Kẹkẹ-Ẹṣin Òkè Ọ̀run Ti Jehofa Wa Lori Ìrìn
“Niti awọn àgbá kẹ̀kẹ́ naa, a ke jade ni etí mi si wọn pe, ‘Óò agbo ètò àgbá kẹ̀kẹ́!’”—ESEKIẸLI 10:13, NW.
1. Iru ọ̀nà irinna wo ni Jehofa ni?
NI AWỌN ọjọ wọnyi ti ọkọ ofuurufu jẹ́ẹ̀tì dídán mèremère ayára bí àṣá, awọn aṣaaju aye le nimọlara pe wọn njẹgbadun ti kò lẹ́gbẹ́ ninu ijafafa irin ajo. Sibẹ, ní 2,600 ọdun sẹhin, Jehofa Ọlọrun ṣipaya pe oun ni ọna kan ti o dara julọ fun irinna, iru eyi ti onimọ iṣẹ-ẹrọ kankan kò tii rí rí. O jẹ kẹkẹ-ẹṣin titobi, ti o kun fun ẹ̀rù kan! O ha dabi ohun iyanu pe Ẹlẹdaa agbaye ńgùn ọkọ ti o dabi kẹkẹ-ẹṣin kan bi? Bẹẹkọ, nitori ọkọ oke ọ̀run ti Jehofa yatọ gidigidi si eyikeyii ti awọn eniyan lè finúrò.
2. Bawo ni Esekiẹli ori 1 ṣe ṣapejuwe kẹkẹ-ẹṣin oke ọ̀run ti Jehofa, si ta ni wolii naa sì kọ́kọ́ pe afiyesi wa?
2 Ni ori 1 asọtẹlẹ Esekiẹli, Jehofa ni a ṣapejuwe gẹgẹ bi ẹni ti ngun kẹkẹ-ẹṣin oke ọ̀run titobi gìrìwò kan. Ọkọ amuni kun fun ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ ti o ni àgbá mẹrin yii ni ngbe araarẹ̀ rìn o sì le ṣe awọn ohun yiyanilẹnu. Esekiẹli ri kẹkẹ-ẹṣin ti ọ̀run yii ninu iran ni 613 B.C.E., nigba ti oun wà leti ọkan lara awọn odò lílà ti Babiloni igbaani. Wolii naa kọkọ pe afiyesi wa si awọn wọnni ti wọn nṣeranṣẹ fun kẹkẹ-ẹṣin oke ọ̀run ti Jehofa. Bi a ti nka a, ẹ jẹ ki a gbiyanju lati foju inu wò ohun ti Esekiẹli rí.
Awọn Ẹda Alaaye Mẹrin
3. Ki ni awọn oju mẹrin ọkọọkan awọn kerubu mẹrin naa tọkasi?
3 Esekiẹli rohin pe: “Mo bẹrẹ sii wòó, sì kiyesi! ìjì lile kan ti nbọ lati ìhà ariwa, àgbájọ awọsanma nla kan ati iná fífì, o sì ni imọlẹyoo yika . . . Ati lati aarin rẹ̀ wá ni irisi awọn ẹda alaaye mẹrin wà.” (Esekiẹli 1:4, 5, NW) Ọkọọkan awọn ẹda alaaye mẹrin wọnyi, tabi awọn kerubu, ní iyẹ apá mẹrin ati oju mẹrin. Wọn ni oju kinniun, ti o tumọsi idajọ-ododo Jehofa; oju akọmaluu, ti o nduro fun agbara Ọlọrun; ati oju idì, ti ntumọsi ọgbọ́n Rẹ̀. Wọn tun ni oju eniyan, ti nsamisi ifẹ Jehofa.—Deuteronomi 32:4; Joobu 12:13; Aisaya 14:26; Esekiẹli 1:10; 1 Johanu 4:8.
4. Eeṣe ti awọn kerubu fi ni oju mẹrin, bawo sì ni awọn kerubu naa ṣe ri niti iyarasare?
4 Kerubu kọọkan ni oju ti nwo ọkan ninu awọn iha mẹrin. Fun ìdí yii, awọn kerubu naa lè yi ipa-ọna pada lọ́gán ki wọn si tẹle oju ti o wò iha ti wọn nifẹẹ ọkan sí. Ṣugbọn bawo ni awọn kerubu wọnni ti ri niti ìyárasáré? Họwu, wọn lè rin pẹlu ìyárasáré mànàmáná! (Esekiẹli 1:14) Kò si ọkọ̀ ti eniyan ṣe ti o tii lé ìyárasáré yẹn bá rí.
5. Bawo ni Esekiẹli ṣe ṣapejuwe awọn àgbá kẹ̀kẹ́-ẹṣin ati awọn àgbá irin wọn?
5 Lojiji, awọn àgbá kẹkẹ-ẹṣin naa wa si ojutaye. Ẹ wo bi wọn ti jẹ aramanda tó! Ẹsẹ 16 ati 18 (NW) wipe: “Ìrísí wọn ati igbekalẹ wọn wulẹ dabi ẹni pe àgbá kẹ̀kẹ́ wà laaarin àgbá kẹ̀kẹ́. Ati niti awọn àgbá irin wọn, wọn ga tobẹẹ debi pe wọn fa ẹ̀rù; awọn àgbá irin wọn sì kun fun oju yika awọn mẹrẹẹrin.” Àgbá kẹ̀kẹ́ kan lẹgbẹẹ kerubu kọọkan yoo jẹ àgbá kẹ̀kẹ́ mẹrin ni awọn ibi mẹrin ti o tanmọra. Awọn àgbá naa tànyòò bii chrysolite, okuta alawọ ìyeyè tabi alawọ ewé ti o fi odikeji hàn rekete tabi ti ko fi odikeji han tobẹẹ. Eyi fi imọlẹ ati ẹwa kun iran ológo yii. Niwọnbi awọn àgbá irin ti awọn àgbá kẹ̀kẹ́ naa ti “kun fun oju yika,” wọn kii lọ si iha eyikeyii bii afọ́jú. Awọn àgbá kẹ̀kẹ́ naa sì ga gògòrò, nipa bayii wọn ni agbara lati kari ibi ti o jinna pupọ ni ìyípo kanṣoṣo lori igun ìyípo wọn. Bii awọn kerubu mẹrin naa, wọn lè yára rìn gẹgẹ bi mànàmáná.
Awọn Àgbá-kẹ̀kẹ́ ninu Awọn Àgbá-kẹ̀kẹ́
6. (a) Bawo ni o ṣe jẹ pe kẹkẹ-ẹṣin naa ní awọn àgbá kẹ̀kẹ́ ninu awọn àgbá kẹ̀kẹ́? (b) Awọn àgbá kẹ̀kẹ́ naa mu apa iha yíyí wọn ba ki ni mu?
6 Ohun miiran kan tun jẹ aramanda. Àgbá kẹ̀kẹ́ kọọkan ní àgbá kẹ̀kẹ́ kan ninu rẹ̀—ọkan ti fífẹ̀ rẹ̀ rí bakan naa ti a dabuu sinu àgbá kẹ̀kẹ́ ti o pilẹ. Kiki ni ọna yii ni a lè sọ pe awọn àgbá kẹ̀kẹ́ naa “lọ ni ẹgbẹ wọn mẹrẹẹrin.” (Ẹsẹ 17, NW) Loju ẹsẹ, awọn àgbá kẹ̀kẹ́ naa le yi iha ti wọn nlọ pada nitori pe ẹgbẹ àgbá kẹ̀kẹ́ ti ndojukọ iha kọọkan wà. Awọn àgbá kẹ̀kẹ́ naa mu yíyí wọn wà ni ibamu pẹlu ti awọn kerubu mẹrin naa. Ara kẹkẹ-ẹṣin Ọlọrun le gun ori awọn àgbá kẹ̀kẹ́ mẹrin naa, nipasẹ agbéhunró ti ko ṣee fi oju ri ti o fi ara jọ ọkọ oju omi alagbara kan ti a gbé lefoo nipasẹ tìmùtìmù afẹ́fẹ́ gẹgẹ bi o ti nlọ téńté lori omi.
7. Ki ni orisun agbara fun awọn àgbá kẹ̀kẹ́ naa?
7 Nibo ni awọn àgbá kẹ̀kẹ́ naa ti ri agbara lati ba gbogbo ìrìn awọn kerubu mẹrẹẹrin mu? Lati ọwọ ẹmi mimọ Ọlọrun Olodumare. Ẹsẹ 20 (NW) wipe: “Nibikibi ti ẹ̀mí ba tẹsi lati lọ, wọn yoo lọ . . . Ẹmi ẹda alaaye naa wà ninu awọn àgbá kẹ̀kẹ́.” Ipá agbekankan ṣiṣẹ́ alaiṣeefojuri ti Ọlọrun kan naa ti o wà ninu awọn kerubu wà ninu awọn àgbá kẹ̀kẹ́ wọnni.
8. Orukọ wo ni a fifun awọn àgbá kẹ̀kẹ́ naa, eesitiṣe?
8 Awọn àgbá kẹ̀kẹ́ naa ni a tọkasi nipasẹ èdè-ìsọ̀rọ̀ naa “agbo ètò àgbá kẹ̀kẹ́.” (Esekiẹli 10:13, NW) Ni kedere, ohun ti o mu ki a pe e bẹẹ jẹ nitori ohun ti àgbá kẹ̀kẹ́ kọọkan nṣe. O nyi bírípo tabi yi gbirigbiri lọ. Ni titọkasi apá kẹkẹ-ẹṣin oke ọ̀run yii ni iru ọna kan bẹẹ pe afiyesi sí ìyárasáré tí kẹkẹ-ẹsin oke ọ̀run naa fi nlọ. Bi o tilẹ jẹ pe awọn àgbá kẹ̀kẹ́ rẹ̀ nyi bírípo lọna ti o yarakankan, wọn lè ri ọ̀nà wọn ni gbogbo ìgbà nitori wọn kun fun oju.
9. Bawo ni Esekiẹli ṣe ṣapejuwe ohun ti o wa lori awọn àgbá kẹ̀kẹ́ mẹrin ti nyara rin ti kẹkẹ-ẹṣin naa?
9 Ṣugbọn nisinsinyi ẹ jẹ ki a ṣàyẹ̀wò ki a sì ri ohun ti o wa lori awọn àgbá kẹ̀kẹ́ mẹrin giga lọna ti o kun fun ẹ̀rù, ti nyarakankan rìn wọnni. Ẹsẹ 22 ti Esekiẹli ori 1 wipe: “Aworan ofuurufu ni ori [awọn] ẹda alaaye naa dabi awọn kristali ti o banilẹru, ti o nà sori wọn loke.” Ofuurufu naa, bi o tilẹ jẹ pe o le koránkorán, han sodikeji, “bi awọn kristali ti wọn banilẹru” ṣugbọn lọna ti kò ṣe rekete. O ńkọ mànà bi ẹgbẹẹgbẹrun awọn okuta diamọndi gẹgẹ bi oorun ti ńta si wọn. Amuni kun fun ìbẹ̀rù-ọlọ́wọ̀ nitootọ!
Olùgun Kẹkẹ-ẹṣin Ologo Naa
10. (a) Bawo ni a ṣe ṣapejuwe ìtẹ́ ati Ẹni ti o wa lori ìtẹ́ naa? (b) Ki ni otitọ naa pe Olùgun kẹkẹ-ẹṣin naa ni a fi ògo wọ̀ tumọ si?
10 Lọna ti o han gbangba, kẹkẹ-ẹṣin naa duro ki Ẹni ti o gùn ún baa lè ba Esekiẹli sọrọ. Loke ofuurufu naa, ohun ti o jọ ìtẹ́, ti o ni irisi sapphire, tabi àwọ̀ búlúù ṣíṣú wà nibẹ. Lori itẹ naa, Ẹnikan ti irisi rẹ̀ dabi ti eniyan kan wà nibẹ. Irisi bii ti eniyan lè ran Esekiẹli lọwọ daradara lati mọriri ifihan kedere atọrunwa yii. Ṣugbọn irisi eniyan yẹn ni a fi ògo bò, debi pe o ntanyoo bii electrum, àyọ́lù fadaka ati wura ti ndan. Ẹ wo iru ẹwà amúnigbọ̀n jìnnìjìnnì ti eyi jẹ! Lati ìgbáròkó irisi ti o dabi eniyan yii, ògo ẹlẹwaa yii gbilẹ soke ati si isalẹ. Odidi irisi naa ni a tipa bayii fi ògo yika. Eyi fihan pe Jehofa jẹ ologo ti ko ṣee ṣapejuwe. Ju bẹẹ lọ, òṣùmàrè ẹlẹwa kan wà pẹlu Olùgun kẹkẹ-ẹṣin naa. Iru ìrọlẹ̀wọ̀ọ̀ ati ìparọ́rọ́ wo ni oṣumare kan maa nfihan gbangba lẹhin òjò oníjì kan! Nipa nini ẹmi ironu píparọ́rọ́ yẹn, Jehofa pa awọn animọ rẹ̀ ti ọgbọ́n, idajọ-ododo, agbára, ati ifẹ mọ ni ìwàdéédéé pipe.
11. Bawo ni iran kẹkẹ-ẹṣin ati ìtẹ́ Jehofa ṣe nipa lori Esekiẹli?
11 Kẹkẹ-ẹṣin ati itẹ Jehofa ni imọlẹ ati awọn àwọ̀ mèremère yika. Ẹ wo bi o ti yatọ gédégédé si ti Satani, alade okunkun ati ti ijinlẹ awo! Bawo sì ni gbogbo eyi ṣe nipa lori Esekiẹli? Oun wi pe, “Nigba ti mo sì rii, mo dojubolẹ, mo sì gbọ́ ohùn ẹnikan ti nsọrọ.”—Esekiẹli 1:28.
Ohun Ti Kẹkẹ-ẹṣin Naa Duro Fun
12. Ki ni kẹkẹ-ẹṣin oke ọ̀run ti Jehofa yaworan rẹ̀?
12 Ki ni kẹkẹ-ẹṣin agbayanu yii yaworan rẹ̀? Eto-ajọ ọ̀run ti Jehofa Ọlọrun ni oke ọ̀run. O parapọ jẹ gbogbo awọn ẹda ẹmi rẹ̀ mimọ ni ilẹ akoso aiṣeefojuri—awọn serafu, kerubu, ati awọn angẹli. Niwọnbi Jehofa ti jẹ Ọlọrun Ọga Ogo, gbogbo awọn ẹda ẹmi rẹ̀ jẹ́ ọmọ-abẹ fun un, oun sì ńgùn wọn ni itumọ ti jijọba le wọn lori lọna oloore ti o sì ńlò wọn ni ibamu pẹlu ète rẹ̀.—Saamu 103:20.
13. (a) Eeṣe ti a fi le sọ pe Jehofa ńgùn eto-ajọ rẹ̀? (b) Bawo ni iran kẹkẹ-ẹṣin alágbàá mẹrin ti Jehofa ti nrin ṣe nipa lori rẹ?
13 Jehofa ńgùn eto-ajọ yii bi ẹni pe o wà lori kẹkẹ-ẹṣin kan, ni mímú un ki o ṣilọ si ibikibi ti ẹmi rẹ̀ ba sún un lati ṣilọ. Kii sare ẹhànnà, laisi ijanu tabi abojuto ọlọ́gbọ́nlóye. Ọlọrun kii jẹ ki eto-ajọ rẹ̀ lọ ni ọna-iha eyikeyii ti o ṣeeṣe ki o ni itẹsi lati lọ. Kaka bẹẹ, o ntẹle awọn itọsọna rẹ̀. Lapapọ, gbogbo wọn nlọ ni iṣọkan siwaju si aṣepari awọn ète Ọlọrun lẹkun-unrẹrẹ. Ẹ wo iru eto-ajọ ti ọ̀run yiyanilẹnu tí a ṣipaya nipasẹ iran yii ti kẹkẹ-ẹṣin oke ọ̀run alágbàá kẹ̀kẹ́ mẹrin ti Jehofa ti o wà lori irin! Ni ibamu pẹlu eyi, eto-ajọ Jehofa ni a yaworan rẹ̀ gẹgẹ bi eyi ti o ni igun mẹrin lọgbọọgba, ni iwadeedee pipe.
A Yàn án Gẹgẹ bi Ẹ̀ṣọ́kùnrin Kan
14. Ta ni wolii Esekiẹli yaworan rẹ̀?
14 Ṣugbọn ta ni wolii Esekiẹli yaworan rẹ̀? Lati inu awọn otitọ ninu ìtàn, o han gbangba pe ẹgbẹ́ awọn Ẹlẹrii Jehofa ẹni ami ororo ti a fi ẹmi yàn ni a ti sopọ mọ́ kẹkẹ-ẹṣin oke ọ̀run naa. Nipa bayii, Esekiẹli yaworan aṣẹku ẹni-ami-ororo ti awọn Ẹlẹrii Jehofa lati 1919. Nipa tẹmi, eto-ajọ ọ̀run ti Ọlọrun kan aṣẹku ẹni-ami-ororo lára ní ọdun yẹn, lati sọ wọn ji gẹgẹ bi Ẹlẹrii Jehofa fun gbogbo aye. (Fiwe Iṣipaya 11:1-12.) Eto-ajọ bii kẹkẹ-ẹṣin yẹn wà lori irin lati igba naa, ani gẹgẹ bi o ti ri lonii gan-an. Nitootọ, awọn àgbá kẹ̀kẹ́ itẹsiwaju rẹ̀ nyara yi ju ti igbakigba ri lọ. Jehofa ńgùn ún tiyaratiyara lọ siwaju!
15. Ki ni ohùn Olùgun kẹkẹ-ẹṣin oke ọ̀run naa wi, iṣẹ akanṣe wo sì ni Esekiẹli gbà?
15 Esekiẹli fẹ lati mọ idi ti kẹkẹ-ẹṣin oke ọ̀run naa fi wá duro ni iwaju rẹ̀. Oun mọ̀ nigba ti ohùn kan jade lati ọ̀dọ̀ Ẹni ti o jokoo lori kẹkẹ-ẹṣin naa. Bi iran ẹlẹ́rù jẹ̀njẹ̀n yii ti bò ó mọlẹ, Esekiẹli dọbalẹ o si doju bọlẹ. Fetisilẹ gẹgẹ bi ohùn Olùgun kẹkẹ-ẹṣin ti oke ọ̀run naa ti nwipe: “Ọmọkunrin eniyan, dide duro lori ẹsẹ rẹ ki emi lè ba ọ sọrọ.” (Esekiẹli 2:1, NW) Lẹhin naa Jehofa fun Esekiẹli niṣẹ lati jẹ ẹ̀ṣọ́kùnrin ati lati kilọ fun ile Israẹli ọlọtẹ. A tilẹ tun fun un niṣẹ lati sọ orukọ atọrunwa naa. Orukọ Esekiẹli tumọsi “Ọlọrun Funni lokun.” Bẹẹ ni o ri pe Ọlọrun ti fun ẹgbẹ Esekiẹli lokun o sì ti ran wọn lọ, ni yiyan wọn gẹgẹ bi ẹ̀ṣọ́kùnrin fun Kristẹndọm.
16, 17. (a) Bawo ni iran kẹkẹ-ẹṣin oke ọ̀run ti ṣanfaani fun Esekiẹli? (b) Ni ọjọ wa, bawo ni liloye iran kẹkẹ-ẹṣin oke ọ̀run naa ṣe nipa lori ẹgbẹ Esekiẹli ati ogunlọgọ nla?
16 Iran kẹkẹ-ẹṣin oke ọ̀run naa mu Esekiẹli ṣe wọ̀ọ̀ o sì yà á lẹnu, ṣugbọn o tun mura rẹ̀ silẹ fun iṣẹ ti a fun un gẹgẹ bi ẹ̀ṣọ́kùnrin kan lati ṣe ikilọ iparun Jerusalẹmu ti nbọ. Ohun kan naa ni o ti jẹ otitọ niti ẹgbẹ ẹ̀ṣọ́kùnrin lonii. Liloye iran kẹkẹ-ẹṣin oke ọ̀run ti Jehofa ti o wà lori irin wọn ti ni iyọrisi nlanla lori aṣẹku ẹni-ami-ororo. Ni 1931 wọn mọ ohun pupọ sii nipa iran Esekiẹli, gẹgẹ bi a ti ṣi i paya ninu Iwe Kìn-ínní Vindication. Wọn kun fun iru imọriri amúniṣewọ̀ọ̀ bẹẹ nigba naa debi pe lati itẹjade ti October 15, 1931, titi di August 1, 1950, iṣẹ́-ọnà iwaju The Watchtower ngbe aworan oniṣẹ-ọna ti iran Esekiẹli nipa kẹkẹ-ẹṣin oke ọ̀run naa jade ni igun apa oke ni ọwọ ọtun. Nipa bayii, ẹgbẹ Esekiẹli ṣiṣẹ lori iṣẹ ti a fifun wọn, wọn sì ti nṣiṣẹsin gẹgẹ bi ẹ̀ṣọ́kùnrin kan, ni pipolongo ikilọ atọrunwa. Akoko fun iparun ajo-bi-ina ti Kristẹndọm lati ọwọ́ Jehofa ti o jokoo lori itẹ kẹkẹ-ẹṣin oke ọ̀run rẹ̀ ti sunmọle ju ti igbakigba ri lọ!
17 Lonii, “ogunlọgọ nla” ti awọn eniyan bi agutan ndarapọ mọ aṣẹku ẹni-ami-ororo naa. (Iṣipaya 7:9, NW) Papọ, wọn npolongo ikilọ iparun ti nbọ sori Kristẹndọm ati eto-igbekalẹ awọn nnkan aburúbèṣù yii. Iṣẹ ikilọ yẹn ntẹsiwaju pẹlu iyarakankan, ati gẹgẹ bi Iṣipaya 14:6, 7 ti fihan, awọn angẹli nti i lẹhin.
Ririnlọ Pẹlu Kẹkẹ-ẹṣin Oke-ọrun Naa
18. Ki ni a gbọdọ ṣe lati ni itilẹhin awọn angẹli ti nbaa lọ, ki ni a sì gbọdọ maa yara dahun sí?
18 Awọn angẹli onitẹriba nrin papọ ni ifohunṣọkan gẹgẹ bi apakan eto-ajọ ọ̀run ti Ọlọrun nigba ti wọn nṣetilẹhin fun awọn iranṣẹ Jehofa ti ori ilẹ-aye ni mimu iṣẹ-aṣẹ wọn lati polongo awọn ikilọ idajọ atọrunwa ṣẹ. Bi awa ba fẹ aabo ati itọsọna ti nbaa lọ lati ọ̀dọ̀ awọn angẹli alagbara iranṣẹ Ọlọrun wọnyi, awa pẹlu gbọdọ rìn papọ ni ifohunṣọkan ki a sì maa ṣisẹrin ni iyara kan naa pẹlu ètò àgbá kẹ̀kẹ́ iṣapẹẹrẹ naa. Ju bẹẹ lọ, gẹgẹ bi apakan eto-ajọ Jehofa ti a lè fojuri ti nrin ni ifẹgbẹkẹgbẹ pẹlu kẹkẹ-ẹṣin oke-ọrun rẹ̀, awa gbọdọ maa yara dahun si idari ẹmi Ọlọrun. (Fiwe Filipi 2:13.) Bi awa ba jẹ Ẹlẹrii Jehofa, a gbọdọ maa rìn ni iha kan naa gẹgẹ bi kẹkẹ-ẹṣin oke ọ̀run naa. Awa dajudaju ko gbọdọ ṣiṣẹ lodisi awọn ète rẹ̀. Nigba ti a ba fun wa ni itọni ni ọna ti awa nilati lọ, awa nilati tẹle e. Nipa bayii, ijọ ni a kò pin yẹ́lẹyẹ̀lẹ.—1 Kọrinti 1:10.
19. (a) Gan-an gẹgẹ bi àgbá kẹ̀kẹ́-ẹṣin oke ọ̀run ti ni awọn oju yika wọn, fun ki ni awọn eniyan Jehofa gbọdọ wa lojufo? (b) Ki ni o nilati jẹ ipa-ọna igbesẹ wa ni awọn akoko onirugudu wọnyi?
19 Awọn oju ti wọn yi awọn àgbá kẹ̀kẹ́-ẹṣin Ọlọrun ká fi iwalojufo hàn. Gan-an gẹgẹ bi eto-ajọ ti ọ̀run ti walojufo, nitori naa awa gbọdọ wa lojufo lati ṣetilẹhin fun eto-ajọ Jehofa ti ori ilẹ-aye. Ninu ijọ, awa lè fi itilẹhin yẹn hàn nipa fifọwọsowọpọ pẹlu awọn alàgbà adugbo. (Heberu 13:17) Ati ni awọn akoko onírúgúdù wọnyi, awọn Kristian nilati wà timọtimọ pẹlu eto-ajọ Jehofa. Awa kò ni gbe itumọ tiwa funraawa kari awọn iṣẹlẹ, nitori ni ọna yẹn awa kò ni maa rin pẹlu kẹkẹ-ẹṣin ọ̀run ti Jehofa. Ẹ jẹ ki a maa bi araawa leere nigba gbogbo pe, ‘Ọna wo ni kẹkẹ-ẹṣin nrin lọ?’ Bi awa ba ntẹsiwaju pẹlu eto-ajọ Ọlọrun ti a le fojuri, awa yoo tun maa rìn pẹlu eto-ajọ ti a ko le fojuri.
20. Imọran rere wo ni apọsteli Pọọlu fifunni ni Filipi 3:13-16?
20 Nipa eyi, Pọọlu kọwe pe: “Ẹyin ara, emi kò tii ka araami si bi ẹni pe mo ti gbá a mu; ṣugbọn ohun kan wà nipa rẹ̀: ni gbigbagbe awọn ohun ti nbẹ lẹhin ati ninaga siwaju si awọn ohun ti nbẹ niwaju, emi nlepa lọ sibi opin ere ije naa fun ẹbun ere ije ìpè soke ti Ọlọrun nipasẹ Kristi Jesu. Nigba naa, ẹ jẹ ki iye awa ti a dàgbàdénú ni ẹmi ironu ero-ori yii; bi ero ori yin ba si tẹsi eyi ti o yatọ ni ọna eyikeyii, Ọlọrun yoo ṣí ẹmi-ironu oke yii paya fun yin. Bi o ti wu ki o ri, iwọn yoowu ti a ti de ninu itẹsiwaju, ẹ jẹ ki a maa baa lọ ni ririn letoleto ninu ọna igbaṣiṣẹ deedee kan naa yii.”—Filipi 3:13-16, NW.
21. Nipa titẹle ọ̀nà igbesẹ deedee wo ni o to le ṣeeṣe lati ni itẹsiwaju tẹmi pẹlu eto-ajọ Ọlọrun?
21 Nihin-in ọrọ naa “ọna igbaṣiṣẹ deedee” ko tumọsi ọ̀nà iṣẹ aṣetunṣe ti nsuni ti ko dara ninu eyi ti awa kò lè gba araawa silẹ. Awọn iranṣẹ Jehofa ni ọna igbaṣiṣẹ deedee didara nipasẹ eyi ti wọn ti nni itẹsiwaju tẹmi. O jẹ ọna igbaṣiṣẹ deedee ti kikopa ninu idakẹkọọ Bibeli funra-ẹni, lilọ si awọn ipade ijọ, wiwaasu ihinrere Ijọba naa deedee, ati fifi awọn animọ eto-ajọ Ọlọrun ti ọ̀run han. Iru ọna igbaṣiṣẹ deedee bẹẹ mu ki o ṣeeṣe fun wọn lati tẹle idari eto-ajọ oke ọ̀run ti Jehofa ti o da bii kẹkẹ-ẹṣin. Nipa titẹpẹlẹmọ ọn ni iru ọna yii, awa yoo lé gongo wa ba, yala o jẹ ẹbun iye ti aileeku ninu awọn ọ̀run tabi iye ainipẹkun ninu paradise ilẹ-aye.
22. (a) Lati ṣeto aṣẹku ẹni ami-ororo ati ogunlọgọ nla ti awọn agutan miiran jọ ni iṣọkan, ki ni a gbọdọ ṣe? (b) Ki ni kii kọja akiyesi Jehofa?
22 Gẹgẹ bi Johanu 10:16 ṣe fihan, “awọn agutan miiran” ati ẹgbẹ Esekiẹli ni a o ṣetojọ ni iṣọkan. Nipa bayii, o ṣe pataki pe ki gbogbo wa ninu eto-ajọ Jehofa loye itumọ kikun ati ijẹpataki iran ti a ṣakọsilẹ rẹ̀ ninu Esekiẹli ori kìn-ínní bi a ba nilati rin papọ ni ifohunṣọkan pẹlu kẹkẹ-ẹṣin oke ọ̀run ti Ọlọrun. Iran rẹ̀ ran wa lọwọ lati mọriri pe a nilati rìn ni ibamu pẹlu eto-ajọ Ọlọrun, ti a le fojuri ati eyi ti a kò lè fojuri. Fi i sọkan pẹlu pe, oju Jehofa “nlọ siwa sẹhin ni gbogbo aye, lati fi agbara fun awọn ẹni ọlọkan pipe si ọdọ rẹ̀.” (2 Kironika 16:9) Ko si ohun kanṣoṣo ti o kọja akiyesi Jehofa, paapaa ohunkohun ti o niiṣe pẹlu ète rẹ̀ lati da ara rẹ̀ lare gẹgẹ bi Ọba-alaṣẹ Agbaye.
23. Pẹlu kẹkẹ-ẹṣin oke ọ̀run ti Jehofa lori irin, ki ni a gbọdọ ṣe?
23 Kẹkẹ-ẹṣin oke ọ̀run ti Jehofa dajudaju wa lori irin lonii. Laipẹ ohun gbogbo ni a o muwa si ògo ni ibamu pẹlu Ẹni ologo ti ngun kẹkẹ-ẹṣin yẹn—gbogbo rẹ̀ si idalare rẹ̀ gẹgẹ bi Oluwa Ọba-alaṣẹ ti agbaye. Awọn serafu, kerubu, ati awọn angẹli rẹ̀ ńtì wá lẹhin ninu iṣẹ bàǹtàbanta ti wiwaasu yika aye. Ẹ jẹ ki a tẹsiwaju, nigba naa, pẹlu eto-ajọ ọ̀run ti Jehofa. Ṣugbọn bawo ni a ṣe lè maa ṣisẹrin ni ìyára kan naa pẹlu kẹkẹ-ẹṣin oke ọ̀run ti nyarasare yẹn?
Bawo Ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun?
◻ Awọn animọ wo ni awọn ẹda alaaye mẹrin ti Esekiẹli rí duro fun?
◻ Kẹkẹ-ẹṣin oke ọ̀run ti Jehofa yaworan ki ni?
◻ Ta ni wolii Ọlọrun Esekiẹli ṣapẹẹrẹ rẹ̀?
◻ Bawo ni liloye kẹkẹ-ẹṣin oke ọ̀run ti Jehofa ṣe nipa lori ẹgbẹ Esekiẹli ati ogunlọgọ nla?