A Ní Ohun Tá A Lè Fún Jèhófà
1 Ǹjẹ́ o mọ̀ pé àwa èèyàn lè fún Ọlọ́run ní nǹkan? Ébẹ́lì fi èyí tó dára jù lọ nínú agbo ẹran rẹ̀ rúbọ sí Jèhófà, Nóà àti Jóòbù sì ṣe bákan náà. (Jẹ́n. 4:4; 8:20; Jóòbù 1:5) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, àwọn ohun tí wọ́n fi rúbọ kò sọ Ẹlẹ́dàá di ọlọ́rọ̀ lọ́nàkọnà, nítorí pé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyẹn ti wá, síbẹ̀ ẹbọ táwọn ọkùnrin olóòótọ́ wọ̀nyẹn rú fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run látọkàn wá. Lónìí, àwa náà lè fi àkókò wa, okun wa àtàwọn ohun ìní wa rú “ẹbọ ìyìn” sí Jèhófà.—Héb. 13:15.
2 Àkókò Wa: Ẹ wo bó ṣe máa dára tó, tá a bá ‘ra’ àkókò tá a fi ń ṣe àwọn nǹkan tí ò fi bẹ́ẹ̀ pọn dandan padà, kó bàa lè ṣeé ṣe fún wa láti kópa lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ nínu iṣẹ́ ìsìn! (Éfé. 5:15, 16) Bóyá ká tún ètò wa ṣe ká bàa lè máa ṣe olùrànlọ́wọ́ aṣáájú-ọ̀nà lóṣù kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lọ́dún. A sì tún lè máa pẹ́ lóde ẹ̀rí ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Tá a bá ń fi ọgbọ̀n ìṣẹ́jú pẹ́ lóde ẹ̀rí ju ti tẹ́lẹ̀ lọ lọ́sẹ̀ kọ̀ọ̀kan, tó bá fi máa di ìparí oṣù, ìròyìn wa máa ti fi wákàtí méjì gbé pẹ́ẹ́lí sí i!
3 Okun Wa: Ká lè ní okun tó tó fún iṣẹ́ ìwàásù, àfi ká ṣọ́ra fáwọn eré ìnàjú àti iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tó máa jẹ́ kó rẹ̀ wá tẹnutẹnu débi tá ò fi ní lè fún Jèhófà lóhun tó dára jù lọ. Bákan náà, a ò gbọ́dọ̀ fàyè gba àníyàn tó lè mú ọkàn wa “tẹ̀ ba” tá ò fi ní lókun láti sin Ọlọ́run. (Òwe 12:25) Ká tiẹ̀ wá sọ pé ohun pàtàkì kan wà tá à ń ṣàníyàn lé lórí, kí ló dé tá ò “ju ẹrù ìnira [náà] sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀”!—Sm. 55:22; Fílí. 4:6, 7.
4 Àwọn Ohun Ìní Wa: A tún lè fàwọn ohun ìní wa ti iṣẹ́ ìwàásù lẹ́yìn. Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni ẹlẹ́gbẹ́ rẹ̀ níyànjú láti máa “ya ohun kan sọ́tọ̀ gedegbe ní ìpamọ́” kí wọ́n bàa lè rí nńkan fún àwọn aláìní. (1 Kọ́r. 16:1, 2) Àwa pẹ̀lú lè ya owó sọ́tọ̀ láti fi ṣètìlẹ́yìn fún ìnáwó ìjọ àti fún iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe kárí ayé. Jèhófà mọrírì ohun tá a bá fi ṣètìlẹ́yìn, bó kéré jù bẹ́ẹ̀ lọ, kó ṣáà ti ti ọkàn wa wá.—Lúùkù 21:1-4.
5 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan ni Jèhófà ti fún wa. (Ják. 1:17) Tá a bá sì ń fi tinútinú yọ̀ǹda àkókò, okun àtàwọn ohun ìní wa láti sìn ín, èyí á fi hàn pé a moore. Inú Jèhófà máa dùn sí wa tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ “nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ olùfúnni ọlọ́yàyà.”—2 Kọ́r. 9:7.