ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/13 ojú ìwé 4-6
  • Àwọn Ìrírí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìrírí
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bá A Ṣe Lè Lo Ìwé Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
  • Fara Wé Jèhófà Nípa Fífi Tinútinú Ṣàníyàn Nípa Àwọn Ẹlòmíràn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Fi Àwọn Ìwé Pẹlẹbẹ Pòkìkí Ìhìn Rere Ìjọba Náà
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • A Máa Lo Ìwé Pẹlẹbẹ Tuntun Lóde Ẹ̀rí!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
km 12/13 ojú ìwé 4-6

Àwọn Ìrírí

◼ Ọsirélíà: Ọkùnrin kan tó kàwé dáadáa, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ John máa ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì nígbà tó wà lọ́mọdé, àmọ́ nígbà tó yá kò tiẹ̀ wá gbà pé Ọlọ́run wà rárá. Aṣáájú-ọ̀nà kan fún un ní ìwé náà Was Life Created? Nígbà tí aṣáájú-ọ̀nà náà tún pa dà lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó fún un ní ìwé Origin of Life. Aṣáájú-ọ̀nà náà wá ń mú àwọn ìwé ìròyìn tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ dé lọ fún un, ó sì máa ń tọ́ka sí àwọn àpilẹ̀kọ tó bá sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀dá tàbí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì. Nígbà tí aṣáájú-ọ̀nà náà rí i pé ó ti tó àkókò, ó fún John ní ìwé náà, The Bible—God’s Word or Man’s? Lẹ́yìn tí John kà á, ó bẹ̀rẹ̀ sí í sọ pé òun ò lè fi taratara sọ pé Ọlọ́run kò sí. Lẹ́yìn náà, aṣáájú-ọ̀nà yẹn fún un ní ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni, ó sì ka ìpínrọ̀ 8 lójú ìwé 20 àtàwọn ìpínrọ̀ 13 sí 16 lójú ìwé 23 sí 24 fún John. Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nínú ìwé náà wọ John lọ́kàn gan-an débi tó fi sọ pé, “Ó dà bíi pé màá bẹ̀rẹ̀ sí í ka Bíbélì lẹ́ẹ̀kan sí i.”

◼ Mẹ́síkò: Ọkùnrin kan sọ fún akéde kan pé òun kò gbà pé Ọlọ́run ló mí sí Bíbélì. Akéde náà ní kó jẹ́ kóun fi ẹ̀rí tó fi hàn pé Ọlọ́run ló mí sí Bíbélì hàn án. Lẹ́yìn ìjíròrò díẹ̀, ohun tí ọkùnrin náà ń kọ́ látinú Bíbélì bẹ̀rẹ̀ sí í wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an. Ohun tó wọ̀ ọ́ lọ́kàn jù lọ ni ohun tó kọ́ nípa àwọn ìlànà Ọlọ́run. Ó sọ fún akéde náà pé: “Tẹ́lẹ̀ tá a bá jọ ń ka Bíbélì, kò yàtọ̀ sí ìgbà tí mò ń ka àwọn ìwé kan ṣáá, kì í sì í wọ̀ mí lọ́kàn. Àmọ́ ní báyìí, ó máa ń jinlẹ̀ lọ́kàn mi, pàápàá tá a bá ka àwọn ìmọ̀ràn Ọlọ́run nípa ìwà rere.”

◼ Amẹ́ríkà: Nígbà tí tọkọtaya kan ń kópa nínú àkànṣe ìwàásù láwọn ìlú tí èrò pọ̀ sí, wọ́n pàdé obìnrin kan tó wá láti orílẹ̀-èdè Taiwan tó gbà pé Ọlọ́run wà, àmọ́ ó rò pé àwọn ará ìwọ̀ oòrùn ayé ni Bíbélì wà fún. Obìnrin náà wá síbi tábìlì tí wọ́n kó àwọn ìwé wa sí torí pé bo tiẹ̀ jẹ́ pé nǹkan ń lọ dáadáa fún un, ayé ti sú u. Ó wò ó pé Bíbélì lè jẹ́ kóun mọ ohun tí òun máa fi ìgbésí ayé òun ṣe. Tọkọtaya náà bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni àti ìwé pẹlẹbẹ náà Lasting Peace and Happiness—How to Find Them láti kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́. Wọn fi orí kejì nínú ìwé náà sílẹ̀, wọ́n wá jíròrò apá tó sọ pé, “A Guidebook for the Blessing of All Mankind” pẹ̀lú rẹ̀. Lẹ́yìn tí wọ́n jíròrò ìpínrọ̀ mẹ́fà àkọ́kọ́ ní apá yẹn, obìnrin náà sọ pé ó ya òun lẹ́nu pé ìyàtọ̀ tó pọ̀ gan-an ló wà láàárín Bíbélì àti àwọn ìwé ẹ̀sìn míì. Lẹ́yìn tí wọ́n jíròrò àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó ti ní ìmúṣẹ, obìnrin náà sọ pé, “Kò sí ìwé míì tí mo lè ronú kàn báyìí tí ọ̀rọ̀ rẹ̀ péye bíi ti Bíbélì!”

◼ Japan: Bó tilẹ̀ jẹ́ pé onílé kan sọ fún akéde kan pé òun ò gba Ọlọ́run gbọ́, akéde náà ṣì máa ń ṣe ìbẹ̀wò ṣókí sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì máa ń jíròrò àwọn àpilẹ̀kọ́ tá a pè ní “Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?” tó máa ń jáde nínú Jí! pẹ̀lú rẹ̀. Díẹ̀díẹ̀, ọkùnrin náà yí èrò rẹ̀ pa dà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbà pé ó ṣeé ṣe kí Ẹlẹ́dàá kan wà lóòótọ́. Nísinsìnyí ó ti wá gbà gbọ́ pé Ọlọ́run wà, akéde náà sì ń lo ìwé pẹlẹbẹ náà Ìròyìn Ayọ̀ Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run! láti kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́.

◼ Kánádà: Arábìnrin kan fún obìnrin kan ní ìwé ìròyìn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde bí obìnrin náà ṣe jáde nílé, tó sì ń rìn lọ sídìí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀. Nígbà tí arábìnrin tó fún obìnrin náà ní ìwé ìròyìn pa dà wá, obìnrin náà sọ fún pé òun ò fẹ́ gbọ́ àti pé òun ò gbà pé Ọlọ́run wà. Arábìnrin náà pinnu pé òun ò ní jẹ́ kó sú òun, ó lọ fún obìnrin náà ní ìwé pẹlẹbẹ náà A Satisfying Life—How to Attain It. Nígbà tí arábìnrin náà bá obìnrin yìí nílé, ó sọ fún un pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé òun mọ̀ pé obìnrin náà kò gbà pé Ọlọ́run wà, òun ń ronú nípa rẹ̀ torí obìnrin náà jẹ́ òbí anìkàntọ́mọ. Ó fi ìpínrọ̀ 6 lójú ìwé 4 hàn án nínú ìwé náà, tó sọ̀rọ̀ nípa ibi téèyàn ti lè gba ìmọ̀ràn rere. Lẹ́yìn náà, ó rọ̀ ọ́ pé kó ka àbá tó wà ní ẹ̀kọ́ 2 nípa ọmọ títọ́. Inú obìnrin náà dùn gan-an, ó sì gba ìwé náà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́