ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w95 7/15 ojú ìwé 21-24
  • O Lè Borí Àwọn Ìdènà Wọ̀nyí!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • O Lè Borí Àwọn Ìdènà Wọ̀nyí!
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ó Ha Máa Ń Sú Ọ Bí?
  • Àpẹẹrẹ Búburú Ha Kó Ìrẹ̀wẹ̀sì Bá Ọ Bí?
  • Jíjẹ́ Kristian Ha Dàbí Ohun Tí Ó Ṣòro Gidigidi Bí?
  • Mímú kí Ìsúnniṣe Máa Báa Nìṣó
  • Bí Jèhófà Ṣe Ń ṣamọ̀nà Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ọlọrun Ha Gbapò Kìíní Nínú Ìdílé Rẹ Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Lọ Sípàdé?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Máa Pọkàn Pọ̀?
    Jí!—1998
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
w95 7/15 ojú ìwé 21-24

O Lè Borí Àwọn Ìdènà Wọ̀nyí!

ỌKỌ̀ òfúúrufú ńlá kan lè gbé ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn èrò àti ẹrù rẹpẹtẹ. Báwo ni ọkọ̀ òfúúrufú tí ó tóbi bẹ́ẹ̀ ṣe lè gbéra nílẹ̀? Ní ṣókí, ó jẹ́ nípasẹ̀ agbé-nǹkan-ròkè.

Nígbà tí ọkọ̀ òfúúrufú bá ń sáré lọ ní ọ̀nà tí a là sílẹ̀ fún un, afẹ́fẹ́ yóò máa gba orí àti abẹ́ àwọn ìyẹ́ rẹ̀ títẹ̀ kọjá. Èyí ń pèsè agbára ìlọsókè kan tí a ń pè ní agbé-nǹkan-ròkè. Nígbà tí ó bá mú agbé-nǹkan-ròkè tí ó tó jáde, ọkọ̀ òfúúrufú náà lè gbéra sókè kúrò nílẹ̀ kí ó sì fò. Àmọ́ ṣáá ó, ọkọ̀ òfúúrufú tí a bá ti dẹrùpa kò lè mú agbé-nǹkan-ròkè tí ó tó láti lè gbéra nílẹ̀ jáde.

Àwa pẹ̀lú ni a lè dẹrùpa. Ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn, Ọba Dafidi sọ pé ‘ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ òun dàbí ẹrù tí ó wúwo fún òun.’ (Orin Dafidi 38:4) Bákan náà, Jesu Kristi kìlọ̀ lòdì sí dídi ẹni tí a fi àníyàn ayé dẹrùpa. (Luku 21:34) Ìrònú àti ìmọ̀lára òdì lè dẹrùpa wá débi pé ó lè ṣòro láti “gbéra nílẹ̀.” A ha dẹrùpa ọ́ lọ́nà yìí bí? Tàbí o ha ti ní ìrírí àwọn ìdènà kan sí àwọn ìdàgbàsókè rẹ síwájú síi nípa tẹ̀mí? Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, kí ni ó lè ṣèrànwọ́?

Ó Ha Máa Ń Sú Ọ Bí?

Ẹ̀mí kí nǹkan súni—ìráhùn tí ó wọ́pọ̀ lónìí—lè di ohun ìdènà nípa ti èrò-orí, àní fún àwọn kan lára àwọn ènìyàn Jehofa pàápàá. Àwọn ọmọ kéékèèké ní pàtàkì ní ìtẹ̀sí láti kọ àwọn ìgbòkègbodò kan sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun tí ń súni. O ha máa ń ní ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ nígbà mìíràn nípa àwọn ìpàdé Kristian bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ni o lè ṣe láti mú kí pípésẹ̀ rẹ sí ìpàdé jẹ́ èyí tí ń ru ọ́ sókè?

Kíkópa ni kọ́kọ́rọ́ náà. Paulu kọ̀wé sí ọ̀dọ́mọkùnrin náà Timoteu pé: “Máa kọ́ ara rẹ pẹlu ìfọkànsin Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí ìfojúsùn rẹ. Nitori ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti ara ṣàǹfààní fún ohun díẹ̀; ṣugbọn ìfọkànsin Ọlọrun ṣàǹfààní fún ohun gbogbo, bí ó ti ní ìlérí ìyè ti ìsinsìnyí ati ti èyíinì tí ń bọ̀.” (1 Timoteu 4:7, 8) Ìwé lórí ìlera lè súni kí ìwúlò rẹ̀ sì láàlà bí a kò bá tẹ̀lé bí a ṣe lànà eré ìmáralé náà. Àwọn ìpàdé Kristian ni a ṣe láti mú èrò-inú wa lera yóò sì ṣe bẹ́ẹ̀ bí a bá múrasílẹ̀ tí a sì kópa. Ìlóhùnsí yìí yóò mú kí àwọn ìpàdé mú èrè wá kí ó sì gbádùnmọ́ni síi.

Nínú ọ̀ràn yìí, Kristian obìnrin kékeré kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mara sọ pé: “Bí n kò bá múrasílẹ̀ fún àwọn ìpàdé, n kì í gbádùn wọn. Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí mo bá ti múrasílẹ̀ ṣáájú, èrò-inú àti ọkàn-àyà mi máa ń ṣísílẹ̀ síi. Ìpàdé yóò nítumọ̀ síi, mo sì máa ń wọ̀nà fún lílóhùn síi.”

Kíkọ́ láti fetísílẹ̀ yóò tún ṣèrànwọ́. Fífetísílẹ̀ sí orin dídára rọrùn ó sì ń mú ìgbádùn wá lọ́gán. Ṣùgbọ́n kì í ṣe gbogbo ìtẹ́lọ́rùn ni ń wá lójú ẹsẹ̀. A máa ń rí ìtẹ́lọ́rùn gbà láti inú àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìpàdé kìkì bí a bá fetísílẹ̀ dáradára sí ohun tí wọ́n ń sọ. Kristian kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Rachel ṣàkíyèsí pé: “Bí olùbánisọ̀rọ̀ náà bá tutù, mo níláti pọkànpọ̀ gidi gan-an. Òfin tí ó wà fún mi ni pé, ‘Bí àsọyé náà kò bá gbádùnmọ́ni tó, bẹ́ẹ̀ ni mo níláti pọkànpọ̀ tó.’ . . . Mo máa ń pàfiyèsí àkànṣe sí àwọn ẹsẹ̀ ìwé mímọ́, ní gbígbìyànjú láti jèrè bí ó bá ti ṣeé ṣe tó láti inú wọn.” A níláti bá ara wa wí, bíi Rachel, kí a baà lè fetísílẹ̀. Ìwé Owe sọ pé: “Ọmọ mi, fiyèsí ọgbọ́n mi, kí o sì dẹtí rẹ sí òye mi.”—Owe 5:1.

Àwọn ìsọfúnni kan tí a sọ ní àwọn ìpàdé lè dàbí àwítúnwí. Èyí pọndandan! Gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọrun ni wọ́n nílò ìránnilétí. Ẹran-ara aláìpé, pẹ̀lú àwọn ìtẹ̀sí oníwà wíwọ́ rẹ̀ àti ìrántí tí ó mẹ́hẹ, nílò gbogbo ìrànlọ́wọ́ tí o lè rí gbà. Aposteli Peteru ‘múratán lati rán awọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ létí awọn nǹkan wọnyi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n mọ̀ wọ́n tí wọ́n sì fẹsẹ̀múlẹ̀ gbọn-in-gbọn-in ninu òtítọ́.’ (2 Peteru 1:12) Jesu pẹ̀lú ṣàlàyé pé “olúkúlùkù olùkọ́ni ní gbangba . . . dàbí ọkùnrin kan, baálé ilé kan, tí ń mú awọn ohun titun ati ògbólógbòó jáde lati inú ibi ìtọ́jú ìṣúra pamọ́ rẹ̀.” (Matteu 13:52) Nípa báyìí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìpàdé wa máa ń mú àwọn èrò Ìwé Mímọ́ tí kò ṣàjèjì jáde, tàbí ‘ìṣúra ògbólógbòó,’ àwọn ‘ìṣúra titun’ máa ń sábà wà láti mú ọkàn wa yọ̀.

Pípinnu láti lo àǹfààní àwọn ìpàdé dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ lè yọrí sí ìgbéró nípa tẹ̀mí. Jesu sọ pé: “Aláyọ̀ ni awọn wọnnì tí àìní wọn nipa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn [awọn tí wọ́n jẹ́ alágbe fún ohun tẹ̀mí].” (Matteu 5:3, àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé New World Translation of the Holy Scriptures—With References) Irú ìṣarasíhùwà báyìí sí oúnjẹ tẹ̀mí tí ó gbámúṣé tí a pèsè ní àwọn ìpàdé yóò mú kí nǹkan súni kúrò.—Matteu 24:45-47.

Àpẹẹrẹ Búburú Ha Kó Ìrẹ̀wẹ̀sì Bá Ọ Bí?

Ìwà ẹnì kan nínú ìjọ rẹ ha ti mú ọ bínú bí? Bóyá o ti ṣe kàyéfì pé, ‘Báwo ni arákùnrin kan ṣe lè hùwà ní ọ̀nà yẹn kí ó sì tún ní ìdúró rere?’ Irú àwọn èrò bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ ìdènà èrò-orí, kí ó sì fọ́ wa lójú sí ìníyelórí àjọṣepọ̀ tí ó gbádùnmọ́ni tí a lè ní pẹ̀lú àwọn ènìyàn Ọlọrun.—Orin Dafidi 133:1.

Bóyá àwọn kan lára àwọn mẹ́ḿbà ìjọ ní Kolosse ní ìṣòro tí ó farajọ èyí. Paulu gbà wọ́n níyànjú pé: “Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nìkínní kejì kí ẹ sì máa dáríji ara yín fàlàlà lẹ́nìkínní kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní èrèdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn.” (Kolosse 3:13) Paulu mọ̀ pé àwọn Kristian kan ní Kolosse ti lè hùwà ní ọ̀nà búburú kí wọ́n sì tipa báyìí fún àwọn mìíràn ní ìdí tí ó fẹsẹ̀múlẹ̀ láti ráhùn. Nítorí náà a kò níláti jẹ́ kí ó yà wá lẹ́nu ju bí ó ti yẹ lọ bí ọ̀kan lára àwọn arákùnrin tàbí arábìnrin wa kò bá dé ojú ìwọ̀n lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nínú àwọn ànímọ́ Kristian kan. Jesu fúnni ní ìmọ̀ràn tí ó yèkooro lórí yíyanjú àwọn ìṣòro tí ó lekoko. (Matteu 5:23, 24; 18:15-17) Ṣùgbọ́n ní ọ̀pọ̀ ìgbà, a wulẹ̀ lè faramọ́ àṣìṣe àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa kí a sì dáríjì wọ́n. (1 Peteru 4:8) Ní tòótọ́, irú ìgbésẹ̀ báyìí lè jẹ́ fún ire wa àti ti àwọn mìíràn. Èéṣe tí èyí fi rí bẹ́ẹ̀?

Owe 19:11 sọ pé: “Ìmòye ènìyàn mú un lọ́ra àti bínú; ògo rẹ̀ sì ní láti ré ẹ̀ṣẹ̀ kọjá.” Ẹ wo bí ó ti sàn tó láti dáríjì ju láti yọ̀ọ̀da fún ìbínú àti ìkannú láti dàgbà síi! Salvador, alàgbà kan tí a mọ̀ fún ẹ̀mí ìfẹ́ rẹ̀, sọ pé: “Nígbà tí arákùnrin kan bá bá mi lò lọ́nà tí ó burú tàbí tí ó bá sọ ohun kan tí kò fi inúrere hàn, mo máa ń bi ara mi pé: ‘Báwo ni mo ṣe lè ran arákùnrin mi lọ́wọ́? Báwo ni mo ṣe lè yẹra fún pípàdánù ipò-ìbátan mi tí ó ṣeyebíye pẹ̀lú rẹ̀?’ Mo máa ń bìkítà nípa bí ó ti rọrùn tó láti sọ ohun tí ó lòdì. Bí ẹnì kan bá sọ̀rọ̀ láìronú, ojútùú tí ó tọ́ yóò jẹ́ pé kí ó kó ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ kí ó sì tún bẹ̀rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan síi. Ṣùgbọ́n èyí kò ṣee ṣe, nítorí náà mo máa ń ṣe ohun tí ó kàn nípa gbígbójúfo ọ̀rọ̀ náà. Mo wulẹ̀ máa ń kà á sí pé ó jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ ẹran-ara aláìpé kàkà kí n máa ronú lórí irú ẹni tí arákùnrin mi jẹ́ níti gidi.”

O lè ronú pé èyí dùn-ún sọ. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ sinmi lórí ọ̀nà tí a gbà ń tọ́ ìrònú wa. Paulu fún wa nímọ̀ràn pé: “Ohun yòówù tí ó dára ní fífẹ́, . . . ẹ máa bá a lọ ní gbígba nǹkan wọnyi rò.” (Filippi 4:8) “Dára ní fífẹ́” ní òwuuru túmọ̀ sí “èyí tí ń súnni fi ìfẹ́ni hàn.” Jehofa fẹ́ kí a ṣàgbéyẹ̀wò ohun tí ó dára nínú àwọn ènìyàn, kí a tẹjú mọ́ èyí tí yóò mú ìfẹ́ni wá dípò ìbínú. Òun fúnra rẹ̀ fún wa ní àpẹẹrẹ tí ó ga jùlọ nínú ọ̀ràn yìí. Onipsalmu náà rán wa létí èyí, ní sísọ pé: “Oluwa, ìbáṣepé kí ìwọ kó máa sàmì ẹ̀ṣẹ̀, Oluwa, ta ni ìbá dúró?”—Orin Dafidi 103:12; 130:3.

Nítòótọ́, ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ kan ìwà arákùnrin kan lè múni nímọ̀lára ìjákulẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ jùlọ nínú àwọn arákùnrin wa jẹ́ àpẹẹrẹ ológo-ẹwà fún ìgbé-ayé Kristian. Bí a bá rántí èyí, bíi ti Dafidi a óò láyọ̀ láti ‘fi ẹnu wa yin Oluwa gidigidi; kí a sì yìn ín láàárín ọ̀pọ̀ ènìyàn.’—Orin Dafidi 109:30.

Jíjẹ́ Kristian Ha Dàbí Ohun Tí Ó Ṣòro Gidigidi Bí?

Ó baninínújẹ́ pé, nítorí ìdènà èrò-orí mìíràn, àwọn kan kò tí ì bẹ̀rẹ̀ síí yin Jehofa. Ọ̀pọ̀ àwọn ọkùnrin tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jehofa ń ṣe ojúṣe wọn ti pípèsè fún àwọn ìdílé wọn, wọ́n sì ń ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ìyàwó wọn nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ Kristian. Wọ́n jẹ́ ẹni-bí-ọ̀rẹ́ wọ́n sì lè ní ìfẹ́-ọkàn sí ìjọ, ṣùgbọ́n wọ́n fàsẹ́yìn kúrò nínú dídi ìránṣẹ́ olùṣèyàsímímọ́ fún Ọlọrun. Kí ni ohun tí ń fà wọ́n sẹ́yìn?

Ìṣòro kan lè jẹ́ pé àwọn ọkọ wọ̀nyí ṣàkíyèsí bí ìgbòkègbodò ìjọba Ọlọrun ṣe ń mú ọwọ́ àwọn ìyàwó wọn dí, kí wọ́n sì ronú pé jíjẹ́ Ẹlẹ́rìí ń béèrè ohun tí ó pọ̀ jù. Tàbí bóyá wọ́n ń bẹ̀rù pé àwọn kò lè lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé láé. Lójú-ìwòye wọn, ẹrù-iṣẹ́ náà dàbí èyí tí ó bo àwọn ìbùkún náà mọ́lẹ̀. Kí ni ó fa ìdènà èrò-orí náà? Ọ̀pọ̀ jùlọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ń kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ wọ́n sì ń fi sílò díẹ̀díẹ̀. Ṣùgbọ́n ní ọ̀pọ̀ ìgbà àwọn ọkọ aláìgbàgbọ́ ti mọ gbogbo ẹrù-iṣẹ́ Kristian dáradára ṣáájú kí wọ́n tó mú ìsúnniṣe náà dàgbà láti tẹ́wọ́gbà wọ́n.

Manuel, ẹni tí ó wà nínú ipò yìí, ṣàlàyé pé: “Fún nǹkan bí ọdún mẹ́wàá, mo máa ń bá aya mi lọ sí àwọn àpéjọ àti sí àwọn ìpàdé. Kí n sọ tòótọ́, ó tẹ́ mi lọ́rùn láti wà lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí ju láti wà lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn ayé, mo sì láyọ̀ láti ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà tí mo bá lè ṣe bẹ́ẹ̀. Ìfẹ́ tí ó gbilẹ̀ láàárín wọn wú mi lórí. Ṣùgbọ́n èrò ti lílọ láti ilé-dé-ilé jẹ́ ohun ìdínà ńláǹlà fún mi, mo sì máa ń bẹ̀rù pé àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ mi yóò fi mí ṣe yẹ̀yẹ́.

“Ìyàwó mi mú sùúrù gan-an pẹ̀lú mi kò sì gbìyànjú rí láti fi ipá mú mi láti kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Òun àti àwọn ọmọ ‘wàásù’ ní pàtàkì nípa àpẹẹrẹ rere wọn. José, alàgbà kan nínú ìjọ, ní ọkàn-ìfẹ́ àkànṣe sí mi. Mo lérò pé ìṣírí rẹ̀ ni ó pàpà jẹ́ kí n bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ dáradára. Lẹ́yìn ṣíṣe ìrìbọmi, mo rí i pé ju ohunkóhun lọ àwọn ohun ìdínà náà wà nínú èrò-inú tèmi fúnra mi. Gbàrà tí mo pinnu láti sin Jehofa, mo ní ìrírí ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ ní bíborí àwọn ìbẹ̀rù mi.”

Báwo ni àwọn aya àti àwọn Kristian alàgbà ṣe lè ran àwọn ọkọ bíi Manuel lọ́wọ́ láti borí ìdènà èrò-orí wọn? Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli lè mú ìmọrírì àti ìfẹ́-ọkàn láti ṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun dàgbà. Nítòótọ́, ìmọ̀ Ìwé Mímọ́ tí ó kún dáradára jẹ́ ìpìlẹ̀ fún lílo ìgbàgbọ́ àti níní ìgbọ́kànlé nínú ìrètí tí ó wà níwájú.—Romu 15:13.

Kí ni yóò fún irú ọkọ bẹ́ẹ̀ ní ìṣírí láti tẹ́wọ́gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli? Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, dídọ́rẹ̀ẹ́ pẹ̀lú arákùnrin tí ó lóye nínú ìjọ lè jẹ́ kókó kan fún ṣíṣe ìpinnu. Bóyá alàgbà kan tàbí arákùnrin mìíràn tí ó ní ìrírí lè túbọ̀ wá láti mọ ọkọ̀ náà. Níwọ̀n ìgbà tí a bá ti fìdí ipò-ìbátan tí ó dára múlẹ̀, gbogbo ohun tí ó lè nílò ni kí ẹnì kan nawọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ sí i. (1 Korinti 9:19-23) Láàárín àkókò náà, Kristian aya kan tí ó jẹ́ ọlọgbọ́n lè máa ṣàjọpín àwọn oúnjẹ nípa tẹ̀mí pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ aláìgbàgbọ́, ní mímọ̀ pé ó ṣeé ṣe kí ó má dáhùnpadà sí ìkìmọ́lẹ̀.—Owe 19:14.

Gẹ́gẹ́ bí Manuel ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìrírí, nígbà tí ẹnì kan bá ti jèrè okun nípa tẹ̀mí, àwọn òkè ìṣòro yóò di pẹ̀tẹ́lẹ̀. Jehofa ń fún àwọn tí wọ́n bá nífẹ̀ẹ́-ọkàn láti sìn ín lókun. (Isaiah 40:29-31) Ní agbára Ọlọrun àti pẹ̀lú ìtìlẹ́yìn àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n dàgbàdénú, ìdènà àwọn ọkọ aláìgbàgbọ́ ni a lè mú kúrò. Ìrẹ̀wẹ̀sì iṣẹ́ ilé-dé-ilé lè di èyí tí ó dínkù kí ìmáyàpáni àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ ẹni sì dínkù, nígbà tí iṣẹ́-ìsìn tọkàntọkàn yóò wá di ohun tí ó túbọ̀ fanimọ́ra.—Isaiah 51:12; Romu 10:10.

Mímú kí Ìsúnniṣe Máa Báa Nìṣó

Ó ṣeé ṣe láti borí àwọn ìdènà irú bí àwọn mẹ́ta tí a gbéyẹ̀wò yìí. Nígbà ti ọkọ̀ òfúúrufú kan bá gbéra, agbára ẹ́ńjìnnì tí ó ga jùlọ ni ó nílò bákan náà sì ni ìpọkànpọ̀ agbo òṣìṣẹ́ àwọn awakọ̀ náà. Nígbà tí ó bá ń gbéra nílẹ̀, ẹ́ńjìnnì náà ń lo epo tí ó pọ̀ ju ti ìgbàkígbà tí ó bá ń fò lọ. Bákan náà, láti já gbogbo àwọn ìrònú àti ìmọ̀lára òdì sílẹ̀ ń béèrè ìsapá àti ìpọkànpọ̀ tí ó ga jùlọ. Bíbẹ̀rẹ̀ lè jẹ́ ìpele tí ó ṣòro jùlọ níbẹ̀, nígbà tí ó jẹ́ pé ìtẹ̀síwájú yóò wá di ohun tí ó rọrùn níwọ̀n ìgbà tí a bá ti jèrè ìsúnniṣe náà.—Fiwé 2 Peteru 1:10.

Ìsúnniṣe síwájú síi ni a lè ní nípa títẹ̀lé ìṣírí Ìwé Mímọ́ ní àsìkò. (Orin Dafidi 119:60) A lè ní ìdánilójú pé ìjọ yóò fẹ́ láti ṣèrànwọ́. (Galatia 6:2) Bí ó ti wù kí ó rí, ìtìlẹ́yìn Jehofa Ọlọrun, ni ó ṣe pàtàkì jùlọ. Gẹ́gẹ́ bí Dafidi ti sọ, “olùbùkún ni Jehofa, ẹni tí ń bá wa gbé ẹrù wà lójoojúmọ́.” (Orin Dafidi 68:19, NW) Nígbà tí a bá sọ ẹrù-ìnira wa kalẹ̀ nínú àdúrà, ẹrù wa yóò fúyẹ́.

Nígbà mìíràn, ọkọ òfúúrufú máa ń gbéra nígbà tí ojú ọjọ́ dágùdẹ̀ tí òjò sì ń rọ̀, yóò la ìpele-ìpele ìkúukùu kọjá, tí yóò sì fò lọ sínú òfúúrufú tí ó kún fún òòrùn mímọ́lẹ̀ yòò. Àwa pẹ̀lú lè pa àwọn ìrònú òdì tì. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àtọ̀runwá, a lè la àwọn ìpele-ìpele ìkúukùu kọjá, lọ́nà àpèjúwe, kí a sì máa gbádùn yìn-ìn nínú ìmọ́lẹ̀, àyíká aláyọ̀ ti ìdílé àwọn olùjọsìn Jehofa kárí-ayé.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jehofa, a lè borí àwọn ìdènà èrò-orí

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́