Ẹ̀yin Èwe, Ẹ Pinnu Láti Sin Jèhófà
“Lónìí yìí, ẹ yan ẹni tí ẹ̀yin yóò máa sìn fún ara yín.”—JÓṢÚÀ 24:15.
1, 2. Irú àwọn ìrìbọmi tí kò tọ́ wo làwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ń ṣe?
“NÍGBÀ tí [àwọn ọmọdé] bá dàgbà tó láti mọ Kristi ni kẹ́ ẹ jẹ́ kí wọ́n di Kristẹni.” Òǹkọ̀wé kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tertullian ló kọ gbólóhùn yẹn nígbà tó kù díẹ̀ kí ọ̀rúndún kejì Sànmánì Kristẹni parí. Ìrìbọmi fáwọn ọmọdé, èyí tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í fìdí múlẹ̀ nínú àwọn ìsìn Kristẹni apẹ̀yìndà ti ìgbà ayé rẹ̀ ló ń ta ko. Augustine tó jẹ́ Bàbá Ìjọ lẹ́yìn àkókò àwọn àpọ́sítélì kò fara mọ́ ohun tí Tertullian àti Bíbélì sọ lórí ọ̀ràn yìí, ó sọ pé ìrìbọmi máa ń mú àbàwọ́n ẹ̀ṣẹ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ kúrò àti pé inú iná ọ̀run àpáàdì làwọn ọmọ ọwọ́ tó bá kú láìṣe ìrìbọmi ń lọ. Ìgbàgbọ́ yẹn ló mú kí wọ́n máa ṣèrìbọmi fáwọn ọmọ ọwọ́ tí wọ́n bá ti bí wọn.
2 Ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì tó lórúkọ kárí ayé ṣì ń ṣèrìbọmi fáwọn ọmọ ọwọ́. Síwájú sí i, àtayébáyé làwọn alákòóso àtàwọn olórí ìsìn láwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n pè ní tàwọn ẹlẹ́sìn Kristẹni ti máa ń ṣèrìbọmi tipátipá fún “àwọn kèfèrí” tí wọ́n mú lóǹdè. Àmọ́ ṣá o, Bíbélì kò fọwọ́ sí ìrìbọmi ọmọdé tàbí ìrìbọmi tá a fipá mú àwọn àgbà ṣe.
Ìyàsímímọ́ Kì Í Ṣe Àfipáṣe Lónìí
3, 4. Kí ló lè ran àwọn ọmọ táwọn òbí wọn ti yara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run lọ́wọ́ láti fínnúfíndọ̀ ṣe ìyàsímímọ́?
3 Bíbélì fi hàn pé Ọlọ́run ka àwọn ọmọ sí mímọ́ kódà bó jẹ́ ọ̀kan lára òbí wọn ni Kristẹni olóòótọ́. (1 Kọ́ríńtì 7:14) Ǹjẹ́ ìyẹn wá sọ irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ di ìránṣẹ́ Jèhófà to ti ṣe ìyàsímímọ́? Rárá o. Àmọ́, àwọn ọmọ táwọn òbí tó ti yara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà bá tọ́ máa ń gba ẹ̀kọ́ tó lè mú kí wọ́n fínnúfíndọ̀ yara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà. Sólómọ́nì ọlọ́gbọ́n Ọba kọ̀wé pé: “Ìwọ ọmọ mi, pa àṣẹ baba rẹ mọ́, má sì ṣe ṣá òfin ìyá rẹ tì. . . . Nígbà tí ìwọ bá ń rìn káàkiri, yóò máa ṣamọ̀nà rẹ; nígbà tí o bá dùbúlẹ̀, yóò máa ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí rẹ; nígbà tí o bá sì jí, yóò máa fi ọ́ ṣe ìdàníyàn rẹ̀. Nítorí pé àṣẹ jẹ́ fìtílà, òfin sì jẹ́ ìmọ́lẹ̀, àwọn ìtọ́sọ́nà inú ìbáwí sì ni ọ̀nà ìyè.”—Òwe 6:20-23.
4 Ìtọ́sọ́nà látọ̀dọ̀ àwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni lè dáàbò bo àwọn ọmọ tí wọ́n bá múra tán láti tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà náà. Sólómọ́nì tún sọ pé: “Ọlọ́gbọ́n ọmọ ni ẹni tí ń mú kí baba yọ̀, arìndìn ọmọ sì ni ẹ̀dùn-ọkàn ìyá rẹ̀.” “Ìwọ, ọmọ mi, gbọ́, kí o sì di ọlọ́gbọ́n, kí o sì máa ṣamọ̀nà ọkàn-àyà rẹ nìṣó ní ọ̀nà.” (Òwe 10:1; 23:19) Dájúdájú, kí ẹ̀yin ọmọ tó ó lè jàǹfààní látinú ìdálẹ́kọ̀ọ́ àwọn òbí yín, ẹ ní láti tẹ́wọ́ gba ìmọ̀ràn àti ìbáwí tinútinú. Wọn ò bí ọgbọ́n mọ́ yín, àmọ́ ẹ lè “di ọlọ́gbọ́n” kí ẹ sì fínnúfíndọ̀ máa tẹ̀ lé “ọ̀nà ìyè.”
Kí Ni Ìlànà Èrò Orí?
5. Ìmọ̀ràn wo ni Pọ́ọ̀lù fún àwọn ọmọ àtàwọn bàbá?
5 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin ọmọ, ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn òbí yín ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Olúwa, nítorí èyí jẹ́ òdodo: ‘Bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ’; èyí tí í ṣe àṣẹ kìíní pẹ̀lú ìlérí: ‘Kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún ọ, kí ìwọ sì lè wà fún àkókò gígùn lórí ilẹ̀ ayé.’ Àti ẹ̀yin, baba, ẹ má ṣe máa sún àwọn ọmọ yín bínú, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní títọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.”—Éfésù 6:1-4.
6, 7. Kí ló túmọ̀ sí láti máa tọ́ àwọn ọmọ ní “ìlànà èrò orí Jèhófà,” kí sì nìdí téyìí kò fi túmọ̀ sí pé àwọn òbí ń darí àwọn ọmọ wọn lọ́nà tí kò yẹ?
6 Ṣé ńṣe làwọn òbí tó jẹ́ Kristẹni ń darí àwọn ọmọ wọn lọ́nà tí kò yẹ ni, nígbà tí wọ́n bá ń tọ́ wọ́n nínú “ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà”? Rárá o. Ta ló máa dá àwọn òbí lẹ́bi nítorí pé wọ́n ń kọ́ àwọn ọmọ wọn lóhun tó tọ́ àtohun tó máa mú káwọn ọmọ náà máa hùwà rere? Kò sẹ́ni tó ń dá àwọn aláìgbà-pọ́lọ́run-wà lẹ́bi pé wọ́n ń kọ́ àwọn ọmọ wọn pé Ọlọ́run kò sí. Àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì sọ pé dandan làwọn gbọ́dọ̀ fi ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Kátólíìkì kọ́ ọmọ àwọn, kò sì sẹ́ni tó ń sọ pé ohun tí wọ́n ṣe burú. Bákan náà ló ṣe yẹ kí ọ̀rọ̀ tàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí, ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ fẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọ́n ń ra àwọn ọmọ wọn níyè nígbà tí wọ́n ń bá tọ́ wọn láti gba èrò Jèhófà lórí àwọn ẹ̀kọ́ téèyàn kọ́kọ́ ń mọ̀ nínú Bíbélì àti lórí àwọn ìlànà ìwà rere.
7 Gẹ́gẹ́ bí ìwé kan tó ń jẹ́ Theological Dictionary of the New Testament tó ń ṣàlàyé ọ̀rọ̀ Bíbélì ti wí, ọ̀rọ̀ Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n tú sí “ìlànà èrò orí” nínú Éfésù 6:4 ń sọ nípa ọ̀nà téèyàn ń gbà “ṣàtúnṣe ìrònú, téèyàn ń gbà tún ohun tó wọ́ ṣe, tàbí ọ̀nà téèyàn gbà túbọ̀ ń nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run.” Ká sọ pé èwe kan kò fẹ́ gba ẹ̀kọ́ àwọn òbí rẹ̀ ńkọ́, nítorí pé àwọn ẹgbẹ́ rẹ̀ fẹ́ kó máa ṣohun táwọn ń ṣe, òun náà sì fẹ́ máa ṣe bẹ́ẹ̀. Ta la lè sọ pé ó ń darí ọmọ náà láìyẹ, ṣe àwọn òbí ọmọ náà ni àbí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ náà tí wọ́n ń fẹ́ kó ṣohun táwọn ń ṣe? Báwọn ẹgbẹ́ ọmọ náà bá ń fúngun mọ́ ọn pé kó lo oògùn olóró, kó mutí yó, tàbí kó ṣèṣekúṣe, ṣé ó yẹ ká bá àwọn òbí wí bí wọ́n bá ń gbìyànjú láti tún èrò ọmọ wọn ṣe tí wọ́n sì ń ràn án lọ́wọ́ láti rí ewu tó wà nínú irú àwọn ìwà abèṣe bẹ́ẹ̀?
8. Àwọn nǹkan wo ló mú kó ṣeé ṣe fún Tímótì láti dẹni tá a ‘yí lérò padà láti gbà gbọ́’?
8 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí ọ̀dọ́kùnrin tó ń jẹ́ Tímótì pé: “Máa bá a lọ nínú àwọn ohun tí o ti kọ́, tí a sì ti yí ọ lérò padà láti gbà gbọ́, ní mímọ ọ̀dọ̀ àwọn tí o ti kọ́ wọn àti pé láti ìgbà ọmọdé jòjòló ni ìwọ ti mọ ìwé mímọ́, èyí tí ó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n fún ìgbàlà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù.” (2 Tímótì 3:14, 15) Látìgbà tí Tímótì ti wà ní ọmọdé jòjòló ni ìyá rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ àgbà tí wọ́n jẹ́ Júù ti mú kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú Ọlọ́run fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin nípasẹ̀ ìmọ̀ látinú Ìwé Mímọ́. (Ìṣe 16:1; 2 Tímótì 1:5) Nígbà tí wọ́n wá di Kristẹni, wọn ò fipá mú Tímótì láti gba ohun tí wọ́n ń sọ fún un gbọ́, àmọ́ wọ́n “yí i lérò padà” nípa ṣíṣe àwọn àlàyé tó bọ́gbọ́n mu fún un látinú Ìwé Mímọ́.
Jèhófà Ń Ké sí Ọ Pé Kó O Pinnu Láti Sin Òun
9. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe pọ́n àwa èèyàn lé, kí sì nìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀? (b) Báwo ni Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Ọlọ́run ṣe lo òmìnira tí Ọlọ́run fún un?
9 Ká ní ó wu Jèhófà bẹ́ẹ̀, ó lè dá àwọn èèyàn bí ẹ̀rọ, tó jẹ́ pé ohun tó fẹ́ ni wọ́n á máa ṣe, wọn ò ní lè ṣe ohun tó yàtọ̀ síyẹn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó pọ́n wọn lé, ó fún wọn ní òmìnira láti yan ohun tó wù wọ́n. Àwọn èèyàn tó máa fínnúfíndọ̀ ṣègbọràn ni Ọlọ́run wa ń fẹ́. Inú rẹ̀ máa ń dùn nígbà táwọn èèyàn, lọ́mọdé lágbà, bá ń sìn ín nítorí ìfẹ́ tí wọ́n ní fún un. Ẹnì kan tó jẹ́ àpẹẹrẹ tó dára jù lọ nínú ṣíṣègbọràn sí Ọlọ́run tìfẹ́tìfẹ́ ni Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo, ẹni tí Jèhófà sọ nípa rẹ̀ pé: “Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.” (Mátíù 3:17) Àkọ́bí Ọmọ yìí sọ fún Bàbá rẹ̀ pé: “Láti ṣe ìfẹ́ rẹ, ìwọ Ọlọ́run mi, ni mo ní inú dídùn sí, òfin rẹ sì ń bẹ ní ìhà inú mi.”—Sáàmù 40:8; Hébérù 10:9, 10.
10. Kí ló ń mú wa sin Jèhófà lọ́nà tó tẹ́wọ́ gbà?
10 Jèhófà fẹ́ káwọn tó ń sin òun lábẹ́ ìdarí Ọmọ òun máa tẹrí ba tinútinú bí wọ́n ti ń ṣe ìfẹ́ òun gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ń ṣe. Onísáàmù kọ orin kan tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀, ó ní: “Àwọn ènìyàn rẹ yóò fi tinútinú yọ̀ǹda ara wọn ní ọjọ́ ẹgbẹ́ ológun rẹ. Nínú ọlá ńlá ìjẹ́mímọ́, láti inú ilé ọlẹ̀ ọ̀yẹ̀, ìwọ ní àwùjọ rẹ ti àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n rí bí ìrì tí ń sẹ̀.” (Sáàmù 110:3) Ìgbọràn táwọn ẹ̀dá Ọlọ́run ń ṣe sí i nítorí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ ló ń mú kí ètò Jèhófà lódindi, ìyẹn apá ti ọ̀run àti ti orí ilẹ̀ ayé máa bá iṣẹ́ lọ.
11. Ìpinnu wo làwọn èwe tó jẹ́ ọmọ àwọn òbí tó ti ṣèyàsímímọ́ ní láti ṣe?
11 Nítorí náà, ó yẹ kí ẹ̀yin èwe mọ̀ pé àwọn òbí yin tàbí àwọn alàgbà inú ìjọ kò lè fipá mú un yín ṣèrìbọmi. Fífẹ́ tẹ́ ẹ fẹ́ láti sin Jèhófà gbọ́dọ̀ wá látọkàn yín. Jóṣúà sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Kí ẹ sì máa sin [Jèhófà] ní àìlálèébù àti ní òtítọ́ . . . Ẹ yan ẹni tí ẹ̀yin yóò máa sìn fún ara yín.” (Jóṣúà 24:14-22) Bẹ́ẹ̀ ló ṣe jẹ́ pé ẹ̀yin fúnra yín lẹ gbọ́dọ̀ fínnúfíndọ̀ pinnu láti ya ara yín sí mímọ́ fún Jèhófà kẹ́ ẹ sì máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní gbogbo ìgbésí ayé yín.
Ìwọ Ló Máa Gbé Ẹrù Ara Rẹ
12. (a) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn òbí lè kọ́ àwọn ọmọ wọn lẹ́kọ̀ọ́, kí ni wọ́n ò lè ṣe fún àwọn ọmọ wọn? (b) Ìgbà wo ni èwe kan máa dẹni tí yóò gbé ẹrù ara rẹ̀ níwájú Jèhófà fún ohun tó bá yàn láti ṣe?
12 Tó bá yá, ìṣòtítọ́ àwọn òbí yín kò ní dáàbò bo ẹ̀yin ọmọ mọ́. (1 Kọ́ríńtì 7:14) Jákọ́bù ọmọ ẹ̀yìn Jésù kọ̀wé pé: “Nítorí náà, bí ẹnì kan bá mọ bí a ti ń ṣe ohun tí ó tọ́, síbẹ̀ tí kò ṣe é, ẹ̀ṣẹ̀ ni fún un.” (Jákọ́bù 4:17) Àwọn òbí kò lè sin Ọlọ́run fún àwọn ọmọ wọn gẹ́gẹ́ báwọn ọmọ náà kò ti lè sin Ọlọ́run fún àwọn òbí wọn. (Ísíkíẹ́lì 18:20) Ǹjẹ́ o ti mọ̀ nípa Jèhófà àtàwọn ohun tó fẹ́ ṣe fún ìran èèyàn? Ǹjẹ́ o ti dàgbà tó láti lóye ohun tí o kọ́ àti láti bẹ̀rẹ̀ sí í ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run? Ǹjẹ́ kò ní bọ́gbọ́n mu láti gbà pé Ọlọ́run ti kà ọ́ sẹ́ni tó lè dá pinnu láti sin òun nìyẹn?
13. Àwọn ìbéèrè wo ló yẹ káwọn ọ̀dọ́ tí kò tíì ṣèrìbọmi bi ara wọn?
13 Ṣé èwe tí kò tíì ṣèrìbọmi ni ọ́, tó o ní òbí tó jẹ́ olùjọ́sìn Ọlọ́run, tó ò ń wá sípàdé, tó o tiẹ̀ ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run pàápàá? Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, fi òótọ́ inú béèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé: ‘Kí nìdí tí mo fi ń ṣe ohun tí mò ń ṣe yìí? Ṣé nítorí pé àwọn òbí mi fẹ́ kí n máa lọ sípàdé kí n sì máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù ni mo ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀ àbí nítorí pé mo fẹ́ múnú Jèhófà dùn?’ Ǹjẹ́ ìwọ fúnra rẹ ti ṣàwárí “ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé”?—Róòmù 12:2.
Kí Nìdí Tí O Fi Ń Sún Ṣíṣe Ìrìbọmi Síwájú?
14. Àwọn àpẹẹrẹ wo nínú Bíbélì ló fi hàn pé kò yẹ kéèyàn máa sún ṣíṣe ìrìbọmi síwájú láìnídìí?
14 “Kí ni ó dí mi lọ́wọ́ dídi ẹni tí a batisí?” Ńṣe ni ọkùnrin ará Etiópíà kan tó béèrè ìbéèrè yìí lọ́wọ́ Fílípì ajíhìnrere ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ̀ pé Jésù ni Mèsáyà. Àmọ́ ará Etiópíà yìí ti ní ìmọ̀ Ìwé Mímọ́ tí ó tó láti mọ̀ pé kò yẹ kóun jáfara láti jẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ̀ pé, látìgbà yẹn lọ, òun á máa sin Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ara ìjọ Kristẹni, ìyẹn sì múnú rẹ̀ dùn jọjọ. (Ìṣe 8:26-39) Bákan náà, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni obìnrin kan tó ń jẹ́ Lìdíà, tí ọkàn rẹ̀ ṣí sílẹ̀ “láti fiyè sí àwọn ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ” ‘ṣèrìbọmi,’ òun àti agbo ilé rẹ̀. (Ìṣe 16:14, 15) Bẹ́ẹ̀ náà ni onítúbú kan tó wà nílùú Fílípì fetí sí Pọ́ọ̀lù àti Sílà bí wọ́n ti ń “sọ ọ̀rọ̀ Jèhófà fún un . . . òun àti àwọn tirẹ̀ ni a sì batisí láìjáfara.” (Ìṣe 16:25-34) Nítorí náà, tó o bá ti ní ìmọ̀ téèyàn kọ́kọ́ ń ní nípa Jèhófà àtohun tó fẹ́ ṣe fún ìran èèyàn, tó sì wá látọkàn rẹ láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀, tó o sì ní orúkọ rere nínú ìjọ, tó ò ń wá sípàdé déédéé, tó o sì tún ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, kí nìdí tó ò fi ní fẹ́ ṣèrìbọmi?—Mátíù 28:19, 20.
15, 16. (a) Èrò tí kò tọ́ wo ló lè mú káwọn èwe kan máa lọ́ tìkọ̀ láti ṣèrìbọmi? (b) Ọ̀nà wo ni ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi lè gbà jẹ́ ààbò fáwọn èwe?
15 Àbí ó lè jẹ́ nítorí ìbẹ̀rù pé bó bá ṣẹlẹ̀ pé o dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá kan wàá dáhùn fún un lo ṣe ń lọ́ tìkọ̀ láti ṣe ohun pàtàkì yìí? Bó bá jẹ́ èrò rẹ nìyẹn, wò ó lọ́nà yìí ná: Tó o bá ti mọ ọkọ̀ wà, ṣé wàá kọ̀ láti gba ìwé àṣẹ ìwakọ̀ nítorí pé ẹ̀rù ń bà ọ́ pé lọ́jọ́ kan o lè lọ wakọ̀ jáàmù? Rárá o! Bó bá rí bẹ́ẹ̀ nígbà náà, kò yẹ kó o lọ́ tìkọ̀ láti ṣèrìbọmi tó o bá ti kúnjú ìwọ̀n. Ká sòótọ́, bó o bá ya ìgbésí ayé rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà tó o sì gbà láti máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀, èyí yóò mú kó o sa gbogbo ipá rẹ láti yẹra fún ṣíṣe ohun tí kò tọ́. (Fílípì 4:13) Ẹ̀yin èwe, ẹ jọ̀wọ́, ẹ má ṣe rò pé sísún ìrìbọmi yín síwájú ni kò ní jẹ́ kẹ́ ẹ jíhìn fún Ọlọ́run. Tó o bá ti tó ọjọ́ orí ẹni tó mọ nǹkan tó tọ́, ìwọ fúnra rẹ ló máa dáhùn níwájú Jèhófà fún ìwà tó o bá hù, yálà o ti ṣèrìbọmi tàbí o kò tíì ṣèrìbọmi.—Róòmù 14:11, 12.
16 Ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí karí ayé ló sọ pé ìpinnu táwọn ṣe láti ṣèrìbọmi nígbà táwọn wà ní èwe ti ran àwọn lọ́wọ́ gan-an. Gbé àpẹẹrẹ ọmọ ọdún mẹ́tàlélógún kan ní Ìwọ̀ Oòrùn Yúróòpù yẹ̀ wò. Ó rántí pé ṣíṣe ìrìbọmi lọmọ ọdún mẹ́tàlá mú kóun lè túbọ̀ kíyè sára gan-an láti má ṣe jẹ́ kí “àwọn ìfẹ́-ọkàn tí ó máa ń bá ìgbà èwe rìn” gbá òun lọ. (2 Tímótì 2:22) Àtìgbà tó ti wà ní ọ̀dọ́ ló ti pinnu pé òun máa di òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún. Lónìí, ó ń sìn tayọ̀tayọ̀ ní ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Gbogbo èwe tó yàn láti sin Jèhófà ni yóò rí ìbùkún rẹpẹtẹ gbà, títí kan ìwọ náà.
17. Àwọn apá ibo ló ti ṣe pàtàkì pé ká máa bá a lọ ní ríróye ohun tí “ìfẹ́ Jèhófà” jẹ́?
17 Ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé kan tá a ti máa ń ronú nípa ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Jèhófà nínú gbogbo ohun tá a bá ń ṣe. Ṣíṣe ohun tó bá ìyàsímímọ́ wa mu ní í ṣe pẹ̀lú ‘ríra àkókò padà.’ Ọ̀nà wo là ń gbà ṣe ìyẹn? Bí a ṣe ń ṣe é ni pé, àkókò tá à ń lò fáwọn nǹkan tí kò mọ́yán lórí la wá ń lò fún kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́nà tó jinlẹ̀, lílọ sípàdé déédéé, àti kíkópa kíkún nínú wíwàásù “ìhìn rere ìjọba” náà. (Éfésù 5:15, 16; Mátíù 24:14) Ìyàsímímọ́ wa sí Jèhófà àti fífi gbogbo ọkàn wa fẹ́ láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀ yóò nípa tó dára lórí gbogbo ohun tí a bá ń ṣe nígbèésí ayé wa. Títí kan bá a ṣe ń lo àkókò ìsinmi wa, bá a ṣe ń jẹ àti bí a ṣe ń mu, àti irú orin tá à ń gbọ́. O ò ṣe yan eré ìtura tí wàá lè gbádùn títí ayé? Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èwe aláyọ̀ tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí yóò sọ fún ọ pé ọ̀pọ̀ ọ̀nà ló wà téèyàn lè fi gbádùn ara rẹ̀ láìṣe ohun tó lòdì sí “ìfẹ́ Jèhófà.”—Éfésù 5:17-19.
“Àwa Yóò Bá Yín Lọ”
18. Ìbéèrè wo ló yẹ káwọn èwe bi ara wọn?
18 Láti ọdún 1513 ṣáájú Sànmánì Kristẹni sí ìgbà Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni ni Jèhófà ti ní àwọn èèyàn tó kó jọ lórí ilẹ̀ ayé, ìyẹn àwọn tó yàn pé kí wọ́n máa jọ́sìn òun kí wọ́n sì jẹ́ Ẹlẹ́rìí òun. (Aísáyà 43:12) Inú orílẹ̀-èdè yẹn ni wọ́n bí àwọn èwe tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì sí. Látìgbà Pẹ́ńtíkọ́sì yẹn ni Jèhófà ti ní “orílẹ̀-èdè” tuntun lórí ilẹ̀ ayé, ìyẹn Ísírẹ́lì tẹ̀mí, “àwọn ènìyàn kan fún orúkọ rẹ̀.” (1 Pétérù 2:9, 10; Ìṣe 15:14; Gálátíà 6:16) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé, Kristi ti wẹ “àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ tirẹ̀ lákànṣe mọ́ fún ara rẹ̀, àwọn onítara fún iṣẹ́ àtàtà.” (Títù 2:14) Ẹ̀yin èwe lómìnira láti fúnra yín mọ ibi tí ẹ ti lè rí àwọn èèyàn náà. Àwọn wo lónìí ló jẹ́ “orílẹ̀-èdè òdodo tí ń pa ìwà ìṣòtítọ́ mọ,” tó ń fi àwọn ìlànà Bíbélì ṣèwàhù, tó sì jẹ́ Ẹlẹ́rìí olóòótọ́ fún Jèhófà, tó tún ń polongo Ìjọba Ọlọ́run pé ìrètí kan ṣoṣo tí aráyé ní nìyẹn? (Aísáyà 26:2-4) Wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì àtàwọn ìsìn mìíràn, kó o wá fi ìwà wọn wé ohun tí Bíbélì sọ pé káwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run máa ṣe.
19. Kí ló dá ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn jákèjádò ayé lójú?
19 Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn jákèjádò ayé, títí kan ọ̀pọ̀ àwọn èwe ló gbà pé àwọn àṣẹ́kù ẹni àmì òróró ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni “orílẹ̀-èdè òdodo” yẹn. Àwọn èèyàn wọ̀nyí ń sọ fún Ísírẹ́lì tẹ̀mí yìí pé: “Àwa yóò bá yín lọ, nítorí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.” (Sekaráyà 8:23) Ìrètí wa àti àdúrà wa àtọkànwá ni pé, kẹ́yin èwe pinnu láti jẹ́ ara àwọn èèyàn Ọlọ́run kí ẹ sì “yan ìyè,” tí í ṣe ìyè àìnípẹ̀kun nínú ayé tuntun Jèhófà.—Diutarónómì 30:15-20; 2 Pétérù 3:11-13.
Àtúnyẹ̀wò
• Kí ni kíkọ́ àwọn ọmọ ní ìlànà èrò Jèhófà túmọ̀ sí?
• Irú iṣẹ́ ìsìn wo ni Jèhófà tẹ́wọ́ gbà?
• Ìpinnu wo làwọn èwe tó jẹ́ ọmọ àwọn òbí tó ti ṣèyàsímímọ́ ní láti ṣe?
• Kí nìdí tí kò fi yẹ kéèyàn sún ṣíṣe ìrìbọmi síwájú láìnídìí?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ta lo máa fetí sí?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Báwo ni ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi ṣe lè jẹ́ ààbò fún ọ?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Kí ló ń dí ọ lọ́wọ́ láti ṣèrìbọmi?