ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 11/99 ojú ìwé 1
  • Ta Ló Lè Gbà Ká Bá Òun Ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ta Ló Lè Gbà Ká Bá Òun Ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Lo Àwọn Ìwé Wa Lọ́nà Ọgbọ́n
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • A Ń Fẹ́ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Púpọ̀ Sí I
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Ó Yẹ Kí A Jẹ́ Olùkọ́, Kì Í Ṣe Oníwàásù Nìkan
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Máyà Le Láti Ṣe Ìpadàbẹ̀wò
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
km 11/99 ojú ìwé 1

Ta Ló Lè Gbà Ká Bá Òun Ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?

1 Wòlíì Ámósì polongo pé ìyàn yóò wà ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì, “ìyàn, tí kì í ṣe fún oúnjẹ, àti òùngbẹ, tí kì í ṣe fún omi, bí kò ṣe fún gbígbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà.” (Ámósì 8:11) Fún àǹfààní àwọn tí ebi tẹ̀mí ń pa tí òùngbẹ tẹ̀mí sì ń gbẹ, ètò Jèhófà ń pín ọ̀pọ̀ yanturu ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jákèjádò ayé.

2 Di bí a ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, a ti tẹ àádọ́rin mílíọ̀nù ìwé Ìmọ̀ àti mílíọ̀nù mọ́kànléláàádọ́rùn-ún ìwé pẹlẹbẹ Béèrè jáde. Bó bá dọ̀ràn ká kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, a mọrírì bí àwọn ìtẹ̀jáde yìí ṣe rọrùn tó sì gbéṣẹ́. Ṣùgbọ́n ká sọ tòótọ́, ọ̀pọ̀ yanturu lára àwọn èèyàn tó gba ìwé wa ni a kò tíì máa bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kí la lè ṣe nípa rẹ̀?

3 Ọ̀kọ̀ọ̀kan Ìwé Tí A Bá Fi Sóde Ló Lè Di Ìkẹ́kọ̀ọ́! Gbọ́ ìrírí akéde kan tó fi ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ obìnrin kan ní ìgbà àkọ́kọ́ tó bá obìnrin náà sọ̀rọ̀ lẹ́nu ọ̀nà. Ojú ẹsẹ̀ ló gbà láti máa kẹ́kọ̀ọ́. Nígbà tó yá, obìnrin náà sọ fún akéde yẹn pé, “Ìwọ lẹni àkọ́kọ́ tó sọ pé òun máa bá mi ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Ní ìpínlẹ̀ rẹ, èèyàn mélòó tó ti gba ìwé wa ló ṣeé ṣe kó sọ ohun kan náà? Ìwé kọ̀ọ̀kan tí a bá fi sóde ń mú kó ṣeé ṣe fún wa láti ṣe ìpadàbẹ̀wò, ká sì darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

4 Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé a sábà máa ń rí àwọn èèyàn tó ti gba ìwé wa tẹ́lẹ̀, báwo la ṣe lè mú ìfẹ́ wọn sọ jí láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn nǹkan tí ń bẹ nínú ìwé wa? Ẹlẹ́rìí kan béèrè lọ́wọ́ onílé ní tààràtà bóyá ìbéèrè èyíkéyìí wà tó fẹ́ bi òun láti inú Bíbélì, ṣùgbọ́n ó sọ pé, “Rárá.” Arábìnrin náà tẹnu mọ́ ọn pé, “Ó dájú pé àwọn ìbéèrè kan wà tí o fẹ́ béèrè.” Lobìnrin náà bá béèrè ìbéèrè kan, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́. Oò ṣe bi onílé bí yóò bá fẹ́ láti mọ ìdáhùn Bíbélì sí ìbéèrè kan tàbí ohun tí Bíbélì sọ nípa ọ̀ràn kan tí ó ń ṣàníyàn nípa rẹ̀? Múra tán láti béèrè ìbéèrè kan tí ń fani lọ́kàn mọ́ra bí kò bá lè ronú kan ìbéèrè kankan. Irú àwọn ìjíròrò bẹ́ẹ̀ lè ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún kíkẹ́kọ̀ọ́ déédéé nípa òtítọ́ ṣíṣekókó tó wà nínú Bíbélì.

5 Iṣẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lolórí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Bó ti jẹ́ pé a ò mọ ẹni tó lè gbà ká bá òun ṣèkẹ́kọ̀ọ́, má ṣe lọ́ tìkọ̀ láti fi ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ gbogbo ẹni tí o bá bá pàdé. Mú ọ̀rọ̀ náà tọ Jèhófà lọ nínú àdúrà kí o sì ṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà rẹ. Ó lè máà pẹ́ tí wàá fi rí i pé ẹni tí o fi ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ̀ gbà kí o bá òun ṣèkẹ́kọ̀ọ́!—1 Jòh. 5:14, 15.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́