Fífi Ìwé Pẹlẹbẹ Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I? Lọni
1 Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń sapá láti mọ ọ̀nà tó tọ́ láti gbà sin Ọlọ́run. Wọ́n ń fẹ́ ìyè àìnípẹ̀kun. Àmọ́, ibo ni wọ́n ti lè rí i? À ń hára gàgà láti fi ọ̀nà tóóró náà hàn wọ́n. Iṣẹ́ àjẹ́ ti mú àràádọ́ta èèyàn nígbèkùn. A fẹ́ láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè já ara wọn gbà. Ìwé pẹlẹbẹ tuntun náà, Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I? jẹ́ ohun èlò gbígbéṣẹ́ fún ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Díẹ̀ rèé lára àwọn ọ̀nà tá a lè gbà fi lọni.
2 Ṣé oríṣiríṣi ọ̀nà tó lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run ni àwọn ìsìn jẹ́? (A gbé e ka Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú.) “Jọ̀wọ́ wo àwòrán tó wà nínú ìwé pẹlẹbẹ yìí. (Ojú ìwé 2 àti 3) Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà gbọ́ pé àwọn ìsìn jẹ́ oríṣiríṣi ọ̀nà tí gbogbo wọn lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run. Kí lo rò? (Jẹ́ kó fèsì.) Wo ohun tí ìpínrọ̀ kejì lójú ìwé kejì sọ. (Kà á.) Bíi ti ìdílé tó wà nínú àwòrán yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò mọ ọ̀nà tó yẹ kí wọ́n tọ̀. Ìwé pẹlẹbẹ yìí yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rí ọ̀nà tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun.”
3 Ǹjẹ́ gbogbo ìsìn ló ń fi òtítọ́ kọ́ni? (A gbé e ka Ẹ̀kọ́ 1.) “Kí lo rò? Ǹjẹ́ gbogbo ìsìn ló ń fi òtítọ́ kọ́ni? (Lẹ́yìn tó bá fèsì, máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ.) Ọ̀pọ̀ àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tuntun ni wọ́n ń dá sílẹ̀, àwọn èèyàn kan sì lè máa rò pé èyíkéyìí lára wọn ló lè tọ́ wa sọ́nà nípa bí a ṣe lè sin Ọlọ́run. Àmọ́ o, ní 1 Tẹsalóníkà 5:21, Bíbélì kìlọ̀ fún wa láti ṣọ́ra. (Kà á.) Kí nìdí tó fi jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ìsìn ni Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà? Wo gbólóhùn méjì àkọ́kọ́ yìí nínú ìpínrọ̀ 3, lábẹ́ Ẹ̀kọ́ 1, lójú ìwé 5, nínú ìwé pẹlẹbẹ yìí. (Kà á.) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo ìsìn ló lè jẹ́ òótọ́, báwo la ṣe lè rí ìsìn tòótọ́? Ìwé pẹlẹbẹ yìí á jẹ́ kó o mọ̀ ọ́n.”
4 Ǹjẹ́ ó yẹ ká máa jọ́sìn àwọn baba ńlá wa? (A gbé e ka Ẹ̀kọ́ 4.) “Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń jọ́sìn àwọn baba ńlá wọn. Ọ̀pọ̀ ààtò ìsìnkú ni wọ́n gbé ka ìjọsìn àwọn baba ńlá. Kí nìdí táwọn èèyàn fi máa ń jọ́sìn àwọn baba ńlá wọn tàbí tí wọ́n máa ń júbà wọn? Jọ̀wọ́ wo ohun tí ìpínrọ̀ 1 àti 2 lójú ìwé 12 nínú ìwé pẹlẹbẹ yìí sọ. (Kà á.) Ǹjẹ́ àwọn baba ńlá tó ti kú mọ̀ nípa ohun tí à ń ṣe? (Jẹ́ kí onílé fèsì.) Jẹ́ ká ka ohun tí Bíbélì sọ ní Oníwàásù 9:5, 10. Níwọ̀n bí wọn ò ti mọ ohunkóhun, kò ní bójú mu láti máa jọ́sìn wọn. O lè túbọ̀ kà nípa èyí nínú Ẹ̀kọ́ 4 nínú ìwé pẹlẹbẹ yìí.”
5 Ǹjẹ́ ó yẹ ká bẹ̀rù àwọn àjẹ́? (A gbé e ka Ẹ̀kọ́ 5.) “À ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn èèyàn láti jíròrò ìbéèrè kan tí ọ̀pọ̀ èèyàn ti ń ronú nípa rẹ̀, ìyẹn ni pé, Ǹjẹ́ ó yẹ ká bẹ̀rù àwọn àjẹ́? Kí lo rò? (Jẹ́ kí onílé fèsì.) Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà gbọ́ pé bí ohun burúkú kan bá ṣẹlẹ̀, àwọn àjẹ́ ló fà á. Ìdí nìyẹn tí àwọn kan fi máa ń lo oògùn ìṣọ́ra. Ǹjẹ́ ó yẹ ká máa lo oògùn ìṣọ́ra láti dáàbò bo ara wa? Kíyè sí ohun tí ìwé pẹlẹbẹ yìí sọ ní ojú ìwé 18, ìpínrọ̀ 16. (Kà á.) Jèhófà Ọlọ́run, Olódùmarè, lágbára ju Sátánì lọ fíìfíì. Ó lè dáàbò bò wá lọ́wọ́ Sátánì. (Ka Jákọ́bù 4:7.) Fún ìsọfúnni síwájú sí i, ka Ẹ̀kọ́ 5 nínú ìwé pẹlẹbẹ yìí.”
6 Ǹjẹ́ gbogbo ẹ̀sìn ni Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà? (A gbé e ka Ẹ̀kọ́ 6.) “Ǹjẹ́ gbogbo ẹ̀sìn ni Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà? Níwọ̀n bí ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀sìn tí wọ́n sọ pé àwọ́n jẹ́ Kristẹni ti gbà gbọ́ nínú Ọlọ́run, Jésù àti Bíbélì, ọ̀pọ̀ máa ń ronú pé ìyẹn ló fi hàn pé inú Ọlọ́run dùn sí wọn. Kí lo rò? (Jẹ́ kó fèsì.) Jésù sọ ohun kan nípa èyí nínú Mátíù 7:13, 14. (Kà á.) Oríṣi ìsìn méjì péré ló wà, ọ̀kan jẹ́ òótọ́, èkejì jẹ́ èké. Ìsìn tòótọ́ ń sinni lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun. Ìsìn èké ń sinni lọ sí ìparun. Báwo la ṣe lè mọ èyí tó jẹ́ òótọ́? Jésù dáhùn ìbéèrè yìí ní Mátíù 7:16-20. (Kà á.) Bí ìsìn kan bá jẹ́ òótọ́ èso rere ni yóò máa so, ṣùgbọ́n bí ìsìn kan bá jẹ́ ti Sátánì èso búburú ni yóò máa so. Ìwé pẹlẹbẹ yìí ṣàlàyé nípa èso rere náà ní ojú ìwé 19, ìpínrọ̀ 4. (Kà á.) Ǹjẹ́ o gbà pé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ rí? Ó tún wá ṣàlàyé nípa àwọn èso búburú tí ọ̀pọ̀ ìsìn ń so. Láìsí àní-àní, wàá fẹ́ láti ka Ẹ̀kọ́ 6 nínú ìwé pẹlẹbẹ yìí.”
7 Ǹjẹ́ ṣíṣe iṣẹ́ ìyanu ló ń fi hàn pé ìsìn kan jẹ́ ìsìn tòótọ́? (A gbé e ka Ẹ̀kọ́ 7.) “Mò ń ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ láti dáhùn ìbéèrè kan, ìyẹn ni pé, Ǹjẹ́ ó pọn dandan kí ìsìn kan máa ṣe iṣẹ́ ìyanu láti fi hàn pé ó jẹ́ ìsìn tòótọ́? (Jẹ́ kí onílé fèsì.) Ọ̀pọ̀ èèyàn ló rò bẹ́ẹ̀, bóyá nítorí pé Jésù ṣiṣẹ́ ìyanu. Àmọ́, Jésù tún sọ ọ̀rọ̀ yìí tó wà nínú Mátíù 7:21-23. (Kà á.) Kíyè sí i pé, ó ní àwọn kan á sọ pé àwọ́n ń sọ tẹ́lẹ̀, àwọ́n ń lé ẹ̀mí èṣù jáde, àwọ́n sì ń ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ agbára ní orúkọ òun. Síbẹ̀, wọ́n ò ní rí ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀. Ìpínrọ̀ 10 lójú ìwé 24 nínú ìwé pẹlẹbẹ yìí sọ pé: (Kà á.) Ta ni yóò wọ Ìjọba ọ̀run? Kì í ṣe gbogbo ẹni tó ń sọ pé ‘Olúwa, Olúwa,’ àmọ́ ẹni tó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni. Báwo lèèyàn ṣe lè mọ ìsìn tòótọ́? Ìwé pẹlẹbẹ yìí dáhùn ìbéèrè yìí ní Ẹ̀kọ́ 7.”
8 Ìwọ̀nyí jẹ́ díẹ̀ lára àwọn àkòrí àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a lè lò láti fi ìwé tó gbéṣẹ́ gan-an yìí lọni. Bí onílé bá fìfẹ́ hàn, bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nínú ẹ̀kọ́ tó o sọ̀rọ̀ lé lórí tàbí nínú Ẹ̀kọ́ 1. Nígbà tó o bá parí ìwé pẹlẹbẹ náà, máa bá ìjíròrò náà lọ nínú ìwé pẹlẹbẹ Béèrè. Rí i pé ò ń lo ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí dáadáa láti ran ọ̀pọ̀ èèyàn sí i lọ́wọ́ láti mọ ọ̀nà tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun!