ́dọ̀ kọ òfin Ọlọ́run sí ọkàn-àyà wa. Bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀rí-ọkàn wa yóò túbọ̀ lè darí ìṣísẹ̀ wa, yóò sì ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tí ó yẹ.

Àmọ́, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra. Òwe Bíbélì sọ pé: “Ọ̀nà kan wà tí ó dúró ṣánṣán lójú ènìyàn, ṣùgbọ́n àwọn ọ̀nà ikú ni òpin rẹ̀ ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀.” (Òwe 14:12) Èé ṣe tí èyí fi sábà máa ń rí bẹ́ẹ̀? Nítorí pé, Bíbélì sọ pé: “Ọkàn-àyà ṣe àdàkàdekè ju ohunkóhun mìíràn lọ, ó sì ń gbékútà. Ta ni ó lè mọ̀ ọ́n?” (Jeremáyà 17:9) Nítorí náà, ìdí wà fún gbogbo wa láti tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ ìṣílétí inú Òwe 3:5, 6 pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.”

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Nínú lẹ́tà rẹ̀ sí àwọn ará Hébérù, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù darí ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú Sáàmù 40 sí Jésù Kristi.—Hébérù 10:5-10.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Gẹ́gẹ́ bí ìhùmọ̀ atọ́ka, ẹrí-ọkàn tí a fi Bíbélì kọ́ lè darí wa sọ́nà tí ó tọ́

[Credit Line]

Ìhùmọ̀ atọ́ka: Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda onínúure, Peabody Essex Museum, Salem, Mass.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́