ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • A Kò Ní Sẹ́ Ìgbàgbọ́ Wa
    Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2016
    • INDONÉṢÍÀ

      A Kò Ní Sẹ́ Ìgbàgbọ́ Wa

      Daniel Lokollo

      • WỌ́N BÍ I NÍ 1965

      • Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1986

      • ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe tó fi ìdúróṣinṣin kojú inúnibíni.

      Daniel Lokollo

      NÍ APRIL 14, 1989, mo ń darí ìpàdé kan lọ́wọ́ nílùú Maumere tó wà ní erékùṣù Flores, ṣàdédé ni àwọn aláṣẹ ìjọba kan já wọnú ilé tí wọ́n sì wá mú èmi àti àwọn mẹ́ta míì.

      Àwọn tó ń bójú tó ọgbà ẹ̀wọ̀n gbìyànjú láti fipá mú wa pé ká kí àsíá orílẹ̀-èdè. Nígbà tá a kọ̀, wọ́n lù wá bí ẹni máa kú, wọ́n tún fi ẹsẹ̀ gbá wa, wọ́n sì sá wa sínú oòrùn fún ọjọ́ márùn-ún. Tó bá dalẹ́, wọ́n á dá wa pa dà sínú ẹ̀wọ̀n kótópó tá a máa sùn. Nígbà tá a bá máa fi débẹ̀, á ti rẹ̀ wá tẹnutẹnu, tí gbogbo ara á sì máa ro wá. Yàtọ̀ síyẹn, yàrá ẹ̀wọ̀n ọ̀hún kéré, ó sì dọ̀tí. Kó sí ẹní, kò sí bẹ́ẹ̀dì, orí sìmẹ́ǹtì lásán la máa ń sùn, nígbà tó bá fi máa di òru, ṣe ni otútù máa ń mú wa. Bẹ́ẹ̀ ni aláṣẹ ọ̀gbà ẹ̀wọ̀n náà ń rọ̀ wá pé ká sẹ́ ìgbàgbọ́ wa kí wọ́n lè tú wa sílẹ̀, àmọ́ a sọ fún un pé: “Títí tá a máa fi kú, àwa kò ní kí àsíá náà.” Bíi ti àwọn Kristẹni ìṣáájú, a gbà pé àǹfààní ló jẹ́ pé a “jìyà nítorí òdodo.”​—1 Pét. 3:14.

  • A Tẹ̀ Lé Ìtọ́ni—A Sì Yè!
    Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2016
    • INDONÉṢÍÀ

      A Tẹ̀ Lé Ìtọ́ni​—A sì Yè!

      Blasius da Gomes

      • WỌ́N BÍ I NÍ 1963

      • Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1995

      • ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Ọ̀kan lára àwọn alàgbà tó bójú tó àwọn ará nígbà ìjà ẹ̀sìn tó wáyé nílùú Ambon tó jẹ́ ara àwọn erékùṣù Maluku.

      Blasius da Gomes

      NÍ January 19, 1999, àìgbọ́ra-ẹni-ye tó ti wà láàárín àwọn Mùsùlùmí àtàwọn Kristẹni wá di ìjà ìgboro. Ibi tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ ìjà yìí ò ju nǹkan bí kìlómítà mẹ́ta sí ilé tí mò ń gbé. Ìjà tá à ń wí yìí gbóná, ó kọjá àfẹnusọ.a

      Mo kọ́kọ́ dáàbò bo ìdílé mi, lẹ́yìn náà ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í fóònù àwọn ará láti béèrè àlàáfíà wọn. Mo fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀, mo sì rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n má ṣe rìn lágbègbè ibi tí wàhálà náà ti ń ṣẹlẹ̀. Nígbà tó yá, àwọn alàgbà bẹ àwọn ará wò láti gbé wọn ró nípa tẹ̀mí, wọ́n sì tún rọ̀ wọ́n láti jọ́sìn pọ̀ ní àwùjọ kéékèèké.

      Ẹ̀ka ọ́fíìsì náà tún rọ̀ wá pé ká ṣètò bí àwọn ará tó wà ní àgbègbè tó léwu ṣe máa kúrò níbẹ̀, a sì ṣètò bí ìsọfúnni náà ṣe máa dé ọ̀dọ̀ gbogbo ìdílé. Arákùnrin kan kọ̀ láti kúrò níbẹ̀. A pa dà gbọ́ pé àwọn jàǹdùkú náà pa á. Àmọ́ gbogbo àwọn ará tó tẹ̀ lé ìtọ́ni náà ló yè.

      a Ìjà yìí gba gbogbo àgbègbè Maluku fún nǹkan bí ọdún méjì, ó sì mú kí ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn sá kúrò nílé.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́