Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
SEPTEMBER 4-10
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌSÍKÍẸ́LÌ 42-45
“Ìjọsìn Mímọ́ Pa Dà Bọ̀ Sípò!”
“Fi Ọkàn-àyà Rẹ Sí” Tẹ́ńpìlì Ọlọ́run!
3 Ìran gbígbòòrò yìí, tí ó kún orí mẹ́sàn-án nínú ìwé Ìsíkíẹ́lì, pèsè ìlérí afúngbàgbọ́-lókun fún àwọn ará Jùdíà tó wà nígbèkùn. Dájúdájú, a ó mú ìjọsìn mímọ́ gaara padà bọ̀ sípò! Fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún láti ìgbà náà wá, àní títí di òní olónìí pàápàá, ìran yìí ti jẹ́ orísun ìṣírí fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Lọ́nà wo? Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ohun tí ìran alásọtẹ́lẹ̀ yìí túmọ̀ sí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà nígbèkùn. Ìran náà ní apá mẹ́rin pàtàkì: tẹ́ńpìlì, àwọn àlùfáà, ìjòyè, àti ilẹ̀ náà.
it-2 1082 ¶2
Tẹ́ńpìlì
Ìran tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí. Lọ́dún 593 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ìyẹn lẹ́yìn ọdún kẹrìnlá tí wọ́n pa Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì tí Sólómọ́nì kọ́ run, Ìsíkíẹ́lì rí ìran kan pé Ọlọ́run mú òun wá sí orí òkè ńlá kan, tẹ́ńpílì ńlá Jèhófà sì wà lórí òkè ńlá yìí. (Isk 40:1, 2) Ọlọ́run sọ pé kí Ìsíkíẹ́lì sọ gbogbo ohun tó rí nínú ìran náà fún “ilé Ísírẹ́lì” bóyá ìtìjú á bá àwọn Júù tó wà nígbèkùn yìí, wọ́n á sì lè ronú pìwà dà, èyí á sì tún tu àwọn olóòótọ́ àárín wọn nínú. (Isk 40:4; 43:10, 11) Ìran yẹn ṣàlàyé tó kún rẹ́rẹ́ nípa bí wọ́n ṣe díwọ̀n tẹ́ńpílì náà. Wọ́n fi “ọ̀pá esùsú” (tí gígùn rẹ̀ jẹ́ 10.2 ẹsẹ bàtà) àti “ìbú” (gígùn rẹ̀, íǹṣì 20.4) díwọ̀n rẹ̀. (Isk 40:5) Àwọn kan sọ pé àwọn ìdíwọ̀n yìí ni Serubábélì lò láti fi kọ́ tẹ́ńpìlì lẹ́yìn táwọn Júù dé láti ìgbèkùn. Àmọ́ kò sí ẹ̀rí tó fìdí múlẹ̀ pé àwọn ìdíwọ̀n yẹn ló lò lóòótọ́.
“Fi Ọkàn-àyà Rẹ Sí” Tẹ́ńpìlì Ọlọ́run!
10 Ẹ wo bí gbogbo èyí yóò ti mú inú àwọn tí ó wà nígbèkùn dùn tó! A mú un dá ìdílé kọ̀ọ̀kan lójú pé yóò ní ogún ní ilẹ̀ náà. (Fi wé Míkà 4:4.) Ìjọsìn mímọ́ gaara yóò wà ní ibi gíga, tó wà ní àárín gbùngbùn. Sì kíyè sí i pé nínú ìran Ìsíkíẹ́lì àwọn ìjòyè náà, gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà, yóò máa gbé lórí ilẹ̀ tí àwọn ènìyàn náà fi tọrẹ. (Ìsíkíẹ́lì 45:16) Nítorí náà, nínú ilẹ̀ tí a ti mú padà bọ̀ sípò yìí, àwọn ènìyàn yóò máa ṣèrànwọ́ fún iṣẹ́ àwọn tí Jèhófà ti yàn láti mú ipò iwájú, wọ́n yóò máa kọ́wọ́ tì wọ́n lẹ́yìn nípa fífọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ìtọ́sọ́nà wọn. Látòkè délẹ̀, ilẹ̀ yìí jẹ́ àpẹẹrẹ ìṣètò, ìfọwọ́sowọ́pọ̀, àti ààbò tí ó ga lọ́lá.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-2 467 ¶4
Orúkọ
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ èèyàn Ọlọ́run kò pa àwọn àṣẹ òdodo Ọlọ́run mọ́, ńṣe ni wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ sọ orúkọ Ọlọ́run di ẹlẹ́gbin. (Isk 43:8; Am 2:7) Ọlọ́run fìyà jẹ wọ́n torí pé wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́, èyí wá jẹ́ kí àwọn orílẹ̀-èdè tó kù bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí Ọlọ́run. (Fi wé Sm 74:10, 18; Ais 52:5.) Ńṣe ni àwọn orílẹ̀-èdè yìí ń sọ̀rọ̀ òdì sí Jèhófà pé kò lágbára láti gba àwọn èèyàn rẹ̀ là, láìmọ̀ pé Jèhófà funra rẹ̀ ló ń fìyà jẹ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ọlọ́run dá orúkọ ara rẹ̀ láre, ó sì mú ẹ̀gàn yìí kúrò nígbà tó dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ṣẹ́ kù pa dà sí ilẹ̀ wọn.—Isk 36:22-24.
it-2 140
Ìdájọ́ òdodo
Torí náà, Jèhófà máa ń fẹ́ kí àwọn tó ń wá ojú rere rẹ̀ mọ àwọn ìlànà òdodo rẹ̀ dunjú kí wọ́n sì máa tẹ̀ lé e. (Ais 1:17, 18; 10:1, 2; Jer 7:5-7; 21:12; 22:3, 4; Isk 45:9, 10; Am 5:15; Mik 3:9-12; 6:8; Sek 7:9-12)
SEPTEMBER 11-17
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | ÌSÍKÍẸ́LÌ 46-48
“Ohun Tí Àwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Máa Gbádùn Tí Wọ́n Bá Kúrò Nígbèkùn”
“Fi Ọkàn-àyà Rẹ Sí” Tẹ́ńpìlì Ọlọ́run!
11 Jèhófà yóò ha bù kún ilẹ̀ wọn bí? Àsọtẹ́lẹ̀ náà fi àpèjúwe amọ́kànyọ̀ dáhùn ìbéèrè yìí. Omi kan ń ṣàn wá láti inú tẹ́ńpìlì, bí ó ti ń ṣàn lọ, bẹ́ẹ̀ ló ń gbòòrò sí i, ó sì ti di ọ̀gbàrá nígbà tó fi máa wọnú Òkun Òkú. Nígbà tí ó ṣàn débẹ̀, ó mú kí omi tí kò sí ohun alààyè kankan nínú rẹ̀ sọ jí, iṣẹ́ òwò ẹja sì gbèrú lẹ́bàá èbúté gbígbòòrò náà. Ọ̀pọ̀ igi tí ń so èso yípo ọdún, tí èso rẹ̀ ń ṣara lóore, tí ó sì ń woni sàn, wà lẹ́bàá odò náà.—Ìsíkíẹ́lì 47:1-12.
12 Fún àwọn ìgbèkùn náà, ìlérí yìí ṣàtúnsọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìmúpadàbọ̀sípò tí wọ́n ṣìkẹ́, tí a ti sọ ṣáájú, ó sì fìdí àwọn ìlérí náà múlẹ̀. Ó ju ẹ̀ẹ̀kan lọ tí àwọn wòlíì Jèhófà tí a mí sí ti fi àwọn ipò bí ti Párádísè ṣàpèjúwe Ísírẹ́lì tí a mú padà bọ̀ sípò, tí àwọn ènìyàn tún ti ń gbé inú rẹ̀. Àwọn àgbègbè tó ti dahoro tẹ́lẹ̀ tó sì tún ti bẹ̀rẹ̀ sí kún fún ìgbòkègbodò ti jẹ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tí a ń sọ léraléra. (Aísáyà 35:1, 6, 7; 51:3; Ìsíkíẹ́lì 36:35; 37:1-14) Nítorí náà, àwọn ènìyàn náà lè retí pé àwọn ìbùkún Jèhófà tí ń fúnni ní ìyè yóò máa ṣàn wá gẹ́gẹ́ bí odò láti inú tẹ́ńpìlì tí a ti mú padà bọ̀ sípò. Nítorí èyí, orílẹ̀-èdè tí ó ti kú nípa tẹ̀mí yóò sọ jí. A óò fi àwọn ọkùnrin tẹ̀mí tí ó tayọ bù kún àwọn ènìyàn tí a ti mú padà bọ̀ sípò—àwọn ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ olódodo tí wọ́n sì dúró ṣinṣin bí àwọn igi tí ó wà lẹ́bàá odò inú ìran yẹn, àwọn ọkùnrin tí yóò mú ipò iwájú nínú títún ilẹ̀ tí ó ti di ahoro kọ́. Aísáyà pẹ̀lú ti kọ̀wé nípa àwọn “igi ńlá òdodo” tí yóò “tún àwọn ibi ìparundahoro tí ó ti wà tipẹ́tipẹ́ kọ́.”—Aísáyà 61:3, 4.
“Fi Ọkàn-àyà Rẹ Sí” Tẹ́ńpìlì Ọlọ́run!
10 Ẹ wo bí gbogbo èyí yóò ti mú inú àwọn tí ó wà nígbèkùn dùn tó! A mú un dá ìdílé kọ̀ọ̀kan lójú pé yóò ní ogún ní ilẹ̀ náà. (Fi wé Míkà 4:4.) Ìjọsìn mímọ́ gaara yóò wà ní ibi gíga, tó wà ní àárín gbùngbùn. Sì kíyè sí i pé nínú ìran Ìsíkíẹ́lì àwọn ìjòyè náà, gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà, yóò máa gbé lórí ilẹ̀ tí àwọn ènìyàn náà fi tọrẹ. (Ìsíkíẹ́lì 45:16) Nítorí náà, nínú ilẹ̀ tí a ti mú padà bọ̀ sípò yìí, àwọn ènìyàn yóò máa ṣèrànwọ́ fún iṣẹ́ àwọn tí Jèhófà ti yàn láti mú ipò iwájú, wọ́n yóò máa kọ́wọ́ tì wọ́n lẹ́yìn nípa fífọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ìtọ́sọ́nà wọn. Látòkè délẹ̀, ilẹ̀ yìí jẹ́ àpẹẹrẹ ìṣètò, ìfọwọ́sowọ́pọ̀, àti ààbò tí ó ga lọ́lá.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
“Fi Ọkàn-àyà Rẹ Sí” Tẹ́ńpìlì Ọlọ́run!
14 Ṣé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyí ni kìkì ìmúṣẹ ìran Ìsíkíẹ́lì ni? Bẹ́ẹ̀ kọ́; ó tún ń tọ́ka sí ohun tí ó tóbi ju èyí lọ. Gbé èyí yẹ̀ wò: Kò ṣeé ṣe láti kọ́ tẹ́ńpìlì náà tí Ìsíkíẹ́lì rí nínú ìran gẹ́gẹ́ bí a ṣe ṣàpèjúwe rẹ̀. Lóòótọ́, àwọn Júù fọwọ́ pàtàkì mú ìran yẹn, àní wọ́n tilẹ̀ lo àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀ kan gẹ́gẹ́ bí ó ṣe rí gan-an nínú ìran náà. Ṣùgbọ́n, tẹ́ńpìlì inú ìran náà tóbi débi pé Òkè Ńlá Mòráyà, ibi tí tẹ́ńpìlì ti tẹ́lẹ̀ wà, kò tilẹ̀ lè gbà á. Ní àfikún sí i, tẹ́ńpìlì tí Ìsíkíẹ́lì rí kò sí nínú ìlú ńlá náà, ṣùgbọ́n ó wà lókèèrè lórí abá ilẹ̀ ọ̀tọ̀, nígbà tí ó sì jẹ́ pé orí ilẹ̀ tí tẹ́ńpìlì àkọ́kọ́ wà gan-an ní ìlú Jerúsálẹ́mù ni a kọ́ tẹ́ńpìlì ti èkejì sí. (Ẹ́sírà 1:1, 2) Síwájú sí i, kò sí odò gidi kan tí ó ṣàn wá láti inú tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù. Nítorí náà, kìkì díẹ̀ táṣẹ́rẹ́ ni Ísírẹ́lì ìgbàanì rí nínú ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì. Èyí túmọ̀ sí pé ìmúṣẹ ìran yìí lọ́nà títóbi jù, tí ó jẹ́ ti ẹ̀mí, ní láti wà.
it-2 1001
Ọmọ Ènìyàn
Nínú Ìwé Mímọ́ ní èdè Hébérù, inú ìwé Ìsíkíẹ́lì ni ọ̀rọ̀ yìí ti fara hàn jù lọ. Níbẹ̀, ó lé ní àádọ́rùn-ún ìgbà tí Ọlọ́run pe wòlíì náà ní “ọmọ ènìyàn.” (Isk 2:1, 3, 6, 8) Ó jọ pé ńṣe ni ọ̀rọ̀ yìí ń fi hàn pé ìyàtọ̀ ńlá ló wà láàárín wòlíì náà tó jẹ́ èèyàn àti Ọlọ́run Gíga Jù Lọ tó rán an níṣẹ́. Wọ́n lo ọ̀rọ̀ yìí kan náà fún wòlíì Dáníẹ́lì ní Dáníẹ́lì 8:17.
SEPTEMBER 18-24
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | DÁNÍẸ́LÌ 1-3
“Jèhófà Máa San Wá Lẹ́san Tá A Bá Jẹ́ Adúróṣinṣin sí I”
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
it-2 382
Méṣákì
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ìdí mẹ́ta yìí ló mú kí wọ́n gbà pé àwọn oúnjẹ adùnyùngbà ọba lè sọ àwọn di eléèérí: (1) Àwọn ará Bábílónì máa ń jẹ àwọn ẹran tí Òfin Mosè sọ pé wọ́n jẹ́ aláìmọ́; (2) tí wọ́n bá pa ẹran, wọn kì í fara balẹ̀ ro ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ dà nù, ó sì lè jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n lọ́ àwọn eran kan lọ́rùn pa; (3) àwọn abọ̀rìṣà máa ń kọ́kọ́ fi àwọn ẹran tí wọ́n bá pa rúbọ sí àwọn òrìṣà wọn, tí wọ́n bá sì wá jẹ irú àwọn ẹran bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé àwọn náà ń lọ́wọ́ sí ìjọsìn àwọn ọ̀rìṣà náà nìyẹn.—Da 1:8; fi wé 1Kọ 10:18-20, 28.
Ohun Náà Gan-an Tó Máa Mú Ayé Aláyọ̀ Wá
Ìdáhùn rẹ̀ wà nínú Dáníẹ́lì 2:44, tó kà pé: “Ní ọjọ́ àwọn ọba wọ̀nyẹn [tó ń ṣàkóso ní òpin ètò ìsinsìnyí], Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé. Ìjọba náà ni a kì yóò sì gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn. Yóò fọ́ ìjọba [ènìyàn] wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.” Èé ṣe tí Ìjọba Ọlọ́run fi ní láti “fọ́” àwọn ìṣàkóso ayé “túútúú”? Nítorí pé àwọn wọ̀nyí ń ṣagbátẹrù ẹ̀mí ìṣetinú ẹni, ẹ̀mí àìnáání Ọlọ́run, tí Sátánì dá sílẹ̀ nígbà yẹn lọ́hùn-ún nínú ọgbà Édẹ́nì. Yàtọ̀ sí pé kò lè ṣe ìran ènìyàn láǹfààní kankan, àwọn tí wọ́n ń ṣagbátẹrù ẹ̀mí yẹn ń múra àtibá Ẹlẹ́dàá fìjà pẹẹ́ta. (Sáàmù 2:6-12; Ìṣípayá 16:14, 16) Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ bi ara wa pé, ‘Ṣé a fara mọ́ ìṣàkóso Ọlọ́run àbí a lòdì sí i?’
SEPTEMBER 25–OCTOBER 1
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | DÁNÍẸ́LÌ 4-6
“Ṣé Ò Ń Sin Jèhófà Láìyẹsẹ̀?”
Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Ẹ Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Máa Darí Yín
16 Kí nìdí tó o fi ní láti ṣègbọràn sí Jèhófà nígbà tó o bá tiẹ̀ dá wà? Rántí èyí: Bákan méjì ni, yálà kó o ṣe ohun tó dun Jèhófà tàbí kó o mú ọkàn rẹ̀ yọ̀. (Jẹ́n. 6:5, 6; Òwe 27:11) Ohun tó o bá ṣe kan Jèhófà torí pé ‘ó bìkítà fún ẹ.’ (1 Pét. 5:7) Ó fẹ́ kó o gbọ́ràn sí òun lẹ́nu, kó o lè ṣe ara rẹ láǹfààní. (Aísá. 48:17, 18) Nígbà tí àwọn kan lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ní Ísírẹ́lì ìgbàanì kọ̀ láti tẹ̀ lé àṣẹ rẹ̀, wọ́n mú kí inú rẹ̀ bà jẹ́. (Sm. 78:40, 41) Lọ́wọ́ kejì, Jèhófà ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún wòlíì Dáníẹ́lì, kódà áńgẹ́lì kan tiẹ̀ pè é ní “ọkùnrin fífani-lọ́kàn-mọ́ra gidigidi.” (Dán. 10:11) Kí nìdí? Ìdí ni pé Dáníẹ́lì jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run, kì í ṣe ní gbangba nìkan àmọ́ nígbà tó dá wà pẹ̀lú.—Ka Dáníẹ́lì 6:10.
Ṣé Ojú Tí Jèhófà Fi Ń Wo Ohun Mímọ́ Ni Ìwọ Náà Fi Ń Wò Ó?
12 Kò yani lẹ́nu rárá pé ọ̀pọ̀ nǹkan tó ní í ṣe pẹ̀lú ìgbésí ayé àwọn ẹni àmì òróró àti tàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn ló jẹ́ mímọ́. Ohun mímọ́ ni àjọṣe àárín àwa àti Jèhófà jẹ́. (1 Kíróníkà 28:9; Sáàmù 36:7) Àjọṣe náà ṣeyebíye gan-an débi pé a ò jẹ́ gbà kí ohunkóhun ba àárín àwa àti Jèhófà Ọlọ́run jẹ́. (2 Kíróníkà 15:2; Jákọ́bù 4:7, 8) Àdúrà ń kó ipa pàtàkì nínú mímú kí àjọṣe àárín àwa àti Jèhófà dán mọ́rán. Àdúrà jẹ́ ohun mímọ́ gan-an lójú wòlíì Dáníẹ́lì débi pé, kò jáwọ́ nínú gbígbàdúrà sí Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, kódà nígbà tí èyí fi ẹ̀mí rẹ̀ sínú ewu. (Dáníẹ́lì 6:7-11) Bíbélì fi “àdúrà àwọn ẹni mímọ́” tàbí ti àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró wé tùràrí táwọn àlùfáà máa ń lò nínú ìjọsìn inú tẹ́ńpìlì. (Ìṣípayá 5:8; 8:3, 4; Léfítíkù 16:12, 13) Tùràrí tá a fi ṣàpẹẹrẹ yìí túbọ̀ jẹ́ ká mọ bí àdúrà ti jẹ́ ohun mímọ́ tó. Àǹfààní ńláǹlà mà ni o, pé èèyàn lè bá Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run sọ̀rọ̀! Abájọ tá a fi ka àdúrà sí ohun mímọ́ ní ìgbésí ayé wa!
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Gbàdúrà Láìdabọ̀?
2 Irú èèyàn wo ni Jèhófà ka Dáníẹ́lì sí? Nígbà tí áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì wá dáhùn àdúrà kan tí Dáníẹ́lì gbà, ó pè é ní “ẹnì kan tí ó fani lọ́kàn mọ́ra gidigidi” tàbí “ayanfẹ gidigidi.” (Dáníẹ́lì 9:20-23; Bibeli Mimọ) Nínú àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì, Jèhófà pe Dáníẹ́lì ní olódodo. (Ìsíkíẹ́lì 14:14, 20) Nígbà tí Dáníẹ́lì wà láyé, àwọn àdúrà rẹ̀ mú kó ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́rùn, àní Dáríúsì pàápàá mọ̀ bẹ́ẹ̀.—Dáníẹ́lì 6:16.
“Ẹ̀mí Àti Ìyàwó Ń Bá A Nìṣó Ní Sísọ Pé: ‘Máa Bọ̀!’ ”
15 Lẹ́yìn tí Dáníẹ́lì ti lo òru ọjọ́ kan nínú ihò kìnnìún, ọba fúnra rẹ̀ lọ síbẹ̀ ó sì kígbe pé: “Dáníẹ́lì, ìránṣẹ́ Ọlọ́run alààyè, Ọlọ́run rẹ tí ìwọ ń sìn láìyẹsẹ̀ ha lè gbà ọ́ sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn kìnnìún bí?” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ Dáníẹ́lì dáhùn pé: “Kí ọba kí ó pẹ́ àní fún àkókò tí ó lọ kánrin. Ọlọ́run mi rán áńgẹ́lì rẹ̀, ó sì dí ẹnu àwọn kìnnìún náà, wọn kò sì run mí, níwọ̀n bí a ti rí mi ní ọlọ́wọ́ mímọ́ níwájú rẹ̀; àti níwájú rẹ pẹ̀lú, ọba, èmi kò gbé ìgbésẹ̀ aṣenilọ́ṣẹ́ kankan.” Jèhófà bù kún Dáníẹ́lì torí pé ó ń sìn ín “láìyẹsẹ̀.”—Da 6:19-22.
Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Dáníẹ́lì
4:10, 11, 20-22—Kí ni arabaríbí igi inú àlá Nebukadinésárì dúró fún? Nebukadinésárì tó jẹ́ olùṣàkóso ìjọba ayé ni igi yẹn kọ́kọ́ dúró fún. Àmọ́ níwọ̀n bí ìṣàkóso yẹn ti gbilẹ̀ dé “ìkángun gbogbo ilẹ̀ ayé,” igi yẹn ní láti dúró fún ohun kan tó ju Nebukadinésárì lọ fíìfíì. Ohun tó wà nínú Dáníẹ́lì 4:17 jẹ́ ká mọ̀ pé àlá yẹn kan ìṣàkóso “Ẹni Gíga Jù Lọ” lórí aráyé. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, igi yẹn tún dúró fún ìṣàkóso Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba láyé àtọ̀run, pàápàá bó ṣe ń ṣàkóso lórí ilẹ̀ ayé. Èyí wá túmọ̀ sí pé ẹ̀ẹ̀mejì ni àlá yẹn ní ìmúṣẹ. Ó ṣẹ lákọ̀ọ́kọ́ sórí ìṣàkóso Nebukadinésárì, ìmúṣẹ ẹ̀ẹ̀kejì sì jẹ́ sórí ìṣàkóso Jèhófà gẹ́gẹ́ bí aláṣẹ láyé àtọ̀run.
w88 10/1 30 ¶3-5
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Nígbà tí wọ́n mú Dáníẹ́lì ọkùnrin Hébérù náà wá, ọba tún ọ̀rọ̀ rẹ sọ pé kí wọ́n wọ aṣọ aláwọ̀ àlùkò fún un, kí wọ́n fi ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn tí ó jẹ́ wúrà sí i lọ́rùn, kí ó sì máa ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí igbá kẹta nínú ìjọba òun. Wòlíì náà dáhùn tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pé: “Kí ẹ̀bùn rẹ jẹ́ tìrẹ, sì fi ọrẹ rẹ fún àwọn ẹlòmíràn. Àmọ́ ṣá o, èmi yóò ka ìkọ̀wé náà fún ọba, èmi yóò sì sọ ìtumọ̀ náà di mímọ̀ fún un.”—Dáníẹ́lì 5:17.
Dáníẹ́lì gbà pé kò dìgbà tí òun bá gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ kí òun tó lè sọ ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ náà. Ó ní kí ọba tọ́jú ẹ̀bùn rẹ̀ tàbí kó fún ẹlòmíì. Kì í ṣe ẹ̀bùn tí ọba fẹ́ fún Dáníẹ́lì ló má jẹ́ kó sọ ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ náà, àmọ́ ó jẹ́ nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́ tó máa tó mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ sórí ìlú Bábílónì fún un lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀.
Ní Dáníẹ́lì 5:29, lẹ́yìn tí Dáníẹ́lì ti ka ọ̀rọ̀ náà tó sì ti túmọ̀ rẹ̀ bó ṣe sọ pé òun máa ṣe, ọba ṣì pàpà sọ pé kí wọ́n fún Dáníẹ́lì ní ẹ̀bùn tó sọ pé òun máa fún un. Dáníẹ́lì fúnra rẹ̀ kọ́ ló wọ aṣọ àti ìlẹ̀kẹ̀ náà sọ́rùn ara rẹ̀. Bẹliṣásárì ọba aláṣẹ ló pàṣẹ pé kí wọ́n fún un. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí kò ta ko ohun tó wà ní Dáníẹ́lì 5:17, níbi tí wòlíì náà ti sọ ní kedere pé kì í ṣe torí àtigba ẹ̀bùn ni òun ṣe fẹ́ sọ ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ náà.
Ọ̀rọ̀ Mẹ́rin tí Ó yí Ayé Padà
22 Bí a ṣe rójútùú àdììtú náà nìyẹn. Bábílónì alágbára ńlá yóò ṣubú sọ́wọ́ agbo ọmọ ogun Mídíà òun Páṣíà láìpẹ́. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìkéde ègbé yìí dorí Bẹliṣásárì kodò, ó mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ. Ó mú kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ fi aṣọ aláwọ̀ àlùkò wọ Dáníẹ́lì, kí wọ́n fi ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn tí ó jẹ́ wúrà ṣe ọrùn rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́, kí wọ́n sì kéde ní gbangba pé ó di igbá-kẹta olùṣàkóso nínú ìjọba. (Dáníẹ́lì 5:29) Dáníẹ́lì kò kọ ìbọláfúnni yìí, ní kíkà á sí pé wọ́n jẹ́ ọ̀nà láti gbà fi ọlá tí ó tọ́ sí Jèhófà hàn. Lóòótọ́, ó ṣeé ṣe kí Bẹliṣásárì retí pé kí ìdájọ́ Jèhófà rọjú bí òun bá bọlá fún wòlíì Rẹ̀. Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ̀pa kò bóró mọ́.