ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | NEHEMÁYÀ 9-11
Àwọn Ìránṣẹ́ Jèhófà Máa Ń Kọ́wọ́ Ti Gbogbo Ètò Tó Jẹ Mọ́ Ìjọsìn Ọlọ́run
Àwọn èèyàn Ọlọ́run fi tinútinú ṣètìlẹyìn fún ìsìn tòótọ́ ní onírúurú ọ̀nà
Àwọn èèyàn náà múra sílẹ̀ fún Àjọyọ̀ Àtíbàbà bó ṣe yẹ
Ojoojúmọ́ làwọn èèyàn náà ń kóra jọ láti tẹ́tí sí Òfin Ọlọ́run, èyí sì jẹ́ kí wọ́n láyọ̀
Àwọn èèyàn náà jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn, wọ́n gbàdúrà, wọ́n sì bẹ Jèhófà pé kó bù kún àwọn
Àwọn èèyàn náà gbà pé àwọn á máa kọ́wọ́ ti gbogbo ètò tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run
Onírúurú ọ̀nà tí wọ́n gbà ń kọ́wọ́ ti àwọn ètò tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run ni:
Wọ́n ń fẹ́ kìkì àwọn tó jẹ́ olùjọ́sìn Jèhófà
Wọ́n ń fowó ṣètìlẹyìn
Wọ́n ń pa Sábáàtì mọ́
Wọ́n ń kó àwọn igi tí wọ́n á fi mọ pẹpẹ wá
Wọ́n ń fún Jèhófà ní àwọn àkọ́so wọn àti àkọ́bí àwọn nǹkan ọ̀sìn wọn