Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run ti Ọdún 2000
1 Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run ti jẹ́ ìbùkún ńláǹlà fún àwọn èèyàn Jèhófà. Ní àádọ́ta ọdún tó ti kọjá, ó ti ran àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn lọ́wọ́ láti mú kí wọ́n lè sọ̀rọ̀ dáadáa ní gbangba kí wọ́n sì lè kọ́ni ní òtítọ́ Bíbélì lọ́nà tó gbéṣẹ́. (Sm. 145:10-12; Mát. 28:19, 20) Ǹjẹ́ o ti rí bí ilé ẹ̀kọ́ náà ṣe ràn ọ́ lọ́wọ́? Ó tún lè máa ràn ọ́ lọ́wọ́ nìṣó lọ́dún 2000 bí o bá kópa nínú rẹ̀ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́, tí o sì ń fi ìmọ̀ràn tí a bá fún ọ sílò.
2 Ìtọ́ni nípa àwọn iṣẹ́ tí a óò yàn fúnni àti ìtẹ̀jáde tí a óò lò wà lójú ìwé kìíní nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ilé ẹ̀kọ́ ti ọdún 2000. A sọ àkókò tí a yàn fún apá kọ̀ọ̀kan, ibi tí a ó ti mú ọ̀rọ̀ jáde, bí a ṣe ní láti gbé ọ̀rọ̀ kalẹ̀, àti àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ mìíràn. Jọ̀wọ́, wá àyè, kí o fara balẹ̀ ka ìtọ́ni náà, kí o sì fi wọ́n sílò.
3 Bíbélì Kíkà Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀: Apá méjì ni ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó wà fún Bíbélì kíkà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ tí a tó sórí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ilé ẹ̀kọ́ pín sí. Ọ̀kan ni ètò gúnmọ́ tó wà fún kíka Bíbélì, tó ń kárí nǹkan bí ojú ìwé márùn-ún nínú Bíbélì. Orí Bíbélì kíkà yìí la máa ń gbé ṣíṣàlàyé àwọn kókó pàtàkì láti inú Bíbélì kà. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíkà kejì ni èyí tó jẹ́ àfikún, ó sì máa ń kárí ojú ìwé tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlọ́po méjì ti àkọ́kọ́. Nípa títẹ̀lé ìtòlẹ́sẹẹsẹ yìí, yóò ṣeé ṣe fún ọ láti ka Bíbélì tán lódindi láàárín ọdún mẹ́ta. A mọ̀ pé àwọn kan lè fẹ́ láti kà ju ohun tí a ṣètò nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ àfikún náà, ó sì lè má ṣeé ṣe fún àwọn míì láti kà tó bẹ́ẹ̀. Dípò tí wàá máa fi ara rẹ wé àwọn ẹlòmíràn, máa yọ̀ nínú ohun tí o bá lè ṣe. (Gál. 6:4) Ohun tó ṣe kókó ni pé kí a máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́.—Sm. 1:1-3.
4 Láti forúkọ sílẹ̀ nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run, bá alábòójútó ilé ẹ̀kọ́ sọ̀rọ̀. Jọ̀wọ́, máa fi ọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ tí a bá yàn fún ọ, má sì ṣe kùnà láti ṣe é, àyàfi tó bá di dandangbọ̀n pé kí o yẹ̀ ẹ́ sílẹ̀. Mọrírì ilé ẹ̀kọ́ yìí pé ó jẹ́ ìpèsè látọ̀dọ̀ Jèhófà. Múra sílẹ̀ dáadáa, mọ iṣẹ́ tí a yàn fún ọ dunjú, kí o sì sọ̀rọ̀ tọkàntọkàn, wàá sì tipa báyìí jèrè ní kíkún nínú ilé ẹ̀kọ́ aláìlẹ́gbẹ́ yìí.