SIERRA LEONE ÀTI GUINEA
1945 sí 1990 ‘Mímú Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Wá sí Òdodo’—Dán. 12:3. (Apá Kẹrin)
Bí A Ṣe Gbógun Ti Ìṣòro Àìmọ̀ọ́kọ-Mọ̀ọ́kà
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1963, Arákùnrin Milton Henschel pa dà wá sí orílẹ̀-èdè Sierra Leone, ó sì sọ ohun tí ẹ̀ka ọ́fíìsì lè ṣe sí ìṣòro kan tó ti ń bá wọn fínra tipẹ́. Ó rọ àwọn ará pé kí wọ́n túbọ̀ gbógun ti ìṣòro àìmọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà.
Àwọn ìjọ kan ní kíláàsì mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà lédè Gẹ̀ẹ́sì. Àmọ́, lẹ́yìn ìbẹ̀wò Arákùnrin Henschel, wọ́n bẹ̀rẹ̀ kíláàsì náà ní èdè àbínibí. Àwọn ìjọ kan tiẹ̀ ní kíláàsì fún èdè bíi méjì tàbí mẹ́ta. Ètò tí wọ́n ṣe yìí gbajúmọ̀ débi pé ọ̀pọ̀ akéde lórílẹ̀-èdè náà ló wá fi orúkọ sílẹ̀.
Lọ́dún 1966, àwọn ará tó wà ní orílẹ̀-èdè Làìbéríà ṣe ìwé akọ́mọlédè ti èdè Kisi. Nígbà tí wọ́n fi ìwé akọ́mọlédè náà han àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Làìbéríà, inú wọn dùn gan-an, wọ́n sọ pé àwọn máa tẹ̀ ẹ́ jáde, àwọn á sì pín in lọ́fẹ̀ẹ́. Wọ́n pín ìwé náà lórílẹ̀-èdè Guinea, Làìbéríà àti Sierra Leone, ó sì ran ọ̀pọ̀ àwọn tó ń sọ èdè Kisi lọ́wọ́ láti mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà. Nígbà tó yá, wọ́n tún tẹ ìwé akọ́mọlédè jáde ní àwọn èdè míì, èyí sì ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà.
Sia kept track of her witnessing activity with black and red strings
Yàtọ̀ sí pé ilé ẹ̀kọ́ yìí mú kí àwọn èèyàn lè kàwé kí wọ́n sì lè kọ̀wé, ó tún jẹ́ kí wọ́n tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Bí àpẹẹrẹ, Sia Ngallah jẹ́ ẹni àádọ́ta [50] ọdún, ó ti di akéde tí kò tíì ṣèrìbọmi, àmọ́ kò mọ̀wé kà. Okùn dúdú àti pupa ló máa fi ń ṣe àmì kó lè rántí iṣẹ́ tó bá ṣe lóde ẹ̀rí. Tó bá ti wàásù fún wákàtí kan, ó máa ta kókó kan sára okùn dúdú. Tó bá ti ṣe ìpadàbẹ̀wò, ó máa ta kókó kan sára okùn pupa. Nígbà tí Sia lọ sí kíláàsì mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà, ó kọ́ bí á ṣe máa ṣe àkọsílẹ̀ iṣẹ́ tó bá ṣe lóde ẹ̀rí. Èyí mú kó tẹ̀ síwájú títí tó fi ṣe ìrìbọmi, ó sì túbọ̀ já fáfá nínú bó ṣe ń wàásù àti bó ṣe ń kọ́ni.
Lónìí, ọ̀pọ̀ ìjọ lórílẹ̀-èdè Sierra Leone ṣì ní kíláàsì mọ̀ọ́kọ-mọ̀ọ́kà. Ọ̀gá àgbà kan tó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìjọba lórílẹ̀-èdè Sierra Leone sọ fún àwọn tó wà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa pé: “Láfikún sí bí ẹ ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, iṣẹ́ ribiribi lẹ̀ ń ṣe bí ẹ tún ṣe ń kọ́ wọn kí wọ́n lè mọ̀wé kà, kí wọ́n sì mọ̀ ọ́n kọ.”
Àwọn Púrúǹtù Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Kàwé
Bí àwọn èèyàn tó wá láti onírúurú ẹ̀yà ṣe ń kọ́ bí wọ́n ṣe lè kàwé, a rí i pé ó yẹ ká máa túmọ̀ àwọn ìwé wa. Èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ẹ̀yà ni kò fi bẹ́ẹ̀ ní àwọn ìwé lédè wọn, ìyẹn tó bá tiẹ̀ wà rárá. Èdè Gẹ̀ẹ́sì ni àwọn tó kàwé ní Sierra Leone máa ń kà, àmọ́ èdè Faransé ni wọ́n ń kà lórílẹ̀-èdè Guinea. Kí la wá ṣe ká lè tẹ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jáde ní èdè àbínibí wọn?
Lọ́dún 1959, àwọn méjì kan tó kẹ́kọ̀ọ́ yege nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì tú ìwé àṣàrò kúkúrú àti ìwé kékeré kan sí èdè Mende, àmọ́ ìwọ̀nba ẹ̀dà ni wọ́n pín. Ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn náà, wọ́n túmọ̀ ìwé “Ihinrere Ijọba Yi” àti ìwé Gbigbe ni Ireti Eto Titun Ododo sí èdè Kisi. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n [30,000] ni wọ́n pín lára àwọn ìwé náà, tí wọ́n sì fi kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Lọ́dún 1975, ẹ̀ka ọ́fíìsì wa bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ àwọn àpilẹ̀kọ tó wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú Ilé Ìṣọ́ jáde lédè Kisi. Inú àwọn akéde tó ń sọ èdè Kisi dùn gan-an! Arákùnrin kan sọ pé: “Iṣẹ́ àrà ni Jèhófà ṣe fún wa yìí o. Kò sí ìkankan nínú wa tó lọ ilé ìwé rí. A ò lè kàwé rárá, ṣe la dà bí òkúta lásán tí kò lè sọ̀rọ̀. Púrúǹtù ni wá tẹ́lẹ̀, àmọ́ ní báyìí a ti ní Ilé Ìṣọ́ ní èdè wa, a sì lè sọ nípa àwọn iṣẹ́ àrà Jèhófà.” (Lúùkù 19:40) Ètò Ọlọ́run sì túmọ̀ àwọn ìtẹ̀jáde wá míì lédè Kisi.
Lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ní orílẹ̀-èdè Sierra Leone àti Guinea ṣì ń ka àwọn ìtẹ̀jáde wa lédè Gẹ̀ẹ́sì tàbí Faransé, àwọn èdè yìí ni wọ́n sì fi ń ṣe àwọn ìpàdé ìjọ. Àmọ́ lẹ́nu àìpẹ́ yìí, iye ìtẹ̀jáde tó wà lédè àbínibí ti yára pọ̀ sí i. Ní báyìí, àwọn ìwé wa ti wà ní èdè Guerze, Kisi, Krio, Maninkakan, Mende, Pular àti Susu. Ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run àti Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé ti wà láwọn èdè yìí. Àwọn ìwé tó rọrùn láti fi kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ yìí ń ran àwọn èèyàn púpọ̀ tí kò fí bẹ́ẹ̀ mọ̀wé kà lọ́wọ́ láti lóye ẹ̀kọ́ Bíbélì, kí wọ́n sì mọyì rẹ̀.
A Kọ́ Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tiwa
Láti ọdún 1960 làwọn ará tó wà ní ìlú Freetown ti ń wá ilẹ̀ tí wọ́n máa fi kọ́ ẹ̀ka ọ́fíísì tuntun. Nígbà tó fi máa di ọdún 1965, wọ́n ra ilẹ̀ kan sí Òpópónà Wilkinson. Ó bọ́ sí tòsí etíkun, ní ọ̀kan lára àwọn ibi tó dára jù táwọn èèyàn ń gbé ní ìlú náà.
Gbọ̀ngàn Ìjọba kan, ilé àwọn míṣọ́nnárì àtàwọn ọ́fíìsì ni wọ́n fẹ́ kọ́ pa pọ̀ sínú ilé kan ṣoṣo tó fani mọ́ra náà. Nígbà tí iṣẹ́ ìkọ́lé náà ń lọ lọ́wọ́, sún-kẹẹrẹ fà-kẹẹrẹ ọkọ̀ sábà máa ń pọ̀ sí i ní Òpópónà Wilkinson, torí pé àwọn èèyàn máa ń fẹ́ wòran láti inú àwọn ọkọ̀ tó ń kọjá lọ. Ní August 19, ọdún 1967, a ya ilé náà sí mímọ́. Nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún [300] èèyàn ló pésẹ̀ síbẹ̀, títí kan àwọn èèyàn jàǹkàn-jàǹkàn ní àgbègbè náà àtàwọn tó ti pẹ́ nínú ètò Ọlọ́run tó sì jẹ́ pé Arákùnrin Bible Brown ló ṣèrìbọmi fún wọn lọ́dún 1923.
Ẹ̀ka ọ́fíìsì àti ilé àwọn míṣọ́nnárì ní ìlú Freetown (1965 sí 1997)
Ẹ̀ka ọ́fíìsì tuntun yìí buyì kún iṣẹ́ ìwàásù àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́kàn ọ̀pọ̀ èèyàn. Ó tún pa àwọn alátakò lẹ́nu mọ́ torí ohun tí wọ́n ń sọ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò ní pẹ́ dàwátì nílẹ̀ Sierra Leone. Ilé tuntun yìí jẹ́ ẹ̀rí pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti fìdí múlẹ̀ lórílẹ̀-èdè náà.
Àwọn Míṣọ́nnárì Onítara Mú Kí Ìbísí Wáyé
Àwọn ará tó wà lóde ẹ̀rí ń gba inú oko ìrẹsì tó wà nínú irà kọjá
Láti nǹkan bí ọdún 1975 ni ètò Ọlọ́run ti ń rán àwọn míṣọ́nnárì tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì wá sílẹ̀ Sierra Leone àti Guinea, wọ́n sì mú kí iṣẹ́ náà túbọ̀ gbilẹ̀. Àwọn kan lára wọn ti ṣiṣẹ́ ìsìn láwọn ibì kan nílẹ̀ Áfíríkà tẹ́lẹ̀, torí náà ara wọn tètè mọlé. Àmọ́ àwọn kan lára wọn kò dé ilẹ̀ Áfíríkà rí. Báwo ní wọ́n á ṣe wá lè gbé ní ìlú táwọn kan sọ pé “ojú ọjọ́ ibẹ̀ lè pa aláwọ̀ funfun”? Gbọ́ díẹ̀ lára ohun tí wọ́n sọ.
“Àwọn èèyàn yìí jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, àmọ́ ebi ń pa wọ́n nípa tẹ̀mí. Inú mi ń dùn gan-an bí mo ṣe ń rí i pé ẹ̀kọ́ òtítọ́ ń tún ìgbésí ayé wọn ṣe.”—Hannelore Altmeyer.
“Bí ojú ọjọ́ ṣe máa ń rí àtàwọn àìsàn tó wà níbí kò jẹ́ kí nǹkan rọrùn rárá. Àmọ́ ayọ̀ tí mò ń rí bí mo ṣe ń ran àwọn tó nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ lọ́wọ́ láti wá sin Jèhófà tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ.”—Cheryl Ferguson.
“Mo ti kọ́ bí mo ṣe lè túbọ̀ máa ní sùúrù. Nígbà tí mo bi arábìnrin kan pé ìgbà wo ni àwọn àlejò rẹ̀ máa dé, ó sọ pé: ‘Bóyá lónìí, lọ́la tàbí ní ọ̀túnla.’ Bó ṣe fèsì yẹn yà mí lẹ́nu gan-an, torí ó tẹnu mọ́ ọn pé ó dá òun lójú pé wọ́n máa dé!”—Christine Jones.
“Àwa míṣọ́nnárì mẹ́rìnlá láti ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la jọ ń gbé ilé kan náà ní ìlú Freetown. Àṣà ìbílẹ̀ àti ẹ̀yà wa yàtọ̀ síra pátápátá. Ilé ìgbọ̀nsẹ̀ méjì, ilé ìwẹ̀ kan ṣoṣo, ẹ̀rọ ìfọṣọ kan àti ilé ìdáná kan náà ni gbogbo wa ń lo. A kì í rí oúnjẹ tó dọ́ṣọ̀ jẹ, oúnjẹ ọ̀hún kò sì fi bẹ́ẹ̀ tó nǹkan. Iná mànàmáná máa ń ṣe ségesège, ó sì máa ń tó ọjọ́ mélòó kan kí wọ́n tó mú un dé nígbà míì. Ọ̀pọ̀ nínú wa ni àìsàn ibà àtàwọn àìsàn tó wọ́pọ̀ nílẹ̀ olóoru máa ń hàn léèmọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí lè dá wàhálà sílẹ̀, síbẹ̀ a kọ́ bí a ṣe lè máa gbé ní ìrẹ́pọ̀, ká sì máa dárí ji ara wa àti bí a ṣe lè máa para wa lẹ́rìn-ín nígbà tí nǹkan bá le koko pàápàá. A máa ń gbádùn iṣẹ́ ìwàásù gan-an, bí ọmọ ìyá la máa ń ṣe síra wa.”—Robert àti Pauline Landis.
Arábìnrin Pauline Landis ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì
“Àkókò tí a lò ní Sierra Leone wà lára àwọn àkókò tá a gbádùn jù lọ ní ìgbésí ayé wa. A ò kábàámọ̀ kankan, a sì ní ìtẹ́lọ́rùn. Ṣe ló dà bíi pé ká tún pa dà síbẹ̀.”—Benjamin àti Monica Martin.
“Ìgbà kan wà tí a sun ilé obìnrin kan tó nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ Bíbélì, ó sì fún wa ní oúnjẹ kan tó bani lẹ́rù. Obìnrin náà sọ pé, ‘Ejò olóró ni, àmọ́ mo ti yọ gbogbo oró rẹ̀ dà nù. Ṣé ẹ máa jẹ díẹ̀?’ A dọ́gbọ́n sọ fún un pé kó má ṣèyọnu, àmọ́ kò gbà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ohun tójú wa rí máa ń bani lẹ́rú nígbà míì, a mọyì bí wọ́n ṣe máa ń ṣe wá lálejò, a sì wá fẹ́ràn àwọn èèyàn náà gan-an.”—Frederick àti Barbara Morrisey.
“Ní gbogbo ọdún mẹ́tàlélógójì [43] tí mo fi ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì, ó ju ọgọ́rùn-ún [100] míṣọ́nnárì tí mo bá gbélé. Àǹfààní ńlá ni mo ní láti mọ adúrú àwọn èèyàn yẹn! Irú ẹni tí kálukú wọn jẹ́ yàtọ̀ síra, àmọ́ ohun kan náà ni gbogbo wa jọ ń lé. Inú mi dùn gan-an pé mò ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run, mo sì ń rí bí àwọn èèyàn ṣe ń gba ẹ̀kọ́ òtítọ́!”—Lynette Peters.
“Inú mi dùn gan-an pé mò ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run, mo sì ń rí bí àwọn èèyàn ṣe ń gba ẹ̀kọ́ òtítọ́!”
Láti ọdún 1947, míṣọ́nnárì mẹ́rìn-lé-láàádọ́jọ [154] ló ti wá sìn nílẹ̀ Sierra Leone, àwọn méjì-dín-láàádọ́rùn-ún [88] sì ti wá sìn nílẹ̀ Guinea. Ọ̀pọ̀ àwọn ará ló tún ti wá sìn láwọn ibi tí a ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Ní báyìí, míṣọ́nnárì mẹ́rìnlélógójì [44] ló wà ní Sierra Leone, àwọn mọ́kànlélọ́gbọ̀n [31] sì wà ní Guinea. Iṣẹ́ takun-takun tí wọ́n ṣe àti bí wọ́n ṣe fi tọkàntọkàn sin Ọlọ́run ti jẹ́ kí wọ́n lè ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́. Arákùnrin Alfred Gunn, tó ti wà lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka orílẹ̀-èdè náà tipẹ́tipẹ́ sọ pé, “Inú wa máa ń dùn gan-an tá a bá rántí wọn.”