ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 3/15 ojú ìwé 13-18
  • Maa Ṣísẹ̀rìn ní Ìyára kan naa Pẹlu Kẹkẹ-Ẹṣin Òkè Ọ̀run Ti Jehofa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Maa Ṣísẹ̀rìn ní Ìyára kan naa Pẹlu Kẹkẹ-Ẹṣin Òkè Ọ̀run Ti Jehofa
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • O Tẹwọgba Iṣẹ Ti A Fun Un O Si Mu Un Ṣẹ
  • Awọn Ọ̀rọ̀ Ọlọrun Ni O Fi Sọ́kàn
  • Idagunla Kò Dá A Lọ́wọ́kọ́
  • A Sun Un Ṣiṣẹ lati Ṣisẹrin ni Iyara Kan Naa
  • Maa Baa Lọ ni Ṣiṣisẹrin Ní Iyara Kan Naa
  • Kẹkẹ-Ẹṣin Òkè Ọ̀run Ti Jehofa Wa Lori Ìrìn
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Jèhófà Máa Ń Ràn Wá Lọ́wọ́ Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìwàásù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Ìsíkíẹ́lì—Apá Kìíní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • ‘Mo Rí Ìran Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run’
    Ìjọsìn Mímọ́ Jèhófà Ti Pa Dà Bọ̀ Sípò!
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 3/15 ojú ìwé 13-18

Maa Ṣísẹ̀rìn ní Ìyára kan naa Pẹlu Kẹkẹ-Ẹṣin Òkè Ọ̀run Ti Jehofa

“Iwọ sì gbọdọ sọ awọn ọrọ mi fun wọn, laika yala wọn gbọ́ tabi wọn fasẹhin sí.”—ESEKIẸLI 2:7, NW.

1, 2. Kẹkẹ ọlọba wo ni Esekiẹli ri, ki ni a sì sọ fun un?

KẸKẸ-ẸṢIN oke ọ̀run ti Jehofa duro niwaju awọn iranṣẹ rẹ̀ nisinsinyi. Pẹlu oju igbagbọ, wọn ri ohun irinna ọlọla ńlá ti Oluwa Ọba-alaṣẹ wọn. O jẹ ologo, ẹlẹru, ọlọla ọba.

2 Kẹkẹ ọlọba kan naa wá siwaju wolii Ọlọrun naa Esekiẹli ninu iran ni nnkan bii 2,600 ọdun sẹhin. Lati inu kẹkẹ-ẹṣin tí ńgbé ìtẹ́ yii—eto-ajọ ọ̀run ti awọn ẹda ẹmi Ọlọrun—Jehofa pa aṣẹ amunijígìrì yii fun Esekiẹli pe: “Ọmọ alafojudi ati ọlọkan lile ni wọn. Emi ran ọ si wọn; iwọ yoo sì wi fun wọn pe, bayii ni Oluwa Ọlọrun wi. Ati awọn bi wọn yoo gbọ́, tabi bi wọn yoo kọ̀, (nitori ọlọ̀tẹ̀ ile ni wọn) sibẹ wọn yoo mọ̀ pe wolii kan ti wà laaarin wọn.”—Esekiẹli 2:4, 5.

3. Alabaadọgba ode oni wo ni Esekiẹli ni?

3 Esekiẹli mu iṣẹ yẹn ṣẹ pẹlu ipinnu fifidimulẹ gbọnyin, ni ṣiṣiṣẹsin gẹgẹ bi ohun eelo kanṣoṣo ni ọwọ Ọlọrun. Lọna ti o farajọra, nisinsinyi Ọlọrun ní ohun eelo eto-ajọ kanṣoṣo ní ikawọ rẹ̀. Ẹgbẹ Esekiẹli, awọn aṣẹku ẹni ami-ororo, nmu ipo iwaju ninu iṣẹ naa ti fifunni ni ijẹrii ikẹhin, pẹlu “ogunlọgọ nla” ti “awọn agutan miiran” ti wọn rọgba yi wọn ka ní títì wọn lẹhin. (Iṣipaya 7:9, 10; Johanu 10:16) Lapapọ wọn jẹ “agbo kan,” pẹlu Oluṣọ-agutan Rere, Jesu Kristi, tí ndari wọn labẹ ipo ọba-alaṣẹ atobilọla Olùgùn Kẹkẹ-ẹṣin naa, Jehofa Ọlọrun.

4, 5. Bawo ni eto-ajọ Ọlọrun ti a le fojuri ṣe di eyi ti o wa, ki ni o sì ti ni iriri rẹ̀ ni ibamu pẹlu Aisaya 60:22?

4 Labẹ idari Jehofa, eto-ajọ yika aye yii ti bisii lati ibẹrẹ kekere ti wọn fi di aṣoju alagbara kan fun pipolongo aṣẹ naa lati “bẹru Ọlọrun, ki ẹ sì fi ògo fun un, nitori ti wakati idajọ rẹ̀ de.” (Iṣipaya 14:7) Gẹgẹ bi Esekiẹli ko ti gbe ara rẹ̀ dide tabi yan ara rẹ̀ sipo gẹgẹ bi wolii kan, bẹẹ gẹ́gẹ́ ni eto-ajọ Ọlọrun ti a le fojuri ko da araarẹ silẹ tabi yan ara rẹ̀ sipo. Ko jẹyọ lati inu ifẹ inu tabi isapa eniyan. Olùgùn Kẹkẹ-ẹṣin atọrunwa naa ni o mu ki eto-ajọ yii di wíwà. Pẹlu agbara nipasẹ ẹmi Ọlọrun ati itilẹhin awọn angẹli mimọ, awọn eniyan Jehofa, ti ni iriri iru imugbooro amúnijígìrì bẹẹ ti o fi jẹ pe ‘ẹni kekere kan ti di alagbara orilẹ-ede.’—Aisaya 60:22.

5 Iye ti o ju 4,000,000 awọn Ẹlẹrii Jehofa ni wọn npolongo ihin-iṣẹ Ijọba naa ni 212 ilẹ̀. A pin wọn si ohun ti o ju 63,000 ijọ ti a ṣeto wọn si awọn ayika ati agbegbe. Ẹka ọfiisi ati ohun eelo itẹwe gbigbooro nṣiṣẹ labẹ idari Ẹgbẹ Oluṣakoso gẹgẹ bi ibudo eto orile-iṣẹ. Gẹgẹ bi ẹni pe wọn jẹ ẹnikan, gbogbo wọn ntẹsiwaju, ni wiwaasu ihinrere, ni kikọ awọn wọnni ti wọn dahunpada lẹkọọ, ni kikọ awọn ibi ipade. Bẹẹni, eto-ajọ Jehofa ti a le fojuri nṣisẹrin ni iyara kan naa pẹlu kẹkẹ-ẹṣin oke ọ̀run ati Ẹni ti o gùn ún.

6. Ki ni ṣiṣisẹrin ni iyara kan naa pẹlu eto-ajọ Jehofa ti a le fojuri ní ninu?

6 Bi iwọ ba jẹ ọkan lara awọn Ẹlẹrii Jehofa, njẹ iwọ nṣisẹrin ni iyara kan naa pẹlu eto-ajọ Ọlọrun ti a le fojuri bi? Ṣiṣe bẹẹ kii wulẹ ṣe lilọ si awọn ipade Kristian ati lilo akoko ninu iṣẹ-ojiṣẹ nikan. Ni ipilẹ, iṣisẹrin ni iyara kan naa niiṣe pẹlu ilọsiwaju ati idagba nipa tẹmi. O ni ninu nini oju-iwoye onifojusọna fun rere, gbigbe awọn ohun akọmuṣe bibojumu kalẹ, ati mímọ̀ isọfunni lọ́ọ́lọ́ọ́. Bi awa ba nṣisẹrin ni iyara kan naa pẹlu kẹkẹ-ẹṣin oke ọ̀run ti Jehofa, igbesi-aye wa yoo wà ni iṣedeedee pẹlu ihin-iṣẹ ti a npolongo.

7. Eeṣe ti a fi nilati yẹ iwa Esekiẹli wò gẹgẹ bi wolii Ọlọrun?

7 Ninu ọran ṣiṣisẹrin ni iyara kan naa, awọn iranṣẹ Jehofa ode-oni le kẹkọọ ohun pupọ lati inu apẹẹrẹ Esekiẹli. Bi o tilẹ jẹ pe a yàn án sipo lọna akanṣe gẹgẹ bi wolii lati ọwọ Jehofa, Esekiẹli ṣì ni imọlara, aniyan, ati aini. Fun apẹẹrẹ, gẹgẹ bi ọ̀dọ́kùnrin kan ni ifiwera ti o ti ni aya, oun jẹ̀rora ibanujẹ ti pipadanu aya rẹ̀ ninu iku. Sibẹ, oun ko gbagbe iṣẹ ti a fun un gẹgẹ bi wolii Jehofa lae. Nipa ṣiṣayẹwo bi Esekiẹli ṣe huwa dari ara rẹ̀ ni awọn ọna miiran pẹlu, awa le fun araawa lokun lati maa ṣisẹrin pẹlu eto-ajọ Ọlọrun ti a le fojuri. Eyi yoo fun wa lagbara lati maa ṣisẹrin pẹlu eto-ajọ rẹ̀ ti a le fojuri.

O Tẹwọgba Iṣẹ Ti A Fun Un O Si Mu Un Ṣẹ

8. Niti iṣẹ ti a fun un, apẹẹrẹ wo ni Esekiẹli fi lelẹ?

8 Esekiẹli fi apẹẹrẹ rere lelẹ nipa titẹwọgba iṣẹ ti a fun un ati mimu un ṣẹ. Bi o ti wu ki o ri, igbọran ati igboya ni a nilo lati mú un ṣẹ, nitori a ka pe: “Óò ọmọkunrin eniyan, maṣe bẹru wọn; ma sì ṣe bẹru ọrọ wọn, nitori pe awọn ọlọkan lile ati awọn ohun ti ńgún ọ wà, laaarin awọn àkéekèe ni iwọ sì ngbe. Awọn ọ̀rọ̀ wọn ni ki iwọ maṣe bẹru, ki iwọ má sì ṣe gbọ̀n jìnnìjìnnì fun ipaya nitori ojú wọn, nitori ọlọtẹ ile ni wọn. Iwọ sì gbọdọ sọ awọn ọrọ mi fun wọn, laika yala wọn gbọ́ tabi wọn fàsẹ́hìn sí, nitori wọn jẹ ọran iṣọtẹ. Ati iwọ, Óò ọmọkunrin eniyan, gbọ ohun ti emi nsọ fun ọ. Iwọ maṣe di ọlọ̀tẹ̀ bi ọlọ̀tẹ̀ ile naa.”—Esekiẹli 2:6-8, NW.

9. Kiki nipa ṣiṣe ki ni ni Esekiẹli yoo to bọ lọwọ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀?

9 Esekiẹli ko nilati dagunla tabi kun fun ibẹru, ti a nilati maa gún un ni kẹ́sẹ́ ni lemọlemọ lati mu iṣẹ ti a fun un ṣẹ. Oun yoo bọ́ lọwọ ẹbi ẹ̀jẹ̀ kiki bi oun ba fi ifẹ inu ati igboya sọ awọn ọrọ Jehofa. Esekiẹli ni a sọ fun pe: “Bi iwọ ba kilọ fun eniyan buburu, ti ko si kuro ninu buburu rẹ̀, ti ko yipada kuro ni ọna buburu rẹ̀, yoo ku ninu ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ṣugbọn ọrùn rẹ mọ́.”—Esekiẹli 3:19.

10. Bawo ni ẹgbẹ Esekiẹli ṣe fi ẹ̀rí hàn lati dabi wolii naa?

10 Gẹgẹ bi o ti ri ninu ọran ti Esekiẹli, ẹgbẹ Esekiẹli ẹni-ami-ororo ti tẹwọgba iṣẹ ti Ọlọrun fifun wọn, wọn sì nmu un ṣẹ. Bi awa ba jẹ Ẹlẹrii Jehofa, awa nilati ranti pe iwalaaye wa ati iwalaaye awọn ẹlomiran sinmi lori igbọran wa. (1 Timoti 4:15, 16) Ẹlẹrii kọọkan nilati maa ṣisẹrin ni iyara kan naa pẹlu eto-ajọ Jehofa. Ọlọrun kii yoo so wa mọ kẹkẹ-ẹṣin rẹ̀ ki o sì maa wọ wa lọ. Idagunla ati ọkan-aya ti o pin yẹlẹyẹlẹ bu Olùgùn Kẹkẹ-ẹṣin naa kù. Nitori naa eto-ajọ Jehofa ti a le fojuri gba wa niyanju lati mu ki igbesi aye wa rọ̀gbà yi awọn ire ti ọ̀run ká. Idahunpada ti o ṣedeedee si iru igbaniniyanju bẹẹ mu wa wà ni iṣisẹrin kan naa pẹlu eto-ajọ Ọlọrun o si gbe iṣẹ-ojiṣẹ mimọ-ọlọwọ wa ga rekọja ọ̀nà iṣiṣẹ alaini iyipada, alafaraṣe máfọkànṣe. Dajudaju, awọn eniyan Jehofa lapapọ maa nfi ifọkansin agbayanu han. Ipa tiwa lẹnikọọkan ni lati pa iṣisẹrin ni iyara kan naa mọ́.

Awọn Ọ̀rọ̀ Ọlọrun Ni O Fi Sọ́kàn

11. Apẹẹrẹ wo ni Esekiẹli fi lelẹ niti awọn ọ̀rọ̀ Ọlọrun?

11 Esekiẹli tun fi apẹẹrẹ rere lelẹ nipa fifi awọn ọ̀rọ̀ Ọlọrun sinu ọkan-aya rẹ̀. Ni titẹle aṣẹ, oun jẹ iwe kíká, tabi akajọ ti Ọlọrun fifun un. Esekiẹli wipe, “o si dabi oyin ni ẹnu ni dídùn.” Bi o tilẹ jẹ pe èkíká ìwé naa kun fun “ohùn réré ẹkun,, ati ọ̀fọ̀, ati igbe,” o dùn ni ẹnu Esekiẹli nitori pe oun mọriri ọla ti ṣiṣoju fun Jehofa. O jẹ iriri aladun fun wolii naa lati mu iṣẹ ti Ọlọrun fifun un ṣẹ. Ọlọrun sọ fun un pe: “Ọmọ eniyan, gba gbogbo ọ̀rọ̀ ti emi yoo sọ fun ọ si ọkàn rẹ, si fi etí rẹ gbọ wọn.” (Esekiẹli 2:9–3:3, 10) Awọn ìran wọnni mu ki Esekiẹli mọ ohun ti Ọlọrun yọnda fun un lati kopa ninu rẹ̀ lọna didaju han-un o sì fun ipo ibatan rẹ̀ pẹlu Jehofa lokun.

12. Ki ni Esekiẹli ṣe ni nnkan ti o ju ẹwadun meji ti iṣẹ-isin alasọtẹlẹ?

12 Esekiẹli ni a fun ni awọn iran ati ihin-iṣẹ fun oniruuru awọn ète ati awujọ eniyan. Oun nilati fetisilẹ daradara lẹhin naa ki o sọrọ ki o sì gbe igbesẹ gẹgẹ bi a ti dari rẹ̀. Isọfunni ati awọn ọna igbaṣiṣẹ titun ni a ṣipaya fun un ni ṣísẹ̀ntẹ̀lé laaarin nnkan bii 22 ọdun iṣẹ-isin alasọtẹlẹ. Ni awọn igba kan Esekiẹli sọ ihin-iṣẹ ti a ṣe àṣàyàn awọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọna akanṣe. Ni awọn igba miiran, oun yí si fifi ara ṣapejuwe, gẹgẹ bi didubulẹ niwaju bíríkì kan ti o duro fun Jerusalẹmu. (Esekiẹli 4:1-8) Apẹẹrẹ rẹ̀ ninu awọn ọran ara-ẹni, iru bii iṣarasihuwa rẹ̀ si iku aya rẹ̀, tun ni ihin-iṣẹ kan. (Esekiẹli 24:15-19) Oun nilati mọ ohun ti ńlọ lọwọ, ni gbigbe ihin-iṣẹ ti o ba a mu gẹ́ ẹ́ kalẹ ki o sì gbe awọn igbegbeesẹ ti o tọ́ ni akoko ti o tọ́. Esekiẹli wà ninu ìdè ibatan iṣẹ onitẹsiwaju ti o ṣe timọtimọ pẹlu Jehofa.

13. Bawo ni a ṣe le gbé ibatan timọtimọ pẹlu Jehofa ró?

13 Lọna ti o farajọra, lati gbéró ati lati pa ipo-ibatan timọtimọ pẹlu Jehofa mọ́ gẹgẹ bi alajumọjẹ oṣiṣẹ rẹ̀, a gbọdọ gba Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sinu ọkan-aya wa. (1 Kọrinti 3:9) Ṣiṣisẹrin ni iyara kan naa pẹlu eto-ajọ Ọlọrun ti a le fojuri ni ọna yii beere pe ki a maa wà deedee laisọsẹ pẹlu ìṣàn ounjẹ tẹmi bi a ti pese rẹ̀ ni akoko ti o yẹ. (Matiu 24:45-47) “Èdè mimọgaara” naa ngbilẹ leralera. (Sẹfanaya 3:9) Kiki bi a ba nmọ isọfunni lọọlọọ ni awa yoo to le dahunpada pẹlu igbọran si idari Olùgun Kẹkẹ-ẹṣin naa.

14, 15. Ọna iṣiṣẹ deedee wo ni a nilo lati maa wà ní iyara kan naa pẹlu iṣisẹrin ti eto-ajọ Ọlọrun fi lelẹ?

14 Fun ète yẹn, a nilo ọna iṣiṣẹ deedee rere ti adura gbígbà funra-ẹni, idakẹkọọ, ati ikopa ninu iṣẹ-ojiṣẹ mimọ ti ihin rere. (Roomu 15:16) Ranti apẹẹrẹ Esekiẹli ni jijẹ èkíká iwe ti o ni ihin-iṣẹ Ọlọrun ninu. Esekiẹli jẹ gbogbo èkíká iwe naa pata, kii ṣe apakan rẹ̀. Oun kò ṣà ki o sì yan awọn ẹ̀já kekere ti o ti lè jẹ́ fun itẹlọrun ara rẹ̀. Lọna ti o farajọra, idakẹkọọ Bibeli ati awọn itẹjade Kristian funraawa ni a nilati mu wà deedee lati maa ṣisẹrin ni iyara kan naa pẹlu ìṣàn ounjẹ tẹmi, a sì nilati jẹ ninu gbogbo ohun ti a gbekari tabili tẹmi, titikan awọn otitọ jijinlẹ.

15 Njẹ awa ha nfi taduratadura sapa lati loye ounjẹ lile naa? Ṣiṣisẹrin pẹlu iyara kan naa beere pe ki ìmọ̀ ati òye wa tẹsiwaju rekọja ipilẹ, nitori a kà pe: “Nitori olukuluku ẹni ti nmu wàrà jẹ alailoye ọ̀rọ̀ òdodo: nitori ọmọ ọwọ́ ni. Ṣugbọn ounjẹ lile ni fun awọn ti o dàgbà, awọn ẹni nipa iriri, ti wọn nlo ọgbọ́n wọn lati mọ iyatọ laaarin rere ati buburu.” (Heberu 5:13, 14) Bẹẹni, nini itẹsiwaju tẹmi jẹ apa pataki wiwa ni iyara kan naa pẹlu iṣisẹrin ti eto-ajọ Ọlọrun fi lelẹ.

Idagunla Kò Dá A Lọ́wọ́kọ́

16, 17. Bawo ni Esekiẹli ṣe ba idagunla, ipẹgan, ati aisi idahunpada lò?

16 Esekiẹli tun fi apẹẹrẹ rere lelẹ nipa jijẹ onigbọran ati laiyọnda ara rẹ̀ lati di ẹni ti a dálọ́wọ́kọ́ nipasẹ idagunla tabi ipẹgan. Lọna ti o farajọra, nipa wiwa ni iyara kan naa pẹlu èdè mimọgaara ti ńgbèrú, awa ti wà ni imuratan lati tẹle ọna ti Olùgùn Kẹkẹ-ẹṣin ọlọba naa ba gbà. Nipa bayii a ti mura wa silẹ lati dahunpada si awọn àṣẹ rẹ̀, a fun wa lokun lati jẹ ẹni ti a kò dáláwọ́kọ́ nipasẹ idagunla tabi ìpẹ̀gàn awọn wọnni ti a nsọ ihin-iṣẹ idajọ Jehofa fun. Gẹgẹ bi o ti ri pẹlu Esekiẹli, Ọlọrun ti kilọ fun wa ṣaaju pe awọn eniyan kan yoo ṣe atako lọna mimuna, ni jijẹ olorikunkun ati ọlọkan lile. Awọn miiran ki yoo gbọ́ nitori pe wọn kò fẹ lati fetisilẹ si Jehofa. (Esekiẹli 3:7-9) Sibẹ awọn miiran yoo jẹ agabagebe, gẹgẹ bi Esekiẹli 33:31, 32 ti wi pe: “Wọn sì tọ̀ ọ́ wa, bi eniyan ti nwa, wọn sì jokoo niwaju rẹ bi eniyan mi, wọn sì gbọ ọ̀rọ̀ rẹ, ṣugbọn wọn kì yoo ṣe wọn: nitori ẹnu wọn ni wọn fi nfi ifẹ pupọ hàn, ṣugbọn ọkan wọn tẹle ojukokoro wọn. Si kiyesi i, iwọ jẹ orin ti o dùn pupọ fun wọn, ti ẹnikan ti o ni ohùn daradara, ti o sì lè fun ohun-eelo orin daradara: nitori wọn gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ, ṣugbọn wọn kò ṣe wọn.”

17 Ki ni yoo jẹ abajade? Ẹsẹ 33 fikun un pe: “Ati nigba ti eyi ba ṣẹ, (kiyesi i, yoo dé,) nigba naa ni wọn yoo mọ̀ pe wolii kan ti wà laaarin wọn.” Awọn ọ̀rọ̀ wọnni fihan pe Esekiẹli kò juwọsilẹ nitori aisi idahunpada. Agunla awọn miiran kò mú un jọ̀gọ̀nù. Yala awọn eniyan fetisilẹ tabi bẹẹkọ, oun ṣegbọran si Ọlọrun o sì mu iṣẹ ti a fun un ṣẹ.

18. Awọn ibeere wo ni iwọ le bi ara rẹ leere?

18 Eto-ajọ Jehofa ti a le fojuri ti nmu ipolongo naa rinlẹ̀ sii nisinsinyi pe gbogbo eniyan nilati bẹru Ọlọrun ki wọn sì fi ògo fun un. Njẹ iwọ ha ntẹramọ ọn nigba ti a ba riwi si ọ fun mimu iduro onigboya ninu fifunni ni ijẹrii Ijọba naa, fun jijẹ oniwa rere ni ọna igbesi-aye rẹ? Njẹ iwọ nduro gbọnyingbọnyin nigba ti o ba jẹ ẹni ti a dari ikimọlẹ si nitori kíkọ̀ lati gba ẹ̀jẹ̀, ṣiṣai jọsin fun ohun iṣapẹẹrẹ orilẹ-ede, kíkọ̀ lati ṣayẹyẹ awọn isinmi aye?—Matiu 5:11, 12; 1 Peteru 4:4, 5.

19. Niti idari, ki ni awa yoo ṣe bi awa yoo ba maa ṣisẹrin ni iyara kan naa pẹlu kẹkẹ-ẹṣin oke ọ̀run ti Jehofa?

19 Ipa-ọna yii kii ṣe eyi ti o rọrun, ṣugbọn awọn wọnni ti wọn bá foriti i titi de opin ni a o gbala. (Matiu 24:13) Pẹlu iranlọwọ Jehofa, awa ki yoo jẹ ki awọn eniyan aye sọ wa da bii tiwọn ki wọn sì tipa bayii da wa duro ninu ṣiṣisẹrin pẹlu kẹkẹ ẹṣin oke ọ̀run ti Jehofa. (Esekiẹli 2:8; Roomu 12:21) Bi awa ba nṣisẹrin ni iyara kan naa pẹlu eto-ajọ awọn angẹli ti o dabii kẹkẹ-ẹṣin naa, awa yoo ṣiṣẹ ni kánmọ́ ni ibamu pẹlu idari ati awọn itọni ti a ngba nipasẹ eto-ajọ Ọlọrun ti a le fojuri. Jehofa pese ohun ti a nilo lati dojukọ awọn ohun ti nkọlu igbagbọ wa, lati pa didi ti a di Ọ̀rọ̀ iye mú mọ́, ati lati pa oju wa mọ sori awọn otitọ tẹmi ti o dalori kabiyesi Olùgùn kẹkẹ-ẹṣin oke ọ̀run naa.

A Sun Un Ṣiṣẹ lati Ṣisẹrin ni Iyara Kan Naa

20. Ki ni awọn nnkan diẹ ti a ṣakọsilẹ rẹ̀ lati ọwọ Esekiẹli ti o gbọdọ sun wa lati maa ṣisẹrin ni iyara kan naa?

20 Awọn ìran Esekiẹli nilati sún wa lati maa ṣisẹrin ni iyara kan naa. Kii ṣe kiki pe oun polongo awọn idajọ Ọlọrun lori Israẹli ṣugbọn o tun ṣe akọsilẹ awọn asọtẹlẹ imupada bọ sipo. Esekiẹli tọkasi Ẹni naa ti yoo ni ẹ̀tọ́ ofin lati ṣakoso lori ìtẹ́ Jehofa ni akoko ti a yàn. (Esekiẹli 21:27) Iranṣẹ Ọlọba yẹn, “Dafidi,” yoo ṣe atunkojọ awọn eniyan Ọlọrun yoo sì ṣoluṣọ agutan wọn. (Esekiẹli 34:23, 24) Bi o tilẹ jẹ pe a o kọlu wọn lati ọ̀dọ̀ Gọọgu ara Magọọgu, Ọlọrun yoo da wọn nide, ọta Rẹ̀ ni a o sì fipa mu lati ‘mọ Jehofa’ ani gan-an gẹgẹ bi wọn ti lọ si iparun. (Esekiẹli 38:8-12; 39:4, 7) Nigba naa awọn iranṣẹ Ọlọrun yoo gbadun iye ti ko lopin ninu eto igbekalẹ onijọsin mimọgaara ti o niiṣe pẹlu tẹmpili tẹmi. Omi iye ti nṣan lati inu ibujọsin naa yoo jẹ orisun iṣaraloore ati iwosan, ogún ilẹ̀ ni a o sì pin fun ibukun wọn.—Esekiẹli 40:2; 47:9, 12, 21.

21. Eeṣe ti ipa ti awọn Ẹlẹrii Jehofa ode oni nko ṣe ju ti Esekiẹli lọ?

21 Bawo ni o ti gbọdọ ru Esekiẹli soke to lati ṣakọsilẹ awọn asọtẹlẹ wọnni! Sibẹ, ipa ti awọn Ẹlẹrii Jehofa ode oni ńkó pọ jù. Awa ngbe ni akoko ti diẹ lara awọn asọtẹlẹ wọnni nni imuṣẹ. Nitootọ, awa jẹ olukopa agbekankanṣiṣẹ ninu awọn imuṣẹ kan. Nipa ọna ti awa ngba gbe igbesi-aye, njẹ awa ha fi idaniloju wa hàn lẹnikọọkan pe Jesu nṣakoso nisinsinyi gẹgẹ bi Ẹni ti o ni ẹ̀tọ́ ti òfin? O ha da wa loju funraawa pe Jehofa yoo da orukọ araarẹ̀ lare laipẹ ti yoo sì da awọn wọnni ti wọn nṣisẹrin ni iyara kan naa pẹlu eto-ajọ rẹ̀ nídè sinu aye titun rẹ̀? (2 Peteru 3:13) Iru idaniloju bẹẹ, ti a fi awọn iṣẹ igbagbọ kín lẹhin, fihan pe awa nitootọ nṣisẹrin ni iyara kan naa pẹlu kẹkẹ-ẹṣin oke ọ̀run ti Jehofa.

Maa Baa Lọ ni Ṣiṣisẹrin Ní Iyara Kan Naa

22. Ki ni a lè ṣe lati yẹra fun awọn ipinya ọkan ki a baa le pa oju-iwoye tẹmi ti o ṣe kedere mọ?

22 Lẹhin ti a ti ‘fi ọwọ́ wa le ohun eelo itulẹ,’ awa kò gbọdọ wẹhin ni iyanhanhan si ohunkohun tí aye yii lè ni lati funni. (Luuku 9:62; 17:32; Titu 2:11-13) Nitori naa ẹ jẹ ki a kiwọ́ itẹsi eyikeyii lati to iṣura jọ sori ilẹ-aye bọlẹ̀, ki a sì pa oju wa mọ́ láìgùn, ni pipa ọkàn pọ̀ sori Ijọba naa. (Matiu 6:19-22, 33) Ni mimu igbesi-aye wa rọrun, dídín awọn ẹrù-ìnira ti aye kù nibi ti o ba ti ṣeeṣe, yoo ran wa lọwọ lati maa ṣisẹrin ni iyara kan naa pẹlu eto-ajọ Jehofa. (Heberu 12:1-3) Awọn iyapa ọkàn lè sọ rírí ti a nri iran kẹkẹ-ẹṣin oke ọ̀run ati Ẹni ti o gùn ún di baibai. Ṣugbọn pẹlu iranlọwọ rẹ̀, awa lè pa oju iwoye tẹmi ti o ṣe kedere mọ́, gẹgẹ bi Esekiẹli ti ṣe.

23. Ki ni awọn Ẹlẹrii oluṣotitọ ni lati ṣe nitori awọn ẹni titun?

23 Apakan ẹru-iṣẹ wa gẹgẹ bi Ẹlẹrii Jehofa ní ninu riran ọpọlọpọ awọn ẹni titun lọwọ lati maa ṣisẹrin ni iyara kan naa pẹlu kẹkẹ-ẹṣin oke ọ̀run ti Ọlọrun. Ni 1990 ohun ti o fẹrẹẹ to 10,000,000 wa si Iṣe-iranti iku Jesu Kristi. Nigba ti ọpọlọpọ awọn ẹni wọnyi lè maa wa si awọn ipade Kristian melookan, wọn nilo lati ri ijẹpataki titẹsiwaju pẹlu eto-ajọ Jehofa ti a lè fojuri. Gẹgẹ bi Ẹlẹrii oluṣotitọ, awa lè ran wọn lọwọ nipa ẹmi ti a fihan ati iṣiri ti a nfifun wọn.

24. Ki ni a nilati ṣe ni awọn akoko ògógóró opin wọnyi?

24 Awọn akoko ògógóró opin ni a wà yii. Pẹlu oju igbagbọ, awa ti ri kẹkẹ-ẹṣin oke ọ̀run ti o duro ni iwaju wa. Olùgùn Kẹkẹ-ẹṣin ọlọla ọba naa ti fi iṣẹ kan fun eto-ajọ rẹ̀ ti a le fojuri lati waasu fun awọn orilẹ-ede ki o baa le jẹ pe, ni opin patapata, wọn yoo mọ̀ ẹni ti Jehofa jẹ́. (Esekiẹli 39:7) Lo anfaani titobilọla yii de ipẹkun lati ṣajọpin ninu dida ipo ọba-alaṣẹ Ọlọrun lare ati isọdimimọ orukọ mimọ rẹ̀ nipa ṣiṣisẹrin ni iyara kan naa pẹlu kẹkẹ-ẹṣin oke ọ̀run ti Jehofa.

Bawo Ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun?

◻ Esekiẹli fi apẹẹrẹ wo lelẹ nipa iṣẹ ti a fun un?

◻ Ki ni o tumọsi lati maa ṣisẹrin ni iyara kan naa pẹlu eto-ajọ Ọlọrun?

◻ Oju wo ni Esekiẹli fi wo awọn ọ̀rọ̀ Jehofa?

◻ Bawo ni awa ṣe le tẹle apẹẹrẹ Esekiẹli ni kikoju idagunla?

◻ Ki ni o gbọdọ sun awọn iranṣẹ Jehofa lati maa ṣisẹrin ni iyara kan naa pẹlu kẹkẹ-ẹṣin oke ọ̀run rẹ̀?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Ki ni a beere fun lati maa ṣisẹrin ni iyara kan naa pẹlu kẹkẹ-ẹṣin oke ọ̀run ti Jehofa?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Esekiẹli mọriri anfaani ti Ọlọrun fifun un. Iwọ nkọ?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́