Mímú Ìhìn Rere Dé Ọ̀dọ̀ Ènìyàn Púpọ̀ Sí I
BÍ MO ti ń ronú nípa àwọn ènìyàn ní orílẹ̀-èdè mi, ó wá sí mi lọ́kàn pé kìkì láti àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn ni ọ̀pọ̀ nínú wọ́n ti mọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Mo ronú pé, ó yẹ kí a kàn sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, kí wọ́n lè mọ irú ẹni tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́, àti ohun tí wọ́n gbà gbọ́ ní ti gidi. Ṣùgbọ́n, báwo ni mo ṣe lè ṣèrànwọ́? Kristẹni alàgbà ni ọkọ mi, ó sì fún mi ní ìtọ́ni àti àbá tí ó mọ́gbọ́n dání.
A rí èrò pàtàkì kan nínú àpilẹ̀kọ náà, “Àwọn Ìwé-Ìròyìn Tí Ó Fúnni ní Ìtùnú Tí Ó Wúlò,” tí a tẹ̀ jáde nínú ìwé ìròyìn Jí! ti January 8, 1995. Nípa ìgbòkègbodò Ẹlẹ́rìí kan, àpilẹ̀kọ náà sọ pé: “Ó ti sọ ọ́ di iṣẹ́ láti ṣa àwọn ògbólógbòó ẹ̀dà irú àwọn ìwé-ìròyìn Jí! kan tí àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn ti kójọ sí ilé. Lẹ́yìn náà, yóò ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn aṣojú tí ó ronú pé wọ́n lè fi ọkàn-ìfẹ́ pàtàkì hàn nínú díẹ̀ lára àwọn àkòrí ọrọ̀ ìwé-ìròyìn náà.”
Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ọkọ mi, kò pẹ́ tí mo fi kó ọgọ́rọ̀ọ̀rún ẹ̀dà ìwé ìròyìn jọ. Láti inú ìwọ̀nyí, ó ṣeé ṣe fún mi láti ṣa onírúurú kókó ẹ̀kọ́ tí ó bá àwọn ènìyàn tí n óò gbìyànjú láti kàn sí mu.
Ní lílo ìwé tẹlifóònù àti àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn ibi tí ó jẹ́ ti gbogbogbòò, mo ṣàkójọ orúkọ àwọn ilé ìwòsàn, ibùgbé àwọn ọ̀dọ́, àti ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó. Mo tún ṣàkójọ orúkọ àwọn olùdarí ayẹyẹ ìsìnkú, àwọn alábòójútó àti olùgbaninímọ̀ràn ní ilé ẹ̀kọ́, àwọn olùṣàyẹ̀wò òkú, àti àwọn òṣìṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n àti ti ilé ẹjọ́. Orúkọ àwọn olùdarí àjọ tí ń mojú tó àwọn onímukúmu àti ajoògùnyó, àwọn ẹgbẹ́ tí ń bójú tó àwọn ọ̀ràn tí ó jẹ mọ́ àyíká, tí ń bójú tó àwọn aláàbọ̀ ara àti àwọn òjìyà ogun, àti àwọn tí ń ṣèwádìí èròjà inú oúnjẹ wà nínú àkójọ mi. N kò sì gbójú fo àwọn ọ̀gá ọ́fíìsì tí ń bójú tó ire ará ìlú, àwọn ohun amáyédẹrùn, àti àlámọ̀rí ìdílé.
Kí Ni N Óò Sọ?
Ohun àkọ́kọ́ tí mo máa ń ṣe nígbà tí mo bá ṣèbẹ̀wò ni láti sọ ẹni tí mo jẹ́ ní kedere. Lẹ́yìn náà, n óò sọ pé ìbẹ̀wò mi kò ní ju ìṣẹ́jú bíi mélòó kan lọ.
Nígbà tí mo bá rí ọ̀gá ibẹ̀, n óò sọ pé: “Mo jẹ́ ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ṣùgbọ́n, n kò wá síhìn-ín láti jíròrò nípa ìsìn, tí ó lè máà bójú mu lákòókò iṣẹ́.” Lọ́pọ̀ ìgbà, ara yóò tu ẹni náà. Lẹ́yìn náà, ní mímú ọ̀rọ̀ mi bá ipò nǹkan mu, n óò máa bá ọ̀rọ̀ mi lọ pé: “Ohun méjì ni ó gbé mi wá síhìn-ín. Àkọ́kọ́, mo fẹ́ láti fi ìmọrírì mi hàn fún iṣẹ́ ribiribi tí ọ́fíìsì yín ń bójú tó. Ó ṣe tán, kò yẹ kí a fojú kéré rẹ̀ pé ẹnì kan ń lo àkókò àti okun rẹ̀ fún gbogbo mùtúmùwà. Dájúdájú, èyí yẹ fún oríyìn.” Lọ́pọ̀ ìgbà, ó máa ń ya àwọn tí mo bá bá sọ̀rọ̀ lọ́nà yìí lẹ́nu.
Ní báyìí, ẹni náà lè ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe kàyéfì nípa ìdí kejì tí mo fi wá síbẹ̀. N óò máa bá ọ̀rọ̀ mi lọ pé: “Ìdí kejì tí ó gbé mi wá síhìn-ín ni èyí: Láti inú ìwé ìròyìn Jí! wa, tí a ń tẹ̀ jáde kárí ayé, mo ti ṣa àwọn àpilẹ̀kọ kan tí ó ní í ṣe ní pàtàkì pẹ̀lú irú iṣẹ́ tí ẹ ń ṣe àti àwọn ìṣòro tí ó wé mọ́ ọn. Ó dá mi lójú pé, ẹ óò fẹ́ láti mọ irú ojú tí ìwé ìròyìn kan tí ó kárí ayé fi wo àwọn ìṣòro wọ̀nyí. Inú mi yóò dùn láti fi àwọn ẹ̀dà wọ̀nyí sílẹ̀ fún yín.” Lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń sọ fún mi pé a mọrírì ìsapá mi.
Àwọn Ìyọrísí Yíyanilẹ́nu, Tí Ó Sì Mérè Wá
Nígbà tí mo lo irú ìyọsíni yìí, ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn gbà mí tọwọ́tẹsẹ̀; ẹnì kan ṣoṣo nínú ẹni 17 ni kò tẹ́wọ́ gbà mí. Mo ní ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìrírí tí ó yà mí lẹ́nu, tí ó sì mérè wá.
Fún àpẹẹrẹ, lẹ́yìn gbígbìyànjú lẹ́ẹ̀mẹ́rin, tí mo sì ń fi sùúrù dúró, ó ṣeé ṣe fún mi láti rí olùbẹ̀wò ilé ẹ̀kọ́ àgbègbè kan. Ọkùnrin tí ọwọ́ rẹ̀ dí gidigidi ni. Síbẹ̀, ọlọ́yàyà ènìyàn ni, ó sì bá mi sọ̀rọ̀ fún ìṣẹ́jú díẹ̀. Bí mo ti ń jáde lọ, ó sọ pé: “Mo mọrírì ìsapá rẹ gidigidi, n óò sì fara balẹ̀ ka ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí o fún mi dáradára.”
Ní àkókò mìíràn, mo ṣèbẹ̀wò sí ilé ẹjọ́ àgbègbè kan, mo sì ṣalábàápàdé adájọ́ àgbà, ọkùnrin ọlọ́jọ́lórí kan. Nígbà tí mo wọ inú ọ́fíìsì rẹ̀, ó gbójú sókè kúrò níbi ìwé tí ó ń kà, pẹ̀lú inú ríru ṣùṣù.
Ó sọ tìbínútìbínú pé: “Òwúrọ̀ Tuesday nìkan ṣoṣo ni mo máa ń gbàlejò, n óò sì ráyè láti fún ọ ní ìsọfúnni èyíkéyìí.”
Mo fèsì ní kíákíá pé: “Ẹ jẹ́ kí n tọrọ àforíjì fún wíwá ní àkókò tí kò rọgbọ.” Mo sì fi kún un pé: “Dájúdájú, inú mi yóò dùn láti padà wá ní àkókò mìíràn. Ṣùgbọ́n, ọ̀ràn ara ẹni ni ó gbé mi wá.”
Wàyí ó, adájọ́ náà ń hára gàgà láti gbọ́ ohun tí ó gbé mi wá. Pẹ̀lú ohùn jẹ́jẹ́, ó béèrè ohun tí mo fẹ́. Mo fèsì pé n óò padà wá ní ọjọ́ Tuesday.
Sí ìyàlẹ́nu mi, ó tẹpẹlẹ mọ́ ọn pé: “Jọ̀wọ́, fìdí kalẹ̀. Kí ni o fẹ́?”
Ìjíròrò alárinrin kan tẹ̀ lé e, ó sì tọrọ àforíjì fún kíkanra mọ́ mi ní ìbẹ̀rẹ̀, nítorí tí ọwọ́ òun dí ní ti gidi.
Nígbà tí ó yá, adájọ́ náà béèrè pé: “Ǹjẹ́ o mọ ohun tí mo fẹ́ràn nípa Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Wọ́n ní àwọn ìlànà tí ó fìdí múlẹ̀ ṣinṣin, tí wọn kì í yà bàrá kúrò nínú rẹ̀. Hitler ṣe gbogbo ohun tí ó lè ṣe, síbẹ̀, Àwọn Ẹlẹ́rìí kò lọ sí ogun.”
Nígbà tí àwa arábìnrin méjì wọnú ọ́fíìsì kan, àwọn akọ̀wé tí ó wà níbẹ̀ dá wa mọ̀. Lẹ́yìn náà, akọ̀wé àgbà sọ̀rọ̀ jáde, láìbìkítà pé, “Ààrẹ kì í gba ẹgbẹ́ kankan rárá.”
Mo fi pẹ̀lẹ́tù fèsì pé: “Ṣùgbọ́n, òun yóò gbà wá, nítorí Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá. A kì í ṣe olùbẹ̀bẹ̀, ìbẹ̀wò wa kò sì ní ju ìṣẹ́jú mẹ́ta lọ.” Mo gbàdúrà nínú ọkàn mi pé, “Dákun, Jèhófà, jẹ́ kí èyí yọrí sí rere!”
Akọ̀wé náà fèsì láìbìkítà pé, “Ó dára nígbà náà, n óò gbìyànjú.” Ó jáde lọ. Lẹ́yìn nǹkan bí ìṣẹ́jú méjì, tí ó dà bí ayérayé lójú mi, ó wọlé, pẹ̀lú ààrẹ fúnra rẹ̀. Láìsọ ohunkóhun, ó mú wa lọ sínú ọ́fíìsì rẹ̀, a gba yàrá méjì mìíràn kọjá.
Bí a ti bẹ̀rẹ̀ sí í jíròrò, ó túbọ̀ ń ṣọ̀yàyà. Ó tẹ́wọ́ gba àwọn ẹ̀dà àkànṣe ìwé ìròyìn Jí! náà tinútinú, nígbà tí a fi lọ̀ ọ́. A fọpẹ́ fún Jèhófà fún àǹfààní yìí tí a ní láti jẹ́rìí dáradára nípa ète iṣẹ́ wa.
Ní bíbojú wẹ̀yìn wo ọ̀pọ̀ ìrírí àgbàyanu tí mo ní, mo ti wá mọrírì ohun tí àpọ́sítélì Pétérù sọ ní kíkún sí i pé: “Dájúdájú, mo róye pé Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” (Ìṣe 10:34, 35) Ìfẹ́ inú Ọlọ́run ni pé kí a fún àwọn ènìyàn láti inú gbogbo ìpele ìgbésí ayé, èdè, tàbí ipò nínú àwùjọ ní àǹfààní láti mọ ète rẹ̀ fún aráyé àti fún orí ilẹ̀ ayé.—A kọ ọ́ ránṣẹ́.