ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/99 ojú ìwé 1
  • Ṣé A Ò Gbọ́yẹn Rí Ni?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé A Ò Gbọ́yẹn Rí Ni?
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ǹjẹ́ o Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Ìránnilétí Jèhófà Lọ́nà Tó Kọyọyọ?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Àwọn Ìránnilétí Jèhófà Ṣeé Gbẹ́kẹ̀ Lé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Máa Tànmọ́lẹ̀ Sí Òpópónà Rẹ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
  • Gbẹ́kẹ̀ Lé Ọ̀rọ̀ Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2005
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
km 12/99 ojú ìwé 1

Ṣé A Ò Gbọ́yẹn Rí Ni?

1 Dájúdájú, a ti gbọ́ ọ rí! Ọ̀pọ̀ nǹkan ni Jèhófà máa ń ṣàtúnsọ wọn nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún àǹfààní àwọn èèyàn rẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jésù ṣàtúnsọ àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ nípa onírúurú apá Ìjọba náà. Àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ kò ṣíwọ́ ṣíṣàtúnyẹ̀wò àwọn ọ̀ràn tẹ̀mí pẹ̀lú àwọn tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin nínú òtítọ́.—Róòmù 15:15; 2 Pét. 1:12, 13; 3:1, 2.

2 Ní àkókò wa, ètò Jèhófà ti ṣètò àwọn kókó ọ̀rọ̀ pàtàkì tí a gbọ́dọ̀ máa tún yẹ̀ wò léraléra nínú àwọn ìpàdé ìjọ. A ti kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìtẹ̀jáde kan léraléra. Bẹ́ẹ̀ ni, ó ṣe pàtàkì láti gbọ́ àwọn nǹkan tí a ti gbọ́ rí!

3 Àsọtúnsọ Ṣe Pàtàkì Gan-an: Àwọn ìránnilétí látọ̀dọ̀ Jèhófà máa ń mú kí òye wa jinlẹ̀ sí i, ó máa ń mú kí ojú ìwòye wa gbòòrò sí i, ó sì máa ń fún ìpinnu wa lókun láti máa rìn ní ọ̀nà tẹ̀mí. (Sm. 119:129) Ṣe ni ṣíṣàtúnyẹ̀wò àwọn ìlànà àti ọ̀pá ìdíwọ̀n Ọlọ́run dà bíi wíwo dígí. Ó máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàyẹ̀wò ara ẹni kí a má bàa jẹ́ “olùgbọ́ tí ń gbàgbé.”—Ják. 1:22-25.

4 Bí a kò bá máa rán ara wa létí ọ̀rọ̀ òtítọ́, àwọn nǹkan mìíràn yóò ní ipa lórí ọkàn wa. Àwọn ìránnilétí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ń fún wa lókun láti dènà ìdarí ayé Sátánì tí ń sọni dìbàjẹ́. (Sm. 119:2, 3, 99, 133; Fílí. 3:1) Àwọn ìránnilétí ìgbà gbogbo tí a ń rí gbà nípa ìmúṣẹ àwọn ète Ọlọ́run ń sún wa láti “máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà.” (Máàkù 13:32-37) Àsọtúnsọ àwọn òtítọ́ Ìwé Mímọ́ ń ràn wá lọ́wọ́ láti wà lójú ọ̀nà ìyè àìnípẹ̀kun.—Sm. 119:144.

5 Bí Ẹnì Kòòkan Wa Ṣe Lè Jàǹfààní: A gbọ́dọ̀ ‘tẹ ọkàn-àyà wa síhà àwọn ìránnilétí látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.’ (Sm. 119:36) Nígbà tí a bá fẹ́ jíròrò kókó ọ̀rọ̀ kan ní ìpàdé ìjọ, tó sì wá jẹ́ pé a mọ kókó náà dunjú, ó yẹ ká múra sílẹ̀, ká wo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a tọ́ka sí, ká sì ronú lórí bí a ṣe lè fi ìsọfúnni náà sílò. Ẹ má ṣe jẹ́ ká gbàgbé láti máa múra sílẹ̀ fún àtúnyẹ̀wò alákọsílẹ̀ nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run, ká má ronú pé kò pọndandan. (Lúùkù 8:18) Kó má ṣe ṣẹlẹ̀ láé pé a ò fetí sílẹ̀ ní àwọn ìpàdé wa nítorí pé a sábà máa ń sọ àwọn ọ̀rọ̀ òtítọ́ tó ṣe kókó lásọtúnsọ.—Héb. 5:11.

6 Ǹjẹ́ kí a ní ẹ̀mí ìrònú bíi ti onísáàmù náà, tó sọ pé: “Èmi ti yọ ayọ̀ ńláǹlà ní ọ̀nà àwọn ìránnilétí rẹ, gan-an gẹ́gẹ́ bí lórí gbogbo àwọn ohun oníyelórí yòókù.” (Sm. 119:14) Dájúdájú, a ti gbọ́ àwọn nǹkan oníyelórí wọ̀nyí rí, ó sì ṣeé ṣe ká tún gbọ́ wọn. Èé ṣe? Ó jẹ́ nítorí Jèhófà mọ̀ pé ó yẹ ká máa gbọ́ wọn!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́