Fara Wé Jèhófà Tí Kì Í Ṣojúsàájú
1 Jèhófà máa ń ṣàníyàn nípa àwọn èèyàn. Ó máa ń tẹ́wọ́ gba ẹnikẹ́ni tó bá ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀ láìṣojúṣàájú. (Ìṣe 10:34, 35) Nígbà tí Jésù ń wàásù fún àwọn èèyàn, òun náà ò ṣojúsàájú. (Lúùkù 20:21) Ó yẹ ká fara wé àpẹẹrẹ wọn gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ti ṣe, tó kọ̀wé pé: “Olúwa kan náà ní ń bẹ lórí gbogbo wọn, ẹni tí ó jẹ́ ọlọ́rọ̀ sí gbogbo àwọn tí ń ké pè é.”—Róòmù 10:12.
2 Pípòkìkí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún gbogbo ẹni tí a bá bá pàdé ń fi ògo fún Ọlọ́run. A gbọ́dọ̀ máa sọ fún àwọn ẹlòmíràn nípa ìhìn àgbàyanu yìí, ẹ̀yà yòówù kí wọ́n jẹ́, ipò yòówù kí wọ́n wà láàárín ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, bó ti wù kí wọ́n kàwé tó, tàbí bó ti wù kí wọ́n lówó tó. (Róòmù 10:11-13) Èyí túmọ̀ sí wíwàásù fún àwọn tó bá fetí sílẹ̀—àwọn ọkùnrin, obìnrin, ọmọdé àti àgbà. Gbogbo ẹnu ọ̀nà ilé ló yẹ ká dé láti fún onílé kọ̀ọ̀kan láǹfààní láti gbọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́.
3 Máa Fi Ìfẹ́ Hàn Nínú Ẹni Gbogbo: Ká dé ọ̀dọ̀ gbogbo ẹni tó bá ṣeé ṣe láti dé ni góńgó wa. Pẹ̀lú èyí lọ́kàn, ó ti ṣeéṣe fáwọn akéde kan láti jẹ́rìí fún àwọn èèyàn ní ibi iṣẹ́ àwọn dókítà, ní ilé ìwòsàn, ní ilé àwọn tó ń tọ́jú ọmọ, ní àwọn ọ́fíìsì ẹgbẹ́ afẹ́nifẹ́re, àti àwọn ibùdó tí wọ́n ti ń dá àwọn tó ti sọ àwọn àṣà kan di bárakú lẹ́kọ̀ọ́. Ní àfikún sí i, àwọn akéde ti jẹ́rìí fún àwọn tí ń bójú tó ilé ìgbókùúsí, àwọn alábòójútó àti olùgbani-nímọ̀ràn ní ilé ẹ̀kọ́, àti àwọn adájọ́. Bí o bá fẹ́ bá àwọn lọ́gàá-lọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ sọ̀rọ̀, ó dáa pé kí o dúpẹ́ fún iṣẹ́ ìrànwọ́ tí wọ́n ń ṣe láàárín ìlú. Bọ̀wọ̀ fún wọn, kí o sì lo àpilẹ̀kọ tó bágbà mu, tó sọ ní pàtàkì nípa irú iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe àti àwọn ìṣòro tí ń bá irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ rìn.
4 Ní àkókò kan, arábìnrin kan gbìyànjú, ó sì bá adájọ́ kan sọ̀rọ̀ ní ọ́fíìsì adájọ́ náà. Lẹ́yìn ìjíròrò ọlọ́yàyà yìí, adájọ́ náà sọ̀rọ̀ wẹ́rẹ́ pé: “Ǹjẹ́ o mọ nǹkan tí mo fẹ́ràn lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Wọ́n ní àwọn ìlànà tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, wọ́n sì máa ń tẹ̀ lé wọn dáadáa.” Arábìnrin yẹn jẹ́rìí dáadáa fún èèyàn ńlá yìí.
5 A ò lè mọ nǹkan tí ń bẹ lọ́kàn àwọn èèyàn. Ṣùgbọ́n, nípa bíbá gbogbo ẹni tí a bá bá pàdé sọ̀rọ̀, a ń fi ìgbàgbọ́ wa hàn nínú agbára tí Ọlọ́run ní láti darí iṣẹ́ wa. Síwájú sí i, èyí ń fún àwọn èèyàn láǹfààní láti gbọ́ ìhìn tí ń fúnni nírètí, kí wọ́n sì gbé ìgbésẹ̀ lórí rẹ̀. (1 Tím. 2:3, 4) Ẹ jẹ́ kí a máa fọgbọ́n lo àkókò wa, kí a sì máa sakun láti fara wé Jèhófà tí kì í ṣojúsàájú nípa mímú ìhìn rere dé ọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn tí a bá lè dé.—Róòmù 2:11; Éfé. 5:1, 2.