ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 11/99 ojú ìwé 1
  • Iṣẹ́ Ìwàásù Mú Ká Yàtọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Iṣẹ́ Ìwàásù Mú Ká Yàtọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ǹjẹ́ O Ní Ìtara Fún “Iṣẹ́ Àtàtà”?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • ‘Àwọn Tí Ń mú Ìhìn Rere Ohun Tí Ó Dára Jù Wá’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Máa Fìtara Wàásù Bíi Jésù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2025
  • Máa Fi Ìtara Wàásù Nìṣó
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
km 11/99 ojú ìwé 1

Iṣẹ́ Ìwàásù Mú Ká Yàtọ̀

1 Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń béèrè pé, “Kí ló mú káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yàtọ̀ sáwọn ẹ̀sìn yòókù?” Báwo lo ṣe máa fèsì? O lè ṣàlàyé díẹ̀ nínú àwọn ohun táa gbà gbọ́ táa gbé karí Bíbélì. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ o tún ronú nípa títọ́ka sí bí iṣẹ́ ìwàásù wa fún gbogbo èèyàn ṣe mú kí a yàtọ̀ sí àwọn ẹ̀sìn yòókù?—Mát. 24:14; 28:19, 20.

2 Lónìí, díẹ̀ làwọn onísìn tó máa ń fẹ́ sọ nípa ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fún àwọn ẹlòmíràn. Wọ́n lè ronú pé báwọn bá ti ń ṣègbọràn sí òfin Késárì, tí àwọn ń hùwà rere tàbí tí àwọn ń ṣe àwọn ẹlòmíràn lóore, ọ̀ràn ti bùṣe nìyẹn. Ṣùgbọ́n, wọn ò ronú pé ó pọndandan fáwọn láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa jíjèrè ìgbàlà. Báwo la ṣe yàtọ̀?

3 Iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí a ń fi ìtara ṣe yàtọ̀ gédégédé sí ìgbòkègbodò ti àwọn ẹ̀sìn yòókù. Fún ohun tó ju ọgọ́rùn-ún ọdún lọ, àwọn Ẹlẹ́rìí òde òní ti fi aápọn wàásù ìhìn rere náà dé òpin ilẹ̀ ayé, ní àfarawé àwọn Kristẹni ìjímìjí. Ète tí a fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni ká lè ṣèrànwọ́ fún gbogbo èèyàn tó bá ṣeé ṣe fún wa láti ràn lọ́wọ́ láti mú ìgbésí ayé wọn bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu.—1 Tím. 2:4; 2 Pét. 3:9.

4 Kí Làwọn Èèyàn Mọ̀ Ẹ́ Pé O Jẹ́? Ṣé àwọn èèyàn mọ̀ ẹ́ gẹ́gẹ́ bí onítara olùwàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? (Ìṣe 17:2, 3; 18:25) Nítorí iṣẹ́ ìwàásù tí o máa ń ṣe, ṣé àwọn èèyàn rí i ní kedere pé ẹ̀sìn tàwọn yàtọ̀ sí tìẹ? Ṣé àṣà rẹ ni pé o máa ń tara ṣàṣà láti sọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa ìrètí tí o ní? Ǹjẹ́ o ṣètò láti máa kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ déédéé? Rántí pé kì í ṣe orúkọ wa nìkan la fi yàtọ̀, ṣùgbọ́n a tún gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun tí orúkọ yẹn ṣàpèjúwe—jíjẹ́rìí nípa Jèhófà.—Aísá. 43:10.

5 Ìfẹ́ tí a ní sí Ọlọ́run àti sí aládùúgbò wa ló ń sún wa láti lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù. (Mát. 22:37-39) Ìdí nìyẹn tí àwa, gẹ́gẹ́ bíi Jésù àtàwọn àpọ́sítélì, ṣe ń fẹ́ láti máa lo gbogbo àǹfààní tó bá ṣí sílẹ̀ láti sọ nípa ìhìn Ìjọba náà fún àwọn ẹlòmíràn. Ǹjẹ́ kí a máa fi ìtara wàásù ìhìn rere náà fún àwọn tó bá fẹ́ láti tẹ́tí sílẹ̀. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò ran àwọn olóòótọ́ ọkàn lọ́wọ́ láti “rí ìyàtọ̀ láàárín . . . ẹni tí ń sin Ọlọ́run àti ẹni tí kò sìn ín.”—Mál. 3:18.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́