Orin 128
Ipò Nǹkan Ń Yí Pa Dà Ní Ayé Yìí
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Ọlọ́run fún wa lẹ́bùn kan
Tó tún ju gbogbo ẹ̀bùn lọ,
Ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo, ká lè
Ṣẹ́gun ẹ̀ṣẹ̀ òun ikú.
(ÈGBÈ)
Bí ipò ayé yìí
tiẹ̀ ńyí pa dà,
Ọlọ́run ti ńfọgbọ́n ṣètò
Ìbùkún fáyé, fọ́run.
2. Ilé ayé yìí dojúrú.
Ètò búburú yìí wó tán.
Ìjọba Ọlọ́run la ńfẹ́;
A ti bí Ìjọba náà.
(ÈGBÈ)
Bí ipò ayé yìí
tiẹ̀ ńyí pa dà,
Ọlọ́run ti ńfọgbọ́n ṣètò
Ìbùkún fáyé, fọ́run.
(Tún wo Sm. 115:15, 16; Róòmù 5:15-17; 7:25; Ìṣí. 12:5.)