Àwọn ohun pàtàkì tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún tó kọjá
Jèhófà fi ìran kan han Ìsíkíẹ́lì nípa kẹ̀kẹ́ ẹṣin gìrìwò kan ní ọ̀run tó ṣàpẹẹrẹ apá tí a kò lè fojú rí lára ètò Jèhófà. Pẹ̀lú bí kẹ̀kẹ́ ẹṣin yẹn ṣe tóbi gìrìwò, ó ń yára sáré, ó sì lè gbabí-gbọ̀hún láàárín ìṣẹ́jú akàn. (Ìsík. 1:15-28) Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń mórí ẹni wú tó wáyé lọ́dún tó kọjá jẹ́rìí sí i pé bíi ti kẹ̀kẹ́ ẹṣin ọ̀run yẹn, apá ti orí ilẹ̀ ayé lára ètò Jèhófà Ọlọ́run pẹ̀lú kò dúró sójú kan.