ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Léfítíkù 20
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Léfítíkù

      • Ìjọsìn Mólékì; ìbẹ́mìílò (1-6)

      • Ẹ jẹ́ mímọ́ kí ẹ sì bọ̀wọ̀ fún àwọn òbí (7-9)

      • Ikú tọ́ sí àwọn oníṣekúṣe (10-21)

      • Ẹ jẹ́ mímọ́ kí ẹ lè wà ní ilẹ̀ náà (22-26)

      • Ikú tọ́ sí àwọn abẹ́mìílò (27)

Léfítíkù 20:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 18:21; Di 18:10

Léfítíkù 20:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Isk 5:11

Léfítíkù 20:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 13:6-9

Léfítíkù 20:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 20:5

Léfítíkù 20:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn náà.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 19:31; Di 18:10-12; Ga 5:19, 20; Ifi 21:8
  • +Le 20:27; Iṣe 16:16
  • +1Kr 10:13

Léfítíkù 20:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 11:44; 1Pe 1:15, 16

Léfítíkù 20:8

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 18:4; Onw 12:13
  • +Ẹk 31:13; Le 21:8; 1Tẹ 5:23; 2Tẹ 2:13

Léfítíkù 20:9

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “pe ibi wá sórí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 21:17; Di 27:16; Owe 20:20; Mt 15:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    5/15/2004, ojú ìwé 24

Léfítíkù 20:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Di 5:18; 22:22; Ro 7:3; 1Kọ 6:9, 10

Léfítíkù 20:11

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ṣí ìhòòhò.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 18:8; Di 27:20

Léfítíkù 20:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 18:15, 29

Léfítíkù 20:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jẹ 19:5; Le 18:22; Ond 19:22; Ro 1:26, 27; 1Kọ 6:9, 10; Jud 7

Léfítíkù 20:14

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ìwà tó ń dójú tini; ìwà ìbàjẹ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 18:17; Di 27:23
  • +Le 21:9

Léfítíkù 20:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 22:19; Di 27:21

Léfítíkù 20:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 18:23

Léfítíkù 20:17

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ṣí ìhòòhò.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 18:9; Di 27:22

Léfítíkù 20:18

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 18:19

Léfítíkù 20:19

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 18:12, 13

Léfítíkù 20:20

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ṣí ìhòòhò.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 18:14

Léfítíkù 20:21

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ní Héb., “ṣí ìhòòhò.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 18:16; Di 25:5

Léfítíkù 20:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 21:1; Di 5:1
  • +Onw 12:13
  • +Le 18:26, 28

Léfítíkù 20:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 18:3, 24; Di 12:30
  • +Le 18:27; Di 9:5

Léfítíkù 20:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 3:17; 6:8; Di 8:7-9; Isk 20:6
  • +Ẹk 19:5; 33:16; 1Ọb 8:53; 1Pe 2:9

Léfítíkù 20:25

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ọkàn yín.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 11:46, 47; Di 14:4-20
  • +Le 11:43

Léfítíkù 20:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Le 19:2; Sm 99:5; 1Pe 1:15, 16; Ifi 4:8
  • +Di 7:6

Léfítíkù 20:27

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “tó ní ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 22:18; Le 19:31; 20:6; Di 18:10-12; Ifi 21:8

Àwọn míì

Léf. 20:2Le 18:21; Di 18:10
Léf. 20:3Isk 5:11
Léf. 20:4Di 13:6-9
Léf. 20:5Ẹk 20:5
Léf. 20:6Le 19:31; Di 18:10-12; Ga 5:19, 20; Ifi 21:8
Léf. 20:6Le 20:27; Iṣe 16:16
Léf. 20:61Kr 10:13
Léf. 20:7Le 11:44; 1Pe 1:15, 16
Léf. 20:8Le 18:4; Onw 12:13
Léf. 20:8Ẹk 31:13; Le 21:8; 1Tẹ 5:23; 2Tẹ 2:13
Léf. 20:9Ẹk 21:17; Di 27:16; Owe 20:20; Mt 15:4
Léf. 20:10Di 5:18; 22:22; Ro 7:3; 1Kọ 6:9, 10
Léf. 20:11Le 18:8; Di 27:20
Léf. 20:12Le 18:15, 29
Léf. 20:13Jẹ 19:5; Le 18:22; Ond 19:22; Ro 1:26, 27; 1Kọ 6:9, 10; Jud 7
Léf. 20:14Le 18:17; Di 27:23
Léf. 20:14Le 21:9
Léf. 20:15Ẹk 22:19; Di 27:21
Léf. 20:16Le 18:23
Léf. 20:17Le 18:9; Di 27:22
Léf. 20:18Le 18:19
Léf. 20:19Le 18:12, 13
Léf. 20:20Le 18:14
Léf. 20:21Le 18:16; Di 25:5
Léf. 20:22Ẹk 21:1; Di 5:1
Léf. 20:22Onw 12:13
Léf. 20:22Le 18:26, 28
Léf. 20:23Le 18:3, 24; Di 12:30
Léf. 20:23Le 18:27; Di 9:5
Léf. 20:24Ẹk 3:17; 6:8; Di 8:7-9; Isk 20:6
Léf. 20:24Ẹk 19:5; 33:16; 1Ọb 8:53; 1Pe 2:9
Léf. 20:25Le 11:46, 47; Di 14:4-20
Léf. 20:25Le 11:43
Léf. 20:26Le 19:2; Sm 99:5; 1Pe 1:15, 16; Ifi 4:8
Léf. 20:26Di 7:6
Léf. 20:27Ẹk 22:18; Le 19:31; 20:6; Di 18:10-12; Ifi 21:8
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Léfítíkù 20:1-27

Léfítíkù

20 Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé: 2 “Sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ẹ gbọ́dọ̀ pa ọmọ Ísírẹ́lì àti àjèjì èyíkéyìí tó ń gbé ní Ísírẹ́lì tó bá fún Mólékì ní ìkankan nínú àwọn ọmọ rẹ̀.+ Kí àwọn èèyàn ilẹ̀ náà sọ ọ́ lókùúta pa. 3 Èmi fúnra mi kò ní fi ojú rere wo ọkùnrin yẹn, màá sì pa á, kí n lè mú un kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀, torí ó ti fún Mólékì lára àwọn ọmọ rẹ̀, ó ti sọ ibi mímọ́+ mi di ẹlẹ́gbin, ó sì ti sọ orúkọ mímọ́ mi di aláìmọ́. 4 Tí àwọn èèyàn ilẹ̀ náà bá mọ̀ọ́mọ̀ gbójú fo ohun tí ọkùnrin yẹn ṣe nígbà tó fún Mólékì ní ọmọ rẹ̀, tí wọn ò sì pa á,+ 5 ó dájú pé èmi fúnra mi kò ní fi ojú rere wo ọkùnrin yẹn àti ìdílé rẹ̀.+ Màá pa ọkùnrin náà kí n lè mú un kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo àwọn tí wọ́n jọ ń bá Mólékì ṣèṣekúṣe.

6 “‘Ní ti ẹni tó bá tọ àwọn abẹ́mìílò+ lọ àti àwọn woṣẹ́woṣẹ́+ kó lè bá wọn ṣe àgbèrè ẹ̀sìn, ó dájú pé màá bínú sí onítọ̀hún,* màá sì pa á, kí n lè mú un kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀.+

7 “‘Kí ẹ ya ara yín sí mímọ́, kí ẹ sì di mímọ́,+ torí èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín. 8 Kí ẹ máa pa àwọn àṣẹ mi mọ́, kí ẹ sì máa tẹ̀ lé wọn.+ Èmi ni Jèhófà, ẹni tó ń sọ yín di mímọ́.+

9 “‘Tí ẹnì kan bá wà tó ń ṣépè* fún bàbá tàbí ìyá rẹ̀, ẹ gbọ́dọ̀ pa á.+ Ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wà lórí òun fúnra rẹ̀, torí ó ti ṣépè fún bàbá tàbí ìyá rẹ̀.

10 “‘Tí ọkùnrin kan bá bá ìyàwó ọkùnrin míì ṣe àgbèrè: Ẹ gbọ́dọ̀ pa ẹni tó bá ìyàwó ẹnì kejì rẹ̀ ṣe àgbèrè, ọkùnrin alágbèrè àti obìnrin alágbèrè náà.+ 11 Ọkùnrin tó bá bá ìyàwó bàbá rẹ̀ sùn ti dójú ti* bàbá rẹ̀.+ Ẹ gbọ́dọ̀ pa àwọn méjèèjì. Ẹ̀jẹ̀ wọn wà lórí wọn. 12 Tí ọkùnrin kan bá bá ìyàwó ọmọ rẹ̀ sùn, ẹ gbọ́dọ̀ pa àwọn méjèèjì. Ohun tí kò tọ́ ni wọ́n ṣe. Ẹ̀jẹ̀ wọn wà lọ́rùn wọn.+

13 “‘Tí ọkùnrin kan bá bá ọkùnrin sùn bí ìgbà tó ń bá obìnrin sùn, ohun ìríra ni àwọn méjèèjì ṣe.+ Ẹ gbọ́dọ̀ pa wọ́n. Ẹ̀jẹ̀ wọn wà lórí wọn.

14 “‘Tí ọkùnrin kan bá bá ìyà àti ọmọ lò pọ̀, ìwà àìnítìjú* ló hù.+ Ṣe ni kí ẹ fi iná sun+ òun pẹ̀lú wọn, kí ìwà àìnítìjú má bàa gbilẹ̀ láàárín yín.

15 “‘Tí ọkùnrin kan bá bá ẹranko lò pọ̀, ẹ gbọ́dọ̀ pa á, kí ẹ sì pa ẹranko náà.+ 16 Tí obìnrin kan bá sì sún mọ́ ẹranko èyíkéyìí láti bá a lò pọ̀,+ ṣe ni kí ẹ pa obìnrin náà àti ẹranko náà. Ẹ gbọ́dọ̀ pa wọ́n. Ẹ̀jẹ̀ wọn wà lọ́rùn wọn.

17 “‘Tí ọkùnrin kan bá bá arábìnrin rẹ̀ tó jẹ́ ọmọ bàbá rẹ̀ tàbí ọmọ ìyá rẹ̀ lò pọ̀, tó rí ìhòòhò obìnrin náà, tí obìnrin náà sì rí ìhòòhò rẹ̀, ohun ìtìjú ni.+ Kí ẹ pa wọ́n níṣojú àwọn ọmọ àwọn èèyàn wọn. Ó ti dójú ti* arábìnrin rẹ̀. Kó jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

18 “‘Tí ọkùnrin kan bá sùn ti obìnrin tó ń ṣe nǹkan oṣù, tó sì bá a lò pọ̀, àwọn méjèèjì ti fi ìsun ẹ̀jẹ̀ obìnrin náà hàn síta.+ Ṣe ni kí ẹ pa àwọn méjèèjì, kí ẹ lè mú wọn kúrò láàárín àwọn èèyàn wọn.

19 “‘O ò gbọ́dọ̀ bá arábìnrin ìyá rẹ tàbí arábìnrin bàbá rẹ lò pọ̀, torí ìyẹn máa dójú ti mọ̀lẹ́bí rẹ tó sún mọ́ ọ.+ Kí wọ́n jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. 20 Ọkùnrin tó bá bá ìyàwó arákùnrin òbí rẹ̀ lò pọ̀ ti dójú ti* arákùnrin òbí rẹ̀.+ Kí wọ́n jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Kí wọ́n kú láìbímọ. 21 Tí ọkùnrin kan bá gba ìyàwó arákùnrin rẹ̀, ohun ìríra ni.+ Ó ti dójú ti* arákùnrin rẹ̀. Kí wọ́n di aláìlọ́mọ.

22 “‘Kí ẹ máa pa gbogbo àṣẹ mi àti gbogbo ìdájọ́+ mi mọ́, kí ẹ sì máa tẹ̀ lé wọn,+ kí ilẹ̀ tí màá mú yín lọ láti máa gbé má bàa pọ̀ yín jáde.+ 23 Ẹ ò gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé àṣẹ àwọn orílẹ̀-èdè tí màá lé jáde kúrò níwájú yín;+ torí wọ́n ti ṣe gbogbo nǹkan yìí, mo sì kórìíra wọn.+ 24 Ìdí nìyẹn tí mo fi sọ fún yín pé: “Ẹ ó gba ilẹ̀ wọn, màá sì fún yín kó lè di tiyín, ilẹ̀ tí wàrà àti oyin ti ń ṣàn.+ Èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín, ẹni tó yà yín sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn èèyàn yòókù.”+ 25 Kí ẹ fi ìyàtọ̀ sáàárín ẹranko tó mọ́ àti èyí tó jẹ́ aláìmọ́ àti sáàárín ẹyẹ tó jẹ́ aláìmọ́ àti èyí tó mọ́;+ ẹ ò gbọ́dọ̀ sọ ara yín* di ohun ìríra nípasẹ̀ ẹranko tàbí ẹyẹ tàbí ohunkóhun tó ń rákò lórí ilẹ̀ tí mo yà sọ́tọ̀ pé ó jẹ́ aláìmọ́ fún yín.+ 26 Kí ẹ jẹ́ mímọ́ fún mi, torí èmi Jèhófà jẹ́ mímọ́,+ mo sì ń yà yín sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn èèyàn yòókù kí ẹ lè di tèmi.+

27 “‘Ẹ gbọ́dọ̀ pa ọkùnrin tàbí obìnrin èyíkéyìí tó jẹ́ abẹ́mìílò tàbí woṣẹ́woṣẹ́.*+ Kí àwọn èèyàn sọ wọ́n lókùúta pa. Ẹ̀jẹ̀ wọn wà lórí wọn.’”

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́