Fi Hàn Pé Ọ̀rọ̀ Àwọn Èèyàn Jẹ Ọ́ Lógún Nípa Fífi Inúure Hàn sí Wọn
1 Obìnrin kan tó ń ṣe ẹ̀tanú sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ tó kọ́kọ́ pàdé Ẹlẹ́rìí kan, ó ní: “Mi ò lè rántí àwọn nǹkan tí obìnrin náà bá mi sọ, ṣùgbọ́n mi ò jẹ́ gbàgbé bó ṣe finúure hàn sí mi, àti bó ṣe láàánú lójú tó, kí n má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ bó ṣe jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ èèyàn tó. Kò wù mí kó fi mí sílẹ̀.” Àlàyé tí obìnrin yìí ṣe jẹ́ ká rí i bó ṣe ṣe kókó tó pé ká jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn tá à ń wàásù fún máa jẹ wá lógún.—Fílí. 2:4.
2 Ìfẹ́ A Máa Ní Inú Rere: Ọ̀nà kan tá a gbà ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn ni pé ká máa fi inúure hàn sí wọn. (1 Kọ́r. 13:4) Onínúure èèyàn máa ń ro táwọn ẹlòmíì mọ́ tiẹ̀, á sì máa wá bó ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́. Kò ṣẹ̀ṣẹ̀ ní pé à ń sọ, inúure ni iṣẹ́ ìwàásù jẹ́. Síbẹ̀, àwọn ọ̀nà míì wà tá a lè gbà fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn jẹ wá lógún ju pé ká kàn wàásù fún wọn lọ. Gbogbo bá a ṣe ń báwọn èèyàn lò ló máa fi hàn pé a fi wọ́n sọ́kàn. Ìyẹn ni bá a ṣe ń mú wọn bí ọ̀rẹ́, bá a ṣe ń fọ̀wọ̀ wọn wọ̀ wọ́n, bá a ṣe ń fetí sílẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ ẹnu wa àti ọ̀nà tá a gbà ń sọ ọ́, kódà ọ̀nà tá a gbà ń wo àwọn èèyàn nígbà tá a bá ń sọ̀rọ̀ ṣe pàtàkì.—Mát. 8:2, 3.
3 Bá a bá nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn dénú, a óò tún máa ṣoore fún wọn láwọn ọ̀nà míì. Nígbà tí arákùnrin kan tó jẹ́ aṣáájú ọ̀nà ń wàásù láti ilé dé ilé, àgbàlagbà opó kan tó ní kóun wàásù fún lé e bí ẹni lé ajá nígbà tó mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí ni. Obìnrin náà sọ pé orí àkàbà lòun wà nínú ilé ìdáná níbi tóun ti ń wá bóun á ṣe pààrọ̀ gílóòbù tó ti jó nígbà tóun gbọ́ tí aago ẹnu ọ̀nà dún. Arákùnrin yẹn ní: “Ìyá àgbà, ó léwu fẹ́yin nìkan láti dàyà kọ irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀.” Lọ́rọ̀ kan ṣá, ìyá ní kí arákùnrin náà wọlé. Ó wọlé, ó bá ìyá pààrọ̀ gílóòbù ó sì bá tiẹ̀ lọ. Kò pẹ́ sígbà yẹn tí ọmọ ìyá yẹn kan fi wá wò ó. Ìyá kó gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀, ó rò ó fún un. Inú ọmọ yẹn dùn gan-an ló bá ní kí ìyá òun jẹ́ kóun mọ onítọ̀hún kóun lè dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀. Ìdúpẹ́ yẹn mú kí wọ́n túbọ̀ fọ̀rọ̀ jomi toro ọ̀rọ̀, àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló yọrí sí.
4 Bá a bá jẹ́ onínúure, a ó lè máa jẹ́ káwọn èèyàn máa rí ìfẹ́ tí Jèhófà ní fún wọn àti pé a ó lè máa bu ẹwà kún ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Nítorí náà, ǹjẹ́ ká máa bá a lọ ní gbogbo ìgbà láti máa “dámọ̀ràn ara wa fún ìtẹ́wọ́gbà gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run . . . nípa inú rere.”—2 Kọ́r. 6:4, 6.