ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ February 17
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—2014 | February
    • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ February 17

      Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ FEBRUARY 17

      Orin 15 àti Àdúrà

      Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:

      cl orí 3 ìpínrọ̀ 1 sí 10 (30 min.)

      Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:

      Bíbélì kíkà: Jẹ́nẹ́sísì 29-31 (10 min.)

      No. 1: Jẹ́nẹ́sísì 29:21-35 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

      No. 2: Ọlọ́run Kò Fọwọ́ Sí Ìgbàgbọ́ Wò-ó-sàn Òde Òní—td 32D (5 min.)

      No. 3: Ìgbọràn Ń Dáàbò Bò Ọ́—lr orí 7 (5 min.)

      Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:

      Orin 92

      10 min: Àwọn Àṣeyọrí Wo La Ṣe? Ìjíròrò. Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ni kó ṣe iṣẹ́ yìí. Jẹ́ kí ìjọ mọ bẹ́ ẹ ṣe kárí ìpínlẹ̀ ìwàásù yín tó nígbà tẹ́ ẹ pín Ìròyìn Ìjọba No. 38. Ní kí àwọn ará sọ àwọn àǹfààní tí wọ́n rí nígbà tí wọ́n ń pín ìwé náà àtàwọn ìrírí tó gbádùn mọ́ni tí wọ́n ní.

      5 min: Ṣé Ò Ń Lo Ìkànnì jw.org Lẹ́nu Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ? Ìjíròrò. Ní kí àwọn ará sọ àwọn ìrírí tó gbádùn mọ́ni tí wọ́n ní nígbà tí wọ́n lo ìkànnì jw.org lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. Fún àwọn ará ní ìṣírí pé kí wọ́n máa sọ fún àwọn èèyàn nípa ìkànnì jw.org ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá rí i pé ó yẹ bẹ́ẹ̀.

      15 min: “Ṣe Ohun Tó Máa Mú Kó O Láyọ̀ Lákòókò Ìrántí Ikú Kristi Tó Ń Bọ̀!” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn tó ní ìṣòro àìlera tàbí tí ọwọ́ wọn dí gan-an àmọ́ tí wọ́n ti ń ṣètò láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lákòókò Ìrántí Ikú Kristi. Ní kí wọ́n sọ àwọn ìyípada tí wọ́n máa ṣe kí wọ́n lè lo àkókò púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Tẹ́ ẹ bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 3, ní kí alábòójútó iṣẹ́ ìsìn sọ ètò tí ìjọ ṣe fún ìpàdé iṣẹ́ ìsìn pápá ní oṣù March, April àti May.

      Orin 8 àti Àdúrà

  • Ṣe Ohun Tó Máa Mú Kó O Láyọ̀ Lákòókò Ìrántí Ikú Kristi Tó Ń Bọ̀
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba—2014 | February
    • Ṣe Ohun Tó Máa Mú Kó O Láyọ̀ Lákòókò Ìrántí Ikú Kristi Tó Ń Bọ̀

      1. Kí la lè ṣe láti fi kún ayọ̀ wa lákòókò Ìrántí Ikú Kristi tó ń bọ̀?

      1 Ṣé wàá fẹ́ túbọ̀ láyọ̀ ní oṣù March, April àti May? Ọ̀nà kan tó o lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kó o ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, o sì lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Báwo lèyí ṣe máa fi kún ayọ̀ rẹ?

      2. Tá a bá ń ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, báwo nìyẹn ṣe máa mú kí ayọ̀ wa pọ̀ sí i?

      2 Mú Kí Ayọ̀ Rẹ Pọ̀ Sí I: Jèhófà dá wa ká lè láyọ̀, kí ọkàn wa sì balẹ̀ bá a ṣe ń sìn ín. (Mát. 5:3) Ọlọ́run tún dá wa ká lè máa láyọ̀ tá a bá ń fún àwọn ẹlòmíì ní nǹkan. (Ìṣe 20:35) Iṣẹ́ ìwàásù máa ń jẹ́ ká lè jọ́sìn Ọlọ́run, ó sì tún ń jẹ́ ká lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Abájọ tí ayọ̀ wa fi máa ń pọ̀ sí i tá a bá ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ohun kan tún ni pé, bá a bá ṣe ń wàásù léraléra tó bẹ́ẹ̀ lá ó máa mọwọ́ ẹ̀ sí i. Èyí á jẹ́ ká túbọ̀ nígboyà, á sì jẹ́ kí ara wa balẹ̀ nígbà tá a bá ń wàásù. Á tún jẹ́ ká láǹfààní púpọ̀ sí i láti wàásù, ká sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn nǹkan yìí máa ń mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ wa túbọ̀ gbádùn mọ́ni.

      3. Kí nìdí tó fi máa dára ká ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù March àti April?

      3 Ó máa dáa gan-an ká ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù March àti April tórí a lè yàn bóyá ọgbọ̀n [30] wákàtí la fẹ́ ní lóṣù yẹn tàbí àádọ́ta [50] wákàtí. Bákan náà, bẹ̀rẹ̀ láti Sátidé, March 22, títí di ọjọ́ tá a máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi ní Monday, April 14, a máa pín ìwé ìkésíni sí Ìrántí Ikú Kristi fún àwọn èèyàn. Inú gbogbo àwọn ará máa dùn bí ọ̀pọ̀ ti ń ṣiṣẹ́ ní “ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́” lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù kí wọ́n lè kárí ìpínlẹ̀ ìwàásù wọn láàárín àkókò tá a yàn.—Sef. 3:9.

      4. Tá a bá fẹ́ ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, kí ló yẹ ká ṣe?

      4 Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Múra Sílẹ̀: Tètè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣètò àkókò rẹ báyìí, bí o kò báà tíì ṣe bẹ́ẹ̀, kó o lè mọ àwọn àyípadà tó yẹ kó o ṣe kó o bàa lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà fún oṣù kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Gbádùrà sí Jèhófà nípa rẹ̀. (Ják. 1:5) Sọ ohun tó o fẹ́ ṣe fún ìdílé rẹ àtàwọn ará ìjọ rẹ. (Òwe 15:22) Bó o bá tilẹ̀ ní àìléra tàbí tí ọwọ́ rẹ bá máa ń dí gan-an, o ṣì lè ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, ó sì máa fún ẹ láyọ̀.

      5. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ tá a bá ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ lákòókò Ìrántí Ikú Kristi tó ń bọ̀?

      5 Jèhófà fẹ́ káwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láyọ̀. (Sm. 32:11) Tá a bá sapá láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ lákòókò Ìrántí Ikú Kristi tó ń bọ̀, ayọ̀ wa máa pọ̀ sí i, a sì tún máa mú inú Baba wa ọ̀run dùn.—Òwe 23:24; 27:11.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́