-
Diutarónómì 14:4-20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
4 Àwọn ẹran tí ẹ lè jẹ nìyí:+ akọ màlúù, àgùntàn, ewúrẹ́, 5 àgbọ̀nrín, egbin, èsúwó, ẹ̀kìrì,* ẹtu, àgùntàn igbó àti àgùntàn orí àpáta. 6 Ẹ lè jẹ ẹran èyíkéyìí tí pátákò rẹ̀ là sí méjì, tó sì ń jẹ àpọ̀jẹ. 7 Àmọ́, ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ àwọn ẹran yìí tí wọ́n ń jẹ àpọ̀jẹ tàbí tí pátákò wọn là nìkan: ràkúnmí, ehoro àti gara orí àpáta, torí pé wọ́n ń jẹ àpọ̀jẹ ṣùgbọ́n pátákò wọn ò là. Aláìmọ́ ni wọ́n jẹ́ fún yín.+ 8 Bákan náà ni ẹlẹ́dẹ̀, torí pátákò rẹ̀ là, àmọ́ kì í jẹ àpọ̀jẹ. Aláìmọ́ ló jẹ́ fún yín. Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹran wọn, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ fọwọ́ kan òkú wọn.
9 “Nínú gbogbo ohun tó ń gbé inú omi, èyí tí ẹ lè jẹ nìyí: Ẹ lè jẹ ohunkóhun tó bá ní lẹ́bẹ́ àti ìpẹ́.+ 10 Àmọ́ ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ohunkóhun tí kò bá ní lẹ́bẹ́ àti ìpẹ́. Aláìmọ́ ló jẹ́ fún yín.
11 “Ẹ lè jẹ ẹyẹ èyíkéyìí tó bá mọ́. 12 Àmọ́ ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ àwọn ẹyẹ yìí: idì, idì ajẹja, igún dúdú,+ 13 àwòdì pupa, àwòdì dúdú, onírúurú ẹyẹ aṣọdẹ, 14 gbogbo onírúurú ẹyẹ ìwò, 15 ògòǹgò, òwìwí, ẹyẹ àkẹ̀, onírúurú àṣáǹwéwé, 16 òwìwí kékeré, òwìwí elétí gígùn, ògbùgbú, 17 ẹyẹ òfú, igún, ẹyẹ àgò, 18 ẹyẹ àkọ̀, onírúurú ẹyẹ wádòwádò, àgbìgbò àti àdán. 19 Gbogbo ẹ̀dá abìyẹ́ tó ń gbá yìn-ìn* pẹ̀lú jẹ́ aláìmọ́ fún yín. Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ wọ́n. 20 Ẹ lè jẹ ẹ̀dá èyíkéyìí tó ń fò, tó sì mọ́.
-