‘Ẹ Lọ, Ẹ Máa Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn, Ẹ Máa Batisí Wọn’
“Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn . . . , ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.”—MÁTÍÙ 28:19, 20.
1. Ìpinnu wo ni orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ṣe lẹ́gbẹ̀ẹ́ Òkè Sínáì?
NÍ NǸKAN bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [3,500] ọdún sẹ́yìn, odindi orílẹ̀-èdè kan jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Ọlọ́run. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kóra jọ sẹ́gbẹ̀ẹ́ Òkè Sínáì, wọ́n sọ ní gbangba pé: “Gbogbo ohun tí Jèhófà sọ ni àwa ti múra tán láti ṣe.” Látìgbà yẹn lọ, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run, ó di “àkànṣe dúkìá” fún Ọlọ́run. (Ẹ́kísódù 19:5, 8; 24:3) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í wọ̀nà fún ààbò Ọlọ́run lórí wọn, wọ́n tún ń wọ̀nà fún ìgbà tí ìrandíran wọn yóò máa gbé ilẹ̀ kan “tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin.”—Léfítíkù 20:24.
2. Àjọṣe wo làwọn èèyàn lè ní pẹ̀lú Ọlọ́run lónìí?
2 Àmọ́, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Ásáfù onísáàmù sọ, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì “kò pa májẹ̀mú Ọlọ́run mọ́, wọ́n sì kọ̀ láti máa rìn nínú òfin rẹ̀.” (Sáàmù 78:10) Wọ́n kùnà láti mú ẹ̀jẹ́ tí àwọn baba ńlá wọn jẹ́ fún Jèhófà ṣẹ. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, orílẹ̀-èdè yẹn pàdánù àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ tí wọ́n ní pẹ̀lú Ọlọ́run. (Oníwàásù 5:4; Mátíù 23:37, 38) Ọlọ́run sì tìtorí bẹ́ẹ̀ “yí àfiyèsí rẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè . . . láti mú àwọn ènìyàn kan fún orúkọ rẹ̀ jáde láti inú wọn.” (Ìṣe 15:14) Láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí náà, ó tún ń kó “ogunlọ́gọ̀ ńlá, tí ẹnì kankan kò lè kà, láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n” jọ, ìyẹn àwọn tó ń sọ tayọ̀tayọ̀ pé: “Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa, ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́, àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà ni ìgbàlà wa ti wá.”—Ìṣípayá 7:9, 10.
3. Kí ló yẹ kẹ́nì kan ṣe kó tó lè ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Ọlọ́run?
3 Téèyàn bá fẹ́ wà lára àwọn tó ní àjọṣe ṣíṣeyebíye yẹn pẹ̀lú Ọlọ́run, onítọ̀hún gbọ́dọ̀ ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, kó sì fi ẹ̀rí èyí hàn fáwọn èèyàn nípa ṣíṣe ìrìbọmi. Àṣẹ tí Jésù pa fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ gan-an nìyí, nígbà tó sọ fún wọn pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.” (Mátíù 28:19, 20) Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tẹ́tí sílẹ̀ bí Mósè ṣe ń ka “ìwé májẹ̀mú” náà. (Ẹ́kísódù 24:3, 7, 8) Nípa bẹ́ẹ̀, wọ́n lóye ohun tí Jèhófà fẹ́ kí wọ́n ṣe. Bákan náà lọ̀rọ̀ rí lónìí, ìmọ̀ pípéye nípa ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe gẹ́gẹ́ bá a ti rí i nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ṣe pàtàkì gan-an kéèyàn tó lè ṣèrìbọmi.
4. Kí lẹnì kan gbọ́dọ̀ ṣe kó tó lè kún ojú ìwọ̀n láti ṣèrìbọmi? (Fi ohun tó wà nínú àpótí tó wà lókè kún un.)
4 Ó ṣe kedere pé, Jésù fẹ́ káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ní ìgbàgbọ́ tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáadáa kí wọ́n tó ṣe ìrìbọmi. Kì í ṣe pé ó ní káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun lọ sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn nìkan ni, àmọ́ ó tún ní kí wọ́n máa kọ́ wọn ‘láti máa pa gbogbo ohun tí òun ti pa láṣẹ fún wọn mọ́.’ (Mátíù 7:24, 25; Éfésù 3:17-19) Nítorí náà, àwọn tó kún ojú ìwọ̀n láti ṣèrìbọmi ti máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún ọ̀pọ̀ oṣù tàbí fún ọdún kan tàbí méjì pàápàá kí wọ́n tó ṣèrìbọmi, kí ìpinnu wọn má bàa jẹ́ èyí tí wọ́n kánjú ṣe tàbí èyí tí wọ́n ṣe láìronú jinlẹ̀. Kódà nígbà ìrìbọmi ọ̀hún pàápàá, wọ́n tún máa ń dáhùn bẹ́ẹ̀ ni, sí àwọn ìbéèrè pàtàkì méjì. Níwọ̀n bí Jésù ti tẹnu mọ́ ọn pé ká jẹ́ kí ‘Bẹ́ẹ̀ ni wa jẹ́ Bẹ́ẹ̀ ni, kí Bẹ́ẹ̀ kọ́ wa sì jẹ́ Bẹ́ẹ̀ kọ́,’ yóò dára kí gbogbo wa fara balẹ̀ ṣàgbéyẹ̀wò ìjẹ́pàtàkì àwọn ìbéèrè méjèèjì yìí tí wọ́n máa ń béèrè lọ́wọ́ àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi.—Mátíù 5:37.
Ìrònúpìwàdà àti Ìyàsímímọ́
5. Àwọn ìgbésẹ̀ pàtàkì méjì wo ni ìbéèrè àkọ́kọ́ tí wọ́n máa ń bi ẹni tó bá fẹ́ ṣèrìbọmi jẹ́ ká mọ̀?
5 Ìbéèrè àkọ́kọ́ la fi ń mọ̀ bóyá ẹni tó fẹ́ ṣèrìbọmi náà ti ronú pìwà dà ọ̀nà tó gbà ń gbé ìgbésí ayé rẹ̀ tẹ́lẹ̀ àti bóyá ó ti ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Ìbéèrè yìí jẹ́ ká mọ ìgbésẹ̀ pàtàkì méjì téèyàn gbọ́dọ̀ gbé kó tó ṣe ìrìbọmi, ìyẹn ni ìrònúpìwàdà àti ìyàsímímọ́.
6, 7. (a) Kí nìdí tí ìrònúpìwàdà fi ṣe pàtàkì fún gbogbo àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi? (b) Àwọn ìyípadà wo lèèyàn gbọ́dọ̀ ṣe lẹ́yìn tó bá ti ronú pìwà dà?
6 Kí nìdí tó fi yẹ kéèyàn ronú pìwà dà kó tó ṣèrìbọmi? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé ìdí náà, ó ní: “Ní àkókò kan, gbogbo wa hùwà láàárín wọn ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìfẹ́-ọkàn ti ẹran ara wa.” (Éfésù 2:3) Ká tó dẹni tó ní ìmọ̀ tó péye nípa ohun tí Ọlọ́run fẹ́, ibi táyé ń tẹ̀ sí làwa náà ń tẹ̀ sí, ohun tí ayé sì kà sí pàtàkì àtàwọn ìlànà táyé ń tẹ̀ lé làwa náà ń kà sí pàtàkì. Abẹ́ àkóso Sátánì tó jẹ́ ọlọ́run ètò nǹkan ìsinsìnyí ni ọ̀nà tá a gba ń gbé ìgbésí ayé wa wà nígbà yẹn. (2 Kọ́ríńtì 4:4) Àmọ́ nígbà tá a wá mọ ohun tí Ọlọ́run fẹ́, a pinnu láti máa gbé ìgbésí ayé wa lọ́nà tí “kì í tún ṣe fún ìfẹ́-ọkàn ènìyàn mọ́, bí kò ṣe fún ìfẹ́ Ọlọ́run.”—1 Pétérù 4:2.
7 Ọ̀nà tuntun tá a gbà ń gbé ìgbésí ayé wa yìí ń ṣe wá láǹfààní tó pọ̀ rẹpẹtẹ. Ní pàtàkì, ó ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún wa láti ní àjọṣe tó dára gan-an pẹ̀lú Jèhófà, èyí tí Dáfídì fi wé pípè tá a pè wá láti wá sínú “àgọ́” Ọlọ́run àti “òkè ńlá mímọ́” rẹ̀, ìyẹn sì jẹ́ àǹfààní ńláǹlà. (Sáàmù 15:1) Ó bọ́gbọ́n mu pé Jèhófà kò kàn ní pe ẹnì kan ṣáá, àwọn tó máa ń pè ni kìkì àwọn tó ‘ń rìn láìlálèébù, tí wọ́n ń fi òdodo ṣèwà hù, tí wọ́n sì ń sọ òtítọ́ nínú ọkàn-àyà wọn.’ (Sáàmù 15:2) Nítorí ipò tí olúkúlùkù wa wà ká tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ó lè gba pé ká ṣe àwọn ìyípadà kan nínú ìwà àti ìṣe wa ká tó lè ṣe àwọn ohun tí Bíbélì ní ká ṣe. (1 Kọ́ríńtì 6:9-11; Kólósè 3:5-10) Ohun tó máa sún wa ṣe irú ìyípadà bẹ́ẹ̀ ní ìrònúpìwàdà, ìyẹn ni pé ká kábàámọ̀ gan-an lórí ọ̀nà tá a gbà ń gbé ìgbésí ayé wa tẹ́lẹ̀, ká sì fi gbogbo ọkàn wa pinnu pé a ó máa múnú Jèhófà dùn. Èyí ló máa wá mú ká yí padà pátápátá, tí a óò pa ìgbésí ayé onímọtara-ẹni-nìkan tí à ń gbé tẹ́lẹ̀ tì, tí a ó sì máa hùwà tó ń múnú Ọlọ́run dùn.—Ìṣe 3:19.
8. Báwo la ṣe máa ń ṣe ìyàsímímọ́, báwo ló sì ṣe tan mọ́ ìrìbọmi?
8 Apá kejì ìbéèrè àkọ́kọ́ tí wọ́n máa ń bi àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi la fi ń mọ̀ bóyá wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Ìyàsímímọ́ jẹ́ ohun pàtàkì kan téèyàn gbọ́dọ̀ ṣe kó tó ṣe ìrìbọmi. Inú àdúrà lèèyàn ti máa ń ṣe é, tá a ó sọ bó ṣe wù wá láti fi gbogbo ìgbésí ayé wa fún Jèhófà nípasẹ̀ Kristi. (Róòmù 14:7, 8; 2 Kọ́ríńtì 5:15) Jèhófà yóò wá di Ọ̀gá wa àti Ẹni tó ni wá, tí inú àwa náà yóò sì wá máa dùn láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run bínú Jésù ṣe máa ń dùn láti ṣe é. (Sáàmù 40:8; Éfésù 6:6) Ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo lèèyàn máa ń jẹ́ ẹ̀jẹ́ yìí fún Jèhófà. Àmọ́, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ló mọ̀ pé a ti ya ara wa sí mímọ́ fóun, bá a ṣe polongo èyí nígbà tá a dáhùn àwọn ìbéèrè méjì yẹn lọ́jọ́ ìrìbọmi wa ló máa jẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ̀ pé a ti ya ara wa sí mímọ́ fún Bàbá wa ọ̀run.—Róòmù 10:10.
9, 10. (a) Kí ni ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run túmọ̀ sí? (b) Báwo làwọn aláṣẹ ìjọba Násì pàápàá ṣe fi hàn pé àwọn mọ̀ nípa ìyàsímímọ́ wa?
9 Kí ni títẹ̀lé àpẹẹrẹ Jésù nínú ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run gba pé ká ṣe? Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ níní ara rẹ̀, kí ó sì gbé òpó igi oró rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn nígbà gbogbo.” (Mátíù 16:24) Nínú ọ̀rọ̀ yìí, Jésù mẹ́nu kan ohun mẹ́ta tá a gbọ́dọ̀ ṣe. Ìkíní, a ó “sẹ́” ara wa. Ìyẹn ni pé a ó kọ ìtẹ̀sí ọkàn wa tó máa ń dá lórí ìmọtara-ẹni-nìkan àti àìpé sílẹ̀, a ó sì máa ṣègbọràn sí ìmọ̀ràn àti ìtọ́ni Ọlọ́run. Ìkejì, a ó ‘gbé òpó igi oró wa.’ Nígbà ayé Jésù, àmì ìtìjú àti ìyà ni òpó igi oró jẹ́. Nítorí pé a jẹ́ Kristẹni, a gbà pé àwa náà lè jìyà nítorí ìhìn rere nígbà míì. (2 Tímótì 1:8) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ayé lè fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí kí wọ́n pẹ̀gàn wa, síbẹ̀ bíi ti Kristi, à ń ‘tẹ́ńbẹ́lú ìtìjú,’ inú wa sì ń dùn pé à ń múnú Ọlọ́run dùn. (Hébérù 12:2) Èyí tó kẹ́yìn ni pé, a ó máa tẹ̀ lé Jésù “nígbà gbogbo.”—Sáàmù 73:26; 119:44; 145:2.
10 Ó dùn mọ́ni pé, àwọn kan tó ń ta kò wá pàápàá mọ̀ nípa ìyàsímímọ́ tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe fún Ọlọ́run láti máa fi gbogbo ọkàn wa sìn ín. Bí àpẹẹrẹ, ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ìjọba Násì tó wà nílùú Buchenwald lórílẹ̀-èdè Jámánì, wọ́n ní káwọn Ẹlẹ́rìí tó kọ̀ láti sẹ́ ìgbàgbọ́ wọn fọwọ́ sí ìwé tí wọ́n tẹ ọ̀rọ̀ kan sí. Ọ̀rọ̀ náà lọ báyìí: “Tinútinú ni mo ṣì fi jẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mi ò sì ní ba ẹ̀jẹ́ tí mo ti jẹ́ fún Jèhófà jẹ́ láé.” Láìsí àní-àní, èyí fi irú ẹ̀mí tí gbogbo àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní hàn kedere!— Ìṣe 5:32.
Bá A Ṣe Ń Mọ̀ Pé Ẹnì Kan Ti Di Ẹlẹ́rìí Jèhófà
11. Àǹfààní wo lẹni tó bá ṣèrìbọmi ní?
11 Ìbéèrè kejì ló ń fi hàn bóyá ẹni tó fẹ́ ṣèrìbọmi náà lóye pé ìrìbọmi tóun fẹ́ ṣe yìí ló máa fi hàn pé òun ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lẹ́yìn tó bá ṣèrìbọmi tán, ó di òjíṣẹ́ tí Jèhófà yàn láti jẹ́ orúkọ mọ́ òun nìyẹn. Àǹfààní ńlá gan-an ni èyí jẹ́, iṣẹ́ bàǹtàbanta ló sì gbé lé ẹni náà lọ́wọ́ pẹ̀lú. Ó sì tún fi hàn pé ẹni tó ṣèrìbọmi náà ní ìrètí àtirí ìgbàlà ayérayé, ìyẹn tó bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà títí dópin.—Mátíù 24:13.
12. Ohun wo ló ń bá àǹfààní jíjẹ́ orúkọ mọ́ Jèhófà rìn?
12 Dájúdájú, iyì tí kò lẹ́gbẹ́ ló jẹ́ láti máa bá Jèhófà, Ọlọ́run Olódùmarè jẹ́ orúkọ. Wòlíì Míkà sọ pé: “Gbogbo àwọn ènìyàn, ní tiwọn, yóò máa rìn, olúkúlùkù ní orúkọ ọlọ́run tirẹ̀; ṣùgbọ́n àwa, ní tiwa, yóò máa rìn ní orúkọ Jèhófà Ọlọ́run wa fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.” (Míkà 4:5) Síbẹ̀, ohun kan máa ń bá àǹfààní yìí rìn. Ohun náà ni pé a gbọ́dọ̀ sapá láti gbé ìgbésí ayé wa lọ́nà tó máa mú ìyìn bá Jèhófà, ẹni tí à ń jẹ́ orúkọ mọ́. Gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe rán àwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù létí, bí ẹnì kan kò bá ń fi ohun tó ń wàásù rẹ̀ ṣèwàhù, orúkọ Ọlọ́run ti di èyí tí à “ń sọ̀rọ̀ òdì sí” tàbí tí à ń pẹ̀gàn rẹ̀ nìyẹn.—Róòmù 2:21-24.
13. Kí nìdí táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó ti ya ara wọn sí mímọ́ fi gbọ́dọ̀ máa jẹ́rìí nípa Ọlọ́run wọn?
13 Nígbà tẹ́nì kan bá di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó ti tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ jíjẹ́rìí nípa Ọlọ́run nìyẹn. Jèhófà ké sí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún un pé kí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́rìí òun kí wọ́n bàa lè jẹ́rìí sí jíjẹ́ tóun jẹ́ Ọlọ́run ayérayé. (Aísáyà 43:10-12, 21) Àmọ́ orílẹ̀-èdè náà kùnà láti ṣe bẹ́ẹ̀, Jèhófà sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀ pátápátá níkẹyìn. Lónìí, àwa Kristẹni tòótọ́ ń fi àǹfààní tá a ní láti máa jẹ́rìí nípa Jèhófà yangàn. À ń ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, a sì fẹ́ kí orúkọ rẹ̀ di èyí tí a sọ di mímọ́. Báwo la ṣe máa dákẹ́ nígbà tá a mọ irú ẹni tí Bàbá wa ọ̀run jẹ́ tá a sì mọ ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe fún aráyé? Bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gẹ́ẹ́ ló rí lára àwa náà nígbà tó sọ pé: “Àìgbọ́dọ̀máṣe wà lórí mi. Ní ti gidi, mo gbé bí èmi kò bá polongo ìhìn rere!”—1 Kọ́ríńtì 9:16.
14, 15. (a) Báwo ni ètò Jèhófà ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn wa? (b) Àwọn nǹkan wo ló wà lárọ̀ọ́wọ́tó wa láti ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa sin Jèhófà?
14 Ìbéèrè kejì tún ń rán ẹni tó fẹ́ ṣe ìrìbọmi náà létí pé ó gbọ́dọ̀ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ètò tí Jèhófà ń fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ darí. A ò lè dá nìkan máa sin Ọlọ́run, a nílò ìrànlọ́wọ́, ìtìlẹ́yìn àti ìṣírí “gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará.” (1 Pétérù 2:17; 1 Kọ́ríńtì 12:12, 13) Ètò Ọlọ́run sì ń kó ipa tó ṣe pàtàkì gan-an nínú bá a ṣe ń tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn wa. Ó ń pèsè ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, èyí tó ń ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ pípéye ká bàa lè fi ọgbọ́n hùwà nígbà tá a bá wà nínú ìṣòro, ká sì lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run. Bí ìyá kan tó ń pèsè oúnjẹ fún ọmọ rẹ̀ dáadáa tó sì ń tún bójú tó o, bẹ́ẹ̀ ni “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ṣe ń pèsè ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ tẹ̀mí lásìkò tó yẹ, kí àjọṣe àárín àwa àti Jèhófà lè máa dán mọ́rán sí i.—Mátíù 24:45-47; 1 Tẹsalóníkà 2:7, 8.
15 Inú àwọn ìpàdé tá a máa ń ṣe lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ làwa èèyàn Jèhófà ti máa ń gba ẹ̀kọ́ àti ìṣírí láti jẹ́ Ẹlẹ́rìí olóòótọ́ fún Jèhófà. (Hébérù 10:24, 25) Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ń kọ́ wa béèyàn ṣe lè sọ̀rọ̀ níwájú ọ̀pọ̀ èèyàn, Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn sì ń kọ́ wa bá a ṣe lè bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lọ́nà tó gbéṣẹ́. A óò rí ọ̀nà tí ẹ̀mí Jèhófà gbà ń ṣiṣẹ́ àti bó ṣe ń darí ètò rẹ̀ tá a bá ń lọ sáwọn ìpàdé wa déédéé tá a sì ń kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì. Àwọn ìpèsè déédéé yìí ni Ọlọ́run fi ń mú ká wà lójúfò ká má bàa kó sínú ewu, àwọn ló ń lò láti kọ́ wa ká lè jẹ́ òjíṣẹ́ tó mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́, ó sì tún ń lò wọ́n láti ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa wà lójúfò.—Sáàmù 19:7, 8, 11; 1 Tẹsalóníkà 5:6, 11; 1 Tímótì 4:13.
Ohun Tó Ń Mú Kéèyàn Fẹ́ Láti Ṣèrìbọmi
16. Kí ló mú ká ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà?
16 Àwọn ìbéèrè méjèèjì tá a ti gbé yẹ̀ wò yìí ń rán àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi létí bí ìrìbọmi ti ṣe pàtàkì tó àtàwọn ohun tó so mọ́ ọn. Kí ló wá yẹ kó sún wọn láti pinnu pé àwọn fẹ́ ṣe ìrìbọmi? Kì í ṣe nítorí pé ẹnì kan fagbára mú wa la ṣe di ọmọ ẹ̀yìn tó ṣèrìbọmi, bí kò ṣe nítorí pé Jèhófà “fà” wá. (Jòhánù 6:44) Nítorí pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́,” ìfẹ́ yìí ló fi ń ṣàkóso gbogbo àgbáyé, kì í ṣe pẹ̀lú ipá. (1 Jòhánù 4:8) Àwọn ànímọ́ rere tí Jèhófà ní àti ọ̀nà tó ń gbà bá wa lò ló ń fà wá wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Jèhófà fún wa ní ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n kan ṣoṣo, ó sì tún ṣèlérí ọjọ́ ọ̀la tó dára gan-an fún wa. (Jòhánù 3:16) Ìyẹn ló sì wá mú káwa náà ya ìgbésí ayé wa sí mímọ́ fún un.—Òwe 3:9; 2 Kọ́ríńtì 5:14, 15.
17. Kí ni a kò ya ara wa sí mímọ́ fún?
17 A kò ya ara wa sí mímọ́ fún ìlànà kan tàbí iṣẹ́ kan ní pàtó, Jèhófà fúnra rẹ̀ la ya ara wa sí mímọ́ fún. Iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ yóò yí padà, àmọ́ ìyàsímímọ́ wọn sí i kò lè yí padà. Bí àpẹẹrẹ, ohun tó sọ pé kí Ábúráhámù ṣe yàtọ̀ sí ohun tó sọ pé kí Jeremáyà ṣe. (Jẹ́nẹ́sísì 13:17, 18; Jeremáyà 1:6, 7) Síbẹ̀, àwọn méjèèjì ló ṣe ohun tí Ọlọ́run ní kí wọ́n ṣe nítorí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, wọ́n sì fẹ́ fi gbogbo ọkàn wọn ṣe ohun tó wù ú. Lákòókò òpin yìí, gbogbo àwọn tó ti ṣèrìbọmi tí wọ́n jẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi ló ń sapá láti pa àṣẹ Kristi mọ́ pé ká wàásù ìhìn rere Ìjọba náà ká sì máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. (Mátíù 24:14; 28:19, 20) Ṣíṣe iṣẹ́ yẹn tọkàntọkàn ni ọ̀nà tó dára jù lọ tá a lè gbà fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Bàbá wa ọ̀run àti pé lóòótọ́ la ti ya ara wa sí mímọ́ fún un.—1 Jòhánù 5:3.
18, 19. (a) Kí là ń jẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ̀ nígbà tá a bá ṣèrìbọmi? (b) Kí la ó gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
18 Láìsí àní-àní, ìrìbọmi ń ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ìbùkún, àmọ́ kì í ṣe ohun tá a kàn lè ṣe láìronú jinlẹ̀. (Lúùkù 14:26-33) Ìrìbọmi ń fi hàn pé a ti ṣe ìpinnu kan tó lágbára tó sì ṣe pàtàkì gan-an ju ohun èyíkéyìí mìíràn téèyàn lè dáwọ́ lé. (Lúùkù 9:62) Nígbà tá a bá ṣe ìrìbọmi, ohun tá a dìídì ń sọ fún gbogbo èèyàn ni pé: “Ọlọ́run yìí, Ọlọ́run wa ni fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé. Òun fúnra rẹ̀ yóò máa ṣamọ̀nà wa títí a ó fi kú.”—Sáàmù 48:14.
19 Nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí, a óò gbé àwọn ìbéèrè mìíràn tó lè wáyé lórí ọ̀rọ̀ ìrìbọmi yẹ̀ wò. Ǹjẹ́ àwọn ìdí pàtàkì kan lè wà tó lè mú kí ẹnì kan kọ̀ láti ṣèrìbọmi? Ǹjẹ́ ọjọ́ orí lè dá èèyàn dúró àtiṣe ìrìbọmi? Kí ni gbogbo wa lè ṣe láti fi hàn pé àkókò ọ̀wọ̀ ni àkókò ìrìbọmi jẹ́?
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Kí nìdí tí Kristẹni kọ̀ọ̀kan fi ní láti ronú pìwà dà kó tó ṣèrìbọmi?
• Kí ni yíya ara ẹni sí mímọ́ fún Ọlọ́run ní nínú?
• Iṣẹ́ wo ni àǹfààní jíjẹ́ orúkọ mọ́ Jèhófà gbé léni lọ́wọ́?
• Kí ló yẹ kó sún wa láti pinnu pé a fẹ́ ṣe ìrìbọmi?
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Àwọn Ìbéèrè Méjì Tí Wọ́n Máa Ń Bi Àwọn Tó Fẹ́ Ṣèrìbọmi
Lọ́lá ẹbọ Jésù Kristi, ǹjẹ́ ẹ ti ronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín, ṣé ẹ sì ti ya ara yín sí mímọ́ fún Jèhófà láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀?
Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi yín ń fi hàn pé ẹ jẹ́ ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nínú ètò tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń darí?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ìyàsímímọ́ ni ẹ̀jẹ́ téèyàn jẹ́ fún Jèhófà nínú àdúrà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Iṣẹ́ ìwàásù wa fi hàn pé a ti ya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run