ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 10/15 ojú ìwé 19-24
  • Jerúsálẹ́mù Kan Tí Orúkọ Rò

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jerúsálẹ́mù Kan Tí Orúkọ Rò
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọjọ́ Àpéjọ Kíkọyọyọ
  • Àpéjọ Mìíràn Tí Ó Tún Jẹ́ Onídùnnú
  • Kò Yẹ Kí A Ṣàìnáání Ilé Ọlọ́run
  • Ayẹyẹ Onídùnnú Ti Ṣíṣí Odi
  • Ohun Tí Ó Lè Mú Ìdùnnú Àìnípẹ̀kun Wá
  • Jerúsálẹ́mù—Ó Ha ‘Ré Kọjá Olórí Ìdí Tí O Ní fún Ayọ̀ Yíyọ̀ Bí’?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Nehemáyà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ògiri Jerúsálẹ́mù
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Odi Jerúsálẹ́mù
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 10/15 ojú ìwé 19-24

Jerúsálẹ́mù Kan Tí Orúkọ Rò

“Ẹ . . . kún fún ìdùnnú títí láé nínú ohun tí èmi yóò dá. Nítorí pé kíyè sí i, èmi yóò dá Jerúsálẹ́mù ní ohun tí ń fa ìdùnnú.”—AÍSÁYÀ 65:18.

1. Kí ni ìmọ̀lára Ẹ́sírà nípa ìlú tí Ọlọ́run yàn?

GẸ́GẸ́ bí onílàákàyè akẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, àlùfáà Júù náà, Ẹ́sírà, mọyì ìbátan tí Jerúsálẹ́mù ní pẹ̀lú ìjọsìn mímọ́ gaara ti Jèhófà nígbà kan rí. (Diutarónómì 12:5; Ẹ́sírà 7:27) Ìfẹ́ rẹ̀ fún ìlú Ọlọ́run hàn nínú apá tí a mí sí i láti kọ nínú Bíbélì—Kíróníkà Kìíní àti Ìkejì pẹ̀lú ìwé Ẹ́sírà. Nínú àwọn ìwé ìtàn yìí, orúkọ náà, Jerúsálẹ́mù, fẹ́rẹ̀ẹ́ fara hàn tó ìdámẹ́rin nínú ìgbà 800 tí ó fi fara hàn nínú Bíbélì lódindi.

2. Nígbà mìíràn, báwo ni Ẹ́sírà ṣe kọ orúkọ náà Jerúsálẹ́mù, kí sì ni ìjẹ́pàtàkì èyí?

2 Nínú èdè Hébérù tí a fi kọ Bíbélì, “Jerúsálẹ́mù” lè túmọ̀ sí oríṣi ọ̀rọ̀ èdè Hébérù kan tí a ń pè ní ọ̀rọ̀ oníbejì. A sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ oníbejì yìí fún àwọn nǹkan tí ó jẹ́ méjì-méjì, bí ojú, etí, ọwọ́, àti ẹsẹ̀. Bí a bá fojú ọ̀rọ̀ oníbejì yìí wò ó, a lè ka orúkọ náà Jerúsálẹ́mù sí àsọtẹ́lẹ̀ àlàáfíà alápá méjì tí àwọn ènìyàn Ọlọ́run yóò ní—nípa tẹ̀mí àti nípa ti ara. Ìwé Mímọ́ kò sọ bóyá Ẹ́sírà lóye èyí lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí àlùfáà, ó sa gbogbo ipá rẹ̀ láti ran àwọn Júù lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run. Dájúdájú, ó ṣiṣẹ́ kára kí orúkọ Jerúsálẹ́mù lè rò ó, ìtumọ̀ orúkọ náà sì ni, “Níní [tàbí Ìpìlẹ̀] Àlàáfíà Alápá Méjì.”—Ẹ́sírà 7:6.

3. Ọdún mélòó ni ó kọjá kí ó tó di pé a tún jẹ́ kí a mọ̀ nípa ìgbòkègbodò Ẹ́sírà, ipò wo sì ni ó wà?

3 Bíbélì kò sọ ibi tí Ẹ́sírà wà ní ọdún 12 tí ó wà láàárín ìgbà tí ó ṣe ìbẹ̀wò sí Jerúsálẹ́mù àti ìgbà tí Nehemáyà dé sí ìlú náà. Ipò tẹ̀mí tí ó ṣeni láàánú tí orílẹ̀-èdè náà wà nígbà yẹn fi hàn pé Ẹ́sírà kò sí níbẹ̀. Síbẹ̀, a rí i pé Ẹ́sírà tún sìn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà olóòótọ́ ní Jerúsálẹ́mù kété lẹ́yìn tí a ti tún odi ìlú náà mọ tán.

Ọjọ́ Àpéjọ Kíkọyọyọ

4. Kí ni ìjẹ́pàtàkì ọjọ́ kìíní oṣù keje nínú oṣù àwọn ọmọ Ísírẹ́lì?

4 Mímọ odi Jerúsálẹ́mù parí gẹ́lẹ́ nígbà tí àkókò àjọyọ̀ oṣù Tíṣírì, oṣù keje lórí kàlẹ́ńdà ìsìn ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé. Ọjọ́ àkọ́kọ́ nínú oṣù Tíṣírì jẹ́ ọjọ́ àkànṣe àsè oṣù tuntun tí a ń pè ní Àjọyọ̀ Fífun Kàkàkí. Lọ́jọ́ náà, àwọn àlùfáà yóò fun kàkàkí nígbà tí wọ́n bá ń rúbọ sí Jèhófà. (Númérì 10:10; 29:1) Ọjọ́ yìí ń mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì múra sílẹ̀ fún Ọjọ́ Ètùtù ọdọọdún tó máa ń wáyé ní ọjọ́ kẹwàá oṣù Tíṣírì àti Àjọyọ̀ Ìkórèwọlé tí ó ń kún fún ìdùnnú, tó sì máa ń wáyé ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún sí ọjọ́ kọkànlélógún oṣù kan náà.

5. (a) Báwo ni Ẹ́sírà àti Nehemáyà ṣe lo “ọjọ́ kìíní oṣù keje” lọ́nà rere? (b) Èé ṣe tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi sunkún?

5 “Ní ọjọ́ kìíní oṣù keje,” “gbogbo ènìyàn” pé jọ, ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ Nehemáyà àti Ẹ́sírà ni ó fún wọ́n níṣìírí láti ṣe bẹ́ẹ̀. Tọkùnrin, tobìnrin, àti “gbogbo àwọn tí ó ní làákàyè tó láti fetí sílẹ̀” ni wọ́n wà níbẹ̀. Nípa báyìí, àwọn ọmọ kéékèèké wá, wọ́n sì tẹ́tí sílẹ̀ nígbà tí Ẹ́sírà dúró lórí ibi ìdúró-sọ̀rọ̀, tí ó sì ka Òfin náà “láti àfẹ̀mọ́jú títí di ọjọ́kanrí.” (Nehemáyà 8:1-4) Ní ìdágbá kọ̀ọ̀kan, àwọn ọmọ Léfì yóò ran àwọn ènìyàn náà lọ́wọ́ láti lóye ohun tí a kà jáde. Èyí mú kí omi bọ́ lójú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí wọ́n gbọ́ bí àwọn àti àwọn baba ńlá wọn ti kùnà tó nínú ṣíṣe ìgbọràn sí Òfin Ọlọ́run—Nehemáyà 8:5-9.

6, 7. Kí ni àwọn Kristẹni lè kọ́ nínú ohun tí Nehemáyà ṣe láti mú kí àwọn Júù dákẹ́ ẹkún sísun?

6 Ṣùgbọ́n àkókò yìí kì í ṣe àkókò ẹkún ìbànújẹ́. Àjọyọ̀ ni wọ́n ń ṣe, àwọn ènìyàn náà sì ṣẹ̀ṣẹ̀ parí mímọ odi Jerúsálẹ́mù ni. Nítorí náà, Nehemáyà ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣara gírí nípa sísọ pe: “Ẹ lọ, ẹ jẹ àwọn ohun ọlọ́ràá, kí ẹ sì mu àwọn ohun dídùn, kí ẹ sì fi ìpín ránṣẹ́ sí ẹni tí a kò pèsè nǹkan kan sílẹ̀ fún; nítorí ọjọ́ yìí jẹ́ mímọ́ lójú Olúwa wa, ẹ má sì ba inú jẹ́, nítorí ìdùnnú Jèhófà ni odi agbára yín.” Tìgbọràntìgbọràn, “gbogbo àwọn ènìyàn náà lọ láti jẹ, àti láti mu, àti láti fi ìpín ránṣẹ́, wọ́n sì ń bá a lọ nínú ayọ̀ yíyọ̀ ńláǹlà, nítorí wọ́n lóye ọ̀rọ̀ tí a ti sọ di mímọ̀ fún wọn.”—Nehemáyà 8:10-12.

7 Àwọn ènìyàn Ọlọ́run lónìí lè rí ẹ̀kọ́ púpọ̀ kọ́ nínú ìtàn yìí. Ó yẹ kí àwọn tí wọ́n ń láǹfààní láti kó ipa nínú àwọn ìpàdé àti àpéjọ fi ìtàn tí a sọ tàn yìí sọ́kàn. Yàtọ̀ sí fífúnni ní àwọn ìmọ̀ràn tí a pète láti múni ṣàtúnṣe, èyí tí ó sàbá máa ń pọndandan, a tún ń lo irú àkókò bẹ́ẹ̀ láti tẹnu mọ́ àwọn àǹfààní àti ìbùkún tí ń wá láti inú kíkúnjú ìwọ̀n àwọn ohun tí Ọlọ́run ń béèrè. A máa ń gbóríyìn fúnni fún àwọn iṣẹ́ rere tí a ti ṣe, a sì ń fúnni níṣìírí láti ní ìfaradà. Ṣe ni ó yẹ kí àwọn ènìyàn Ọlọ́run fi tayọ̀tayọ̀ kúrò ní irú àpéjọ bẹ́ẹ̀, nítorí ìtọ́ni tí ń gbéni ró tí wọ́n ti rí gbà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.—Hébérù 10:24, 25.

Àpéjọ Mìíràn Tí Ó Tún Jẹ́ Onídùnnú

8, 9. Ìpàdé àkànṣe wo ni ó wáyé ní ọjọ́ kejì oṣù keje, kí sì ni ó yọrí sí fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run?

8 Ní ọjọ́ kejì oṣù àrà ọ̀tọ̀ yẹn, “àwọn olórí àwọn baba gbogbo àwọn ènìyàn náà, àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì, kó ara wọn jọ sọ́dọ̀ Ẹ́sírà adàwékọ, àní láti ní ìjìnlẹ̀ òye nínú ọ̀rọ̀ òfin náà.” (Nehemáyà 8:13) Ẹ́sírà dáńgájíá dáadáa láti darí ìpàdé yìí, níwọ̀n bí ó “ti múra ọkàn-àyà rẹ̀ sílẹ̀ láti ṣe ìwádìí nínú òfin Jèhófà àti láti pa á mọ́ àti láti máa kọ́ni ní ìlànà àti ìdájọ́ òdodo ní Ísírẹ́lì.” (Ẹ́sírà 7:10) Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, ìpàdé yìí darí àfiyèsí sí àwọn ibi tí ó kù kí àwọn ènìyàn Ọlọ́run máa tẹ̀ lé májẹ̀mú Òfin náà délẹ̀délẹ̀. Èyí tí ó jẹ́ olórí àníyàn wọn nígbà náà ni ṣíṣe ìmúrasílẹ̀ tí ó yẹ láti lè ṣayẹyẹ Àjọyọ̀ Àwọn Àtíbàbà tí ń bọ̀.

9 Wọ́n ṣe àjọyọ̀ ọlọ́sẹ̀ kan yìí lọ́nà tí ó tọ́, tí gbogbo àwọn ènìyàn náà gbé nínú ilé onígbà díẹ̀ tí wọ́n fi ẹ̀ka àti ewé onírúurú igi kọ́. Àwọn ènìyàn kọ́ àtíbàbà wọ̀nyí sórí àjà pẹrẹsẹ ilé wọn, wọ́n kọ́ ọ sí àgbàlá wọn, wọn kọ́ ọ sí àgbàlá tẹ́ńpìlì, wọ́n tún kọ́ ọ sí àwọn ojúde ìlú, ní Jerúsálẹ́mù. (Nehemáyà 8:15, 16) Ẹ wo irú àǹfààní ńláǹlà tí èyí jẹ́ láti kó àwọn ènìyàn náà jọ, kí a sì ka Òfin Ọlọ́run sí wọn létí! (Fi wé Diutarónómì 31:10-13.) Wọ́n ṣe èyí lójoojúmọ́, “láti ọjọ́ kìíní títí di ọjọ́ tí ó kẹ́yìn” àjọyọ̀ náà, ó sì yọrí sí “ayọ̀ yíyọ̀ ńláǹlà” fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run.—Nehemáyà 8:17, 18.

Kò Yẹ Kí A Ṣàìnáání Ilé Ọlọ́run

10. Èé ṣe tí a fi ṣètò àpéjọ àkànṣe kan lọ́jọ́ kẹrìnlélógún oṣù keje?

10 Ó lákòókò tí ó yẹ láti pe àfiyèsí àwọn ènìyàn Ọlọ́run sí ṣíṣàtúnṣe àwọn àbùkù tí ó léwu, ó sì ní ibi tí ó bójú mu tí a ti lè ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí tí Ẹ́sírà àti Nehemáyà mọ̀ dájú ṣáká pé àkókò tí ó yẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀ nìyí, wọ́n ṣètò ọjọ́ ààwẹ̀ sí ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù Tíṣírì. Wọ́n tún ka Òfin Ọlọ́run, àwọn ènìyàn náà sì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Lẹ́yìn náà, àwọn ọmọ Léfì ṣàtúnyẹ̀wò bí Ọlọ́run ṣe fi àánú bá àwọn ènìyàn rẹ̀ oníwà wíwọ́ lò, wọ́n fi ọ̀rọ̀ amóríwú yin Jèhófà, wọ́n sì ṣe “ètò tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé,” èyí tí àwọn ọmọ aládé wọn, àwọn ọmọ Léfì, àti àwọn àlùfáà fi èdìdì jẹ́rìí sí.—Nehemáyà 9:1-38.

11. “Ètò tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé” wo ni àwọn Júù fi de ara wọn?

11 Àwọn ènìyàn náà lápapọ̀ búra láti tẹ̀ lé ohun tí a kọ sílẹ̀ nínú “ètò tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé” náà. Wọn yóò “rìn nínú òfin Ọlọ́run tòótọ́.” Wọ́n sì fẹnu kò pé àwọn kò tún ní wọnú àdéhùn ìgbéyàwó pẹ̀lú “àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà” mọ́. (Nehemáyà 10:28-30) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, àwọn Júù fòfin de ara wọn láti máa kíyè sí Sábáàtì, láti máa fi owó ṣètọrẹ lọ́dọọdún láti ṣètìlẹ́yìn fún ìjọsìn tòótọ́, láti wá igi fún pẹpẹ ìrúbọ, láti fi àkọ́bí ọ̀wọ́ ẹran wọn àti àwọn agbo ẹran wọn sílẹ̀ fún ìrúbọ, àti láti mú àkọ́so ilẹ̀ wọn wá sí àwọn gbọ̀ngàn ìjẹun ti tẹ́ńpìlì. Ó ṣe kedere pé, wọ́n pinnu ‘láti má ṣàìnáání ilé Ọlọ́run wọn.’—Nehemáyà 10:32-39.

12. Kí ni nínáání ilé Ọlọ́run ní nínú lónìí?

12 Lónìí, àwọn ènìyàn Jèhófà gbọ́dọ̀ ṣọ́ra láti má ṣàìnáání àǹfààní wọn ti ‘ṣíṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀’ nínú àgbàlá tẹ́ńpìlì ńlá ti Jèhófà nípa tẹ̀mí. (Ìṣípayá 7:15) Èyí ní àdúrà àtọkànwá nínú, tí a ń gbà déédéé fún ìtẹ̀síwájú ìjọsìn Jèhófà. Gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú irú àwọn àdúrà bẹ́ẹ̀ ń béèrè fún mímúra àwọn ìpàdé Kristẹni sílẹ̀ àti lílọ́wọ́ nínú wọn, kíkópa nínú ètò wíwàásù ìhìn rere náà, àti ríran àwọn olùfìfẹ́hàn lọ́wọ́ nípa pípadà bẹ̀ wọ́n wò, bí ó bá sì ṣeé ṣe, kí a darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn. Ọ̀pọ̀ àwọn tí kò fẹ́ ṣàìnáání ilé Ọlọ́run fi owó ṣètọrẹ fún iṣẹ́ ìwàásù náà àti títọ́jú àwọn ibi ìjọsìn tòótọ́. Àwa pẹ̀lú lè ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ibi ìpàdé tí a nílò ní kíákíá, tí a ń kọ́ lọ́wọ́lọ́wọ́, kí a mú kí wọ́n wà ní mímọ́ tónítóní, kí wọ́n sì ṣeé wò. Ọ̀nà pàtàkì kan láti fi ìfẹ́ hàn fún ilé Ọlọ́run nípa tẹ̀mí ni láti gbé àlàáfíà lárugẹ láàárín àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa, kí a sì ran àwọn tí wọ́n nílò ìrànwọ́ nípa ti ara tàbí tẹ̀mí lọ́wọ́.—Mátíù 24:14; 28:19, 20; Hébérù 13:15, 16.

Ayẹyẹ Onídùnnú Ti Ṣíṣí Odi

13. Ọ̀ràn pàjáwìrì wo ni ó nílò àfiyèsí kí a tó lè ṣayẹyẹ ṣíṣí odi Jerúsálẹ́mù, àpẹẹrẹ rere wo sì ni èyí fi lélẹ̀?

13 “Ètò tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé” tí a fi èdìdì jẹ́rìí sí ní ọjọ́ Nehemáyà múra àwọn ènìyàn Ọlọ́run ní ìgbàanì sílẹ̀ fún ọjọ́ ayẹyẹ ṣíṣí odi Jerúsálẹ́mù. Ṣùgbọ́n ọ̀ràn pàjáwìrì mìíràn ṣì wà tí ó ń fẹ́ àfiyèsí. Jerúsálẹ́mù tí a ti wá fi ẹnubodè 12 ká mọ́ nísinsìnyí nílò àwọn olùgbé tí ó pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan ń gbé níbẹ̀, “ìlú ńlá náà gbòòrò, ó sì tóbi, àwọn ènìyàn díẹ̀ ni ó wà nínú rẹ̀.” (Nehemáyà 7:4) Láti yanjú ìṣòro yìí, àwọn ènìyàn “ṣẹ́ kèké láti mú ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú mẹ́wàá-mẹ́wàá wá láti máa gbé ní Jerúsálẹ́mù ìlú ńlá mímọ́.” Ẹ̀mí ìmúratán tí àwọn kan fi hàn sí ìṣètò yìí sún àwọn ènìyàn náà láti súre fún “gbogbo ọkùnrin tí wọ́n fínnú-fíndọ̀ yọ̀ǹda ara wọn láti máa gbé ní Jerúsálẹ́mù.” (Nehemáyà 11:1, 2) Ẹ wo irú àpẹẹrẹ rere tí èyí jẹ́ fún àwọn olùjọsìn tòótọ́ lónìí, àwọn tí àyíká ipò wọn yọ̀ǹda fún wọn láti ṣí lọ sí ibi tí àìní fún ìrànlọ́wọ́ àwọn Kristẹni tí wọ́n dàgbà dénú gbé pọ̀!

14. Kí ní ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ ayẹyẹ ìyàsímímọ́ odi Jerúsálẹ́mù?

14 Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn ìyẹn ni ìmúrasílẹ̀ pàtàkì bẹ̀rẹ̀ fún ọjọ́ ńlá ti ayẹyẹ ṣíṣí odi Jerúsálẹ́mù. A kó àwọn olórin àti àwọn akọrin jọ láti àwọn ìlú ńláńlá tí ó yí Júdà ká. A pín wọn sí ẹgbẹ́ akọrin méjì tí ń kọrin ìdúpẹ́, ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń tọ́wọ̀ọ́rìn yóò sì tẹ̀ lé ẹgbẹ́ kọ̀ọ̀kan. (Nehemáyà 12:27-31, 36, 38) Àwọn ẹgbẹ́ akọrin náà pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ń tọ́wọ̀ọ́rìn náà gbéra láti igun odi ìlú náà tí ó jìnnà jù lọ sí tẹ́ńpìlì, tí ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ Ẹnubodè Àfonífojì, wọ́n sì gba ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ títí tí wọ́n fi wá pàdé ní ilé Ọlọ́run. “Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí rú àwọn ẹbọ ńláǹlà ní ọjọ́ yẹn, wọ́n sì ń yọ̀, nítorí Ọlọ́run tòótọ́ ti mú kí wọ́n máa yọ̀ pẹ̀lú ìdùnnú ńláǹlà. Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé pàápàá sì yọ̀, tí ó fi jẹ́ pé a gbọ́ ayọ̀ yíyọ̀ Jerúsálẹ́mù ní ibi jíjìnnà réré.”—Nehemáyà 12:43.

15. Èé ṣe tí ayẹyẹ ṣíṣí odi Jerúsálẹ́mù kò fi ní lè mú ìdùnnú pípẹ́ títí wá?

15 Bíbélì kò sọ ọjọ́ náà gan-an tí ayẹyẹ onídùnnú yìí wáyé. Láìsí àní-àní, ó jẹ́ apá pàtàkì ìmúpadàbọ̀sípò Jerúsálẹ́mù, bí kò bá jẹ́ òtéńté rẹ̀ pàápàá. Àmọ́ ṣá o, ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìkọ́lé ṣì wà láti ṣe nínú ìlú náà. Kò pẹ́ kò jìnnà, àwọn ọmọ Jerúsálẹ́mù pàdánù ìdúró rere wọn nípa tẹ̀mí. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí Nehemáyà bẹ ìlú náà wò lẹ́ẹ̀kejì, ó rí i pé a kò tún náání ilé Ọlọ́run mọ́ àti pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún ti bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́ àwọn obìnrin abọ̀rìṣà. (Nehemáyà 13:6-11, 15, 23) Àkọsílẹ̀ wòlíì Málákì jẹ́rìí sí àwọn ipò búburú kan náà yìí. (Málákì 1:6-8; 2:11; 3:8) Nítorí náà, ayẹyẹ ṣíṣí odi Jerúsálẹ́mù kò mú ìdùnnú pípẹ́ títí wá.

Ohun Tí Ó Lè Mú Ìdùnnú Àìnípẹ̀kun Wá

16. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí yóò jẹ́ òtéńté ìyípadà pàtàkì wo ni àwọn ènìyàn Ọlọ́run ń wọ̀nà fún?

16 Lónìí, àwọn ènìyàn Jèhófà ń wọ̀nà fún àkókò náà nígbà tí Ọlọ́run yóò ṣẹ́gun gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀. Èyí yóò bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìparun “Bábílónì Ńlá”—ìlú ìṣàpẹẹrẹ kan tí ó ní gbogbo onírúurú ìsìn èké nínú. (Ìṣípayá 18:2, 8) Ìparun ìsìn èké ni yóò jẹ́ apá àkọ́kọ́ nínú ìpọ́njú ńlá náà tí ń bọ̀. (Mátíù 24:21, 22) Pẹ̀lúpẹ̀lù, ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kan ṣì tún wà níwájú wa—ìgbéyàwó tí yóò wáyé ní ọ̀run láàárín Jésù Kristi Olúwa àti aya rẹ̀, 144,000 àwọn ọmọ ìlú “Jerúsálẹ́mù Tuntun.” (Ìṣípayá 19:7; 21:2) A kò lè sọ ní pàtó ìgbà tí a óò parí ìsopọ̀ náà tí yóò jẹ́ òtéńté ìyípadà pàtàkì, ṣùgbọ́n ó dájú pé yóò jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ onídùnnú.—Wo Ilé Ìṣọ́nà, August 15, 1990, ojú ìwé 30 sí 31.

17. Kí ni a mọ̀ nípa píparí kíkọ́ Jerúsálẹ́mù Tuntun?

17 A mọ̀ dájú pé píparí kíkọ́ Jerúsálẹ́mù Tuntun ti sún mọ́lé. (Mátíù 24:3, 7-14; Ìṣípayá 12:12) Kò ní jáni kulẹ̀ láé, nítorí kò dà bí Jerúsálẹ́mù orí ilẹ̀ ayé. Ìdí rẹ̀ ni pé gbogbo àwọn aráàlú ọ̀hún jẹ́ ẹni àmì òróró, ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi, tí a ti dán wò, tí a sì ti yọ́ mọ́. Nítorí ìṣòtítọ́ wọn títí dójú ikú, ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ti ní láti jẹ́ adúróṣinṣin títí láé sí Ọba Aláṣẹ Àgbáyé, Jèhófà Ọlọ́run. Ìtumọ̀ pàtàkì ni èyí ní fún ìyókù aráyé—àwọn tí ó wà láàyè àti àwọn tí ó ti kú!

18. Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a ‘yọ ayọ̀ ńlá, kí a sì kún fún ìdùnnú títí láé’?

18 Ronú nípa ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jerúsálẹ́mù Tuntun bá yí àfiyèsí rẹ̀ sí àwọn ẹ̀dá ènìyàn tí wọ́n ń lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù. Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Wò ó! Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé, yóò sì máa bá wọn gbé, wọn yóò sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú wọn. Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.” (Ìṣípayá 21:2-4) Síwájú sí i, Ọlọ́run yóò lo ìṣètò ìlú yìí láti gbé aráyé dé ìjẹ́pípé ẹ̀dá ènìyàn. (Ìṣípayá 22:1, 2) Ẹ wo bí ìwọ̀nyí ti jẹ́ ìdí àgbàyanu tó fún wa láti ‘yọ ayọ̀ ńláǹlà, kí a sì kún fún ìdùnnú títí láé nínú ohun tí Ọlọ́run ń dá nísinsìnyí’!—Aísáyà 65:18.

19. Kí ni párádísè tẹ̀mí tí a kó àwọn Kristẹni jọ sí?

19 Ṣùgbọ́n, àwọn ẹ̀dá ènìyàn tí wọ́n ti ronú pìwà dà kò ní láti dúró títí di ìgbà yẹn kí wọ́n tó gba ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ní ọdún 1919, Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí kó àwọn mẹ́ńbà tí ó kù lára 144,000 jọ sínú párádísè tẹ̀mí, níbi tí àwọn èso ti ẹ̀mí Ọlọ́run—bí ìfẹ́, ìdùnnú, àti àlàáfíà—ti gbilẹ̀. (Gálátíà 5:22, 23) Apá fífanimọ́ra jù lọ nínú párádísè tẹ̀mí yìí ni ìgbàgbọ́ àwọn ẹni àmì òróró tí ó wà níbẹ̀, àwọn tí wọ́n ti ń méso jáde lọ́nà àgbàyanu nínú mímú ipò iwájú nínú wíwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé. (Mátíù 21:43; 24:14) Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, nǹkan bí mílíọ̀nù mẹ́fà “àwọn àgùntàn mìíràn,” tí wọ́n ní ìrètí ti ilẹ̀ ayé, ni a tún ti yọ̀ǹda fún láti wọnú párádísè tẹ̀mí náà, kí wọ́n sì gbádùn ṣíṣe iṣẹ́ tí ń méso jáde. (Jòhánù 10:16) Wọ́n ti tóótun fún èyí nípa yíya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run lórí ìpìlẹ̀ ìgbàgbọ́ wọn nínú ẹbọ ìràpadà Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi. Bíbá tí wọ́n ń bá àwọn tí yóò di mẹ́ńbà Jerúsálẹ́mù Tuntun kẹ́gbẹ́ ti jẹ́ ìbùkún. Nípa báyìí, nípasẹ̀ ìbálò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, Jèhófà ti fi ìpìlẹ̀ tí ó lágbára lélẹ̀ fún “ilẹ̀ ayé tuntun”—àwùjọ àwọn ènìyàn tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run, àwọn tí yóò jogún ilẹ̀ ayé tí Ìjọba ti ọ̀run yóò ṣàkóso lé lórí.—Aísáyà 65:17; 2 Pétérù 3:13.

20. Báwo ni orúkọ yóò ṣe ro Jerúsálẹ́mù Tuntun?

20 Àlàáfíà tí àwọn ènìyàn Jèhófà ń gbádùn nísinsìnyí nínú párádísè tẹ̀mí yóò kárí ayé láìpẹ́ nínú párádísè tí a lè fojú rí lórí ilẹ̀ ayé. Ìyẹn yóò ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jerúsálẹ́mù Tuntun bá sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run láti bù kún aráyé. Lọ́nà méjì, àwọn ènìyàn Ọlọ́run yóò gbádùn àlàáfíà tí a ṣèlérí nínú Aísáyà 65:21-25. Gẹ́gẹ́ bí àwọn olùjọsìn Jèhófà tí wọ́n ṣọ̀kan nínú párádísè tẹ̀mí, àwọn ẹni àmì òróró tí kò tí ì dé ipò wọn nínú Jerúsálẹ́mù Tuntun ti ọ̀run àti àwọn tí wọ́n jẹ́ “àgùntàn mìíràn” ń gbádùn àlàáfíà Ọlọ́run nísinsìnyí. Irú àlàáfíà bẹ́ẹ̀ yóò sì nasẹ̀ dé Párádísè tí a lè fojú rí náà, nígbà tí ‘ìfẹ́ Ọlọ́run bá ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run.’ (Mátíù 6:10) Bẹ́ẹ̀ ni, ìlú ńlá ológo ti Ọlọ́run ni ọ̀run, ni orúkọ náà, Jerúsálẹ́mù yóò rò, ní ti pé ó jẹ́ ‘Ìpìlẹ̀ Àlàáfíà Alápá Méjì’ tí ó dúró gbọn-in. Títí ayérayé, yóò máa jẹ́ ohun ìyìn fún Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá rẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run, àti fún Jésù Kristi, Ọba rẹ̀, tí ó jẹ́ Ọkọ Ìyàwó.

Ìwọ Ha Rántí Bí?

◻ Kí ni Nehemáyà ṣàṣeparí rẹ̀ nígbà tí ó pe àwọn ènìyàn jọ sí Jerúsálẹ́mù?

◻ Kí ni àwọn Júù ìgbàanì gbọ́dọ̀ ṣe kí wọ́n má bàa ṣàìnáání ilé Ọlọ́run, kí sì ni a rọ̀ wá láti ṣe?

◻ Báwo ni ọ̀ràn ṣe kan “Jerúsálẹ́mù” nínú mímú ìdùnnú àti àlàáfíà pípẹ́ títí wá?

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 23]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

ÀWỌN ẸNUBODÈ JERÚSÁLẸ́MÙ

Nọ́ńbà ń fi bí ibẹ̀ ṣe ga tó lónìí hàn ní ìṣirò mítà

ẸNUBODÈ ẸJA

ẸNUBODÈ ÌLÚ ŃLÁ ÀTIJỌ́

ẸNUBODÈ ÉFÚRÁÍMÙ

ẸNUBODÈ IGUN

Ògiri Fífẹ̀

Ojúde Ìlú

ẸNUBODÈ ÀFONÍFOJÌ

ÌHÀ KEJÌ

Ògiri Àríwá ní Ìjímìjí

ÌLÚ ŃLÁ DÁFÍDÌ

ẸNUBODÈ ÀWỌN ÒKÌTÌ EÉRÚ

Àfonífojì ti Hínómù

Ilé Aláruru

ẸNUBODÈ ÀGÙNTÀN

ẸNUBODÈ Ẹ̀ṢỌ́

Àgbègbè Tẹ́ńpìlì

ẸNUBODÈ ÀBẸ̀WÒ

ẸNUBODÈ ẸṢIN

ÓFÉLÌ

Ojúde Ìlú

ẸNUBODÈ OMI

Ìsun Gíhónì

ÌLÚ ŃLÁ DÁFÍDÌ

Ọgbà Ọba

Éń-rógélì

Àfonífojì Tírópóónì (ti Àárín Gbùngbùn)

Àfonífojì Olójú Ọ̀gbàrá ti Kídírónì

740

730

730

750

770

770

750

730

710

690

670

620

640

660

680

700

720

740

730

710

690

670

Ibi tó ṣeé ṣe kí odi Jerúsálẹ́mù dé nígbà tí a pa ìlú náà run àti nígbà tí Nehemáyà mú ipò iwájú nínú títún odi náà kọ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́