Orin 19
Ọlọ́run Ṣèlérí Párádísè
Bíi Ti Orí Ìwé
1. Párádísè, ni Jáà ṣèlérí,
Nípasẹ̀ Ìjọba Kristi,
Tí yóò fi pa gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ́,
Àtomijé, pẹ̀lú ikú.
(ÈGBÈ)
Párádísè layé yóò dà.
Ojú ’gbàgbọ́ la fi ń ríi.
Kristi yóò mú ’lérí yìí ṣẹ,
Torí ’nú rẹ̀ dùn sífẹ̀ẹ́ Jáà.
2. Ọlọ́run ti pinnu pé láìpẹ́,
Kọ́mọ òun jí òkú dìde.
Jésù ṣèlérí pé: ‘Ìwọ yóò
Pẹ̀lú mi ní Párádísè.’
(ÈGBÈ)
Párádísè layé yóò dà.
Ojú ’gbàgbọ́ la fi ń ríi.
Kristi yóò mú ’lérí yìí ṣẹ,
Torí ’nú rẹ̀ dùn sífẹ̀ẹ́ Jáà.
3. Párádísè, ni Kristi ńmú bọ̀.
Ọba tó yẹ ayé nìyí.
Ojoojúmọ́ la ńyin Baba wa,
Látọkànwá, a ńkọrin yìnín.
(ÈGBÈ)
Párádísè layé yóò dà.
Ojú ’gbàgbọ́ la fi ń ríi.
Kristi yóò mú ’lérí yìí ṣẹ,
Torí ’nú rẹ̀ dùn sífẹ̀ẹ́ Jáà.
(Tún wo Mát. 5:5; 6:10; Jòh. 5:28, 29.)