ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 3/08 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 10
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 17
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 24
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 31
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 7
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
km 3/08 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 10

Orin 131

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé 4 tàbí ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ míì tó bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè lo Ilé Ìṣọ́ March 1 àti Jí! January-March pa pọ̀ pẹ̀lú ìwé ìkésíni síbi Ìrántí Ikú Kristi. (Lo àbá kẹta lójú ìwé 4 fún Jí! January-March.)

20 min: Kí Nìdí Tó fi Yẹ Ká Máa Lọ Sípàdé? Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ May 15, 2007, ojú ìwé 11 sí 13. Ní kí àwùjọ sọ àwọn àǹfààní tí wọ́n ti rí gbà látinú pípésẹ̀ sáwọn ìpàdé ìjọ déédéé, kí wọ́n sì ṣàlàyé bí wọ́n ṣe borí àwọn ohun tó fẹ́ dí wọn lọ́wọ́, kí wọ́n bàa lè máa wá sípàdé déédéé.

15 min: “A Ní Ohun Tá A Lè Fún Jèhófà.”a Bí àyè bá ṣe wà sí, ní kí àwùjọ sọ̀rọ̀ lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí.

Orin 8

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 17

Orin 144

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù March sílẹ̀. Sọ fún àwọn ará pé kí wọ́n mú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ April 1 àti Jí! January-March wá sí Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀, kí wọ́n sì múra sílẹ̀ láti ṣàlàyé àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tó máa bá ìpínlẹ̀ ìwàásù yín mu. Àwọn ìfilọ̀ tá a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.

15 min: Àpótí Ìbéèrè. Alàgbà ni kó bójú tó o. Ka gbogbo àpilẹ̀kọ náà kó o sì jíròrò rẹ̀.

20 min: “Báwo La Ṣe Lè Ran Àwọn Tó Bá Wá Síbi Ìrántí Ikú Kristi Lọ́wọ́?”b Nígbà tó o bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 5, ṣe àṣefihàn ṣókí lórí bá a ṣe lè bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn àlejò tó bá wá síbi Ìrántí Ikú Kristi.

Orin 214

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 24

Orin 111

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn ará létí pé kí wọ́n mú ìwé pẹlẹbẹ náà, Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I? wá sí Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀, kí wọ́n sì múra ẹ̀kọ́ 5 nínú ìwé náà sílẹ̀. Ka ìròyìn ìnáwó àti lẹ́tà tí ẹ̀ka ọ́fíìsì kọ láti dúpẹ́.

15 min: Múra Sílẹ̀ Láti Fàwọn Ìwé Ìròyìn Tó Bá Ṣẹ̀ṣẹ̀ Dé Lọni. Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ April 1 àti Jí! January-March. Lẹ́yìn tó o bá ti sọ̀rọ̀ ṣókí lórí ìwé ìròyìn méjèèjì, ní káwọn ará sọ àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣeé ṣe kó fa àwọn èèyàn lọ́kàn mọ́ra ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín, kí wọ́n sì sọ ìdí tí wọ́n fi rò bẹ́ẹ̀. Ní kí wọ́n mẹ́nu ba àwọn kókó kan látinú àwọn àpilẹ̀kọ tí wọ́n ní lọ́kàn láti lò lóde ẹ̀rí. Ìbéèrè wo ni wọ́n lè fi bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò? Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ni wọ́n máa fẹ́ láti kà látinú àpilẹ̀kọ náà? Lo àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tá a dábàá nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa tàbí ọ̀kan tí àwùjọ dámọ̀ràn láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi ìwé ìròyìn kọ̀ọ̀kan lọni. (Lo àbá kẹrin lójú ìwé 4 fún Jí! January-March)

20 min: Àwọn Tí Ń Mú Ìhìn Rere Ohun Tí Ó Dára Jù Wá. Lẹ́yìn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí kò tó ìṣẹ́jú kan, kí alàgbà kan sọ àsọyé tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ July 1, 2005, ojú ìwé 18 àti 19, ìpínrọ̀ 10 sí 14. Ní kí àwùjọ sọ̀rọ̀ lórí bí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ṣe jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé nǹkan ṣì ń bọ̀ wá dáa, àti bó ṣe tù wọ́n nínú nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ gbọ́ ọ.

Orin 29

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní March 31

Orin 37

5 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù March sílẹ̀.

25 min: Àṣírí Iṣẹ́ Òkùnkùn. Alàgbà ni kó bójú tó o. Fi ìpínrọ̀ 1 sí 5 ní Orí 5 ìwé pẹlẹbẹ náà, Ọ̀nà Tó Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun—Ṣé O Ti Rí I? nasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ láàárín ìṣẹ́jú méjì sí mẹ́ta. Kó o wá jíròrò ìpínrọ̀ 6 sí 17 lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Ka ìpínrọ̀ 10, 11, 12 àti àpótí tó wà lójú ìwé 18, kó o sì ṣe àwọn àlàyé tó máa jẹ́ káwọn ará lóye àwọn kókó ẹ̀kọ́ tó ń yíni lérò padà, èyí tá a gbé karí òtítọ́ Bíbélì tó ń gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn irọ́ tí Sátánì ń pa àtàwọn ẹ̀kọ́ ẹ̀mí Èṣù.—Jòh. 8:32, 44.

15 min: “Bá A Ṣe Lè Máa Gbé Ara Wa Ró Lóde Ẹ̀rí”c

Orin 155

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní April 7

Orin 186

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.

20 min: Kí Nìdí Tí O Fi Ń Sún Ṣíṣe Ìrìbọmi Síwájú? Àsọyé tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ July 1, 2006, ojú ìwé 29 àti 30, ìpínrọ̀ 14 sí 17. Alàgbà ni kó bójú tó o. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò ní ṣókí lẹ́nu akéde kan tàbí méjì tí wọ́n ṣèrìbọmi nígbà tí wọ́n wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá sí mọ́kàndínlógún. Kí ló mú wọn ṣe irú ìpinnu pàtàkì yìí nígbà tí wọ́n ṣì kéré? Báwo ni ìrìbọmi wọn ṣe ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dàgbà nípa tẹ̀mí tó sì tipa bẹ́ẹ̀ dáàbò bò wọ́n?

15 min: Fífi Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọni Ní Tààràtà. Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti January 2002, ojú ìwé 6. Jíròrò àwọn ìgbékalẹ̀ ọ̀rọ̀ tá a dábàá, kó o sì ṣàlàyé bá a ṣe lè fi àwọn àbá wọ̀nyẹn bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì látinú ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni. Lẹ́yìn náà kó o ṣe àṣefihàn kan tàbí méjì. Gba àwọn ará níyànjú láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní tààràtà lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀ látinú ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni.

Orin 225

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

b Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

c Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kó o wá darí àpilẹ̀kọ náà lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́