Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni
OCTOBER 2-8
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | DÁNÍẸ́LÌ 7-9
“Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì Sọ Ìgbà Tí Mèsáyà Máa Dé”
it-2 902 ¶2
Àádọ́rin Ọ̀sẹ̀
Ìrélànàkọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ dópin. Bí Jésù ṣe kú, tó jíǹde, tó sì fara hàn lọ́run ‘mú kí ìrélànàkọjá kásẹ̀ nílẹ̀, kó pa ẹ̀ṣẹ̀ rẹ́, kó sì ṣe ètùtù nítorí ìṣìnà’ wa. (Da 9:24) Ńṣe ni Májẹ̀mú Òfin fi hàn pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni àwọn Júù yẹn àti pé wọ́n ti dẹni ègún bí wọ́n ṣe da májẹ̀mú náà. Níbi tí Òfin Mósè ti mú kí ẹ̀ṣẹ̀ fara hàn tó sì “di púpọ̀,” ńṣe ni àánú àti ojú rere Ọlọ́run túbọ̀ di púpọ̀ gidigidi nípasẹ̀ Mèsáyà. (Ro 5:20) Lọ́lá ẹbọ Mèsáyà, Ọlọ́run lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tó ronú pìwà dà, kó sì mú ìyà ẹ̀ṣẹ̀ náà kúrò.
it-2 900 ¶7
Àádọ́rin Ọ̀sẹ̀
Mèsáyà dé lẹ́yìn ‘Ọ̀sẹ̀ Mọ́kàndínláàádọ́rin.’ Ní ti “ọ̀sẹ̀ méjì-lé-lọ́gọ́ta” tó tẹ̀ lé e (Da 9:25), ó wà lára àádọ́rin ọ̀sẹ̀ náà, òun sì ni ìkejì nínú àwọn ọ̀sẹ̀ tá a mẹ́nu bà, ó máa bẹ̀rẹ̀ ní ìparí “ọ̀sẹ̀ méje” náà. Nítorí náà, “ìjáde lọ ọ̀rọ̀ náà” láti tún Jerúsálẹ́mù kọ́ “títí di ìgbà Mèsáyà Aṣáájú” yóò jẹ́ àròpọ̀ ọ̀sẹ̀ méje ati “ọ̀sẹ̀” méjìlélọ́gọ́ta [62] tàbí “ọ̀sẹ̀” mọ́kàndínláàádọ́rin [69] èyí tó túmọ̀ sí 483 ọdún, tó bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 455 ṣáájú Sànmánì Kristẹni sí ọdún 29 Sànmánì Kristẹni. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ, ìgbà ìwọ́wé ọdún 29 Sànmánì Kristẹni, ni Jésù ṣe ìrìbọmi, tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ yàn án tó sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ òjíṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “Mèsáyà Aṣáájú.”—Lk 3:1, 2, 21, 22.
it-2 901 ¶2
Àádọ́rin ọ̀sẹ̀
“A óò ké Mèsáyà kúrò” ní ìdajì ọ̀sẹ̀ náà. Áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì tún sọ fún Dáníẹ́lì pé: “Àti lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjìlélọ́gọ́ta náà, a óò ké Mèsáyà kúrò, kì yóò sì sí nǹkan kan fún un.” (Da 9:26) Ní àkókò kan lẹ́yìn òpin ‘àròpọ̀ ọ̀sẹ̀ méje àti ọ̀sẹ̀ méjìlélọ́gọ́ta’ náà, ìyẹn jẹ́ nǹkan bí ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ lẹ́yìn náà, wọ́n ké Kristi kúrò nígbà tí wọ́n pa á lórí òpó igi oró, ó tipa bẹ́ẹ̀ fi gbogbo nǹkan tó ní ṣe ìràpada fún aráyé. (Ais 53:8) Ẹ̀rí fi hàn pé Jésù lo ìdajì “ọ̀sẹ̀” náà lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Ní àkókò kan tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìgbà ìwọ́wé ọdún 32 Sànmánì Kristẹni, Jésù sọ àpèjúwe kan nínú èyí tí ó fi orílẹ̀-èdè Júù náà wé igi ọ̀pọ̀tọ́ (fi wé Mt 17:15-20; 21:18, 19, 43) tí kò so èso kankan fún “ọdún mẹ́ta.” Olùrẹ́wọ́ àjàrà wá sọ fún ẹni tó ni ọgbà àjàrà náà pé: “Ọ̀gá, jọ̀wọ́ rẹ̀ jẹ́ẹ́ ní ọdún yìí pẹ̀lú, títí èmi yóò fi walẹ̀ yí i ká, kí n sì fi ajílẹ̀ sí i; nígbà náà bí ó bá sì mú èso jáde ní ẹ̀yìn ọ̀la, dáadáa náà ni; ṣùgbọ́n bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣe ni ìwọ yóò ké e lulẹ̀.” (Lk 13:6-9) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Jésù ń fi àkókò yìí wé ìgbà tó ń wàásù fún orílẹ̀-èdè Júù yẹn, àmọ́ tí wọn kò gbọ́. Lákòókò yẹn sì rèé, ó tí fẹ́rẹ̀ẹ́ lò tó ọdún mẹ́ta lẹ́nu iṣẹ́ ojíṣẹ́ rẹ̀, á sì máa báa nìṣó títí di ọdún kẹrin.
it-2 901 ¶5
Àádọ́rin Ọ̀sẹ̀
“Ìdajì ọ̀sẹ̀ náà” máa bọ́ sí àárín ọdún méje tàbí lẹ́yìn ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ “ọ̀sẹ̀” ti ọdún. Níwọ̀n bí àádọ́rin “ọ̀sẹ̀” ti bẹ̀rẹ̀ ní nǹkan bí ìgbà ìwọ́wé ọdún 29 Sànmánì Kristẹni ní ìgbà tí Jésù ṣèrìbọmi tí Jèhófà sì yàn án gẹ́gẹ́ bíi Kristi, ìlàjì ọ̀sẹ̀ yẹn (ọdún mẹ́ta àtààbọ̀) máa nasẹ̀ dé ìgbà ìrúwé ọdún 33 Sànmánì Kristẹni tàbí ìgbà ìrékọjá (Nisan 14) ọdún yẹn. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ April 1, 33 Sànmánì Kristẹni ni ọjọ́ yìí, bó ṣe wà nínú kàlẹ́ńdà Gregory. (Wo LORD’S EVENING MEAL [Time of Its Institution].) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé Jésù ‘wá sí ayé kó lè ṣe ìfẹ́ Ọ̇lọ́run’ ìyẹn láti ‘fi òpin sí èyí tí ó jẹ́ ti àkọ́kọ́ [ẹbọ àti ọrẹ ẹbọ gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Òfin] kí ó lè fìdí èyí tí ó jẹ́ èkejì múlẹ̀.’ Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tó fi ara rẹ̀ rúbọ.— Heb 10:1-10.
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ìgbà wo ni a fòróró yan “Ibi Mímọ́ nínú Àwọn Ibi Mímọ́ gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ọ́ tẹ́lẹ̀ nínú Dáníẹ́lì 9:24?
Dáníẹ́lì 9:24-27 jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ kan tó dá lé ìfarahàn “Mèsáyà Aṣáájú”—ìyẹn Kristi. Nítorí náà àsọtẹ́lẹ̀ nípa fífòróró yan “Ibi Mímọ́ nínú Àwọn Ibi Mímọ́,” kò tọ́ka sí fífòróró yan Ibi Mímọ́ Jù Lọ nínú tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù. Kàkà bẹ́ẹ̀, gbólóhùn náà “Ibi Mímọ́ nínú Àwọn Ibi Mímọ́” ń tọ́ka sí ibùjọsìn ti Ọlọ́run ní ọ̀run—ìyẹn Ibi Mímọ́ Jù Lọ ní ọ̀run—nínú tẹ́ńpìlì ńlá ti Jèhófà nípa tẹ̀mí.—Hébérù 8:1-5; 9:2-10, 23.
Ìgbà wo ni tẹ́ńpìlì Ọlọ́run nípa tẹ̀mí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́? Tóò, ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù wá láti ṣe batisí ní ọdún 29 Sànmánì Tiwa. Láti àkókò yẹn lọ ni Jésù ti ń mú ọ̀rọ̀ inú Sáàmù 40:6-8 ṣẹ nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù wá ṣàlàyé lẹ́yìn náà pé Jésù ti gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Ẹbọ àti ọrẹ ẹbọ ni ìwọ kò fẹ́, ṣùgbọ́n ìwọ ti pèsè ara kan fún mi.” (Hébérù 10:5) Jésù mọ̀ pé Ọlọ́run “kò fẹ́” kí fífi ẹran rúbọ máa bá a nìṣó nínú tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù. Dípò ìyẹn, Jèhófà ti pèsè ara ènìyàn pípé fún Jésù láti fi lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ. Jésù fi hàn pé inú òun dùn sí èyí, ó sì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Wò ó! Mo dé (nínú àkájọ ìwé ni a ti kọ ọ́ nípa mi) láti ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọ́run.” (Hébérù 10:7) Kí sì ni Jèhófà fi dá a lóhùn? Ìhìn Rere Mátíù sọ pé: “Lẹ́yìn tí a batisí rẹ̀, Jésù jáde lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láti inú omi; sì wò ó! ọ̀run ṣí sílẹ̀, ó sì rí tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń sọ̀kalẹ̀ bí àdàbà bọ̀ wá sórí rẹ̀. Wò ó! Pẹ̀lúpẹ̀lù, ohùn kan wá láti ọ̀run tí ó wí pé: ‘Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.’ ”—Mátíù 3:16, 17.
Bí Jèhófà Ọlọ́run ṣe tẹ́wọ́ gba ara Jésù tó fi rúbọ túmọ̀ sí pé pẹpẹ kan tó tóbi ju pẹpẹ tó ṣeé fojú rí nínú tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù ti wà. Èyí ni pẹpẹ “ìfẹ́” Ọlọ́run, tàbí ìṣètò fún títẹ́wọ́ gba ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn Jésù gẹ́gẹ́ bí ẹbọ. (Hébérù 10:10) Fífi ẹ̀mí mímọ́ yan Jésù túmọ̀ sí pé Ọlọ́run ti gbé ìṣètò tẹ́ńpìlì rẹ̀ nípa tẹ̀mí látòkèdélẹ̀ kalẹ̀ nísinsìnyí. Nítorí náà, nígbà ìbatisí Jésù, ibi tí Ọlọ́run wà ní òkè ọ̀run ni a fi òróró yàn tàbí ni a yà sọ́tọ̀, bí “Ibi Mímọ́ nínú Àwọn Ibi Mímọ́” nínú ìṣètò tẹ́ńpìlì ńlá nípa tẹ̀mí.
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Dáníẹ́lì
9:27—Májẹ̀mú wo ló ń “ṣiṣẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀” títi di òpin àádọ́rin ọ̀sẹ̀, tó jẹ́ ọdún 36 Sànmánì Kristẹni? Nígbà tí wọ́n kan Jésù mọ́gi lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni, Jèhófà kásẹ̀ májẹ̀mú Òfin nílẹ̀. Àmọ́, Jèhófà mú kí májẹ̀mú tó bá Ábúráhámù dá máa báṣẹ́ lọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì títí di ọdún 36 Sànmánì Kristẹni, ó tipa báyìí fi kún àkókò tó fi ṣe ojúure àrà ọ̀tọ̀ sáwọn Júù nítorí jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù. Májẹ̀mú tó bá Ábúráhámù dá ṣì ń báṣẹ́ lọ fún “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.”—Gálátíà 3:7-9, 14-18, 29; 6:16.
OCTOBER 9-15
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | DÁNÍẸ́LÌ 10-12
“Jèhófà Mọ Ohun Tó Máa Ṣẹlẹ̀ sí Àwọn Ọba”
OCTOBER 16-22
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | HÓSÉÀ 1-7
“Ṣé Inú Rẹ Máa Ń Dùn sí Ìfẹ́ Tí Kì Í Yẹ̀ Bíi Ti Jèhófà?”
Jẹ́ Kí “Òfin Inú-rere-onífẹ̀ẹ́” Máa Fi Ìṣọ́ Ṣọ́ Ahọ́n Rẹ
18 Ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ gbọ́dọ̀ hàn gbangba nínú gbogbo àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ olùjọ́sìn Jèhófà. Kódà, tí ipò nǹkan bá le koko, òfin inú-rere-onífẹ̀ẹ́ kò gbọ́dọ̀ kúrò lẹ́nu wa. Inú Jèhófà kò dùn sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nígbà tí inú-rere-onífẹ̀ẹ́ wọn dà “gẹ́gẹ́ bí ìrì tí ń tètè lọ.” (Hós. 6:4, 6) Àmọ́, inú Jèhófà máa ń dùn sí inú-rere-onífẹ̀ẹ́ tí kò yẹ̀. Ṣàgbéyẹ̀wò bó ṣe ń bù kún àwọn tó ń lépa ànímọ́ yìí.
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Hóséà
6:6. Téèyàn bá sọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá dàṣà, a jẹ́ pé ìfẹ́ Ọlọ́run ò jinlẹ̀ lọ́kàn onítọ̀hún. Kò sí bí ẹbọ tẹ̀mí tá a rú ṣe lè pọ̀ tó tó máa rọ́pò irú àbùkù bẹ́ẹ̀.
Jèhófà Mọyì Ìgbọràn Rẹ
7 Lórí ọ̀rọ̀ tá à ń sọ yìí, ẹ jẹ́ ká rántí pé Jèhófà jẹ́ káwọn èèyàn rẹ̀ láyé àtijọ́ mọ̀ pé ìgbọràn sàn ju ẹbọ tí wọ́n ń fi ẹran rú lọ. (Òwe 21:3, 27; Hóséà 6:6; Mátíù 12:7) Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jèhófà fúnra rẹ̀ ló sọ pé kí wọ́n máa fẹran rúbọ sóun? Ó dáa, kí ló mú kí ẹni tó rúbọ sí Ọlọ́run rú ẹbọ náà? Ṣé kó bàa lè ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni, àbí ṣe ló sáà kàn ń tẹ̀ lé àṣà tó ti wà nílẹ̀? Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ló wu ẹnì kan tó jẹ́ olùjọsìn Ọlọ́run láti ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, yóò rí i dájú pé òun ń pa gbogbo àṣẹ Ọlọ́run mọ́. Téèyàn bá fi ẹran rúbọ sí Ọlọ́run, kò da nǹkan kan fún Ọlọ́run, àmọ́ nǹkan iyebíye kan tá a lè fún un ni pé ká máa ṣègbọràn sí i.
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Hóséà
1:7—Ìgbà wo ni Jèhófà fi àánú hàn sí ilé Júdà tó sì gbà wọ́n là? Èyí nímùúṣẹ lọ́dún 732 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, nígbà ayé Hesekáyà Ọba. Àkókò yẹn ni Jèhófà fòpin sí gbogbo báwọn ará Ásíríà ṣe ń halẹ̀ mọ́ Jerúsálẹ́mù. Ó mú kí áńgẹ́lì kan ṣoṣo pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀rún márùn-ún [185,000] lára àwọn ọmọ ogun ọ̀tá náà lóru ọjọ́ kan ṣoṣo. (2 Àwọn Ọba 19:34, 35) Bí Jèhófà ṣe gba Júdà là nìyẹn, àmọ́ kì í ṣe “nípasẹ̀ ọrun tàbí nípasẹ̀ idà tàbí nípasẹ̀ ogun, nípasẹ̀ àwọn ẹṣin tàbí àwọn ẹlẹ́ṣin,” bí kò ṣe nípasẹ̀ áńgẹ́lì kan ṣoṣo.
Àsọtẹ́lẹ̀ Hóséà Ń fún Wa Níṣìírí Láti Bá Ọlọ́run Rìn
16 Ìlérí míì tí Ọlọ́run tún mú ṣẹ nìyí: “Dájúdájú, èmi yóò sì dá májẹ̀mú fún wọn ní ọjọ́ yẹn ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹranko inú pápá àti pẹ̀lú àwọn ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run àti ohun tí ń rákò lórí ilẹ̀, ọrun àti idà àti ogun ni èmi yóò sì ṣẹ́ kúrò ní ilẹ̀ náà, èmi yóò sì mú kí wọ́n dùbúlẹ̀ ní ààbò.” (Hóséà 2:18) Ìbàlẹ̀ ọkàn wà fún àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn Júù tó wà nígbèkùn tí wọ́n padà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn, kò sì sí pé àwọn ẹranko ń halẹ̀ mọ́ wọn. Àsọtẹ́lẹ̀ yìí tún ṣẹ lọ́dún 1919 nígbà tí Ọlọ́run dá àwọn tó ṣẹ́ kù lára Ísírẹ́lì tẹ̀mí nídè kúrò lóko ẹrú “Bábílónì Ńlá,” ìyẹn ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé. Ní báyìí, ìbàlẹ̀ ọkàn wà fún àwọn àtàwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run yòókù tí wọ́n ń wọ̀nà láti wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé, inú párádísè tẹ̀mí ni wọ́n sì wà. Kò sí èyíkéyìí lára àwọn Kristẹni tòótọ́ wọ̀nyí tó ń hu ìwà ẹranko.—Ìṣípayá 14:8; Aísáyà 11:6-9; Gálátíà 6:16.
Nígbà Tí Ìrẹ́pọ̀ Máa Wà Kárí Ayé
Kódà, àwọn tó ní ìrètí láti gbé ní orilẹ̀ ayé máa wà ní ìrẹ́pọ̀ lọ́nà tó tún ṣàrà ọ̀tọ̀, torí Ọlọ́run máa kọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ olóòótọ́ bí wọ́n á ṣe máa ṣètọ́jú ilẹ̀ ayé. Ńṣe ló máa dà bíi pé ó “dá májẹ̀mú,” pẹ̀lú àwọn ẹranko ẹhànnà, á sì mú kí wọ́n wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ènìyàn.—Hóséà 2:18; Jẹ́nẹ́sísì 1:26-28; Aísáyà 11:6-8.
OCTOBER 23-29
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | HÓSÉÀ 8-14
“Fún Jèhófà Ní Ohun Tó Dára Jù Lọ”
Bá A Ṣe Lè Máa Rú Àwọn Ẹbọ Tí Inú Ọlọ́run Dùn Sí
Láfikún sí i, Bíbélì fi hàn pé ọ̀rọ̀ ìyìn látẹnu wa jẹ́ ẹbọ́ kan tá à ń rú sí Jèhófà. Wòlíì Hóséà lo gbólóhùn náà “ẹgbọrọ akọ màlúù ètè wa,” tó ń fi hàn pé Ọlọ́run ka ìyìn tó ń tẹnu wa jáde sí ọ̀kan lára àwọn ẹbọ tó dára jù lọ. (Hóséà 14:2) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù rọ àwọn Hébérù tí wọ́n jẹ́ Kristẹni pé: “Ẹ jẹ́ kí a máa rú ẹbọ ìyìn sí Ọlọ́run nígbà gbogbo, èyíinì ni, èso ètè tí ń ṣe ìpolongo ní gbangba sí orúkọ rẹ̀.” (Hébérù 13:15) Lóde òní, ọwọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere àti iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn Jésù. (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Wọ́n ń rú ẹbọ ìyìn sí Ọlọ́run tọ̀sán tòru jákèjádò ayé.—Ìṣípayá 7:15.
“Àwọn Ọ̀nà Jèhófà Dúró Ṣánṣán”
7 Tá a bá ń fi òótọ́ ọkàn sin Jèhófà láìsí àgàbàgebè, a ó jàǹfààní inú rere onífẹ̀ẹ́ tàbí ìfẹ́ rẹ̀ tó dúró ṣinṣin. Wòlíì Hóséà sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì oníwàkiwà náà pé: “Ẹ fún irúgbìn fún ara yín ní òdodo; ẹ kárúgbìn ní ìbámu pẹ̀lú inú-rere-onífẹ̀ẹ́. Ẹ ro ilẹ̀ adárafọ́gbìn fún ara yín nígbà tí àkókò wà fún wíwá Jèhófà, títí yóò fi dé, tí yóò sì fún yín ní ìtọ́ni ní òdodo.”—Hóséà 10:12.
OCTOBER 30–NOVEMBER 5
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | JÓẸ́LÌ 1-3
“Àwọn Ohun Ọlá Ńlá Ọlọ́run” Ń ru Wá Sókè
4 Gbàrà táwọn ọmọlẹ́yìn ní Jerúsálẹ́mù rí ẹ̀mí mímọ́ gbà ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wàásù ìhìn rere ìgbàlà fáwọn ẹlòmíì. Wọ́n ti ọ̀dọ̀ ogunlọ́gọ̀ tó kóra jọ ní àárọ̀ ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì yẹn bẹ̀rẹ̀. Ìwàásù wọn jẹ́ ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ pàtàkì kan tí Jóẹ́lì ọmọ Pétúélì kọ sílẹ̀ ní ọ̀rúndún mẹ́jọ ṣáájú ìgbà yẹn, pé: “Èmi yóò tú ẹ̀mí mi jáde sára gbogbo onírúurú ẹran ara, àwọn ọmọkùnrin yín àti àwọn ọmọbìnrin yín yóò sì máa sọ tẹ́lẹ̀ dájúdájú. Ní ti àwọn àgbà ọkùnrin yín, wọn yóò máa lá àlá. Ní ti àwọn ọ̀dọ́kùnrin yín, wọn yóò máa rí ìran. Èmi yóò sì tú ẹ̀mí mi jáde àní sára àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti sára àwọn ìránṣẹ́bìnrin pàápàá ní ọjọ́ wọnnì . . . kí ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà tó dé.”—Jóẹ́lì 1:1; 2:28, 29, 31; Ìṣe 2:17, 18, 20.
5 Ṣé ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé Ọlọ́run máa sọ gbogbo àwọn ènìyàn kan, lọ́kùnrin àti lóbìnrin di wòlíì, gẹ́gẹ́ bó ṣe yan Dáfídì, Jóẹ́lì àti Dèbórà, kí ó sì gbẹnu wọn sọ àwọn ohun tí ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀? Rárá o. Àwọn Kristẹni ‘ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin, ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin’ yóò máa sọ tẹ́lẹ̀ ní ti pé, ẹ̀mí Jèhófà yóò sún wọn láti máa polongo “àwọn ohun ọlá ńlá” tí Jèhófà ti ṣe àti èyí tí yóò ṣe lọ́jọ́ iwájú. Ìyẹn ni pé wọ́n á jẹ́ agbẹnusọ fún Ọ̀gá Ògo. Àmọ́ o, báwo lọ̀rọ̀ yìí ṣe rí lára ogunlọ́gọ̀ náà?—Hébérù 1:1, 2.
jd orí 13 ojú ìwé 166-167 ìpínrọ̀ 4
“Ẹ Pòkìkí Èyí Láàárín Àwọn Orílẹ̀-èdè”
4 Gba ìhà mìíràn wo ọ̀rọ̀ yìí. Jèhófà Ọlọ́run sọ fún wòlíì Jóẹ́lì pé ìgbà kan ń bọ̀ tí àwọn èèyàn lọ́kùnrin lóbìnrin, lọ́mọdé àti lágbà yóò máa sọ tẹ́lẹ̀, ó ní: “Lẹ́yìn ìyẹn, yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, èmi yóò tú ẹ̀mí mi jáde sára gbogbo onírúurú ẹran ara, àwọn ọmọkùnrin yín àti àwọn ọmọbìnrin yín yóò sì máa sọ tẹ́lẹ̀ dájúdájú. Ní ti àwọn àgbà ọkùnrin yín, wọn yóò máa lá àlá. Ní ti àwọn ọ̀dọ́kùnrin yín, wọn yóò máa rí ìran.” (Jóẹ́lì 2:28-32) Lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, àpọ́sítélì Pétérù sọ pé ẹsẹ Bíbélì yìí ló ṣẹ nígbà tí Ọlọ́run tú ẹ̀mí mímọ́ sórí àwọn tí wọ́n pé jọ ní yàrá kan lókè pẹ̀tẹ́ẹ̀sì ní Jerúsálẹ́mù àti ìwàásù tí wọ́n ṣe “nípa àwọn ohun ọlá ńlá Ọlọ́run” lẹ́yìn náà. (Ìṣe 1:12-14; 2:1-4, 11, 14-21) Wá gbé ìgbà tiwa yìí yẹ̀ wò. Àsọtẹ́lẹ̀ Jóẹ́lì ti ń ní ìmúṣẹ pípabanbarì láti ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún. Àwọn Kristẹni tá a fẹ̀mí yàn, lọ́kùnrin lóbìnrin, lọ́mọdé lágbà, bẹ̀rẹ̀ sí í “sọ tẹ́lẹ̀,” ìyẹn ni pé, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kéde “àwọn ohun ọlá ńlá Ọlọ́run,” tó fi mọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tó ti fìdí múlẹ̀ ní ọ̀run báyìí.
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jóẹ́lì àti Ìwé Ámósì
2:12, 13. Ojúlówó ìrònúpìwàdà gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tó ti ọkàn èèyàn wá. Ó ní í ṣe pẹ̀lú ká ‘fa ọkàn wa ya’ nínú lọ́hùn-ún kì í ṣe pé ká ‘fa aṣọ wa ya.’
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jóẹ́lì àti Ìwé Ámósì
3:14—Kí ni “pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti ìpinnu”? Ó ń ṣàpẹẹrẹ ibì kan tí Ọlọ́run ti máa ń mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ. Nígbà ayé Jèhóṣáfátì Ọba Júdà, ẹni tórúkọ rẹ̀ túmọ̀ sí “Jèhófà ni onídàájọ́,” Ọlọ́run gba ilẹ̀ Júdà lọ́wọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tó yí i ká nípa mímú kí ọkàn àwọn ọmọ ogun wọn pòrúurùu. Ìdí nìyẹn tí wọ́n tún fi ń pe ibẹ̀ ní “pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ ti Jèhóṣáfátì.” (Jóẹ́lì 3:2, 12) Lákòókò tiwa yìí, ó dúró fún ibì kan tí Ọlọ́run yóò ti tẹ àwọn orílẹ̀-èdè bí èso àjàrà nínú ìfúntí wáìnì.—Ìṣípayá 19:15.