Kí Lo Máa Sọ fún Ẹni Tí Kò Gbà Pé Ọlọ́run Wà?
1 Ọ̀jọ̀gbọ́n kan láti Poland sọ fún míṣọ́nnárì kan ní ilẹ̀ Áfíríkà pé: “Mi ò gbà pé Ọlọ́run wà.” Bó ti wù kó rí, arábìnrin náà bá obìnrin yẹn jíròrò, ó sì fún obìnrin yẹn ní ìwé náà, Life—How Did It Get Here? By Evolution or by Creation? Nígbà tí arábìnrin náà padà débẹ̀ ní ọ̀sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, ọ̀jọ̀gbọ́n náà sọ fún un pé: “Mo ti wá gbà pé Ọlọ́run wà!” Ó ti ka ìwé Creation tán láti ìbẹ̀rẹ̀ dópin, ó sì wá béèrè fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kí lo lè ṣe kí o bàa lè jẹ́rìí fún àwọn tó bá sọ pé àwọn ò gbà pé Ọlọ́run wà. Lákọ̀ọ́kọ́, ṣàyẹ̀wò onírúurú ìdí tí àwọn èèyàn ṣe máa ń sọ bẹ́ẹ̀.
2 Àwọn Ìdí Tí Ń Mú Kí Àwọn Èèyàn Má Gbà Gbọ́: Kì í ṣe gbogbo àwọn tí kò gbà pé Ọlọ́run wà ló rí bẹ́ẹ̀ láti kékeré. Ọ̀pọ̀ ló jẹ́ pé wọ́n ti ní ẹ̀sìn tiwọn rí, tó sì jẹ́ pé nígbà kan rí, wọ́n gba pé Ọlọ́run wà. Ṣùgbọ́n, bóyá nítorí àìsàn burúkú kan tó ń yọ wọ́n lẹ́nu, ìṣòro ìdílé, tàbí àwọn ìwà ìrẹ́jẹ kan tí a hù sí wọn ló mú kí ìgbàgbọ́ wọn di ahẹrẹpẹ. Àwọn míì sì rèé, irú ẹ̀kọ́ tí wọ́n kọ́ ní yunifásítì ló mú kí wọ́n ní èrò òdì nípa Ọlọ́run. Kíyè sí àwọn àpẹẹrẹ tó tẹ̀ lé e yìí nípa àwọn tí kò gbà pé Ọlọ́run wà ṣùgbọ́n tí wọ́n wá ní ìgbàgbọ́ lílágbára nínú Jèhófà Ọlọ́run lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, tí wọ́n sì di Ẹlẹ́rìí rẹ̀.
3 Obìnrin kan wà ní Paris tó jẹ́ pé ṣe ni wọ́n bíi pẹ̀lú àrùn inú egungun tó máa ń sọni di aláìlágbára. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n batisí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́sìn Kátólíìkì, ó sọ pé òun ò gbà pé Ọlọ́run wà. Nígbà tó béèrè lọ́wọ́ àwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé nípa ìdí tí Ọlọ́run ṣe jẹ́ kí wọ́n bí òun pẹ̀lú irú àbùkù ara bẹ́ẹ̀, ìdáhùn wọn ni pé: “Nítorí pé ó nífẹ̀ẹ́ rẹ ni.” Ó kọ̀ láti gbà pẹ̀lú èrò òdì yẹn. Síwájú sí i, gbọ́ nípa ọ̀dọ́ kan ní Finland, ẹni tí wọ́n ṣàwárí pé àrùn tí kò gbóògùn kan wà nínú ìṣù ẹran ara rẹ̀, tó sì wá jẹ́ pé orí àga arọ ló gbọ́dọ̀ máa wà. Ìyá rẹ̀ gbé e lọ sọ́dọ̀ ẹlẹ́sìn Pẹntikọ́sítà kan tó sọ pé òún máa ń wo àwọn aláìsàn sàn. Ṣùgbọ́n àwọn oníṣẹ́ ìyanu kò lè wò ó sàn. Nítorí èyí, ọ̀dọ́kùnrin yìí kò nífẹ̀ẹ́ sí Ọlọ́run mọ́, kò sì gbà pé Ọlọ́run wà.
4 Ọkùnrin kan wà lórílẹ̀-èdè Honduras, tí wọ́n bí sínú ẹ̀sìn Kátólíìkì, ṣùgbọ́n ẹ̀kọ́ nípa Ọrọ̀ Ajé àti Ìṣèlú àti ẹ̀kọ́ pé Ọlọ́run ò sí ló kọ́. Ẹ̀kọ́ tó kọ́ ní yunifásítì pé ẹ̀dá ènìyàn jẹ́ ìmújáde ẹfolúṣọ̀n yí i lérò padà, ló bá di ẹni tí ò gba Ọlọ́run gbọ́ mọ́. Bákan náà, wọ́n bí obìnrin kan sínú ẹ̀sìn Mẹ́tọ́díìsì, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Ẹ̀kọ́ nípa ìrònú òun ìhùwà ló kọ́ ní yunifásítì. Báwo ló ṣe ní ipa lórí ìgbàgbọ́ rẹ̀? Ó sọ pé: “Ní ìgbà ẹ̀rùn kan ṣoṣo, wọ́n pa gbogbo ìgbàgbọ́ tí mo ní nínú ẹ̀sìn run.”
5 Dídé Inú Ọkàn Àwọn Aláìlábòsí: Ọ̀pọ̀ lára àwọn tí ò gba pé Ọlọ́run wà yóò fẹ́ láti mọ̀ bóyá ìṣòro àìlera, aáwọ̀ nínú ìdílé, ìwà ìrẹ́jẹ, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ní ojútùú. Wọ́n ń fẹ́ tọkàntọkàn láti rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè bíi: ‘Kí ló dé tí nǹkan burúkú fi ń ṣẹlẹ̀?’ ‘Kí ló dé tí nǹkan búburú fi ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn èèyàn rere?’ àti ‘Kí ni ìtumọ̀ ìgbésí ayé?’
6 Wọ́n tọ́ tọkọtaya kan tí ń gbé ní Switzerland dàgbà láti gbà gbọ́ pé Ọlọ́run ò sí. Nígbà tí a kọ́kọ́ mú òtítọ́ dé ọ̀dọ̀ wọn, wọn ò fẹ́ gbọ́. Ṣùgbọ́n, wọ́n ní ìṣòro ńlá nínú ìdílé wọn, wọ́n sì ń ronú láti kọ ara wọn sílẹ̀. Nígbà tí Ẹlẹ́rìí náà tún padà wá, ó fi bí tọkọtaya yìí ṣe lè borí àwọn ìṣòro wọn hàn wọ́n nínú Bíbélì. Ìmọ̀ràn gbígbéṣẹ́ tó wà nínú Ìwé Mímọ́ ya tọkọtaya náà lẹ́nu, wọ́n sì gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìgbéyàwó wọn lókun sí i, wọ́n tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, wọ́n sì ṣe batisí.
7 Ohun Tóo Lè Sọ Fáwọn Tí Kò Gbà Pé Ọlọ́run Wà: Bí ẹnì kan bá sọ fún ẹ pé òun ò gbà pé Ọlọ́run wà, gbìyànjú láti mọ ìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀. Ṣé torí ẹ̀kọ́ tó kọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ ni, ṣé torí àwọn ìṣòro tó ti ní ni, tàbí torí àgàbàgebè àti àwọn ẹ̀kọ́ èké tó rí nínú ẹ̀sìn ni? O lè bíi pé: “Ṣé èrò ẹ nìyí látẹ̀yìnwá?” tàbí “Kí ló dé tí o fi sọ bẹ́ẹ̀?” Ìdáhùn rẹ̀ á jẹ́ kí o mọ ohun tó yẹ kí o sọ. Níbi tó bá jẹ́ pé ó yẹ kí o ṣàlàyé gidigidi, ó lè jẹ́ pé ìwé náà, Is There a Creator Who Cares About You? gan-an lo nílò.
8 O lè wọ́nà láti bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú ẹni tí kò gbà pé Ọlọ́run wà nípa bíbéèrè pé:
◼ “Ǹjẹ́ o ti ṣe kàyéfì rí pé: ‘Bí Ọlọ́run bá wà, kí ló dé tí ìjìyà àti ìrẹ́jẹ fi pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ nínú ayé?’ [Jẹ́ kó fèsì.] Ṣé mo lè fi ohun tí Bíbélì sọ nípa kókó ọ̀rọ̀ yìí hàn ọ́?” Ka Jeremáyà 10:23. Bí o bá kà á tán, sọ pé kó sọ èrò rẹ̀ nípa ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí. Lẹ́yìn náà, fi ojú ìwé 16 àti 17 hàn án nínú ìwé pẹlẹbẹ náà, Will There Ever Be a World Without War? Tàbí dípò èyí, o lè lo orí kẹwàá ìwé Creator. Sọ pé kó gba ìwé náà, kó sì ka ohun tó wà nínú rẹ̀.—Fún àbá síwájú sí i, wo ìwé Reasoning, ojú ìwé 150 àti 151.
9 Lóòótọ́, kì í ṣe gbogbo àwọn tí kò gbà pé Ọlọ́run wà ni yóò tẹ́wọ́ gba òtítọ́. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ wà tí wọ́n ṣe tán láti ronú nípa ojú ìwòye mìíràn. Fọgbọ́n ṣe é, rọ̀ wọ́n, àti ju gbogbo rẹ̀ lọ, lo agbára Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti mú kí wọ́n rí òtítọ́.—Ìṣe 28:23, 24; Héb. 4:12.