Mọrírì Ètò Tí Jèhófà Ṣe Kó O Lè Mọ̀ọ́kọ Mọ̀ọ́kà
1 Ara Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ni Ilé ẹ̀kọ́ mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà tá a dá sílẹ̀ nínú ìjọ. A dá a sílẹ̀ kó bàa lè ran àwọn akéde àtàwọn olùfìfẹ́hàn tí wọn ò mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà lọ́wọ́ káwọn náà lè dẹni tó mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà. Lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló ti sọ bí wọ́n ṣe mọrírì ilé ẹ̀kọ́ yìí tó torí pé o ti sọ wọ́n dẹni tó ń kàwé lọ́nà tó já gaara, wọ́n sì ti tipa bẹ́ẹ̀ di ọ̀jáfáfá olùkọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bó ò bá mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà, tí ilé ẹ̀kọ́ yìí sì wà nínú ìjọ tó ò ń dara pọ̀ mọ́, ṣé wàá fi hàn pé o mọrírì ìṣètò yìí? Báwo lo ṣe lè fìmọrírì hàn?
2 Forúkọ Sílẹ̀ Kó O sì Fojú sí Ohun Tí Wọ́n Bá Ń Kọ́ Ẹ: Bó o bá wà lára àwọn tí kò mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà, a jẹ́ pé o ní láti forúkọ sílẹ̀ nílé ẹ̀kọ́ mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà nìyẹn o. Má ṣe jẹ́ kí ìjọra-ẹni-lójú tàbí ìbẹ̀rù pé àwọn ẹlòmíì lè kẹ́gàn rẹ dí ẹ lọ́wọ́ láti forúkọ sílẹ̀. (Fi wé Àwọn Ọba 5:10-14.) Bó o bá sì ti forúkọ sílẹ̀, ńṣe ni kó o pa kítí mọ́ra kó o sì fojú sí ẹ̀kọ́ rẹ. (Òwe 21:5) Rí i pé o tètè ń débẹ̀, máa fetí sílẹ̀ dáadáa nígbà tí wọ́n bá ń kọ́ọ yín, kó o sì sapá láti máa tètè lóye ohun tí wọ́n ń kọ́ yín. Máa múra ilé ẹ̀kọ́ náà sílẹ̀ dáadáa, máa fi ohun tó o kọ́ dánra wò kó o sì máa ṣe iṣẹ́ tí wọ́n bá gbé fún yín. Ìwọ̀nba díẹ̀ làwọn nǹkan tá a mẹ́nu kàn yìí jẹ́ lára ọ̀nà tó o lè gbà fi hàn pé o mọrírì ilé ẹ̀kọ́ mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà tí Jèhófà ṣètò rẹ̀ yìí.
3 Ní Ohun Tó Yẹ Kó O Ní: Ó pọn dandan kí akẹ́kọ̀ọ́ ní àwọn nǹkan tó máa lò láti ṣe àkọsílẹ̀ nílé ẹ̀kọ́. Nítorí náà, o gbọ́dọ̀ rí i pé gbogbo ohun tó o nílò nílé ẹ̀kọ́ lo ní, àwọn nǹkan bíi Bíbélì, ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́, ìyẹn ìwé How to Read and Write, ìwé tó o máa fi ṣe àkọsílẹ̀, àti bírò tàbí pẹ́ńsù. Bó o bá ní gbogbo nǹkan tó yẹ wọ̀nyí, wàá jàǹfààní ilé ẹ̀kọ́ náà. Ó sì tún máa túmọ̀ sí pé o mọrírì ètò tí Jèhófà ṣe.
4 Mọ Ohun Tó Ò Ń Ṣe: Láìwo ti ipò tẹ́ni kẹ́ni lè wà láwùjọ, ohun tí Jèhófà fẹ́ ni pé káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lè mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà dáadáa kí wọ́n bàa lè jàǹfààní Ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. (Jóṣ. 1:8; Diu. 6:8, 9; 17:18, 19) Nítorí náà, o gbọ́dọ̀ máa rántí ohun tó mú kó o forúkọ sílẹ̀ nílé ẹ̀kọ́ náà, pé nítorí kó o lè ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kó o sì lè ṣàlàyé rẹ̀ lọ́nà tó tọ́ tó sì ṣe kedere ni. Ìdí tó o sì ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ náà ni láti lè ran ara rẹ lọ́wọ́ kó o bàa lè túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run kó o sì lè ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ kí wọ́n lè lóye ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run. Bó o bá ń fi kókó wọ̀nyí sọ́kàn, ó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti lè fara da ìṣòro tó lè kojú ẹ lẹ́nu ẹ̀kọ́ náà.
5 Máa So Èso Ti Ẹ̀mí: Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ fẹ́ ká máa so èso Ìjọba Ọlọ́run. (Jòh. 15:8) Ṣùgbọ́n kó o tó lè sèso yìí, o gbọ́dọ̀ mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà. Ìrírí kan rèé: Arákùnrin kan tí kò mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà ń wàásù láti ilé dé ilé nígbà àkọ́kọ́. Ọkùnrin kan tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì Pùròtẹ́sítáǹtì kíyè sí i pé arákùnrin wa yìí ò lè kàwé, ó sì sọ fún un pé: ‘Má déwájú mi o, kọ́kọ́ lọ wá bó o ṣe lè ka Bíbélì ná.’ Síbẹ̀ akéde tuntun yìí gbìyànjú láti sọ ìwọ̀n tó lè sọ fún ọkùnrin náà, àmọ́ ọkùnrin náà kọ̀ kò gbọ́, ohun tó ṣáà ń ránnu mọ́ ni pé kò sóhun kan tí ẹni tí kò mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà mọ̀ tó lè kọ́ òun. Akéde yẹn wá pinnu pé dandan, òun á rí i pé òun mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà. Dípò tí ì bá fi jẹ́ kí ìkẹ́kọ̀ọ́ yẹn mọ sórí ìwọ̀nba ohun tí wọ́n bá kọ́ wọn ní kíláàsì, ojoojúmọ́ ló máa ń dá kẹ́kọ̀ọ́, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ fún ọ̀sẹ̀ mẹ́fà gbáko. Bó bá ń lọ gbọnsẹ̀, tòun tìwé ẹ̀ ni, bẹ́ẹ̀ ló sì máa ń bi ẹni tó bá rí tó lè kàwé pé kó kọ́ òun bí wọ́n ṣe ń pe àwọn ọ̀rọ̀ kan. Kí wá ni àbárèbábọ̀? Nígbà tó lọ sóde ẹ̀rí lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kẹfà, ó tún padà lọ sọ́dọ̀ ọkùnrin tó sọ pé òun kò fẹ́ gbọ́rọ̀ ẹni tí kò mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà lọ́jọ́sí. Yàtọ̀ sí pé ẹnu ya ọkùnrin Pùròtẹ́sítáǹtì yìí nígbà tó rí i pé ẹni tí kò mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà lọ́jọ́sí ti lè ka Bíbélì, ńṣe ló fara balẹ̀ tó kẹ́kọ̀ọ́. Ó wá ṣe kedere pé ọ̀nà tó dáa láti fi ìmọrírì hàn fún ètò tí Jèhófà ṣe yìí ni pé kéèyàn kọ́ bó ṣe máa mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà, kó sì lo ìmọ̀ tó ní láti kọ́ àwọn ẹlòmíì ní òtítọ́.—Mát. 24:14; 28:19, 20; Jòh. 8:32; 17:3.
6 Má Bẹ̀rù: Lóde òní, ọ̀pọ̀ àwọn àgbàlagbà ni wọ́n ń bẹ̀rù láti forúkọ sílẹ̀ nílé ẹ̀kọ́ mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà, bákan náà, àwọn díẹ̀ tó forúkọ sílẹ̀ ń ṣiyè méjì pé bóyá làwọn lè mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà láé. Ṣùgbọ́n o, bó o bá lè gba ọ̀rọ̀ Jésù ní Mátíù 17:20 gbọ́, ó ṣeé ṣe kó o borí òkè ìṣòro yẹn. Nítorí náà, fojú sí ẹ̀kọ́ rẹ. Má ṣe máa ro tibí tọ̀hún. Jẹ́ kí Jèhófà rí bó o ṣe ń gbìyànjú láti mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà, ó dájú pé ó máa ṣí ẹ níyè láti mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà. Arákùnrin kan tí kò mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà forúkọ sílẹ̀ nílé ẹ̀kọ́ náà, bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ó tẹ̀ síwájú débi pé òun náà tún wá di olùkọ́ nílé ẹ̀kọ́ mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà tó wà ní ìjọ wọn! Kò sí àní-ání pé “lọ́dọ̀ Ọlọ́run ohun gbogbo ṣeé ṣe.” (Mát. 19:26) Bó o bá gbọ́kàn lé Jèhófà tó o sì gbìyànjú débi tí agbára rẹ mọ, ó lè ṣàì pẹ́ tíwọ náà á fi di ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọ́n mọrírì ètò tí Jèhófà ṣe láti mú kí ìjọ ní ilé ẹ̀kọ́ mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà, tí wọ́n sì ti tipa bẹ́ẹ̀ dẹni tó mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà.