ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/99 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Isẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Isẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 6
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 13
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 20
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 27
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 3
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1999
km 12/99 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Isẹ́ Ìsìn

ÀKÍYÈSÍ: Bẹ̀rẹ̀ látorí ìtẹ̀jáde Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí, Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn yóò máa ní apá àkọ́kọ́ nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn toṣù tó tẹ̀ lé e nínú. A ṣe ìyípadà yìí láti mú kó rọrùn tó bá lọ ṣẹlẹ̀ pé ẹ ò tètè rí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa tí a kó ránṣẹ́ gbà.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 6

Orin 207

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ táa yàn látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Ṣàtúnyẹ̀wò “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Tuntun fún Àpéjọ Àyíká.” Ṣèfilọ̀ ọjọ́ tí ẹ óò ṣe àpéjọ àyíká tí ń bọ̀. Fún àwọn ẹni tuntun níṣìírí pé kí wọ́n ronú lórí ṣíṣe batisí. Rọ gbogbo àwùjọ pé kí wọ́n má ṣe pàdánù èyíkéyìí lára ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà.

15 min: “Fara Wé Jèhófà Tí Kì í Ṣojúsàájú.” Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o sì jíròrò rẹ̀ lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Ṣàlàyé ohun tí àìṣojúsàájú túmọ̀ sí, bí Jèhófà ṣe ń fi hàn, àti bí a ṣe lè fi èyí hàn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa.—Wo ìwé Insight, Ìdìpọ̀ Kìíní, ojú ìwé 1192, ìpínrọ̀ 4 sí 7.

20 min: “Ṣé A Ò Gbọ́yẹn Rí Ni?” Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Sọ pé kí àwùjọ sọ bí àsọtúnsọ ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lóye òtítọ́ kí wọ́n sì mọrírì rẹ̀ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ sí i.—Wo Ilé-Ìṣọ́nà, July 15, 1995, ojú ìwé 21 àti 22, àti August 15, 1993, ojú ìwé 13 àti 14, ìpínrọ̀ 10 sí 12.

Orin 218 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 13

Orin 39

ÀKÍYÈSÍ: A ò ṣètò ohunkóhun nínú ìtọ̀lẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn fún ọ̀sẹ̀ yìí. Èyí jẹ́ nítorí pé ìtòlẹ́sẹẹsẹ àkànṣe kan wà tí a fẹ́ ṣe fún ọ̀sẹ̀ yìí. A ó sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀ nígbà tó bá yá. A fún gbogbo yín níṣìírí pé kẹ́ẹ wà níbi ètò àkànṣe náà. Kí àwọn ìjọ tí wọ́n bá ní àpéjọpọ̀ àgbègbè wọn lọ́sẹ̀ yẹn ṣàyẹ̀wò àkójọ ọ̀rọ̀ yẹn lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e.

Orin 8 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 20

Orin 219

15 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó. Dábàá nípa bí a ṣe lè fọgbọ́n dáhùn ìkíni ayẹyẹ ọdún. Bí ìjọ bá ní ẹ̀dà ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ tàbí Olukọ Nla lọ́wọ́, fi hàn bí a ṣe lè lò ó lọ́nà rere nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ lákòókò ọdún Kérésìmesì.

13 min: Fífún Àwọn Tó Lè Fẹ́ Bẹ́gi Dínà Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ Lésì. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ àti àwọn àṣefihàn. Ka “Àlàyé” tó wà ní ojú ìwé 7 àti 8 nínú ìwé kékeré Ìjíròrò Bibeli. Lo méjì tàbí mẹ́ta nínú “àwọn ọ̀rọ̀ tí ó lè bẹ́gidínà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀” lójú ìwé 8 sí 12, tàbí kí o lo àwọn mìíràn tí ẹ sábà máa ń bá pàdé ní ìpínlẹ̀ yín. Ṣàtúnyẹ̀wò díẹ̀ nínú àwọn èsì tí a dábàá, kí o sì ṣàlàyé ìdí tí wọ́n fi lè gbéṣẹ́ ládùúgbò yín. Ní ṣókí, ṣàṣefihàn díẹ̀ nínú wọn. Sọ pé kí àwùjọ ṣàlàyé àwọn ọ̀nà tí wọ́n ti gbà fèsì, tí wọ́n sì ti ṣàṣeyọrí.

17 min: Ṣé Ó Yẹ Kí N Gba Iṣẹ́ Tó Jẹ́ Ti Ètò Ẹ̀sìn Kan? Àsọyé tí alàgbà kan sọ, tí a gbé karí Ilé Ìṣọ́, April 15, 1999, ojú ìwé 28 sí 30. Àwọn kan ti gba irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀, wọ́n sì wá mọ̀ lẹ́yìn náà pé ohun tí àwọ́n ń ṣe kò bá ìlànà Bíbélì mu. Ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ìbéèrè tó yẹ kí a ronú nípa wọn nígbà tí a bá ń pinnu nípa ṣíṣe iṣẹ́ tó ní í ṣe pẹ̀lú ẹ̀sìn. Fún gbogbo àwùjọ níṣìírí pé kí wọ́n máa ṣe ohun tí yóò mú kí wọ́n rí i dájú pé àwọ́n ní ìdúró rere níwájú Jèhófà.—2 Kọ́r. 6:3, 4, 14-18.

Orin 109 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 27

Orin 166

5 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Rán àwọn akéde létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti oṣù December sílẹ̀.

10 min: “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run ti Ọdún 2000.” Àsọyé tí alábòójútó Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run sọ. Ṣàyẹ̀wò àwọn ìyípadà tó tẹ̀ lé e yìí nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún ọdún tuntun. Orí “Àwọn Àkòrí Ọ̀rọ̀ Bíbélì fún Ìjíròrò” gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ni a óò gbé Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kẹta kà. Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kẹrin ni a óò gbé kárí “Àwọn Àkòrí Ọ̀rọ̀ Bíbélì fún Ìjíròrò” gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. A lè yan Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kẹrin fún arákùnrin tàbí arábìnrin. Bí a bá fi àmì yìí, (#) ṣáájú ẹṣin ọ̀rọ̀ fún Iṣẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Kẹrin, ó dáa kó jẹ́ pé arákùnrin ni a óò yàn án fún. Fún gbogbo àwùjọ níṣìírí láti máa bá Bíbélì kíkà wọn ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ nìṣó, kí wọ́n sì máa jẹ́ aláápọn nínú ṣíṣe iṣẹ́ tí a bá yàn fún wọn ní ilé ẹ̀kọ náà.

15 min: “Kí Lo Máa Sọ fún Ẹni Tí Kò Gbà Pé Ọlọ́run Wà?” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ṣàtúnyẹ̀wò onírúurú ìdí tí ọ̀pọ̀ kò fi gba pé Ọlọ́run wà. Dábàá àwọn ọ̀nà díẹ̀ tí a lè gbà bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú wọn láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí i bó ṣe bọ́gbọ́n mu tó láti gbà pé Ọlọ́run wà. Jẹ́ kí a ṣe àṣefihàn kan tàbí méjì ní ṣókí. Fún ìsọfúnni sí i, wo ìwé Reasoning, ojú ìwé 145 sí 151, àti ìwé Mankind’s Search for God, orí 14.

15 min: Fífi Àwọn Ìwé Ògbólógbòó Lọni ní Oṣù January. Àsọyé àti àwọn àṣefihàn. Fi ìwé ogbólógbòó méjì tàbí mẹ́ta tí ìjọ bá ní lọ́wọ́ hàn, tó jẹ́ olójú ìwé 192, tí a tẹ̀ jáde ṣáájú ọdún 1986, kí o sì rọ àwọn akéde láti gba díẹ̀ sọ́wọ́, èyí tí wọn yóò lò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. (Bí kò bá sí èyíkéyìí, jíròrò ìfilọni àfidípò fún oṣù January.) Ṣàlàyé ìdí tí àwọn ìtẹ̀jáde ògbólógbòó wọ̀nyí fi gbéṣẹ́ síbẹ̀ fún mímú kí àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ nínú Bíbélì. Nínú ìwé kọ̀ọ̀kan, ṣàlàyé àwọn kókó ìjíròrò àti àwòrán tí a lè lò lọ́nà rere láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò. Ṣàṣefihàn ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ kan tàbí méjì. Níbi tí wọ́n bá ti fi ìfẹ́ hàn, a lè lo ìwé pẹlẹbẹ Béèrè láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́.

Orin 224 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 3

Orin 10

5 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò.

15 min: Mọ Bí A Ṣeé Dáhùn. (Kól. 4:6) Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Ìwé Reasoning jẹ́ ìrànwọ́ àgbàyanu láti ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún sísọ òtítọ́ Bíbélì fún àwọn ẹlòmíràn. Nígbà tí onílé kan bá gbé àtakò dìde sí ọ̀kan nínú àwọn ohun tí a gbà gbọ́, ó ṣeé ṣe kí a lo apá náà, “If Someone Says—” [Bí ẹnì kan bá sọ pé—], tó wà ní apá ìparí ibi tó sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ tó gbé àtakò dìde sí náà. Jíròrò ohun tí àwọn èèyàn lè sọ nípa Bíbélì tí a kọ sí ojú ìwé 64 sí 68, sì jíròrò ìdí tí àwọn èsì tí a dábàá fi lè gbéṣẹ́.

25 min: “Jẹ́ Kí Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà Jẹ́ Ohun Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ ní Ìgbésí Ayé Rẹ.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu ẹnì kan tí kò tíì ṣe ìgbéyàwó àti olórí ìdílé kan táwọn méjèèjì ti ṣàṣeyọrí ní títẹ̀lé ìṣètò tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, tó sì ṣe déédéé nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Jẹ́ kí wọ́n sọ àwọn ìṣètò ara ẹni tí wọ́n ṣe kí wọ́n tó lè fi àwọn ire tẹ̀mí sí ipò kìíní.

Orin 119 àti àdúrà ìparí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́