Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 10
Orin 17
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Àwọn Ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù October sílẹ̀. Ẹ lo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 8 (tó bá bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu) láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ October 15 àti Jí! November 8. (Lo àbá kẹta fún Jí! November 8.) Lẹ́yìn àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, jẹ́ káwọn ará rí díẹ̀ lára àwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n lè rí kọ́ nínú àṣefihàn yẹn. Láfikún sí i, sọ̀rọ̀ lórí àwọn àpilẹ̀kọ míì tó wà nínú ìwé ìròyìn náà tó o mọ̀ pé ẹni náà máa nífẹ̀ẹ́ sí.
15 min: Ǹjẹ́ O Máa Ń Kàwé Bó Ṣe Yẹ? Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a mú jáde látinú àwọn ibi pàtó tá a tọ́ka sí nínú ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 21 sí 26. Kí ló yẹ ká fi kún ìṣètò tá a ṣe fún kíkàwé? (ojú ìwé 21, àpótí) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa ka àwọn ìwé tí ẹrú náà tẹ̀? (ojú ìwé 23, ìpínrọ̀ 2) Kí lohun tá a gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn ká lè máa tẹ̀lé ìṣètò tá a ṣe fún ìwé kíkà? (ojú ìwé 26, ìpínrọ̀ 3 sí 4) Ètò wo lo ṣe láti lè máa ka ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí!? Oore wo lèyí sì ti ṣe ọ́?
20 min: “Ẹ Máa Sọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Nìṣó Láìṣojo.”a Ní káwọn ará sọ àwọn ipò tó ti máa ń ṣòro láti wàásù láìṣojo. Kí ló sì jẹ́ kí wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀?
Orin 78 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 17
Orin 36
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Lo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti November 2004, ojú ìwé 4 láti fi ṣàtúnyẹ̀wò kókó kan tàbí méjì nípa bá a ṣe lè lo Ìwé Mímọ́ lọ́nà tó jáfáfá nígbà tá a bá ń ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
15 min: Sá fún Ewu Tó Wà Nínú Lílo Íńtánẹ́ẹ̀tì. Alàgbà kan ni kó sọ àsọyé yìí, kó sì mú un látinú Jí! December 8, 2004, ojú ìwé 16 sí 19.
20 min: “Fi Hàn Pé Ọ̀rọ̀ Àwọn Èèyàn Jẹ Ọ́ Lógún Nípa Fífi Inúure Hàn sí Wọn.”b Ní káwọn ará sọ bá a ṣe lè fi inúure hàn sáwọn èèyàn nígbà tá a bá wà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. A óò jíròrò àwọn ọ̀nà míì tá a lè máa gbà fi inúure hàn sáwọn èèyàn tá à ń wàásù fún nínú àwọn Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú.
Orin 2 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 24
Orin 68
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ka ìròyìn ìnáwó, kó o sì tún ka lẹ́tà tí ọ́fíìsì kọ láti dúpẹ́ nítorí ọrẹ tá à ń ṣe. Lo ọ̀kan lára àwọn àbá tó wà nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti January 2005 tàbí ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ mìíràn tó bá bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣàṣefihàn bá a ṣe lè lo ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a ó lò lóṣù November.—Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa, January 2005, ojú ìwé 8 ìpínrọ̀ 5.
15 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
20 min: Bá A Ṣe Lè Máa Rọ̀ Mọ́ Ìlànà Jèhófà Nínú Aṣọ Tá À Ń Wọ̀ àti Ọ̀nà Tá A Gbà Ń Múra. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwọn ará, tí alàgbà kan yóò bójú tó, èyí tá a mú látinú Ilé Ìṣọ́ August 1, 2002, ojú ìwé 17 sí 19. Ní káwọn ará sọ bí ìrísí wa tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì ṣe lè jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti wàásù.
Orin 153 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní October 31
Orin 209
10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn ará létí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù October sílẹ̀. Lo àwọn àbá tó wà ní ojú ìwé 8 (tó bá bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu) láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ November 1 àti Jí! November 8. (Lo àbá kẹrin fún Jí! November 8.) Nínú ọ̀kan lára àwọn àṣefihàn náà, sọ ohun tẹ́ ẹ máa jíròrò nígbà tó o bá padà bẹ ẹni náà wò nípa fífi àpótí náà, “Nínú Ìtẹ̀jáde Wa Tí Ń Bọ̀” hàn án.—Wo Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa October 1998 ojú ìwé 8, ìpínrọ̀ 7 sí 8.
15 min: Mú Kí Ìfẹ́ Àwọn Tó Ò Ń Fún Ní Ìwé Ìròyìn Déédéé Jinlẹ̀ sí I. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwọn ará tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa May 2005 ojú ìwé 8. Báwo la ṣe lè jẹ́ kí ẹnì kan nífẹ̀ẹ́ sí ìwé ìròyìn wa? (ìpínrọ̀ 1) Báwo la ṣe lè múra sílẹ̀ fún onírúurú ìjíròrò téèyàn á fi ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan ṣe? (ìpínrọ̀ 3) Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣe ju pé ká kàn ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ lọ? (ìpínrọ̀ 4) Ọ̀nà wo ni ẹni tó ò ń fún ní ìwé ìròyìn déédéé lè gbà di akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? (ìpínrọ̀ 5) Ṣe àṣefihàn akéde kan tó ń fi ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan ṣoṣo jíròrò pẹ̀lú ẹnì kan tó máa ń gba ìwé ìròyìn déédéé lọ́wọ́ rẹ̀.
20 min: Àwọn Ọ̀dọ́ Tó Dúró Ṣinṣin Síbẹ̀ Tí Wọn Kì Í Yájú. Àsọyé tí alàgbà kan yóò sọ tá a mú jáde látinú Ilé Ìṣọ́ September 15, 2002, ojú ìwé 23 sí 24 lábẹ́ àkòrí náà “Fi Tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ Yàgò Fún Un.” Jẹ́ kí ọ̀dọ́ kan tàbí méjì tó o ti sọ fún tẹ́lẹ̀ múra sílẹ̀ láti sọ àwọn ìṣòro tí wọ́n ti kojú nílé ìwé àti bí wọ́n ṣe borí.
Orin 222 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní November 7
Orin 39
5 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.
20 min: Máa Túbọ̀ Pọkàn Pọ̀ Nígbà Tó O Bá Wà ní Ìpàdé. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwọn ará, èyí tá a mú jáde látinú Ilé Ìṣọ́ September 15, 2002 ojú ìwé 12 sí 14, ìpínrọ̀ 11 sí 14. Jíròrò àwọn àbá tó wà níbẹ̀ kó o sì ní káwọn ará sọ ohun tó ti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti lè jàǹfààní lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ láwọn ìpàdé ìjọ.
20 min: “Ẹ Di Ọ̀jáfáfá Nínú Bíbá Àwọn Èèyàn Fèrò Wérò.”c Ní káwọn akéde tó o ti sọ fún tẹ́lẹ̀ sọ bí wọ́n ṣe máa ń jẹ́ kóhun tí wọ́n ń kọ́ onírúurú èèyàn ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín yé wọn.
Orin 50 àti àdúrà ìparí.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti bójú tó ìjíròrò náà.
b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti bójú tó ìjíròrò náà.
c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti bójú tó ìjíròrò náà.