Fi Hàn Pé Ọ̀rọ̀ Àwọn Èèyàn Jẹ Ọ́ Lógún—Nípa Wíwàásù fún Gbogbo Èèyàn Láìdá Ẹnì Kan Sí
1 Àpọ́sítélì Jòhánù ríran pé áńgẹ́lì kan ń fò lágbedeméjì ọ̀run, ó ń polongo ìhìn rere àìnípẹ̀kun fáwọn èèyàn “orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n.” (Ìṣí. 14:6) Ṣé à ń wàásù fún gbogbo èèyàn láìdá ẹnì kan sí bíi ti áńgẹ́lì yẹn? Láìmọ̀ọ́mọ̀, a lè máa hùwà tó fi hàn pé a fẹ́ràn àwọn kan ju àwọn kan lọ. Èrò wa nípa àwọn èèyàn tá à ń bá pàdé lè ní ipa lórí ọ̀nà tá a máa gbà wàásù fún wọn. Nítorí náà, ìfẹ́ tó dénú ló yẹ ká máa fi bá onírúurú èèyàn tá à ń wàásù fún lò.
2 Wo Irú Àwọn Èèyàn Tó Wà ní Ìpínlẹ̀ Ìwàásù Yín: Ṣé àwọn tó ṣí wá láti ilẹ̀ òkèèrè tàbí àwọn tí ogun lé wọ̀lú wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín? Ó rọrùn láti gbójú fò wọ́n dá. Ìwọ ni kó o kọ́kọ́ wá wọn lọ, kó o sì gbìyànjú láti mọ̀ wọ́n dáadáa. Kí ni wọ́n nílò, kí ló jẹ wọ́n lógún, kí ni wọ́n fẹ́, kí ni wọn ò sì fẹ́, kí ló ń dà wọ́n lọ́kàn rú, ohun tí ò bára dé wo ló sì ń ṣẹlẹ̀ sí wọn? Gbìyànjú láti jẹ́ kí ìwàásù rẹ bá àwọn nǹkan wọ̀nyẹn mu. (1 Kọ́r. 9:19-23) Bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, a gbọ́dọ̀ rí i bí ojúṣe wa láti wàásù ìhìn rere fún gbogbo èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa tó fi mọ́ àwọn tó ṣí wá láti ilẹ̀ òkèèrè, àwọn tí àṣà wọn yàtọ̀ sí tiwa, àwọn tí èdè wọn yàtọ̀ sí tiwa àti àwọn tó rí já jẹ jù wá lọ.—Róòmù 1:14.
3 Ọ̀nà wo la wá lè gbà jẹ́rìí fẹ́ni tó ń sọ èdè tó yàtọ̀ sí tiwa o? Lo ìwé pẹlẹbẹ náà Good News for People of All Nations. O sì tún lè kó ìwé àṣàrò kúkúrú tàbí ìwé pẹlẹbẹ mélòó kan dání lédè táwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín sábà máa ń sọ. (Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa July 2003, ojú ìwé 8, ìpínrọ̀ 2 àti 3.) Láfikún sí i, àwọn akéde kan ti sapá láti kọ́ ìkíni àti ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ ṣókí láwọn èdè míì. Inú àwọn èèyàn máa ń dùn tí wọ́n bá rẹ́ni tó ń gbìyànjú láti bá wọn sọ̀rọ̀ lédè wọn kódà kó jẹ́ pé táátààtá lásán lẹni náà gbọ́, èyí lè mú kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn rere.
4 Fara Wé Jèhófà: Bó bá jẹ́ pé onírúurú èèyàn là ń wàásù fún, a jẹ́ pé Ọlọ́run wa, Jèhófà tí kì í ṣojúsàájú là ń fara wé, “ẹni tí ó jẹ́ ìfẹ́ rẹ̀ pé kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.”—1 Tím. 2:3, 4.