Kópa Nínú Ìpolongo Àsansílẹ̀ Owó Tó Kẹ́sẹ Járí
1 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ló ń dágunlá sí ìhìn Ìjọba náà tí wọ́n sì ń yọ̀ ṣìnkìn nínú ìgbòkègbodò ayé, ìrírí ti fi hàn pé a lè lo ìhìn iṣẹ́ Bíbélì tí a tẹ̀ jáde láti fi borí ìdágunlá. Ọ̀nà kan ni nípa fífi àsansílẹ̀ owó lọni ni gbogbo ìgbà tí àǹfààní bá ṣí sílẹ̀. Àmọ́ o, láti lè ṣe èyí dáadáa, a gbọ́dọ̀ ní ẹ̀mí pé nǹkan yóò ṣẹnuure, ká gbé góńgó kan kalẹ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, ka gbọ́rọ̀ kalẹ̀ lọ́nà tó gbéṣẹ́, ká lo gbogbo àǹfààní tó bá ṣí sílẹ̀, ká sì ní àwọn fọ́ọ̀mù àsansílẹ̀ owó lọ́wọ́.
2 Ní Ẹ̀mí Pé Nǹkan Yóò Ṣẹnuure: Bíbélì sọ nínú ìwé Oníwàásù 11:4 pé: “Ẹni tí ó bá ń ṣọ́ ẹ̀fúùfù kì yóò fún irúgbìn; ẹni tí ó bá sì ń wo àwọsánmà kì yóò kárúgbìn.” A ò gbọ́dọ̀ ronú pé a ò lè fi àsansílẹ̀ owó sóde. Ohun tó wulẹ̀ ń béèrè ni pé ká lẹ́mìí pé nǹkan yóò ṣẹnuure ká sì máa tẹ̀ lé àwọn àbá gbígbéṣẹ́ tí ẹgbẹ́ ẹrú náà pèsè. (Fi wé Lúùkù 5:4-6; Mátíù 24:45-47.) Arákùnrin kan tó gbọ́ nígbà tí àwọn alàgbà ń fún àwọn ará níṣìírí láti wọnú iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà kọ̀wé fún iṣẹ́ náà. Ó gbádùn ẹ̀ débi pé ó ṣe é lóṣù tó tẹ̀ lé e. Láàárín oṣù méjì yẹn, ó fi àsansílẹ̀ owó mọ́kàndínlọ́gọ́rin sóde.
3 Gbé Góńgó Kan Tó Ṣeé Lé Bá Kalẹ̀ fún Ara Rẹ: Àwọn kan tó ti ṣàṣeyọrí dáadáa ní fífi àsansílẹ̀ owó sóde sọ pé gbígbé góńgó kan tó ṣeé lé bá kalẹ̀ kó ipa kan nínú àṣeyọrí àwọn. A rọ gbogbo wa láti gbé góńgó kan kalẹ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ká sì sakun láti lé e bá.
4 Gbọ́rọ̀ Kalẹ̀ Lọ́nà Tí Ń Fani Mọ́ra: Kò tó láti wulẹ̀ sọ fún àwọn èèyàn pé wọ́n lè máa rí àwọn ìwé ìròyìn yìí gbà ní ilé wọn nípasẹ̀ ìfìwéránṣẹ́. Ru ìfẹ́ wọn sókè nípa ohun tí wọ́n ní láti máa retí. Mú kí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ rẹ bá wọn mu. Àwọn àbá díẹ̀ nìyí:
5 Nígbà ìjẹ́rìí ilé-dé-ilé, o lè gbọ́rọ̀ kalẹ̀ báyìí:
◼ “Ẹ ǹlẹ́ ńlé o, orúkọ mi a máa jẹ́ _________________________. Mo ń ṣe ìbẹ̀wò sọ́dọ̀ ẹ̀yin aládùúgbò mi nítorí mo mọ̀ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń fẹ́ gbọ́ ìròyìn ohun tó ń lọ. Bóyá kí wọ́n lè rí nǹkan kọ́ ni tàbí kí wọ́n lè mọ̀ nípa ewu tí ń bọ̀ lọ́nà. Ṣé bẹ́ẹ̀ náà lèrò tìẹ rí? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn wọ̀nyí ní ìròyìn púpọ̀ nínú nípa àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yíká ayé, ó sì ń ràn wá lọ́wọ́ láti kọ́ ẹ̀kọ́ gidi láti inú wọn. [Pe àfiyèsí onílé sí ìròyìn kan tí ń fani mọ́ra kí o sì máa bá ọ̀rọ̀ rẹ nìṣó.] Bóo bá fẹ́, inú mi á dùn láti ṣètò bí àwọn ìtẹ̀jáde ìwé ìròyìn wọ̀nyí tí yóò máa jáde lẹ́yìn èyí yóò ṣe máa tẹ̀ ọ́ lọ́wọ́ déédéé fún odindi ọdún kan.” Bó bá sọ pé òun fẹ́, fi àsansílẹ̀ owó lọ̀ ọ́ fún iye ọrẹ tí ó máa ń jẹ́.
6 Bóo bá bá ẹnì kan pàdé fún ìgbà àkọ́kọ́, o lè sọ pé:
◼ “Inú mi dùn láti rí ọ. Orúkọ mi a máa jẹ́ _________________________. Mo ṣàkíyèsí pé wàhálà ń bẹ ní ilẹ̀ wa àti ní àwọn ibòmíràn yíká ayé. Èyí ń mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ṣe kàyéfì bóyá ojútùú kankan yóò wà sí àwọn ìṣòro wa. Ǹjẹ́ o ti ronú nípa èyí rí bí? [Jẹ́ kó fèsì.] Ìwé ìròyìn wọ̀nyí sọ ọ̀nà tó dára jù lọ láti yanjú àwọn ìṣòro tí èèyàn ò tí ì lè yanjú fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún. Inú mí á dùn láti ṣètò bí àwọn ìtẹ̀jáde ìwé ìròyìn wọ̀nyí tí yóò máa jáde lẹ́yìn èyí yóò ṣe máa tẹ̀ ọ́ lọ́wọ́ déédéé fún odindi ọdún kan, iye rẹ̀ sì jẹ́ ₦320.00. Tàbí kẹ̀, bó bá jẹ́ ilé ìfìwéránṣẹ́ lo ti fẹ́ máa gbà á, iye rẹ̀ yóò jẹ́ ₦450.00.” Ṣètò fún ìpadàbẹ̀wò.
7 Bí ẹnì kan bá wà tóo mọ bí ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe rí látilẹ̀wá, o lè fọgbọ́n mú kí ìhìn iṣẹ́ tí o fẹ́ jẹ́ fún un bá ọ̀ràn rẹ̀ mu láti ràn án lọ́wọ́ kí ó lè rí bí àwọn ìwé ìròyìn náà ṣe wúlò tó. O lè fi àwọn kókó tó lè ru ìfẹ́ rẹ̀ sókè hàn án nínú àwọn ìwé ìròyìn náà. Wáá sọ fún un nípa bí òun àti àwọn tó fẹ́ràn rẹ̀ ṣe lè gbádùn àwọn ìbùkún àgbàyanu látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Bónílé bá sọ pé òun ò lówó, o lè fi àwọn ẹ̀dà ìwé ìròyìn náà lọ̀ ọ́.
8 Lo Gbogbo Àǹfààní Tóo Bá Ní: Lo gbogbo àǹfààní tó bá ṣí sílẹ̀ láti fi àsansílẹ̀ owó lọni. Rí i dájú pé o kópa nínú ìpolongo àsansílẹ̀ owó gẹ́gẹ́ bí apá kan ìgbòkègbodò ìjọ lóṣù yìí. Rántí ṣiṣẹ́ lórí bí a óò ṣe tún àsansílẹ̀ owó tí a ti fi tóni létí pé ó ń tán lọ ṣe. O lè ṣètò láti fúnni lẹ́bùn àsansílẹ̀ owó. Èyí lè tọ́jọ́ ju ọ̀pọ̀ ẹ̀bùn ti ara. Ìhìn iṣẹ́ tó wà nínú rẹ̀ ń gbẹ̀mí là. O tún lè fi àsansílẹ̀ owó lọ àwọn tí o máa ń fún ní ìwé ìròyìn àti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rẹ. Fi í ṣe góńgó rẹ láti máa ṣètìlẹ́yìn fún ètò tí ìjọ ṣe fún Ọjọ́ Ìwé Ìròyìn (gbogbo ọjọ́ Saturday).
9 Má ṣe gbójú fo àwọn àǹfààní láti fi àsansílẹ̀ owó lọni nígbà ìjẹ́rìí láìjẹ́ bí àṣà. (Oníw. 11:6) Ìdílé kan tó ní ọmọdébìnrin ọlọ́dún mẹ́rin kan gba ẹnì kan lálejò. Lọ́jọ́ kan, àlejò yìí ń wá ìwé tó lè kà ló bá ṣàròyé pé, “Ṣéèyàn ò lè rí ìwé kankan kà nínú ilé yìí ni?” Èwe Ẹlẹ́rìí yìí fọwọ́ tẹ̀bàdí, ó wá fèsì pé, “Ṣé pé ẹ ò rí ìwé kankan kà nínú ilé yìí? Ó dáa ẹ dúró ná.” Ó sá wọnú iyàrá ìyá rẹ̀, o gun orí àga, ó sì gbé ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tí ìyá rẹ̀ kó jọ. Ó kó wọn lọ fún àlejò yẹn ó sì sọ pé, “Ẹ ò rí i pé ìwé tí ẹ lè kà wà báyìí!” Àlejò yẹn gbádùn àwọn ìwé ìròyìn yẹn débi pé ọmọ kékeré yẹn sọ pé: “Bí ẹ bá fẹ́, ẹ lè máa rí wọn gbà nílé nípasẹ̀ ìfìwéránṣẹ́.” Ibo ló wá yọrí sí? Àsansílẹ̀ owó méjì ni àlejò yẹn gbà!
10 Fi Àwọn Àsansílẹ̀ Owó Ránṣẹ́ ní Kánmọ́: Ó lè kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn tó san àsansílẹ̀ owó bó bá lọ pẹ́ jù kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí rí àwọn ìwé ìròyìn tí wọ́n san àsansílẹ̀ fún gbà. Bó ti sábà máa ń rí, àwọn àsansílẹ̀ owó tí a bá fi ránṣẹ́ sí Society lè má gbà ju oṣù méjì kí ẹni tó san àsansílẹ̀ tó máa rí ìwé ìròyìn gbà. Ṣùgbọ́n àkókò náà lè gùn jù bẹ́ẹ̀ lọ dáadáa bí a ò bá tètè fi àwọn àsansílẹ̀ owó ránṣẹ́ sí Society. Ìdí nìyí tó fi ṣe pàtàkì láti fi àwọn fọ́ọ̀mù àsansílẹ̀ owó tí a ti kọ ọ̀rọ̀ kún, tí a bá rí gbà, lé ìjọ lọ́wọ́ ní ìpàdé ìjọ tó bá tẹ̀ lé ọjọ́ tí a gbà wọ́n. Lẹ́yìn náà, arákùnrin tí ń bójú tó àsansílẹ̀ owó gbọ́dọ̀ kọ ìwé kún fọ́ọ̀mù Weekly Subscriptions ní kánmọ́ kó sì fi í fún akọ̀wé tí yóò fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò rẹ̀, tí yóò buwọ́ lù ú, tí yóò sì fi í ránṣẹ́ sí Society lọ́sẹ̀ yẹn.
11 Bí olúkúlùkù wa bá ṣe ipa tirẹ̀ nínú ìpolongo àsansílẹ̀ owó yìí, ó dá wa lójú pé Jèhófà yóò bù kún ìsapá wa.