Bá A Ṣe Lè Máa Gbé Ara Wa Ró Lóde Ẹ̀rí
1 Gbogbo wa la máa ń mọrírì “ọ̀rọ̀ [ìṣírí] tí a sọ ní àkókò tí ó tọ́.” (Òwe 25:11) Nígbà tá a bá wà lóde ẹ̀rí, báwo ni ìjíròrò wa ṣe lè fún ẹni tá a jọ ń ṣiṣẹ́ níṣìírí?
2 Ọ̀rọ̀ Tó Ń Gbéni Ró: Ẹ wo bí ìjíròrò wa pẹ̀lú ẹni tá a jọ ń ṣiṣẹ́ ìwàásù ṣe máa kún fún ìṣírí tó, bó bá jẹ́ pé orí nǹkan tẹ̀mí ló dá lé! (Sm. 37:30) A lè jọ sọ̀rọ̀ nípa ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tá a fẹ́ lò tàbí ká sọ àwọn ìrírí tó gbádùn mọ́ni tá a ní lóde ẹ̀rí lẹ́nu àìpẹ́ yìí. (Ìṣe 15:3) Ǹjẹ́ a rí ohun kan tó gbádùn mọ́ni nínú Bíbélì kíkà ara ẹni, nígbà tá à ń ka ìwé ìròyìn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde tàbí nípàdé ìjọ, a ò ṣe kúkú sọ ọ́ fáwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí? A tún lè jọ jíròrò àwọn kókó tó wà nínú àsọyé fún gbogbo ènìyàn tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọ́ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba.
3 Inú wa lè má dùn torí pé kò ṣeé ṣe fún wa láti fèsì àtakò tí onílé kan gbé kò wá lójú. Ó máa dáa tá a bá lo ìṣẹ́jú díẹ̀ lẹ́yìn tá a kúrò lọ́dọ̀ onílé náà láti jíròrò bá a ṣe lè bójú tó irú nǹkan bẹ́ẹ̀ nígbà míì, bóyá nípa ṣíṣàyẹ̀wò ìwé Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Àwọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó. Tá a bá sì rí ohun kan tó wú wa lórí nínú bí ẹni tá a jọ ń ṣiṣẹ́ ṣe gbọ́rọ̀ kalẹ̀, a lè fún un níṣìírí nípa gbígbóríyìn fún un látọkànwá.
4 Lo Ìdánúṣe: Ṣé àwọn kan wà nínú Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ wa tó ti pẹ́ díẹ̀ tá a ti jọ ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí? Tá a bá sọ pé kí wọ́n jẹ́ ká jọ jáde òde ẹ̀rí, ìyẹn á fún wa láǹfààní láti jọ ní “pàṣípààrọ̀ ìṣírí.” (Róòmù 1:12) Inú àwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé àtàwọn aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ máa ń dùn nígbà tí wọ́n bá rí àwọn akéde láti bá ṣiṣẹ́, àgàgà láàárọ̀ kùtùkùtù tàbí lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́ nígbà tó jẹ́ pé ìwọ̀nba làwọn akéde tó máa ń jáde fún iṣẹ́ ìwàásù. A lè gbárùkù ti àwọn aṣáájú-ọ̀nà tá a bá ń wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti jáde òde ẹ̀rí pẹ̀lú wọn. Ṣé akéde aláìlera kan wà nínú ìjọ yín tó jẹ́ pé ìwọ̀nba lohun tó lè ṣe nínú iṣẹ́ ìwàásù nítorí àìlera rẹ̀? Àǹfààní ló máa jẹ́ tá a bá lè ṣètò pé ká jọ jáde, bóyá ká jọ lọ síbi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa.—Òwe 27:17.
5 Tá a bá ń gbóríyìn fáwọn èèyàn tá a sì fi hàn pé a mọrírì wọn, kódà nínú àwọn ọ̀ràn tí ò tó nǹkan pàápàá, kò sígbà tíyẹn ò ní máa fún wọn níṣìírí. Ẹ jẹ́ ká máa fọ̀rọ̀ yìí sọ́kàn ní gbogbo ìgbà tá a bá ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì lóde ẹ̀rí, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ńṣe la fẹ́ “máa gbé ara [wa] ró lẹ́nì kìíní-kejì.”—1 Tẹs. 5:11.