Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Oṣù November
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 1
Orin 156
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ táa yàn látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.
15 min: “Iṣẹ́ Ìwàásù Mú Ká Yàtọ̀.” Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Lo ìwé Ìmọ̀, ojú ìwé 173, ìpínrọ̀ 8, láti ṣàlàyé ní ṣókí nípa ohun tí a lè sọ láti fún akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan níṣìírí láti nàgà fún kíkópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́.
20 min: “Ta Ló Lè Gbà Ká Bá Òun Ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?” Àsọyé àti àwọn àṣefihàn. Ní ìbámu pẹ̀lú ìpínrọ̀ 4, dábàá onírúurú ọ̀nà tí a fi lè mú kí àwọn èèyàn fẹ́ láti mọ ohun tó wà nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa. Jẹ́ kí a ṣe àṣefihàn méjì tí ń fi ohun tí a lè ṣe hàn. Sọ pé kí àwùjọ sọ bí wọ́n ṣe ṣàṣeyọrí nínú bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́.
Orin 198 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 8
Orin 204
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Sọ ètò iṣẹ́ ìsìn pápá ní òpin ọ̀sẹ̀. Rán àwọn ará létí pé kí wọ́n múra sílẹ̀ fún ìjíròrò ọ̀sẹ̀ tí ń bọ̀ lórí ìpínrọ̀ méjìdínlógún àkọ́kọ́ nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti oṣù November. Ṣàtúnyẹ̀wò “Ẹẹ̀ Rí Agbára Tí Bíbélì Ní!”
15 min: Àpótí Ìbéèrè. Àsọyé. Sọ ètò tí ìjọ ṣe láti mú kí Gbọ̀ngàn Ìjọba wà ní mímọ́ kó sì bójú mu.
20 min: “Kí Lo Máa Sọ fún Mùsùlùmí?” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ṣàlàyé ìdí fún lílo òye nígbà tí a bá ń jíròrò pẹ̀lú àwọn èèyàn tí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wọn yàtọ̀. Ṣàṣefihàn ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tí a múra sílẹ̀ dáadáa. Fún àfikún ìsọfúnni nípa ẹ̀sìn Ìsìláàmù, wo àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti February 1998; Ìwé Reasoning, ojú ìwé 23 àti 24; àti ìwé Mankind’s Search for God, orí 12.
Orin 208 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 15
Orin 211
8 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó. Rán àwọn akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìdajì oṣù November sílẹ̀.
25 min: “Lílo Íńtánẹ́ẹ̀tì—Ẹ Ṣọ́ra fún Ewu Tó Wà Níbẹ̀!” Ìjíròrò ìpínrọ̀ 1 sí 18 lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Ka ìpínrọ̀ 4 sí 7, 12, 16, àti 17. Fún gbogbo àwùjọ níṣìírí láti múra sílẹ̀ dáadáa fún ìjíròrò ti ọ̀sẹ̀ tí ń bọ̀ lórí ìpínrọ̀ 19 sí 36.
12 min: Ẹ̀yin Òbí—Ǹjẹ́ Ẹ Máa Ń Ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìdílé Déédéé? Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Ṣàlàyé ìdí tó fi yẹ kí àwọn ìdílé máa kẹ́kọ̀ọ́ pa pọ̀. (Wo Iwe-Amọna Ile Ẹkọ, ojú ìwé 37 àti 38.) Jíròrò àwọn ohun tó tẹ̀ lé e yìí, tó máa ń dènà ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé: (1) ríronú pé àwọn ọmọ ṣì kéré jù láti jàǹfààní nínú rẹ̀, (2) ríronú pé lílọ sí àwọn ìpàdé ìjọ ti tó, (3) àárẹ̀ ara nítorí pé ọwọ́ dí àti (4) tẹlifíṣọ̀n wíwò tí ń gba àkókò ẹni. (Wo Ilé-Ìṣọ́nà, May 15, 1994, ìpínrọ̀ 11 àti 12.) Sọ pé kí àwọn olórí ìdílé sọ bí wọ́n ṣe borí àwọn ìdènà láti máa ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé déédéé. Tẹnu mọ́ ọn pé èyí ń gba ìsapá, ìmúratán, àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀.
Orin 217 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 22
Orin 158
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò àti ìrírí látinú iṣẹ́ ìsìn pápá.
10 min: Ọwọ́ Wo Lo Fi Ń Mú Iṣẹ́ Tí A Bá Yàn fún Ọ? Àsọyé tí alàgbà sọ. Ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ló gbọ́dọ̀ di ṣíṣe kí ìjọ lè máa báṣẹ́ lọ láìsídìíwọ́, àwọn iṣẹ́ bíi: ṣíṣètò àwọn iṣẹ́ lórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìpàdé; gbígbé àwọn èèyàn wá sí ìpàdé tàbí lílọ sí òde ẹ̀rí pẹ̀lú wọn; ríran àwọn àgbàlagbà lọ́wọ́; àti mímú kí Gbọ̀ngàn Ìjọba wà ní mímọ́, ṣíṣàtúnṣe rẹ̀ àti bíbójú tó o, ìyẹn sì kan gígé koríko. Báwo lo ṣe máa ń ṣe nígbà tí a bá sọ pé kí o ṣèrànwọ́? Àwọn kan lè kọ̀ jálẹ̀, wọ́n lè fi ìlọ́tìkọ̀ gbà, tàbí kí wọ́n má ṣe iṣẹ́ náà parí. Jíròrò ìdí tí títẹ́wọ́gba iṣẹ́ tí a yàn fúnni àti ṣíṣe é parí fi jẹ́ àǹfààní aláyọ̀. Fún gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ níṣìírí láti máa fi ẹ̀mí ìyọ̀ǹda ara ẹni hàn pẹ̀lú ìmúratán.—Sm. 110:3, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé New World Translation Reference Bible; Aísá. 6:8.
25 min: “Lílo Íńtánẹ́ẹ̀tì—Ẹ Ṣọ́ra fún Ewu Tó Wà Níbẹ̀!” Ìjíròrò ìpínrọ̀ 19 sí 36 lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Ka ìpínrọ̀ 23 sí 25 àti 34 sí 36.
Orin 223 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 29
Orin 215
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Rán àwọn akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá toṣù November sílẹ̀.
15 min: Fún Àwọn Ẹni Tuntun Níṣìírí Láti Máa Wá sí Ìpàdé. Ìjíròrò láàárín alàgbà kan àti ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan tàbí méjì, èyí tí a gbé karí ìwé pẹlẹbẹ náà, Awọn Ẹlẹrii Jehofah Nfi Pẹlu Isopọṣọkan Ṣe Ifẹ-Inu Ọlọrun Yíká-Ayé, ojú ìwé 14 àti 15. Ṣàtúnyẹ̀wò ìdí tó fi ṣe kókó pé kí àwọn ẹni tuntun máa wá sí ìpàdé. Ibẹ̀ ni wọ́n á ti gba apá tó pọ̀ jù lọ nínú ìtọ́ni, ìṣírí, àti ìrànwọ́ tí wọ́n nílò. Ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ìpàdé márààrún tí a máa ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, ṣàlàyé àǹfààní ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn. Jíròrò bí ìpàdé ṣe ń gbé ìwà tí Ọlọ́run fẹ́ lárugẹ, bó ṣe ń gbé ipò tẹ̀mí ró, bó ṣe ń mú wa sún mọ́ ètò àjọ náà, bó ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìbátan tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì, àti bó ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti lóye ète iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa. Fún àwùjọ níṣìírí láti lo ìwé pẹlẹbẹ yìí láti sún àwọn ẹni tuntun láti máa wá sí ìpàdé.
20 min: Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun La Yàn. Àsọyé àti àwọn àṣefihàn. Láwùjọ àwọn ètò ẹ̀sìn, tiwa ò láfiwé nítorí a mú ìtumọ̀ Bíbélì jáde, èyí tí àwọn ẹni àmì òróró olùjọsìn Jèhófà ṣe, a ń lò ó, a sì ń pín in kiri. Kì í ṣe pé a ń wá èrè owó tàbí pé a fẹ́ tan ìgbàgbọ́ ẹ̀ya ìsìn kálẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìfẹ́ láti bọlá fún orúkọ Ọlọ́run àti láti ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ láti túbọ̀ mọ Ọlọ́run dáadáa ló ń sún wa ṣe èyí. Àwọn ìtumọ̀ míì sábà máa ń túmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́nà tó fi máa ń ṣòro láti lóye, nítorí náà, ṣàyẹ̀wò àwọn àǹfààní ṣíṣe kedere tí Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ní. (Wo ìwé “All Scripture,” ojú ìwé 327 sí 331. Kíyè sí àlàyé tó wà ní ìpínrọ̀ 3, sọ àwọn àpẹẹrẹ ìtumọ̀ tí a mú sunwọ̀n sí i tó wà ní ìpínrọ̀ 6, kí o sì ṣàlàyé àwọn àǹfààní tí a sọ ní ìpínrọ̀ 22 sí 23.) Jẹ́ kí a ṣe àṣefihàn ṣókí méjì tí ń dábàá bí a ṣe lè fèsì nígbà tí àwọn ẹlòmíràn bá sọ pé, “Ẹ ní Bíbélì tiyín.”—Wo ìwé Reasoning, ojú ìwé 279 àti 280.
Orin 205 àti àdúrà ìparí.