ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w12 11/1 ojú ìwé 3
  • Ǹjẹ́ Ó Tọ́ Ká Máa Bi Ọlọ́run Ní Ìbéèrè?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ Ó Tọ́ Ká Máa Bi Ọlọ́run Ní Ìbéèrè?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Báwo Ni Àkókò Tó Ṣẹ́ Kù Fún Àwọn Olubi Ti Pọ̀ Tó?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Kó O Lè Wà Láàyè!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Kíkún Fún Ìdùnnú Nínú Ọlọ́run Ìgbàlà Wa
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Kí Ni Òtítọ́ Nípa Irú Ẹni Tí Ọlọ́run Jẹ́?
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
w12 11/1 ojú ìwé 3

Ǹjẹ́ Ó Tọ́ Ká Máa Bi Ọlọ́run Ní Ìbéèrè?

ÀWỌN kan sọ pé kò tọ́ kéèyàn máa bi Ọlọ́run ní ìbéèrè. Wọ́n máa ń rò pé ìwà àrífín ni téèyàn bá ń béèrè ìdí tí Ọlọ́run fi jẹ́ kí àwọn nǹkan kan ṣẹlẹ̀ tàbí ìdí tí kò fi jẹ́ kí àwọn nǹkan míì ṣẹlẹ̀. Ṣé èrò tìrẹ náà nìyẹn?

Tó o bá ní irú èrò bẹ́ẹ̀, ó lè yà ẹ́ lẹ́nu tó o bá gbọ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn rere ló ti bi Ọlọ́run ní ìbéèrè nípa ìdí tó fi ṣe àwọn nǹkan kan. Wo díẹ̀ nínú irú àwọn ìbéèrè tí wọ́n bi í:

Ọkùnrin olódodo kan tó ń jẹ́ Jóòbù béèrè pé: “Èé ṣe tí àwọn ẹni burúkú fi ń wà láàyè nìṣó, tí wọ́n darúgbó, tí wọ́n sì di ẹni tí ó pọ̀ ní ọlà pẹ̀lú?”—Jóòbù 21:7.

Hábákúkù tó jẹ́ wòlíì olóòótọ́ sọ pé: “Èé ṣe tí o fi ń wo àwọn tí ń ṣe àdàkàdekè, tí o fi dákẹ́ nígbà tí ẹni burúkú gbé ẹnì kan tí ó jẹ́ olódodo jù ú mì?”—Hábákúkù 1:13.

Jésù Kristi náà sọ pé: “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èé ṣe tí ìwọ fi ṣá mi tì?”—Mátíù 27:46.

Tó o bá ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tó ṣáájú àti àwọn tó tẹ̀ lé àwọn ẹsẹ tá a fà yọ sókè yìí, wàá rí i pé ìbéèrè tí àwọn wọ̀nyẹn béèrè tọkàntọkàn kò bí Jèhófàa Ọlọ́run nínú. Ṣùgbọ́n o, kò yani lẹ́nu bí Ọlọ́run kò ṣe bínú sí wọn. Torí kì í kà á sí ìwọ̀sí tí a bá bẹ̀ ẹ́ pé kó pèsè àwọn ohun kòṣeémánìí fún wa kí ara wa lè le dáadáa. Inú Ọlọ́run máa ń dùn láti pèsè àwọn nǹkan wọ̀nyẹn fún wa. (Mátíù 6:11, 33) Bákan náà, tinútinú ni Ọlọ́run fi sọ àwọn ohun tó máa jẹ́ ká ní èrò tó dáa kí ọkàn wa sì balẹ̀. (Fílípì 4:6, 7) Kódà Jésù tiẹ̀ sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní bíbéèrè, a ó sì fi í fún yín.” (Mátíù 7:7) Àlàyé tí Jésù ń ṣe bọ̀ kó tó mẹ́nu kan ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé kì í ṣe nǹkan tara nìkan ló ń ṣèlérí pé a máa rí gbà, ó tún kan rírí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè pàtàkì tá a bá béèrè.

Ká ní o láǹfààní láti béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, èwo nínú àwọn ìbéèrè yìí lo máa fẹ́ béèrè?

  • Ìwọ Ọlọ́run, kí nìdí tó o fi dá mi sáyé?

  • Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí mi nígbà tí mo bá kú?

  • Kí nìdí tó o fi jẹ́ kí ìyà máa jẹ mí?

Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé “gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí,” wàá rí ìdáhùn Ọlọ́run sí ìbéèrè rẹ nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀. (2 Tímótì 3:16) Jẹ́ ká wo ìdí tí àwọn kan fi béèrè irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀ àti bí Bíbélì ṣe dáhùn wọn.

a Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́