ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb16 February ojú ìwé 4
  • February 15 Sí 21

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • February 15 Sí 21
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2016)
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni​—Ìwé Ìpàdé (2016)
mwb16 February ojú ìwé 4

February 15 Sí 21

NEHEMÁYÀ 9-11

  • Orin 84 àti Àdúrà

  • Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

  • “Àwọn Ìránṣẹ́ Jèhófà Máa Ń Kọ́wọ́ Ti Gbogbo Ètò Tó Jẹ Mọ́ Ìjọsìn Ọlọ́run”: (10 min.)

    • Ne 10:28-30​—Wọ́n fẹnu kò pé àwọn kò ní wọnú àdéhùn ìgbéyàwó pẹ̀lú “àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà” mọ́ (w98 10/15 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 11)

    • Ne 10:32-39​—Wọ́n pinnu pé àwọn á ṣètìlẹyìn fún ìsìn tòótọ́ ní onírúurú ọ̀nà (w98 10/15 ojú ìwé 21 ìpínrọ̀ 11 àti 12)

    • Ne 11:1, 2​—Wọ́n fi tinútinú ṣètìlẹyìn fún àkànṣe ètò tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run (w06 2/1 ojú ìwé 11 ìpínrọ̀ 6; w98 10/15 ojú ìwé 22 ìpínrọ̀ 13)

  • Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)

    • Ne 9:19-21​—Báwo ni Jèhófà ṣe jẹ́ kó dá wa lójú pé òun á pèsè ohun táwọn èèyàn rẹ̀ nílò? (w13 9/15 ojú ìwé 9 ìpínrọ̀ 9 àti 10)

    • Ne 9:6-38​—Àpẹẹrẹ rere wo làwọn ọmọ Léfì fi lélẹ̀ fún wa nípa bó ṣe yẹ ká máa gbàdúrà? (w13 10/15 ojú ìwé 22 sí 23 ìpínrọ̀ 6 àti 7)

    • Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?

    • Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí?

  • Bíbélì Kíkà: Ne 11:15-36 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

  • Nígbà Àkọ́kọ́: (2 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Fi àpilẹ̀kọ náà, “Bí Ẹ Ṣe Lè Mú Kí Àlàáfíà Wà Nínú Ilé” tó wà nínú ìwé ìròyìn Jí! ti lọ́ọ́lọ́ọ́ ṣe àṣefihàn kan. Sọ ohun tí wàá bá ẹni náà jíròrò nígbà tó o bá pa dà wá.

  • Ìpadàbẹ̀wò: (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ṣe àṣefihàn bí a ṣe lè ṣe ìpadàbẹ̀wò ẹni tó nífẹ̀ẹ́ sí àpilẹ̀kọ náà, “Bí Ẹ Ṣe Lè Mú Kí Àlàáfíà Wà Nínú Ilé” tó wà nínú ìwé ìròyìn Jí! ti lọ́ọ́lọ́ọ́ tí wọ́n fi lọ̀ ọ́. Sọ ohun tí wàá bá ẹni náà jíròrò nígbà tó o bá tún pa dà wá.

  • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: (6 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀) Ṣe àṣefihàn bí a ṣe máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (bh ojú ìwé32 sí 33 ìpínrọ̀ 13 àti 14)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

  • Orin 19

  • “Ìgbésí Ayé Tó Dára Jù Lọ”: (15 min.) Ìjíròrò. Kọ́kọ́ jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò yìí. Lẹ́yìn náà, jíròrò àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí. Ní ṣókí, fi ọ̀rọ̀ wá akéde kan lẹ́nu wò. Ó lè jẹ́ ẹni tó ti ṣègbéyàwó tàbí ẹni tí kò tíì ṣègbéyàwó. Akéde náà ti lo àǹfààní ọ̀pọ̀ ọdún tó fi wà láì lọ́kọ tàbí láì láya láti ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. (1Kọ 7:35) Àwọn ìbùkún wo ló ti rí gbà?

  • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: ia orí 9 ìpínrọ̀ 1 sí 13 (30 min.)

  • Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)

  • Orin 76 àti Àdúrà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́