ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • od orí 1 ojú ìwé 6-11
  • A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
  • A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • APÁ TI Ọ̀RUN LÁRA ÈTÒ JÈHÓFÀ
  • ÈTÒ JÈHÓFÀ Ń TẸ̀ SÍWÁJÚ
  • Ẹ Máa Wádìí Dájú Àwọn Ohun Tí Ó Ṣe Pàtàkì Jù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • Wà Láìséwu Gẹ́gẹ́ Bí Apá Kan Ètò Àjọ Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Kẹkẹ-Ẹṣin Òkè Ọ̀run Ti Jehofa Wa Lori Ìrìn
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Maa Ṣísẹ̀rìn ní Ìyára kan naa Pẹlu Kẹkẹ-Ẹṣin Òkè Ọ̀run Ti Jehofa
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Àwọn Míì
A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
od orí 1 ojú ìwé 6-11

ORÍ 1

A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà

Ọ̀PỌ̀ ètò ẹ̀sìn, òṣèlú, ìṣòwò àti ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà ló wà kárí ayé. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn yàtọ̀ síra. Ohun tí wọ́n torí ẹ̀ dá wọn sílẹ̀ yàtọ̀ síra, èrò wọn àti ìlànà tó ń darí wọn kò sì jọra. Ṣùgbọ́n, ètò kan wà tó yàtọ̀ pátápátá sí gbogbo wọn. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi hàn kedere pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ètò náà.

2 Inú wa dùn pé ìwọ náà ti ń dara pọ̀ mọ́ ètò Jèhófà. A dúpẹ́ pé o ti mọ ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́, o sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe é. (Sm. 143:10; Róòmù 12:2) Òjíṣẹ́ tó ń ṣe déédéé ni ẹ́, ìwọ àti ẹgbẹ́ ará kárí ayé tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn lẹ sì jọ ń sìn Jèhófà. (2 Kọ́r. 6:4; 1 Pét. 2:17; 5:9) Torí náà, bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ṣèlérí, ò ń gbádùn ọ̀pọ̀ ìbùkún, ayọ̀ rẹ sì pọ̀ gan-an. (Òwe 10:22; Máàkù 10:30) Bó o ṣe ń ṣe ìfẹ́ Jèhófà látọkàn wá nísinsìnyí, ṣe lò ń múra sílẹ̀ de ọjọ́ ọ̀la ológo, èyí tó máa wà títí láé.​—1 Tím. 6:18, 19; 1 Jòh. 2:17.

3 Ẹlẹ́dàá wa Atóbilọ́lá ní ètò kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tó sì kárí ayé, èyí tí òun fúnra rẹ̀ ń darí. Lédè míì, Jèhófà tó jẹ́ Olórí ohun gbogbo ló ń darí ètò náà. A fọkàn tán an pátápátá. Òun ni Onídàájọ́ wa, òun ló ń fún wa lófin, òun sì ni Ọba wa. (Àìsá. 33:22) Torí pé ó jẹ́ Ọlọ́run ètò, ó ti ṣètò àwọn nǹkan lọ́nà táá mú ká lè máa “bá a ṣiṣẹ́,” bá a ṣe ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀.​—2 Kọ́r. 6:1, 2.

4 Bí òpin ètò àwọn nǹkan yìí ṣe túbọ̀ ń sún mọ́lé, à ń tẹ̀ síwájú bí Kristi Jésù tí Ọlọ́run fi ṣe Ọba ṣe ń darí wa. (Àìsá. 55:4; Ìfi. 6:2; 11:15) Jésù náà ló sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé iṣẹ́ ìwàásù tí àwọn ọmọlẹ́yìn òun máa ṣe á ju èyí tóun ṣe nígbà tóun wà láyé. (Jòh. 14:12) Ọ̀rọ̀ yìí á ṣẹ torí pé àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ náà máa pọ̀ sí i, wọ́n á lo àkókò tó gùn ju ti Jésù lọ, wọ́n á sì wàásù dé àwọn ìpínlẹ̀ tó gbòòrò gan-an. Kódà, wọ́n á polongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run dé àwọn ìkángun ayé.​—Mát. 24:14; 28:19, 20; Ìṣe 1:8.

5 Ẹ̀rí fi hàn pé ọ̀rọ̀ yìí ti ṣẹ. Àmọ́, bí Jésù ṣe sọ, iṣẹ́ ìpolongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run máa dópin ní àkókò tí Jèhófà yàn. Àsọtẹ́lẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi hàn pé ọjọ́ ńlá Jèhófà tó ń bani lẹ́rù ti sún mọ́lé.​—Jóẹ́lì 2:31; Sef. 1:14-18; 2:2, 3; 1 Pét. 4:7.

Ó yẹ ká túbọ̀ sapá láti máa ṣe ohun tí Ọlọ́run ní ká ṣe. Èyí gba pé ká mọ ọ̀nà tí ètò Ọlọ́run ń gbà ṣe nǹkan ní àmọ̀dunjú

6 Bá a ṣe ń lóye ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, ó yẹ ká túbọ̀ sapá láti máa ṣe ohun tí Ọlọ́run ní ká ṣe. Èyí gba pé ká mọ ọ̀nà tí ètò Ọlọ́run ń gbà ṣe nǹkan ní àmọ̀dunjú, ká sì máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ dáadáa pẹ̀lú ètò náà. Ọ̀nà tí ètò náà ń gbà ṣe nǹkan máa ń bá ìlànà Ìwé Mímọ́ mu títí kan àwọn àṣẹ, òfin, ìtọ́ni, àtàwọn ẹ̀kọ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.​—Sm. 19:7-9.

7 Tí àwọn èèyàn Jèhófà bá ń tẹ̀ lé àwọn ìtọ́ni tó wà nínú Bíbélì, wọ́n á máa gbé pọ̀ ní àlàáfíà àti ìṣọ̀kan. (Sm. 133:1; Àìsá. 60:17; Róòmù 14:19) Kí ló mú kí ìṣọ̀kan tó wà láàárín àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà níbi gbogbo túbọ̀ máa lágbára? Ìfẹ́ ni. Ìfẹ́ yìí ló ń mú ká máa ṣe àwọn nǹkan tá à ń ṣe, kódà ńṣe la gbé ìfẹ́ wọ̀ bí aṣọ. (Jòh. 13:34, 35; Kól. 3:14) Torí pé Jèhófà ṣojú rere sí wa lọ́nà yìí, à ń bá apá ti ọ̀run lára ètò rẹ̀ rìn.

APÁ TI Ọ̀RUN LÁRA ÈTÒ JÈHÓFÀ

8 Wòlíì Àìsáyà, Ìsíkíẹ́lì àti Dáníẹ́lì rí apá ti ọ̀run lára ètò Jèhófà nínú ìran. (Àìsá., orí 6; Ìsík., orí 1; Dán. 7:9, 10) Bákan náà, àpọ́sítélì Jòhánù rí apá ti ọ̀run lára ètò Jèhófà nínú ìran, ó sì sọ díẹ̀ lára ohun tó rí fún wa nínú ìwé Ìfihàn. Ó rí Jèhófà lórí ìtẹ́ ológo, àwọn áńgẹ́lì sì wà pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n ń kéde pé: “Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Jèhófà Ọlọ́run, Olódùmarè, tó ti wà tipẹ́, tó wà báyìí, tó sì ń bọ̀.” (Ìfi. 4:8) Jòhánù tún rí “ọ̀dọ́ àgùntàn kan” tó “dúró ní àárín ìtẹ́ náà.” Jésù Kristi ni Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run náà.​—Ìfi. 5:6, 13, 14; Jòh. 1:29.

9 Nínú ìran yìí, Jèhófà jókòó sórí ìtẹ́, èyí tó fi hàn pé òun ni Orí nínú ètò náà. Nígbà tí ìwé 1 Kíróníkà 29:11, 12 ń sọ nípa Ọlọ́run àti ipò gíga rẹ̀, ó ní: “Jèhófà, tìrẹ ni títóbi àti agbára ńlá àti ẹwà àti ògo àti ọlá ńlá, nítorí gbogbo ohun tó wà ní ọ̀run àti ní ayé jẹ́ tìrẹ. Jèhófà, tìrẹ ni ìjọba. Ìwọ ni Ẹni tó fi ara rẹ̀ ṣe olórí lórí ohun gbogbo. Ọ̀dọ̀ rẹ ni ọrọ̀ àti ògo ti wá, o sì ń ṣàkóso ohun gbogbo, ọwọ́ rẹ ni agbára àti títóbi wà, ọwọ́ rẹ ló lè sọni di ńlá, òun ló sì lè fúnni lágbára.”

10 Torí pé Jésù Kristi ń bá Jèhófà ṣiṣẹ́, ipò gíga ló wà ní ọ̀run, Ọlọ́run sì ti gbé àṣẹ tó pọ̀ lé e lọ́wọ́. Kódà, Ọlọ́run ti “fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì fi í ṣe orí lórí ohun gbogbo nínú ìjọ.” (Éfé. 1:22) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa Jésù pé: ‘Ọlọ́run gbé e sí ipò gíga, ó sì fún un ní orúkọ tó lékè gbogbo orúkọ mìíràn, kó lè jẹ́ pé ní orúkọ Jésù, kí gbogbo eékún máa wólẹ̀, ti àwọn tó wà lọ́run àti àwọn tó wà láyé pẹ̀lú àwọn tó wà lábẹ́ ilẹ̀, kí gbogbo ahọ́n sì máa jẹ́wọ́ ní gbangba pé Jésù Kristi ni Olúwa fún ògo Ọlọ́run tó jẹ́ Baba.’ (Fílí. 2:9-11) Torí náà, ọkàn wa balẹ̀ pé Jésù Kristi aṣáájú wa jẹ́ olódodo.

11 Nínú ìran, wòlíì Dáníẹ́lì rí Jèhófà, Ẹni Ọjọ́ Àtayébáyé lórí ìtẹ́ rẹ̀ lókè ọ̀run, ó tún rí àwọn áńgẹ́lì tí wọ́n tó “ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹẹgbẹ̀rún [tí wọ́n] ń ṣe ìránṣẹ́ fún un, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá lọ́nà ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá sì dúró níwájú rẹ̀.” (Dán. 7:10) Bíbélì pe àwọn áńgẹ́lì tó jẹ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun yìí ní ‘ẹ̀mí tó ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́, tí a rán jáde láti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn tó máa rí ìgbàlà.’ (Héb. 1:14) Ọlọ́run ṣètò àwọn áńgẹ́lì yìí sí “ìtẹ́ tàbí ipò olúwa tàbí ìjọba tàbí àṣẹ.”​—Kól. 1:16.

12 Tá a bá fara balẹ̀ ronú lórí bí Jèhófà ṣe ṣètò àwọn áńgẹ́lì tó wà nínú apá ti ọ̀run lára ètò rẹ̀, a máa wá lóye bọ́rọ̀ ṣe rí lára Àìsáyà nígbà tó rí i nínú ìran pé ‘Jèhófà jókòó sórí ìtẹ́ gíga, tó ta yọ’ tí ‘àwọn séráfù sì dúró lókè rẹ̀.’ Àìsáyà sọ pé: “Mo gbé! Mo ti kú tán, torí ọkùnrin tí ètè rẹ̀ kò mọ́ ni mí, àárín àwọn èèyàn tí ètè wọn ò mọ́ ni mo sì ń gbé; torí ojú mi ti rí Ọba, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun fúnra rẹ̀!” Ó dájú pé nígbà tí Àìsáyà wá mọ bí ètò Jèhófà ṣe gbòòrò tó, jìnnìjìnnì bò ó, ó sì wá rí i pé òun ò já mọ́ nǹkan kan. Ìran tó rí náà wọ̀ ọ́ lọ́kàn débi pé nígbà tó gbọ́ ìpè kan láti ọ̀run pé kí ẹnì kan lọ jẹ́ iṣẹ́ pàtàkì kan, ìyẹn láti kéde ìdájọ́ Jèhófà, ńṣe ló dáhùn pé: “Èmi nìyí! Rán mi.”​—Àìsá. 6:1-5, 8.

13 Torí pé àwa náà mọ ètò Jèhófà tá a sì mọrírì rẹ̀, àwa náà máa ń ṣe bí Àìsáyà. Bí ètò náà ṣe ń tẹ̀ síwájú lóde òní, à ń sapá láti máa bá a rìn, a sì ń fi hàn ní gbogbo ọ̀nà pé a fọkàn tán ètò Jèhófà.

ÈTÒ JÈHÓFÀ Ń TẸ̀ SÍWÁJÚ

14 Nínú àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní orí kìíní ìwé Ìsíkíẹ́lì, wòlíì náà rí i nínú ìran pé Jèhófà gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin gìrìwò kan. Kẹ̀kẹ́ ológo yìí ṣàpẹẹrẹ apá tí kò ṣeé fojú rí lára ètò Jèhófà. Ó ń gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin yìí ní ti pé ó ń darí rẹ̀ lọ́nà tó ń ṣe àwọn ọmọ abẹ́ rẹ̀ láǹfààní, ó sì ń lò ó láti mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ.​—Sm. 103:20.

15 Ọ̀kọ̀ọ̀kan àgbá kẹ̀kẹ́ ẹṣin náà ní àgbá mìíràn nínú, fífẹ̀ àgbá méjèèjì dọ́gba, a sì fi àgbá kejì dábùú àgbá àkọ́kọ́. Ìdí nìyẹn tá a fi lè sọ pé àwọn àgbá náà “lè lọ sí ibikíbi ní ọ̀nà mẹ́rẹ̀ẹ̀rin.” (Ìsík. 1:17) Àwọn àgbá náà sì lè yí pa dà bìrí. Èyí ò wá túmọ̀ sí pé kẹ̀kẹ́ ẹṣin náà kò ní ìjánu tàbí pé kò sí ẹni tó ń darí rẹ̀ o! Jèhófà ò jẹ́ fi ètò rẹ̀ sílẹ̀ pé kó kàn máa gba ibikíbi lọ. Ìwé Ìsíkíẹ́lì 1:20 sọ pé: “Wọ́n á lọ sí ibi tí ẹ̀mí bá darí wọn sí.” Torí náà, Jèhófà ló ń fi ẹ̀mí rẹ̀ darí ètò náà sí ibi tó bá fẹ́. Ìbéèrè tó wá yẹ ká bi ara wa ni pé, ‘Ṣé mò ń bá ètò náà rìn?’

16 Bíbá ètò Jèhófà rìn kò mọ sórí lílọ sí ìpàdé àti wíwàásù. Ní pàtàkì, bíbá ètò náà rìn gba pé ká máa tẹ̀ síwájú ká sì máa dàgbà nípa tẹ̀mí. Nípa bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká máa “wádìí dájú àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù” ká sì máa rí i dájú pé à ń jẹ àwọn oúnjẹ tẹ̀mí bó ṣe ń dé. (Fílí. 1:10; 4:8, 9; Jòh. 17:3) Ká máa rántí pé níbi tí ètò bá wà, nǹkan á máa lọ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, ìfọwọ́sowọ́pọ̀ sì máa wà. Torí náà, a gbọ́dọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú àwọn nǹkan tara àti tẹ̀mí tí Jèhófà fún wa ká lè ṣe iṣẹ́ rẹ̀ láṣeyọrí. Bá a ṣe ń bá kẹ̀kẹ́ ẹṣin ọ̀run ti Jèhófà rìn, ìgbésí ayé wa á máa bá ìhìn rere tá à ń wàásù mu.

17 Ètò Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́, ìyẹn sì ń mú ká túbọ̀ máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Ká má gbàgbé pé Jèhófà ni Ẹni tó ń gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin ọ̀run náà. Torí náà, bá a ṣe ń bá kẹ̀kẹ́ ẹṣin ọ̀run náà rìn, ṣe là ń fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún Jèhófà a sì gbọ́kàn lé e torí pé òun ni Àpáta wa. (Sm. 18:31) Bíbélì ṣèlérí pé: “Jèhófà yóò fún àwọn èèyàn rẹ̀ ní agbára. Jèhófà yóò fi àlàáfíà jíǹkí àwọn èèyàn rẹ̀.” (Sm. 29:11) Torí pé a wà nínú ètò Jèhófà lónìí, Jèhófà ń fún wa lókun, a sì ń gbádùn àlàáfíà tó fi ń jíǹkí àwa èèyàn rẹ̀ tó wà létòlétò. Ó dá wa lójú pé Jèhófà ò ní yéé bù kún wa bá a ṣe ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀ nísinsìnyí àti títí láé.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́