Ẹ̀KỌ́ 18
Lílo Bíbélì Láti Fi Dáhùn Ìbéèrè
NÍGBÀ táwọn èèyàn bá bi wá nípa ohun tá a gbà gbọ́, nípa bá a ṣe ń gbé ìgbésí ayé wa, tàbí tí wọ́n ń béèrè èrò wa nípa àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́, tàbí nípa ìrètí wa fún ọjọ́ ọ̀la, a máa ń ṣakitiyan láti fi Bíbélì dá wọn lóhùn. Èé ṣe? Nítorí pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni. Inú Bíbélì la ti mú àwọn ohun tá a gbà gbọ́ jáde wá. Bíbélì la gbé ìgbésí ayé wa kà. Ó ń là wá lóye nípa àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé. Àwọn ìlérí onímìísí tó wà nínú Bíbélì la gbé ìrètí wa fún ọjọ́ ọ̀la kà.—2 Tím. 3:16, 17.
A mọ̀ dájú pé ojúṣe wa ni láti máa ṣe ohun tó bá orúkọ wa mu. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá. (Aísá. 43:12) Ìyẹn ló fi jẹ́ pé a kì í lo ọgbọ́n orí ènìyàn nígbà tá a bá ń dáhùn ìbéèrè, bí kò ṣe ohun tí Jèhófà wí nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ onímìísí. Òótọ́ ni pé kálukú wa ló ní ojú tá a fi ń wo àwọn ọ̀ràn, ṣùgbọ́n a máa ń jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run darí èrò wa nítorí pé ó dá wa lójú hán-ún pé òun gan-an ló jẹ́ òtítọ́. Àmọ́ o, Bíbélì kì í ṣe òfin dandan gbọ̀n lórí ọ̀ràn èyí-ó-wù-mí-ò-wù-ọ́. Dípò ṣíṣe òfin má-ṣu-má-tọ̀ fáwọn ẹlòmíràn lórí àwọn ọ̀ràn èyí-ó-wù-mí-ò-wù-ọ́, ìfẹ́ wa ni láti kọ́ wọn ní àwọn ìlànà tí Ìwé Mímọ́ gbé kalẹ̀, kí àwọn tó ń gbọ́ wa lè ní òmìnira kan náà bíi tiwa, ìyẹn ni, láti yan èyí tó wù wọ́n. Gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ìfẹ́ wa ni “láti gbé ìgbọràn ga síwájú sí i nípasẹ̀ ìgbàgbọ́.”—Róòmù 16:26.
A pe Jésù Kristi ní “ẹlẹ́rìí aṣeégbíyèlé àti olóòótọ́” nínú ìwé Ìṣípayá 3:14. Báwo ló ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè, tó sì yanjú àwọn ọ̀ràn tí wọ́n gbé kò ó lójú? Nígbà mìíràn, ó máa ń lo àwọn àpèjúwe tó máa ń mú káwọn èèyàn ronú jinlẹ̀. Ní àwọn ìgbà míì sì rèé, ó máa ń bi oníbèéèrè náà nípa bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan ṣe yé onítọ̀hún sí. Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, ńṣe ló máa ń fa ọ̀rọ̀ Ìwé Mímọ́ yọ, tàbí kí ó tún wọn sọ lọ́rọ̀ mìíràn, tàbí kó sọ wọ́n mọ́ ọ̀rọ̀. (Mát. 4:3-10; 12:1-8; Lúùkù 10:25-28; 17:32) Ní ọ̀rúndún kìíní, wọ́n sábà máa ń kó àwọn àkájọ Ìwé Mímọ́ sínú sínágọ́gù. Kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé Jésù ní àwọn àkájọ Ìwé Mímọ́ tirẹ̀, ṣùgbọ́n ńṣe ni Ìwé Mímọ́ ń hó lágbárí rẹ̀, kò sì lè ṣe kí ó máà tọ́ka sí i nígbà tó bá ń kọ́ àwọn èèyàn. (Lúùkù 24:27, 44-47) Ìyẹn ló fi lè sọ tòótọ́tòótọ́ pé ohun tí òun fi ń kọ́ni kì í ṣe àpilẹ̀ṣe tara òun. Ohun tó gbọ́ látọ̀dọ̀ Baba rẹ̀ ló ń sọ.—Jòh. 8:26.
Àpẹẹrẹ Jésù la fẹ́ tẹ̀ lé. A ò tíì fetí ara wa gbóhùn Ọlọ́run rí gẹ́gẹ́ bí Jésù ti gbọ́ ọ. Ṣùgbọ́n Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì. Bó bá jẹ́ inú rẹ̀ làwọn ìdáhùn wa ti ń wá, kò ní sí pé à ń pe àfiyèsí sí ara wa. A ó fi hàn pé dípò sísọ èrò ẹ̀dá aláìpé, a pinnu látọkànwá láti jẹ́ kí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ sọ ohun tó jẹ́ òtítọ́.—Jòh. 7:18; Róòmù 3:4.
Àmọ́ ṣá o, lílo Bíbélì ní ìlò wọ̀ǹdùrùkù kọ́ ni ohun tí à ń lépa, bí kò ṣe lílò ó lọ́nà tí yóò ṣàǹfààní jù lọ fẹ́ni tó ń gbọ́ wa. A fẹ́ kó gbọ́ wa láìsí ẹ̀tanú. Bí ìṣesí onítọ̀hún bá ṣe rí ni yóò pinnu bóyá kó o bẹ̀rẹ̀ àlàyé ọ̀rọ̀ Bíbélì nípa sísọ pé: “Ǹjẹ́ o ò gbà pé ohun tó jà jù ni mímọ ohun tí Ọlọ́run wí?” Tàbí kẹ̀, o lè sọ pé: “Ǹjẹ́ o mọ̀ pé Bíbélì ṣàlàyé ìbéèrè yẹn?” Bó bá jẹ́ ẹni tí kò ka Bíbélì kún lò ń bá sọ̀rọ̀, ó lè di dandan láti bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ lọ́nà mìíràn. O lè sọ pé: “Jẹ́ kí n fi àsọtẹ́lẹ̀ ìgbà láéláé yìí hàn ọ́.” Tàbí kẹ̀, o lè sọ pé: “Ìwé tí a ti pín kiri jù lọ nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn sọ pé . . . ”
Nínú àwọn ọ̀ràn kan, o kàn lè sọ ohun tó wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan lọ́rọ̀ ara rẹ. Àmọ́, níbi tó bá ti ṣeé ṣe, ohun tó ti dára jù lọ ni kó o ṣí Bíbélì gan-an, kó o sì ka ohun tó wí. Fi ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà han onítọ̀hún nínú ẹ̀dà Bíbélì tirẹ̀, tí ìyẹn bá ṣeé ṣe. Bí àwọn èèyàn bá lo Bíbélì fúnra wọn lọ́nà yìí, ó sábà máa ń ní ipa lílágbára lórí wọn.—Héb. 4:12.
Ojúṣe àwọn Kristẹni alàgbà ni láti lo Bíbélì nígbà tí wọ́n bá ń dáhùn ìbéèrè. Ọ̀kan lára ohun tí à ń béèrè kí arákùnrin kan tó lè sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà ni pé ó ní láti jẹ́ ẹni “tí ń di ọ̀rọ̀ ṣíṣeégbíyèlé mú ṣinṣin ní ti ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀.” (Títù 1:9) Ẹnì kan nínú ìjọ lè lọ lo ìmọ̀ràn tí alàgbà kan fún un láti fi ṣe ìpinnu pàtàkì kan nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé kí ìmọ̀ràn ọ̀hún jẹ́ èyí tá a gbé karí Ìwé Mímọ́! Àpẹẹrẹ tí alàgbà bá fi lélẹ̀ nínú ṣíṣe èyí lè nípa lórí ọ̀nà tí ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn gbà ń kọ́ni.